Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ọmọbìnrin Kan Ran Ọkọ Ọ̀gá Rẹ̀ Lọ́wọ́

ǸJẸ́ o mọ ẹnì kan tó ń ṣàìsàn gan-an?— Ṣé ó wù ẹ́ pé kó o ṣe nǹkan kan láti ràn án lọ́wọ́?— Tó bá jẹ́ pé orílẹ̀-èdè míì ló ti wá tàbí tí ẹ̀sìn rẹ̀ yàtọ̀ sí tìẹ ńkọ́? Ṣé wàá ṣì fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́ kára ẹ̀ lè yá?— Ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn ṣe nìyẹn. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn.

Ìjà sábà máa ń wáyé láàárín orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́, ìyẹn ibi tí ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn ti wá àti orílẹ̀-èdè Síríà tó wà nítòsí rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 22:1) Lọ́jọ́ kan, àwọn ará Síríà wá sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì wọ́n sì mú ọ̀dọ́mọbìnrin náà lẹ́rú. Wọ́n mú un lọ sí ilẹ̀ Síríà níbi tó ti di ìránṣẹ́ fún ìyàwó Náámánì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà. Náámánì ní àrùn burúkú kan tí wọ́n ń pè ní ẹ̀tẹ̀, èyí tó máa ń ba ẹran ara èèyàn jẹ́.

Ìránṣẹ́bìnrin yìí sọ fún ìyàwó Náámánì bí ọkọ rẹ̀ ṣe lè rí ìwòsàn. Ó sọ pé: ‘Bí Olúwa mi bá lè lọ sí Samáríà, wòlíì Jèhófà tó ń jẹ́ Èlíṣà lè wo ẹ̀tẹ̀ wọn sàn.’ Ṣó o rí i, ọ̀nà tí ìránṣẹ́bìnrin yìí gbà sọ̀rọ̀ nípa Èlíṣà fún Náámánì mú kó gbà gbọ́ pé ó ṣeé ṣe kí wòlíì náà wo òun sàn lóòótọ́. Nítorí náà, Bẹni-Hádádì ọba Síríà fọwọ́ sí i pé kí Náámánì àtàwọn ìránṣẹ́ kan rìnrìn-àjò tí ó tó nǹkan bí àádọ́jọ kìlómítà lọ sí Samáríà láti lọ rí Èlíṣà.

Ọ̀dọ̀ Jèhórámù ọba Ísírẹ́lì ni wọ́n kọ́kọ́ lọ. Wọ́n fi lẹ́tà tí Bẹni-Hádádì Ọba kọ pé kí wọ́n ran Náámánì lọ́wọ́ han Jèhórámù. Àmọ́ Jèhórámù kò nígbàgbọ́ nínú Jèhófà àti wòlíì Èlíṣà. Èrò Jèhórámù ni pé ńṣe ni Bẹni-Hádádì kàn ń wá ọ̀nà tó fẹ́ fi bá òun jà. Nígbà tí Èlíṣà gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ó sọ fún Jèhórámù Ọba pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó wá sọ́dọ̀ mi.” Èlíṣà fẹ́ wo àrùn burúkú tó ń ṣe Náámánì yìí sàn, kó lè tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé alágbára ni Ọlọ́run.—2 Àwọn Ọba 5:1-8.

Nígbà tí Náámánì dé ilé Èlíṣà tòun ti àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, Èlíṣà rán ìránṣẹ́ kan sí Náámánì pé: ‘Lọ wẹ̀ ní ìgbà méje nínú Odò Jọ́dánì, ara rẹ yóò sì dá.’ Ọ̀rọ̀ yìí bí Náámánì nínú gan-an ni. Ohun tó rò ni pé Èlíṣà á jáde wá, á sì ju ọwọ́ rẹ̀ síwá-sẹ́yìn lórí àrùn ẹ̀tẹ̀ náà, àrùn náà á sì dàwátì. Àmọ́, ibi tó fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀, ìránṣẹ́ lásán-làsàn ló jáde wá! Nítorí èyí, ìbínú ni Náámánì fi kúrò níwájú ìránṣẹ́ náà, ó sì lọ.—2 Àwọn Ọba 5:9-12.

Ká ní ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Náámánì ni ẹ́, kí ni wàá ṣe?— Àwọn ìránṣẹ́ Náámánì bi í pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ohun tó le jù báyìí lọ ni Èlíṣà ní kẹ́ ẹ ṣe, ṣé ẹ ò ní ṣe é ni? Kí ló wá dé tẹ́ ò lè ṣe ohun kékeré yìí, kẹ́ ẹ kàn wẹ̀ kẹ́ ẹ sì mọ́?’ Náámánì ṣe ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní kó ṣe. “Ó sọ̀ kalẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ri ara rẹ̀ bọ Jọ́dánì ní ìgbà méje. . . , lẹ́yìn èyí tí ẹran ara rẹ̀ padà wá gẹ́gẹ́ bí ẹran ara ọmọdékùnrin kékeré.”

Náámánì padà wá sọ́dọ̀ Èlíṣà, ó sì sọ fún un pé: “Dájúdájú, mo wá mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé, bí kò ṣe ní Ísírẹ́lì.” Ó ṣèlérí fún Èlíṣà pé òun kò ní “rú ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ sí ọlọ́run mìíràn mọ́, bí kò ṣe sí Jèhófà.”—2 Àwọn Ọba 5:13-17.

Ṣé ó wù ẹ́ kó o ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ohun tó lè ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọbìnrin yẹn ti ṣe?— Nígbà tí Jésù wà láyé, ọkùnrin kan tó lárùn ẹ̀tẹ̀ gbà á gbọ́, ó sì sọ pé: ‘Bí ìwọ bá fẹ́ ràn mí lọ́wọ́, ìwọ lè ṣe bẹ́ẹ̀.’ Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Jésù wí fún un?— Ó sọ pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Jésù sì wo ọkùnrin yẹn sàn bí Jèhófà ṣe wo Náámánì sàn.—Mátíù 8:2, 3.

Ṣé o mọ̀ pé Jèhófà máa dá ayé tuntun kan nínú èyí tí ara gbogbo èèyàn á ti jí pépé tí wọ́n á sì máa wà láàyè títí láé?— (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ó dájú pé wàá fẹ́ sọ fáwọn èèyàn nípa àwọn ohun àgbàyanu yìí!

Ìbéèrè:

○ Báwo ni ọ̀dọ́mọbìnrin kan táwọn ọmọ ogun Síríà mú lẹ́rú ṣe ran Náámánì lọ́wọ́?

○ Kí nìdí tí Náámánì ò ṣe kọ́kọ́ ṣègbọràn sóhun tí Èlíṣà sọ, kí sì nìdí tó fi wá yí èrò rẹ̀ padà?

○ Kí ló yẹ kó o ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí?

○ Kí ni Jésù fẹ́ ṣe, kí sì nìdí tí nǹkan á fi dára gan-an nínú ayé tuntun Ọlọ́run?