“Kò Jìnnà sí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Wa”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Kò Jìnnà sí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Wa”
TÁ A bá wo bí ayé ṣe lọ salalu yìí, á dà bíi pé èèyàn ò já mọ́ nǹkan kan. Ó ṣeé ṣe kó o ti ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ èèyàn lásánlàsàn tiẹ̀ lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ìyẹn tí Ọlọ́run Olódùmarè tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà bá fẹ́ ká sún mọ́ òun. Ǹjẹ́ ó sì fẹ́ bẹ́ẹ̀? A lè rí ìdáhùn tó máa tù wá lára nínú ọ̀rọ̀ alárinrin tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bá àwọn ọ̀mọ̀wé ìlú Áténì sọ, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Ìṣe 17:24-27. Kíyè sí ohun mẹ́rin tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jèhófà.
Àkọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run “dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.” (Ẹsẹ 24) Bí ayé ṣe lẹ́wà tó àti oríṣiríṣi nǹkan mèremère inú rẹ̀ tó ń mú kí ìgbésí ayé dùn mọ́ni jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ agbatẹnirò àti onífẹ̀ẹ́. (Róòmù 1:20) Kò ní bọ́gbọ́n mu tá a bá lọ ń ronú pé irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ á mọ̀ọ́mọ̀ jìnnà sáwọn ẹ̀dá tó nífẹ̀ẹ́.
Ìkejì, Jèhófà “fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.” (Ẹsẹ 25) Jèhófà ni Ẹni tí ń gbé ìwàláàyè wa ró. (Sáàmù 36:9) Gbogbo nǹkan tó ṣe pàtàkì tó lè gbé ìwàláàyè ró bí afẹ́fẹ́, omi àti oúnjẹ pátápátá jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá wa. (Jákọ́bù 1:17) Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu ká gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wa ọlọ́làwọ́ yóò ya ara rẹ̀ láṣo, táá sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àǹfààní láti mọ irú ẹni tó jẹ́ àti láti sún mọ́ ọn dù wá?
Ìkẹ́ta, “láti ara ọkùnrin kan ni” Ọlọ́run “ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn.” (Ẹsẹ 26) Jèhófà kì í ṣe ojúsàájú rárá àti rárá, kì í sì í gbè sẹ́yìn ẹnì kan. (Ìṣe 10:34) Kí ló fẹ́ sún un débi táá fi máa ṣojúsàájú? Jèhófà ló dá Ádámù, Ádámù yìí sì ni “ọkùnrin kan” tí gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà jáde wá láti ara rẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (1 Tímótì 2:4) Nítorí náà, àǹfààní láti sún mọ́ ọn ṣí sílẹ̀ fún wa láìka àwọ̀ ara wa, orílẹ̀-èdè wa tàbí ẹ̀yà wa sí.
Ní paríparì, Pọ́ọ̀lù sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an, ó sọ pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” (Ẹsẹ 27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà wà níbi gíga jù lọ, gbogbo ìgbà ló wà nítòsí àwọn tó ń wá ọ̀nà láti sún mọ́ ọn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé ó “ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,” kò jìnnà sí wọn rárá.—Sáàmù 145:18.
Ó ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù sọ pé kìkì àwọn tó bá fẹ́ láti “máa wá Ọlọ́run,” tí wọ́n sì “táràrà fún un” nìkan ni Ọlọ́run yóò jẹ́ kó sún mọ́ òun. (Ẹsẹ 27) Ìwé kan táwọn atúmọ̀ Bíbélì máa ń ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé “ohun tí gbólóhùn méjèèjì yìí yéni sí ni pé ó jẹ́ ohun kan tó ṣeé ṣe kọ́wọ́ tẹ̀ . . . tàbí ohun kan tó wu èèyàn, tọ́wọ́ sì lè tẹ̀.” Àpèjúwe kan rèé: Tó o bá wà nínú yàrá kan tó ṣókùnkùn, àmọ́ tíbẹ̀ ò ṣàjèjì sí ọ, ó ṣeé ṣe kó o máa táràrà láti wá ibi tí wọ́n ti ń tanná tàbí ibi tí wọ́n ti ń ṣí ilẹ̀kùn, ṣùgbọ́n o mọ̀ pé wàá rí ohun tó ò ń wá yìí. Táwa náà bá ń fi tọkàntọkàn wá Ọlọ́run, tá a sì ń táràrà fún un, ó dá wa lójú pé ìsapá wa ò ní já sásán. Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé a óò “rí i ní ti gidi.”—Ẹsẹ 27.
Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o sún mọ́ Ọlọ́run? Tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìgbàgbọ́ “wá Ọlọ́run,” tó o sì ń “táràrà fún un,” wàá rí i. Jèhófà kò ṣòro láti rí, torí pé “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.”