Ibo Lèèyàn Ti Wá?
Ibo Lèèyàn Ti Wá?
KÍ NÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ PÉ KÁ RÍ ÌDÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ? Ohun táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n fi kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kò sí ẹnì kankan tó dá ohun alààyè, pé ńṣe ni wọ́n ṣèèṣì wà. Wọ́n ní àwọn nǹkan kan ló ṣèèṣì bú gbàù, tí gbogbo rẹ̀ sì wá dà rú tó sì ń rọ́ lura wọn títí táwọn kan fi di ohun alààyè tó wá ń yí padà díẹ̀díẹ̀ títí tó fi dèèyàn. Èèyàn tó lọ́gbọ́n lórí, tó máa ń mọ nǹkan lára tó sì tún máa ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la là ń wí yí o!
Àmọ́ rò ó wò ná: Tó bá jẹ́ pé ọ̀nà táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ léèyàn gbà wáyé lóòótọ́, tí kò sí Ẹlẹ́dàá tó dá èèyàn, a jẹ́ pé ńṣe lọmọ èèyàn kàn dá wà lágbàáyé láìní orírun. Kò ní sí ọlọ́gbọ́n-lóye kankan tí ẹ̀dá èèyàn á lè yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà, kò sì ní sẹ́ni táá máa bá wa yanjú ìṣòro wa. Òye ọmọ èèyàn lásán-làsàn la óò wá gbára lé láti lè máa dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjábá, òun náà la ó sì máa fi yanjú rògbòdìyàn ìṣèlú àtàwọn ìṣòro kálukú wa.
Ṣé gbogbo èyí fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀? Tí kò bá fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀, jẹ́ ká yíjú sí ọ̀nà míì, ìyẹn ti pé ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n-lóye wà tó dá wa. Yàtọ̀ sí pé ìyẹn tuni lára, ó tún bọ́gbọ́n mu.
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Bíbélì kọ́ni pé Ọlọ́run ló dá ọmọ èèyàn. Kì í ṣe ọ̀nà rúdurùdu, aláìnírònú àti aláìbìkítà táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n sọ lèèyàn gbà wáyé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọmọ Bàbá ọlọ́gbọ́n-lóye kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ ni wá. Wo àwọn ohun tó ṣe kedere wọ̀nyí tí Bíbélì sọ.
Jẹ́nẹ́sísì 1:27. “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”
Sáàmù 139:14. “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”
Mátíù 19:4-6. “Ẹ kò ha kà pé ẹni tí ó dá wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ṣe wọ́n ní akọ àti abo, ó sì wí pé, ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”
Ìṣe 17:24, 25. “Ọlọ́run tí ó dá ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ẹni yìí ti jẹ́, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, kì í gbé inú àwọn tẹ́ńpìlì àfọwọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì í fi ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn ṣe ìránṣẹ́ fún un bí ẹni pé ó ṣe aláìní nǹkan kan, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí àti ohun gbogbo.”
Ìṣípayá 4:11. “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.”
Bí Ohun Tí Bíbélì Sọ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Ní Ojúlówó Ìbàlẹ̀ Ọkàn
Tá a bá mọ̀ pé “olúkúlùkù ìdílé . . . lórí ilẹ̀ ayé ti gba orúkọ rẹ̀” lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn á jẹ́ ká máa fojú tó dáa wo ọmọnìkejì wa. (Éfésù 3:15) Kò sì ní jẹ́ ká máa ro ìròkurò nígbà tá a bá níṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀nà tó tẹ̀ lé e yìí la óò máa gbà ronú.
Tá a bá ní ìṣòro, a ò ní máa dààmú lórí onírúurú ìmọ̀ràn èèyàn tó ta kora wọn. Dípò ìyẹn, ìmọ̀ràn Bíbélì la óò gbára lé pátápátá. Kí nìdí? Ìdí ni pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.
Lóòótọ́, ó gba kéèyàn sapá, kó sì lè ṣèkáwọ́ ara rẹ̀ kó lè máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Nígbà míì, ìmọ̀ràn Bíbélì tiẹ̀ lè gba pé ká ṣe ohun tó yàtọ̀ sí ohun tí ì bá wu àwa fúnra wa pé ká ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21) Àmọ́, tá a bá gbà pé Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ló dá wa, ó dájú pé àá mọ̀ pé ó mọ ọ̀nà tó dáa jù lọ fún wa láti tọ̀. (Aísáyà 55:9) Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Bá a bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò, àníyàn tá a máa ní nígbà tá a bá ní ìṣòro tàbí tá a bá fẹ́ ṣèpinnu lórí ọ̀ràn tó ta kókó kò ní pọ̀.
Nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ẹ̀tanú sí wa, a ò ní máa rò pé a ò já mọ́ nǹkan kan, pé àwọn ẹ̀yà kan tàbí àwọn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀ sí tiwa sàn jù wa lọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la óò máa fojú ẹni iyì wo ara wa. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà Ọlọ́run tíì ṣe Bàbá wa “kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Ohun tá a tún mọ̀ yìí kò ní jẹ́ káwa náà máa ní ẹ̀mí ẹ̀tanú sáwọn ẹlòmíì. Nítorí a ó ti mọ̀ pé kò sídìí kankan fún wa láti máa ronú pé a sàn ju àwọn ẹ̀yà kan lọ, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘láti ara ọkùnrin kan ni Ọlọ́run ti dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn, láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.’—Ìṣe 17:26.
Dájúdájú, mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá kan wà tó dá wa àti pé ó bìkítà nípa wa jẹ́ ohun pàtàkì kan táá jẹ́ ká lè ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn. Àmọ́, àwọn nǹkan pàtàkì míì tún wà táá mú kí ọkàn wa túbọ̀ máa balẹ̀ gan-an.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Ṣé èèyàn kàn ṣèèṣì wà ni láìsí Ẹlẹ́dàá kankan tó dá a?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Mímọ̀ tá a mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá wa bìkítà nípa wa máa ń jẹ́ ká ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn