Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Wa Yìí Yóò Pa Run?
Ǹjẹ́ Ilẹ̀ Ayé Wa Yìí Yóò Pa Run?
ǸJẸ́ o ti fìgbà kan rí ronú nípa, ‘Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé wa yìí lọ́jọ́ iwájú?’ Nítorí àjálù tó ń bá àgbáálá ayé tó rẹwà yìí, ọ̀pọ̀ ló gbà pé kò sọ́gbọ́n ẹ̀ káyé yìí má pa run.
Lónìí, àwọn èèyàn ń ba ilé ayé jẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń ba àwọn ohun ṣíṣeyebíye tí Ọlọ́run dá jẹ́. Ara ohun tí wọ́n ń ṣe ni pé wọ́n ń sọ omi di ẹlẹ́gbin, wọ́n ń pa igbó run, wọ́n sì ń ba atẹ́gùn jẹ́. Bákan náà, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan kan pa ilẹ̀ ayé yìí àti gbogbo ohun abẹ̀mí inú rẹ̀ run, irú bí àwọn nǹkan kan tó ń já bọ́ látọ̀run, àwọn ìràwọ̀ tó ń bú gbàù tàbí kí oòrùn má ràn mọ́ nítorí pé agbára tó fi ń ràn ti tán.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé ilẹ̀ ayé yìí yóò máa bà jẹ́ lọ díẹ̀díẹ̀ títí tí kò fi ní ṣeé gbé fún èèyàn mọ́, bó tilẹ̀ jẹ pé kí ìyẹn tó ṣẹlẹ̀ ó lè gbà ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica sọ pé “ńṣe ni yóò máa bà jẹ́ lọ láìṣeé tún ṣe títí yóò fi pa rẹ́ ráúráú.”
Àmọ́, ó dùn mọ́ wa pé Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run ò ní gbà kí ohunkóhun pa ilẹ̀ ayé yìí run tàbí kó di ibi tí kò ṣeé gbé mọ́. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá tó ní ọ̀pọ̀ yanturu ‘agbára gíga,’ ó lè mú kí àgbáálá ayé yìí wà títí láé. (Aísáyà 40:26) Nítorí náà, a lè gba ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí gbọ́, ìyẹn: “[Ọlọ́run] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” “Ẹ yìn ín, oòrùn àti òṣùpá. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀ . . . Nítorí pé òun fúnra rẹ̀ ni ó pàṣẹ, a sì dá wọn. Ó sì mú kí wọ́n dúró títí láé.”—Sáàmù 104:5; 148:3-6.
Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé Yìí
Ọlọ́run ò fìgbà kankan rí fẹ́ káwọn èèyàn ba ayé yìí jẹ́ bó ṣe rí lónìí yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run dá ọkùnrin àtobìnrin àkọ́kọ́, ìyẹn Ádámù àti Éfà, ó sì fi wọ́n sínú ọgbà kan tó lẹ́wà. Lóòótọ́, ilé wọn tó jẹ́ Párádísè Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9, 15) Àbẹ́ ò rí nǹkan, iṣẹ́ aláyọ̀ tó sì tún tẹ́ni lọ́rùn ni Ọlọ́run fún àwọn òbí wa tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹni pípé!
yẹn kò ní ṣàdédé máa rẹwà lọ fúnra rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ọlọ́run sọ fún wọn pé kí wọ́n “máa ro ó” kí wọ́n sì “máa bójú tó o.” (Ṣùgbọ́n ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé yìí ju kí wọ́n wulẹ̀ máa bójú tó ọgbà yẹn lọ. Ó fẹ́ kí wọ́n sọ gbogbo ilẹ̀ ayé pátá di Párádísè. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi pàṣẹ yìí fún Ádámù àti Éfà pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé áńgẹ́lì onígbèéraga kan báyìí tá a wà mọ̀ sí Sátánì ò fẹ́ kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn yìí ṣeé ṣe. Gbogbo ọ̀nà ló fi ń wá kí Ádámù àti Éfà máa jọ́sìn òun. Sátánì gbẹnu ejò kan sọ̀rọ̀, ó sì mú kí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Ìṣípayá 12:9) Ẹ wo bí yóò ṣe dun Ẹlẹ́dàá tó pé wọ́n jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti abaraámóorejẹ! Ṣùgbọ́n ìṣọ̀tẹ̀ wọn ò yí ohun kan padà, kò yí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé yìí padà. Ọlọ́run sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.
Kí ọ̀rọ̀ bàa lè lójú ni Jèhófà ò ṣe tíì mú ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì kúrò nílẹ̀ títí di ọjọ́ wa yìí. Lákòókò wa yìí, Sátánì ti mú kí ìràn èèyàn gbìyànjú oríṣiríṣi ìjọba tí wọ́n ń dá ṣe láìfi ti Ọlọ́run pè, ṣùgbọ́n gbogbo ẹ gbògbò ẹ̀, asán ló já sí torí wọn ò fi ti Ọlọ́run ṣe. a—Jeremáyà 10:23.
Àmọ́ ṣá o, láìfi àdánù tí ìṣọ̀tẹ̀ Sátánì ti fà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn pè, Jèhófà bù kún àwọn èèyàn kan tó jẹ́ olódodo. Ó tún jẹ́ kí àkọsílẹ̀ ohun tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ tá a bá ṣègbọràn tàbí ṣàìgbọràn wà nínú Bíbélì. Kò tán síbẹ̀, Jèhófà tún ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu tí yóò ṣe wá láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi pèsè Olùgbàlà fún ìràn èèyàn nípa rírán tó rán Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ olùfẹ́ láti wá kọ́ wa ní ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa gbà gbé ìgbésí ayé wa, kó sì tún fẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. (Jòhánù 3:16) Jésù ò jogún ikú látọ̀dọ̀ Ádámù, nítorí náà Ọlọ́run lè lo ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun to kúnjú ìwọ̀n láti ra ohun tí Ádámù àti Éfà gbé sọ nù padà, ìyẹn ìyè tí kò lópin nínú Párádísè kan tó kárí gbogbo ayé. b Kí ayé lè di Párádísè, Jèhófà Ọlọ́run gbé ìjọba kan kalẹ̀ lọ́run tí yóò ṣàkóso lé gbogbo ìran èèyàn lórí, ó sì ti fi Ọmọ rẹ̀, ìyẹn Jésù Kristi tó jí dìde jẹ Ọba Ìjọba yẹn. Ìṣètò àgbàyanu yìí ni yóò mú kí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nípa ilẹ̀ ayé yìí di èyí tó nímùúṣẹ.—Mátíù 6:9, 10.
Nítorí náà, ó yẹ ká ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Ó ní: “Àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà ni yóò ni ilẹ̀ ayé. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, Wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” “‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’”—Sáàmù 37:9, 29; Ìṣípayá 21:3-5.
Ọ̀rọ̀ Bíbélì Ò Ta Kora
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè máa kọminú pé, ‘Ṣáwọn ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí ò ta ko àwọn ẹsẹ mìíràn nínú Bíbélì tó dà bíi pé wọ́n sọ̀rọ̀ nípa bí ayé ṣe máa wá sópin?’ Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ á fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ò ta kora.
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú káwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tó mọ̀ pé Sáàmù 102:25-27.
ńṣe làwọn nǹkan téèyàn lè fojú rí “yóò máa bà jẹ́ lọ láìṣeé tún ṣe títí yóò fi pa rẹ́ ráúráú” ni onísáàmù ti kọ̀wé nínú Bíbélì pé: “Ìwọ [ìyẹn Ọlọ́run] ti fi àwọn ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Àwọn tìkára wọn yóò ṣègbé, ṣùgbọ́n ìwọ tìkára rẹ yóò máa wà nìṣó; àti gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù, gbogbo wọn yóò gbó. Gẹ́gẹ́ bí aṣọ, ìwọ yóò pààrọ̀ wọn, wọn yóò sì lo ìgbà wọn parí. Ṣùgbọ́n bákan náà ni ìwọ wà, àwọn ọdún rẹ kì yóò sì parí.”—Nígbà tí onísáàmù ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, kì í ṣe pé ó ń ta ko ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, pé kí ilẹ̀ ayé yìí wà títí lọ gbére. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wulẹ̀ ń fi bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ẹni àtayébáyé wé àwọn ohun tí Ọlọ́run dá tó lè ṣègbé. Bí kì í bá ṣe agbára tí Ọlọ́run ní tó fi ń sọ nǹkan di tuntun títí lọ gbére, ìsálú ọ̀run òun ayé wa yìí, títí kan oòrùn tó jẹ́ káyé ṣeé gbé, tó sì ń pèsè ìmọ́lẹ̀ àti agbára, ì bá ti dojú rú kó sì pa rẹ́ níkẹyìn. Abájọ, tí ayé wa yìí fi gbọ́dọ̀ ní ẹnì kan tó ń bójú tó o, kò má bàa “gbó” tàbí pa run.
Àwọn ẹsẹ mìíràn náà sì wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè kọ́kọ́ dà bíi pé ó ta ko ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun ní lọ́kàn nípa ayé yìí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa ọrun àti ilẹ̀ ayé pé ‘ó ń kọjá lọ.’ (Ìṣípayá 21:1) Ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ò ta ko ìlérí tí Jésù ṣe pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ó dáa nígbà náà, kí ló túmọ̀ sí nígbà tí Bíbélì sọ pé ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ‘ń kọjá lọ’?
Lọ́pọ̀ ìgbà, Bíbélì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ilẹ̀ ayé” láti fi ṣàpẹẹrẹ àwùjọ ẹ̀dá èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí: “Gbogbo ilẹ̀ ayé ń bá a lọ láti jẹ́ èdè kan àti irú àwọn ọ̀rọ̀ kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 11:1) Kò síyè méjì pé àwọn èèyàn tó ń gbé orí ilẹ̀ ayé ni “ilẹ̀ ayé” tí a sọ níbí túmọ̀ sí. Àpẹẹrẹ mìíràn ni Orin Dafidi 96:1 nínú Bibeli Yoruba Atọ́ka, tó kà pé: “Ẹ kọrin si Oluwa, gbogbo ayé.” Ó ṣe kedere pé nínú ẹsẹ yìí àtàwọn ẹsẹ mìíràn, ọ̀rọ̀ náà “ayé” túmọ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ sí àwọn èèyàn.—Sáàmù 96:13.
Nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń fàwọn aláṣẹ ayé wé ọ̀run tàbí àwọn ohun tó wà nínú ọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì ṣàpèjúwe àwọn agbonimọ́lẹ̀ aláṣẹ Bábílónì gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ nítorí pé wọ́n gbé ara wọn ga ju àwọn tó yí wọn ká. (Aísáyà 14:12-14) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn aláṣẹ Bábílónì tí “ọ̀run” dúró fún, àtàwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún ìṣàkóso wọn tí “ilẹ̀ ayé” dúró fún, pa run lọ́dún 539 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Aísáyà 51:6) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn Júù tó ronú pìwà dà láti padà sí Jerúsálẹ́mù níbi tí “ọ̀run tuntun,” kan, ìyẹn àwọn aláṣẹ tuntun ti ń ṣàkóso lórí “ilẹ̀ ayé tuntun,” kan, ìyẹn àwùjọ èèyàn tó jẹ́ olódodo.—Aísáyà 65:17.
Nígbà náà, ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ pé ọ̀run àti ilẹ̀ ayé “ń kọjá lọ” ń tọ́ka sí òpin ìjọba èèyàn tó ti bà jẹ́ yìí, àtàwọn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run tó ń tì wọ́n lẹ́yìn. (2 Pétérù 3:7) Ìyẹn á wá mú kó ṣeé ṣe fún ìjọba tuntun tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ láti bù kún àwùjọ tuntun, ìyẹn àwọn èèyàn tó jẹ́ olódodo. Nítorí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run,] nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
Nítorí náà, ó yẹ kó o nígbàgbọ́ nínú ohun tí Ọlọ́run sọ pé ilé wa yìí, ìyẹn ilẹ̀ ayé yìí yóò wà títí lọ gbére. Jù bẹ́ẹ̀ lọ̀, Bíbélì sọ ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe kí ìwọ náà lè wà lára àwọn tí yóò gbádùn àkókò adùnyùngbà náà nígbà tí a bá ti sọ gbogbo ayé yìí di Párádísè. Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) A rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé yìí àti ìran èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe ń ṣàyẹ̀wò yìí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé kíkún lórí ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ aráyé, wà lójú ìwé 106 sí 114 nínu ìwé Kí Ní Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.
b Àlàyé kíkún lórí bí Jésù ṣe fi ikú rẹ̀ ṣe ìràpadà, wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? ojú ìwé 47 sí 56.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Bíbélì sọ pé ilé wa yìí, ìyẹn ayé yìí yóò wà títí lọ gbére
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Ibi tí a ti rí àwòrán yìí: NASA/The Visible Earth (http://visibleearth.nasa.gov/); béárì ilẹ̀ oníyìnyín: © Bryan and Cherry Alexander Photography