Bá A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Tó Bá Jẹ Yọ
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bá A Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Tó Bá Jẹ Yọ
Ọkọ sọ pé: “Ibo làwọn ọmọ lọ?”
Ìyàwó sọ pé: “Wọ́n lọ raṣọ lọ́jà.”
Ọkọ sọ pé: [Ó jágbe mọ́ ọn tìbínú-tìbínú] “Aṣọ kí ni wọ́n tún lọ rà? Ṣebí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ra àwọn aṣọ kan lóṣù tó kọjá yìí ni!”
Ìyàwó sọ pé: [Bí ọkọ ṣe ń dá a lẹ́bi yẹn dùn ún, ó wá fẹ́ fi hàn pé òun ò jẹbi] “Ṣebí rírà làwọn aṣọ tí wọ́n kó wá sọ́jà wà fún. Ká tiẹ̀ pàyẹn tì, wọ́n tọrọ àyè lọ́wọ́ mi, mo sì ní kí wọ́n lọ.”
Ọkọ sọ pé: [Orí ẹ̀ kanrin, ló bá pariwo mọ́ ọn] “O ṣe lè sọ pé kí wọ́n lọ láìkọ́kọ́ sọ fún mi? Báwo lo ṣe ń ṣe nǹkan láìronújinlẹ̀ báyẹn? Bẹ́ẹ̀ lo mọ̀ pé mi ò fẹ́ káwọn ọmọ wa máa náwó láìjẹ́ pé mo fọwọ́ sí i!”
ÌṢÒRO wo lo rò pé àwọn tọkọtaya tí wọ́n sọ àwọn gbólóhùn yìí ní tó yẹ kí wọ́n bójú tó? Ó ṣe kedere pé ọkọ yẹn kì í lè ṣàkóso ara rẹ̀ tó bá ń bínú. Yàtọ̀ síyẹn, ó dà bíi pé ohùn wọn ò ṣọ̀kan lórí ibi tó yẹ kí wọ́n fàyè gba àwọn ọmọ wọn dé. Ó sì tún dà bíi pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó ṣe gúnmọ́ ò sì láàárín wọn.
Gbogbo tọkọtaya ni aláìpé. Torí náà, gbogbo tọkọtaya ni yóò máa rí ìṣòro kan tàbí òmíràn. Ó ṣe pàtàkì pé kí ọkọ àti aya mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa yanjú ọ̀ràn tó bá sú yọ, ì báà jẹ́ kékeré tàbí ńlá. Kí nìdí ẹ̀?
Téèyàn bá fi ìṣòro sílẹ̀ láìyanjú, tó bá yá ó lè bẹgi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀. Sólómọ́nì ọlọgbọ́n ọba sọ pé: “Asọ̀ sì wà tí ó dà bí ọ̀pá ìdábùú ilé gogoro ibùgbé.” (Òwe 18:19) Báwo lẹ ṣe lè jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó mọ́yán lórí wà láàárín yín láwọn ìgbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ yanjú ìṣòro?
Tí tọkọtaya bá jẹ́ ara kan lóòótọ́, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ló dà bí ẹ̀jẹ̀ tí ara náà nílò. Ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ló sì dà bí ọkàn àti ẹ̀dọ̀ tí ẹ̀jẹ̀ máa ń ṣàn gba inú wọn. Torí náà, ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ṣe pàtàkì láti lè jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó mọ́yán lórí wà nínú ìdílé. (Éfésù 5:33) Tó bá dọ̀ràn yíyanjú ìṣòro, ìfẹ́ ló máa mú kí tọkọtaya máa gbójú fo àwọn àṣìṣe tó ti kọjá sẹ́yìn, kí wọ́n sì mójú tó kìkì ọ̀ràn tó wà nílẹ̀, kódà ká tiẹ̀ ní ohun tó ti kọjá sẹ́yìn dùn wọ́n gidigidi. (1 Kọ́ríńtì 13:4, 5; 1 Pétérù 4:8) Táwọn tọkọtaya bá ń fi ọ̀wọ̀ wọ ara wọn, wọ́n á lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ tinútinú, wọ́n á sì máa gbìyànjú láti mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kejì wọn.
Ìgbésẹ̀ Mẹ́rin Tẹ́ Ẹ Lè Gbé Láti Yanjú Ìṣòro
Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́rin tá a tò sílẹ̀ yìí àti báwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn yín lọ́wọ́ láti máa yanjú ìṣòro pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀.
1. Ẹ fohùn ṣọkan lórí àkókò tẹ́ ẹ ó máa jíròrò àwọn ọ̀ràn tó bá wáyé. “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbà Oníwàásù 3:1, 7) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àwọn tọkọtaya tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lẹ́ẹ̀kan yẹn ṣe fi hàn, tí àríyànjiyàn bá bẹ́ sílẹ̀, ó lè ká èèyàn lára ju bó ṣe yẹ lọ. Nígbà tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ẹ lo ìkóra-ẹni-níjàánu kẹ́ ẹ bàa lè fòpin sí ìjíròrò yẹn fúngbà díẹ̀ kó tó di pé inú bí yín jù, kẹ́ ẹ ka àkókò yẹn sí “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́.” Ohun tẹ́ ẹ lè ṣe tí wàhálà kankan ò fi ní da àárín yín rú ni pé kẹ́ ẹ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí pé: “Ẹni ti o daju fun omi dabi olupilẹsẹ ìja; nitorina fi ìja silẹ ki o to di nla.”—Òwe 17:14, Bibeli Mimọ.
sísọ̀rọ̀.” (Àmọ́ ṣá, “ìgbà sísọ̀rọ̀” náà wà o. Ṣe ni ìṣòro dá bí igbó tó ń hù, téèyàn ò bá tètè ro ó dà nù, ṣe lá máa kún sí i. Torí náà, ẹ má ṣe rò pé ẹ kàn lè fi ìṣòro náà sílẹ̀ láìbójútó, pẹ̀lú èrò pé ọ̀ràn á yanjú ara rẹ̀. Tó o bá dábàá pé kẹ́ ẹ fòpin sí ìjíròrò kan, fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ nípa sísọ àkókò tí kò ní pẹ́ púpọ̀ tẹ́ ẹ tún máa padà sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro yẹn. Tẹ́ ẹ bá ṣe irú ìlérí yẹn, á ran ẹ̀yin méjèèjì lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì yìí, pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú.” (Éfésù 4:26) Àmọ́ ṣá, o ní láti mú ìlérí tó o ṣe ṣẹ.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Ẹ mú àkókò kan láàárín ọ̀sẹ̀ tí ẹ ó máa jíròrò àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ nínú ìdílé yín. Tó o bá rí i pé àkókò kan wà tínú máa ń tètè bí ọ tẹ́ ẹ bá dá ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀, ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan láti má ṣe máa jíròrò ìṣòro yín lákòókò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkòkò tẹ́ ẹ bá rí i pé ara ẹ̀yin méjèèjì máa ń balẹ̀ ni kẹ́ ẹ yàn. Bí àpẹẹrẹ ó lè má rọrùn fún ọ láti máa jíròrò ìṣòro tó wà nílẹ̀ lákòókò tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ tibi iṣẹ́ dé tàbí lákòókò tébi bá ń pa ọ́.
2. Fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ òótọ́ tó wà lọ́kàn rẹ. “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) Tó o bá ti ṣègbéyàwó, aládùúgbò rẹ tó sún mọ́ ọ jù lọ ni ọkọ tàbí ìyáwo rẹ. Torí náà máa sọ òótọ́ kó o sì máa sọ bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára rẹ gan-an nígbà tó o bá ń bá ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Margareta, a tó ti wà nílé ọkọ láti ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n sọ pé: “Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé ọkọ, mo retí pé kí ọkọ mi ṣáà máa lóye ohun tó wà lọ́kàn mi láwọn ìgbà tí ìṣòro bá yọjú. Àmọ́ mo wá rí i pé tí mo bá retí ìyẹn, ṣe ni mò ń tan ara mi jẹ. Báyìí mo ti wá ń gbìyànjú láti máa sọ ohun tó wà lọ́kàn mi àtohun tó ń ṣe mí síta kó lè yé ọkọ mi kedere.”
Rántí pé ìdí tó o fi fẹ́ jíròrò ìṣòro tó wà nílẹ̀ kì í ṣe torí kó o bàa lè borí nínú ìjàkadì tàbí kó o bàa lè ṣẹ́gun ọ̀tá rẹ, bí ko ṣe pé ó fẹ́ kí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. Láti wá lè jẹ́ kóhun tó wà lọ́kàn rẹ yé e dáadáa, sọ ohun tó o rò pé ó fa ìṣòro, àti ìgbà tó o rò pé ó ṣẹlẹ̀, lẹ́yìn náà kó o wá sọ ìdí tó fi dùn ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ká ní ohun tó ń dùn ọ́ ni pé ọkọ rẹ máa ń da ilé rú bó o bá ṣe ń tún un ṣe, o lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ pé, ‘Bẹ́ ẹ ṣe máa ń ju aṣọ sílẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá tibi iṣẹ́ dé yẹn [ohun tó fa ìṣòro àti ìgbà tó ṣẹlẹ̀], ṣe ló máa ń jẹ́ kí n gbà pé ẹ ò mọrírì wàhálà tí mò ń ṣe láti tún ilé ṣe [ìyẹn á jẹ́ kó rí ìdí tó fi dùn ọ́].’ Lẹ́yìn ìyẹn kó o wá fi ọgbọ́n sọ ohun tó o rò pé ó máa yanjú ìṣòro náà.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ọ láti ṣàlàyé ara rẹ kedere nígbà tó o bá ń bá ọkọ tàbí ìyàwó rẹ sọ̀rọ̀, ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o rò pé ó jẹ́ ìṣòro àti ọ̀nà tó o rò pé o lè gbà yanjú rẹ̀.
3. Fetí sí ọkọ tàbí aya rẹ kó o sì fi hàn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé o lóye ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé àwọn Kristẹni ní láti “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ohun tó ń dun ẹni tó ti ṣègbéyàwó bíi kó rí i pé ọkọ tàbí aya òun kò mọ bí ìṣòro kan ṣe lágbára tó lọ́kàn òun. Torí náà pinnu pé o ò ní jẹ́ kí ọkọ tàbí aya tìẹ rí nǹkan bẹ́ẹ̀ sọ nípa rẹ!—Mátíù 7:12.
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Wolfgang tó ti gbéyàwó sílé láti ọdún márùndínlógójì sọ pé: “Témi àtìyàwó mí bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro kan tó wà ńlẹ̀, ọkàn mi máa ń dà rú, pàápàá tí mo bá rí i pé ìyàwó mi ò lóye èrò tèmi.” Dianna tó ti wọlé ọkọ láti nǹkan bí ogún ọdún sọ pé, “Mo sábà máa ń sọ fún ọkọ mi pé kì í fetí sí mi nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro tó wà nílẹ̀.” Báwo lo ṣe lè yanjú ìṣòro yìí?
Má kàn ṣàdédé rò pé o ti mọ ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí aya rẹ tàbí ohun tó ń dùn ún. Ọ̀rọ̀ Òwe 13:10) Tó o bá fẹ́ fi hàn pé o pọ́n ọkọ tàbí aya rẹ lé, máa jẹ́ kó sọ èrò rẹ̀ láìdá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu. Láti lè rí i dájú pé ohun tó sọ yé ọ yékéyéké, tún un sọ lọ́nà míì, kì í ṣe pé kó o sọ ọ́ bí ẹní ń ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí pẹ̀lú ìbínú o. Tó ò bá lóye ohun tó ní lọ́kàn dáadáa, jẹ́ kó tún un sọ. Kò yẹ kó jẹ́ pé ìwọ nìkan ni wàá máa sọ̀rọ̀. Tí ẹnì kan nínú yín bá ti ń sọ̀rọ̀ kẹ́nì kejì máa fetí sílẹ̀ títí tẹ́yin méjèèjì fi máa gbà pé ẹ ti mọ ohun tó wà lọ́kàn ara yín àtohun tó ń dùn yín.
Ọlọ́run sọ pé: “Nípasẹ̀ ìkùgbù, kìkì ìjàkadì ni ẹnì kan ń dá sílẹ̀, ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Lóòótọ́, ó lè gba ìrẹ̀lẹ̀ àti sùúrù kó o tó lè tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ, kó o sì tó lè gbà pé òótọ́ ló sọ. Àmọ́ tó o bá ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ọkọ tàbí aya rẹ lọ́nà yẹn, ó máa ṣeé ṣe fún un láti túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ìwọ náà.—Mátíù 7:2; Róòmù 12:10.
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Nígbà tó o bá ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ tí ọkọ tàbí aya rẹ sọ ṣe yé ọ, má ṣe sín in jẹ nípa sísọ ọ̀rọ̀ tó sọ. Ṣe ni kó o gbìyànjú láti fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàpéjúwe ohun tó o rò pé ó ń sọ àti ohun tó o rí pé ó ń dùn ún.—1 Pétérù 3:8.
4. Ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó máa yanjú ìṣòro náà. “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.” (Oníwàásù 4:9, 10) Ó lójú ìṣòro tó lè yanjú nínú ìdílé tí kì í bá ṣe pé tọkọtaya pa ìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́.
Lóòótọ́, ọkọ ni Jèhófà fi ṣe orí nínú ìdílé. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Éfésù 5:23) Àmọ́ pé ọkọ jẹ́ orí kò sọ ọ́ di apàṣẹwàá. Ọkọ tó bá gbọ́n kò ní máa ṣèpinnu láìgba ti ìyàwó rẹ̀ rò. David tó ti gbéyàwó sílé láti ogún ọdún sọ pé, “Mo máa ń gbìyànjú láti wá ibi témi àti ìyàwó mi ti lè fohùn ṣọ̀kan, ìpinnu tí èmi àti ìyàwó mi á lè fara mọ́ ni mo máa ń fẹ́ ṣe.” Obìnrin kan tó ń jẹ́ Tanya, tó ti wọlé ọkọ láti ọdún méje sẹ́yìn sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ta ló tọ̀nà tàbí ta ni kò tọ̀nà là ń sọ yìí. Ohun tó máa ń ṣẹ̀lẹ̀ nígbà míì ni pé èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà lórí bó ṣe yẹ ká yanjú ìṣòro kan. Mo ti wá rí i pé ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ni pé ká má máa rin kinkin, kàkà bẹ́ẹ̀ ó yẹ ká máa fòye bá ara wa lò.”
OHUN TÓ O LÈ ṢE: Ẹ máa ṣe nǹkan lọ́nà tẹ́yin méjèèjì á fi rí ara yín bí ẹni tó jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Èyí á ṣeé ṣe tẹ́yin méjèèjì bá kọ gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá lè ronú kàn pé ó lè yanjú ìṣòro yín sílẹ̀. Lẹ́yin tẹ́ ẹ bá ti rí i pé gbogbo ohun tó wà lọ́kàn yín lẹ ti kọ sílẹ̀, ẹ wá padà ṣàyèwò àkọsílẹ̀ yín kẹ́ ẹ ṣe ohun tẹ́ ẹ fohùn ṣọ̀kan lé lórí pé ó lè yanjú ìṣòro yín. Tó bá tó bí àkókò kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, ẹ wò ó bóyá ẹ ti ṣiṣẹ́ lórí ohun tẹ́ ẹ fohùn ṣọ̀kan lé lórí kẹ́ ẹ sì wo bó ṣe yanjú ìṣòro yín tó.
Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Pọ̀, Ẹ Má Fàyè Gba Kóńkó Jabele
Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó, ó sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “so pọ̀” túmọ̀ sí “fi àjàgà so pọ̀.” Nígbà tí Jésù wà láyé, igi gbọọrọ kan tí wọ́n fi so ẹran méjì pọ̀ kí wọ́n bàa lè ṣiṣẹ́ ni wọ́n ń pè ní àjàgà. Táwọn méjèèjì ò bá ṣiṣẹ́ pa pọ̀, wọn ò ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, àjàgà yẹn á máa ha wọ́n lọ́rùn, ọrùn wọn á sì bó. Àmọ́ tí wọ́n bá jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n á fi àjàgà yẹn wọ́ ẹrù tó bá wúwo, wọ́n á lè fi túlẹ̀ lóko pàápàá.
Bákan náà, tí tọkọtaya bá kọ̀ tí wọn ò ṣiṣẹ́ pa pọ̀, àjàgà ìgbéyàwó wọn lè máa ha wọ́n lọ́rùn, kọ́rùn wọn sì bó. Àmọ́ bí wọ́n bá kọ́ láti máa ṣiṣẹ́ pa pọ̀, ṣàṣà ni ìṣòro tí wọn ò ní yanjú, wọ́n á sì ṣàṣeyọrí tó pọ̀ jọjọ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kalala tóun àti ìyàwó ẹ̀ jọ ń gbádùn ara wọn ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà pé, “Láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, bémi àtìyàwó mi ṣe máa ń yanjú ìṣòro wa ni pé, a máa ń bá ara wa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nígbà tọ́rọ̀ bá délẹ̀, a sì máa ń fọ̀rọ̀ ro ara wa wò, a tún máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, a sì tún máa ń fi ìlànà Bíbélì sílò.” Ṣé ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀?
BI ARA RẸ PÉ . . .
▪ Ìṣòro wo ni mo máa ń fẹ́ bá ìyàwó tàbí ọkọ mi sọ jù?
▪ Báwo ni mo ṣe lè rí i dájú pé mo mọ ohun tó wà lọ́kàn ọkọ tàbí ìyàwó mi lórí ọ̀ràn yìí?
▪ Tí mo bá takú pé bí mo ṣe fẹ́ ká ṣe nǹkan la gbọ́dọ̀ ṣe é, irú ìṣòro wo ni mo lè dá sílẹ̀?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan padà.