Kí Nìdí Tá A Fi Wà Láàyè?
Kí Nìdí Tá A Fi Wà Láàyè?
KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ RÍ ÌDÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ? Kò sóhun tó ń ba ọmọ aráyé nínú jẹ́ bíi pé kó má rídìí tó fi wà láàyè, kí ìgbésí ayé má sì nítumọ̀ lójú rẹ̀. Àmọ́ ẹni tó bá mọ ìdí tó fi wà láàyè máa ń lè borí ìṣòro. Onímọ̀ nípa ètò àti àrùn iṣan ara, Viktor E. Frankl, tó la ìpakúpa ìjọba Násì já, sọ pé: “Ohun kan tó dá mi lójú ni pé, kò sóhun tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè fara da ìṣòro, bó ti wù kí ìṣòro ọ̀hún le tó, bíi pé kéèyàn mọ ìdí tó fi wà láàyè.”
Àmọ́, ìmọ̀ àwọn èèyàn kò ṣọ̀kan nípa ìdí táwa èèyàn fi wà láàyè. Èrò àwọn kan ni pé kálukú ló máa pinnu ìyẹn fúnra rẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tàwọn kan tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ ní tiwọn ni pé, ìgbésí ayé ò nítumọ̀ rárá.
Àmọ́ ká sòótọ́, ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu téèyàn lè gbà mọ ìdí táwa èèyàn fi wà láàyè ni pé ká wádìí rẹ̀ lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, ẹni tó fún wa ní ìwàláàyè. Wo ohun tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ lórí kókó yìí.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Bíbélì kọ́ni pé Jèhófà Ọlọ́run ní ìdí pàtàkì tó fi dá ọkùnrin àti obìnrin sórí ilẹ̀ ayé. Wo àṣẹ tí Jèhófà pa fáwọn òbí wa àkọ́kọ́.
Jẹ́nẹ́sísì 1:28. “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”
Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí Ádámù àti Éfà àtàwọn ọmọ wọn sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ọlọ́run ò ní in lọ́kàn pé káwọn èèyàn máa darúgbó kí wọ́n sì kú, bẹ́ẹ̀ ni kò fẹ́ káwọn èèyàn máa bayé jẹ́. Àmọ́, àṣemáṣe àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ló jẹ́ ká jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:2-6; Róòmù 5:12) Síbẹ̀, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn kò yí padà. Láìpẹ́, ayé yóò di Párádísè.—Aísáyà 55:10, 11.
Jèhófà dá agbára àti ọgbọ́n tá a óò fi lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ wa. Kò dá wa ká máa ṣe ìfẹ́ inú ara wa. Wo ohun táwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa ṣe.
Oníwàásù 12:13. “Òpin ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”
Míkà 6:8. “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”
Mátíù 22:37-39. “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”
Bí Ohun Tí Bíbélì Sọ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Ní Ojúlówó Ìbàlẹ̀ Ọkàn
Kí ẹ̀rọ kan tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, èèyàn gbọ́dọ̀ lò ó bí àwọn tó ṣe é ṣe ní ká lò ó, ká sì máa fi ṣe ohun tí wọ́n ní ká fi ṣe. Bákan náà, láti lè yẹra fún ohun tó lè pa wá lára, ohun tó lè ba àjọṣe àwa àti Ọlọ́run jẹ́, ohun tó lè ṣàkóbá fún ọpọlọ wa àtohun tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá wa, a gbọ́dọ̀ gbé ìgbésí ayé wa bí Ẹlẹ́dàá
wa ṣe fẹ́. Wo bí mímọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa ṣe lè jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn nígbà tá a bá ń ṣe àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí:Tọ́rọ̀ bá kan ohun tá a máa fi ṣáájú nígbèésí ayé, ọrọ̀ lọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn lé. Ṣùgbọ́n Bíbélì kìlọ̀ pé, ńṣe ni “àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́.”—1 Tímótì 6:9, 10.
Àmọ́ ní tàwọn tí wọ́n ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, tí wọn ò máa lépa ọrọ̀, ohun tí wọ́n ní máa ń tẹ́ wọn lọ́rùn. (1 Tímótì 6:7, 8) Wọ́n mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn ṣiṣẹ́ láti máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn. (Éfésù 4:28) Síbẹ̀, wọn ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tí Jésù sọ, pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.”—Mátíù 6:24.
Nítorí náà, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kì í fi iṣẹ́ ajé tàbí ìlépa ọrọ̀ ṣáájú nígbèésí ayé wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lohun tó jẹ wọ́n lógún. Wọ́n mọ̀ pé táwọn bá gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, kò ní ṣaláì bójú tó àwọn. Àní, Jèhófà tiẹ̀ kà á sí ọ̀ranyàn láti bójú tó wọn.—Mátíù 6:25-33.
Tọ́rọ̀ bá kan àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn, tara wọn lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi ṣáájú. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí àlàáfíà nínú ayé lóde òní, torí pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ti di “olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:2, 3) Tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wọ́n tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ tiwọn, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ ọ̀rọ̀ náà di “ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú.” (Éfésù 4:31) Irú ìwà àìní ìkóra-ẹni-níjàánu bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kéèyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ńṣe ló máa “ń ru asọ̀ sókè.”—Òwe 15:18.
Àwọn tó ń pa òfin Ọlọ́run tó sọ pé ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa mọ́ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí. Wọ́n máa ń jẹ́ onínúrere, wọ́n sì ń fi ìyọ́nú hàn, wọ́n sì máa ń dárí jini fàlàlà. (Éfésù 4:32; Kólósè 3:13) Kódà nígbà táwọn èèyàn bá ṣàìdáa sí wọn, wọ́n máa ń gbíyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ń kẹ́gàn rẹ̀, “kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà.” (1 Pétérù 2:23) Bíi ti Jésù làwọn náà ṣe mọ̀ pé, ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ máa ń múnú ẹni dùn, kódà báwọn tí wọ́n ràn lọ́wọ́ kò bá tiẹ̀ mọrírì ohun tí wọ́n ṣe. (Mátíù 20:25-28; Jòhánù 13:14, 15; Ìṣe 20:35) Jèhófà Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀mí yìí sì máa ń mú kí wọ́n ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn.—Gálátíà 5:22.
Báwo wá ni èrò rẹ nípa ọjọ́ ọ̀la ṣe lè jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ó yẹ kéèyàn mọ ìdí pàtàkì tó fi wà láàyè
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jésù jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn