Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Yóò Gbé Ọ Ró

Jèhófà Yóò Gbé Ọ Ró

“Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi.”SM. 41:3.

ORIN: 23, 138

1, 2. Kí la lè máa ronú nípa ẹ̀ nígbà míì, àpẹẹrẹ àwọn wo ló sì lè wá sí wa lọ́kàn?

ṢÉ O ti bi ara rẹ rí pé: ‘Ṣé màá bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí báyìí?’ Tàbí kó o ti máa rò ó pé ṣé ẹbí rẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan máa bọ́ nínú àìsàn tó ń ṣe é. Kò sọ́gbọ́n kí irú èrò yìí má máa wá síni lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba méjì kan nígbà tí wòlíì Èlíjà àti Èlíṣà gbé ayé nìyẹn. Nígbà tí ọmọ Áhábù àti Jésíbẹ́lì, ìyẹn Ahasáyà ọba, jábọ́ láti ojú fèrèsé, ó ní: Ṣé ‘èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?’ Nígbà kan, Bẹni-Hádádì Ọba Síríà náà ṣàìsàn tó le gan-an, ó sọ pé: “Èmi yóò ha sàn nínú àìsàn yìí bí?”2 Ọba 1:2; 8:7, 8.

2 Òótọ́ là ń fẹ́ kára àwa àtàwọn èèyàn wa tó ń ṣàìsàn yá. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ló ń ronú pé báwo ni Ọlọ́run á ṣe ran àwọn lọ́wọ́ káwọn lè bọ́ lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe àwọn. Láyé àwọn ọba tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn tán yìí, Jèhófà máa ń wo àwọn èèyàn sàn lọ́nà ìyanu nígbà míì. Ó tiẹ̀ lo àwọn wòlíì rẹ̀ láti jí àwọn kan dìde. (1 Ọba 17:17-24; 2 Ọba 4:17-20, 32-35) Ǹjẹ́ a lè retí pé Ọlọ́run máa ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu yìí lónìí?

3-5. Kí ni Ọlọ́run àti Jésù lágbára láti ṣe, ìbéèrè wo sì lèyí mú ká béèrè?

3 Ó dájú pé Ọlọ́run lágbára láti woni sàn, ó sì tún lágbára láti fi àìsàn ṣeni. Bíbélì pàápàá jẹ́rìí sí èyí. Nígbà míì Ọlọ́run lè mú kí àìsàn kọlu ẹnì kan. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run mú kí àìsàn kọlu Fáráò ìgbà ayé Ábúráhámù àti Míríámù ẹ̀gbọ́n Mósè. (Jẹ́n. 12:17; Núm. 12:9, 10; 2 Sám. 24:15) Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọn ò bá pa àṣẹ òun mọ́, òun á fi ‘àìsàn àti ìyọnu àjàkálẹ̀’ hàn wọ́n léèmọ̀. (Diu. 28:58-61) Bákan náà, Jèhófà lè mú kí àrùn kásẹ̀ nílẹ̀ tàbí kó dáàbò bo èèyàn kúrò lọ́wọ́ àìsàn. (Ẹ́kís. 23:25; Diu. 7:15) Jèhófà tún lè woni sàn. Nígbà tí Jóòbù ṣàìsàn títí débi pé ó bẹ̀bẹ̀ pé kí òun kú, Ọlọ́run wò ó sàn.Jóòbù 2:7; 3:11-13; 42:10, 16.

4 Ó ṣe kedere pé Ọlọ́run lágbára láti wo aláìsàn kan sàn. Jésù náà lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù wo àwọn alárùn wárápá àtàwọn alárùn ẹ̀gbà sàn, ó sì tún wo àwọn afọ́jú àtàwọn arọ sàn lọ́nà ìyanu. (Ka Mátíù 4:23, 24; Jòh. 9:1-7) Ó dájú pé ó máa tù wá nínú gan-an láti mọ̀ pé ìtọ́wò lásán ni àwọn ìwòsàn tí Jésù ṣe yìí wulẹ̀ jẹ́ tá a bá fi wé èyí tó máa ṣe kárí ayé nínú ayé tuntun. Nígbà yẹn, kò ní “sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”Aísá. 33:24.

5 Àmọ́, ṣó wá yẹ ká máa retí pé kí Jèhófà tàbí Jésù wò wá sàn lọ́nà ìyanu lónìí? Tí àìsàn gbẹ̀mígbẹ̀mí bá ń ṣe ẹnì kan, kí ló yẹ kó ṣe nípa rẹ̀?

JÈHÓFÀ GBÉ WỌN RÓ NÍGBÀ TÍ WỌ́N Ń ṢÀÌSÀN

6. Kí la lè sọ nípa “ẹ̀bùn ìmúniláradá” táwọn Kristẹni kan ní ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní?

6 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ìṣe 3:2-7; 9:36-42) “Ẹ̀bùn ìmúniláradá” jẹ́ ọ̀kan lára “onírúurú ẹ̀bùn” ẹ̀mí mímọ́ tó wà. (1 Kọ́r. 12:4-11) Àmọ́, àwọn ẹ̀bùn yìí àtàwọn ẹ̀bùn míì bíi, fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀ àti ìsọtẹ́lẹ̀ máa dópin. (1 Kọ́r. 13:8) Wọn ò sí mọ́ lónìí. Torí náà, kò sí ìdí kankan tá a fi lè máa retí pé kí Ọlọ́run wò àwa àtàwọn èèyàn wa sàn lọ́nà ìyanu.

7. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ló wà nínú ìwé Sáàmù 41:3?

7 Síbẹ̀ tá a bá ń ṣàìsàn, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó tù wá nínú, kó fún wa lọ́gbọ́n kó sì ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láyé àtijọ́. Dáfídì Ọba sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀; Ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè.” (Sm. 41:1, 2) A mọ̀ pé, nígbà ayé Dáfídì kò sẹ́nì kankan tí kò kú torí pé ó ń ṣàánú àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Torí náà, kò dájú pé ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé kí Jèhófà dá ẹni náà sí lọ́nà ìyanu, kó má bàa kú mọ́. Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé Ọlọ́run máa ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣe é? Dáfídì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sm. 41:3) Ó yẹ kó dá ẹni tó bá ń ṣojú àánú sí ẹni rírẹlẹ̀ lójú pé Ọlọ́run rí gbogbo ìwà rere rẹ̀, kò sì ní gbàgbé láé. Ara rẹ̀ sì lè yá torí Ọlọ́run ti dá wa lọ́nà tí ara wa fi lè gbógun ti àìsàn.

8. ìwé Sáàmù 41:4 ṣe s, kí ni Dáfídì ń béèrè lọ́wọ́ Jèhófà?

8 Dáfídì mọ̀ pé Jèhófà kì í pa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tì, ó ní: “Mo wí pé: ‘Jèhófà, fi ojú rere hàn sí mi. Mú ọkàn mi lára dá, nítorí pé mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ.’” (Sm. 41:4) Ó lè jẹ́ pé ìgbà tí ara Dáfídì ò yá, tí Ábúsálómù sì fẹ́ gba ìjọba mọ́ ọn lọ́wọ́ ni Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ibí yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti dárí ji Dáfídì, Dáfídì ò gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà àti ohun tó yọrí sí. (2 Sám. 12:7-14) Síbẹ̀, ó dá Dáfídì lójú pé Ọlọ́run máa dá òun sí. Àmọ́, ṣé ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé kí Ọlọ́run wo òun sàn lọ́nà ìyanu tàbí kó fi kún ọjọ́ ìwàláàyè òun?

9. (a) Báwo ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì ṣe yàtọ̀ sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Hesekáyà Ọba? (b) Kí ni Dáfídì retí pé kí Jèhófà ṣe fún òun?

9 Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Hesekáyà Ọba “ṣàìsàn dé ojú ikú,” àmọ́, Ọlọ́run wò ó sàn. Ọlọ́run dá sí ọ̀rọ̀ náà, ara Hesekáyà yá, ó sì lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí i. (2 Ọba 20:1-6) Àmọ́, Dáfídì ò sọ pé kí Ọlọ́run wo òun sàn lọ́nà ìyanu. Ọ̀nà kan náà tí Jèhófà máa gbà ran ‘ẹni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀’ lọ́wọ́ ni Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó gbà ran òun lọ́wọ́. Lára ohun tí Ọlọ́run máa ṣe fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì ni pé Ọlọ́run “yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi.” Torí pé Ọlọ́run ti dárí ji Dáfídì, ó lè bẹ Ọlọ́run pé kó tu òun nínú, kó sì ti òun lẹ́yìn, kí ara òun lè tètè kọ́fẹ pa dà. (Sm. 103:3) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.

10. Kí la rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Tírófímù àti Ẹpafíródítù?

10 Bí Jèhófà ò ṣe wo Dáfídì sàn lọ́nà ìyanu, bẹ́ẹ̀ náà ni kò wo Tírófímù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń bá àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò sàn lọ́nà ìyanu, kò sì fi kún ọjọ́ ìwàláàyè rẹ̀. A mọ̀ pé àwọn ìgbà kan wà tí Ọlọ́run fún Pọ́ọ̀lù lágbára láti wo àwọn aláìsàn sàn. (Ka Ìṣe 14:8-10.) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún ‘baba Púbílọ́sì, [ẹni] tí ibà àti ìgbẹ́ ọ̀rìn ń yọ lẹ́nu.’ Pọ́ọ̀lù “gbàdúrà, ó gbé ọwọ́ lé e, ó sì mú un lára dá.” (Ìṣe 28:8) Síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù ò wo Tírófímù sàn, ẹni tó ti rìnrìn àjò pẹ̀lú rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. (Ìṣe 20:3-5, 22; 21:29) Nígbà tí ara Tírófímù ò yá tí ò sì lè bá Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò mọ́, Pọ́ọ̀lù ò wò ó sàn, ńṣe ló ní kó dúró sí Mílétù títí ara rẹ̀ fi máa yá. (2 Tím. 4:20) Bákan náà, nígbà tí Ẹpafíródítù “dùbúlẹ̀ àìsàn títí ó fi fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ojú ikú,” kò sí ẹ̀rí kankan pé Pọ́ọ̀lù wo ọ̀rẹ́ rẹ̀ àtàtà yìí sàn lọ́nà ìyanu.Fílí. 2:25-27, 30.

GBÉ ÌGBÉSẸ̀ TÓ MỌ́GBỌ́N DÁNÍ

11, 12. Kí nìdí tí Lúùkù fi lè ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́, kí la sì mọ̀ nípa Lúùkù?

11 “Lúùkù oníṣègùn olùfẹ́ ọ̀wọ́n” rìnrìn àjò pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù. Òun ló sì kọ ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì. (Kól. 4:14; Ìṣe 16:10-12; 20:5, 6) Ó ṣeé ṣe kí Lúùkù fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò míṣọ́nnárì nímọ̀ràn nípa ìlera kó sì tún tọ́jú wọn. Kí nìdí tó fi ní láti ṣe bẹ́ẹ̀? Torí pé Pọ́ọ̀lù pàápàá ṣàìsàn nígbà tó ń rìnrìn àjò. (Gál. 4:13) Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.”Lúùkù 5:31.

12 A ò mọ ìgbà tí Lúùkù kẹ́kọ̀ ìmọ̀ ìṣègùn a ò sì mọ ibi tó ti kọ́ ọ. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fi ìkíni Lúùkù ránṣẹ́ sí àwọn ará tó wà ní Kólósè, ó pè é ní oníṣègùn torí pé àwọn ará tó wà ní Kólósè pàápàá mọ̀ pé oníṣègùn ni. Ó sì lè jẹ́ pé ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ìṣègùn kan ní ìlú Laodíkíà ló lọ, nítòsí ìlú Kólósè. Lúùkù kì í wulẹ̀ ṣe agbọ̀ràndùn kan lásán tó ń júwe irú ògùn tó yẹ káwọn èèyàn lò fún wọn, oníṣègùn ni. Àwọn èdè ìṣègùn tó lò nínú ìwé Ìhìn Rere tó kọ àti nínú ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì àti bó ṣe ṣàlàyé àwọn ìwòsàn tí Jésù ṣe jẹ́rìí sí i pé oníṣègùn ni lóòótọ́.

13. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá fẹ́ gba ẹnì kan tó ń ṣàìsàn nímọ̀ràn tàbí tí ẹnì kan bá ń gbà wá nímọ̀ràn nípa ìlera wa?

13 Lónìí, a ò lè retí pé kí àwọn Kristẹni bíi tiwa máa fi “ẹ̀bùn ìmúniláradá” wò wá sàn. Àmọ́, àwọn ará kan tó ní ire wa lọ́kàn máa ń fún wa nímọ̀ràn nípa ìlera wa bá ò tiẹ̀ béèrè pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Lóòótọ́, ẹnì kan lè sọ pé ká ṣe ohun kan tí gbogbo èèyàn mọ̀ dáadáa. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn nígbà tí Tímótì ní àìsàn inú, bóyá torí pé omi tó wà ládùúgbò wọn ò dáa. * (Ka 1 Tímótì 5:23.) Ìyẹn yàtọ̀ sí pé ká máa rọ àwọn ará pé kí wọ́n lo egbòogi tàbí ògùn kan tàbí pé kí wọ́n máa jẹ irú àwọn oúnjẹ kan. Àwọn egbòogi tàbí oúnjẹ yìí sì lè má ṣiṣẹ́ kankan lára wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ léwu. Nígbà míì, àlàyé táwọn kan máa ń ṣe ni pé: ‘Irú àìsàn yìí ti ṣe ẹbí mi kan rí, ògùn báyìí báyìí ló lò, ara ẹ sì ti yá.’ Bó ti wù kí àbá náà jóòótọ́ tó, ó yẹ ká fi sọ́kàn pé ìtọ́jú táwọn èèyàn máa ń gbà tàbí ògùn tí wọ́n máa ń lò dáadáa lè léwu nígbà míì.Ka Òwe 27:12.

JẸ́ ỌLỌGBỌ́N

14, 15. (a) Àwọn wo ló yẹ ká ṣọ́ra fún? (b) Báwo ni ìwé Òwe 14:15 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ìlera?

14 Ìlera lòògùn ọrọ̀, ó ṣe tán gbogbo èèyàn ló fẹ́ ìlera tó dáa títí kan àwa Kristẹni, torí pé ó wù wá ká máa wà láàyè ká lè fi gbogbo okun wa sin Jèhófà. Àmọ́, a lè ṣàìsàn torí pé a ti jogún àìpé. Oríṣiríṣi ògùn la lè lò, onírúurú ọ̀nà la sì lè gbà tọ́jú ara wa tá a bá ń ṣàìsàn. Oníkálukú ló máa pinnu irú ìtọ́jú tóun fẹ́ gbà. Àmọ́, nínú ayé oníwọra yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń purọ́ gba tọwọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn. Àwọn kan máa ń ta àwọn “ògùn” tàbí “egbòogi,” wọ́n á máa parọ́ pé àwọn kan ti lò ó, ó sì ti ṣiṣẹ́. Káwọn èèyàn tàbí iléeṣẹ́ kan lè jèrè rẹpẹtẹ, wọn máa ń polówó àwọn ògùn tàbí àwọn èròjà tówó ẹ̀ wọ́n gan-an fáwọn èèyàn, káwọn èèyàn lè máa rò pé èyí tówó ẹ̀ wọ́n gan-an ló máa ṣiṣẹ́ jù. Aláìsàn tó ń fẹ́ kí ara òun yá, tí ò sì fẹ́ kú lè gba irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká máa rántí ìmọ̀ràn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”Òwe 14:15.

15 “Afọgbọ́nhùwà” máa ń wà lójúfò pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹni tí ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa ìmọ̀ ìṣègùn ló ń gbà á nímọ̀ràn nípa àìlera rẹ̀. Á bi ara rẹ̀ pé: ‘Wọ́n ní ògùn tàbí egbòogi yìí ti wo ẹnì kan sàn, àmọ́ ṣé mo ti rí àwọn tí ògùn náà wò sàn lóòótọ́? Àwa èèyàn sì yàtọ̀ síra. Tó bá tiẹ̀ ṣiṣẹ́ fún ẹnì kan, ṣó wá túmọ̀ sí pé ó máa ṣiṣẹ́ fún èmi náà ni? Ǹjẹ́ kò ní dáa kí n ṣe ìwádìí síwájú sí i àbí màá ní láti lọ rí ẹnì kan tó mọ̀ nípa àìsàn náà dáadáa?’Diu. 17:6.

16. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa tó máa jẹ́ ká lo “ìyèkooro èrò inú” tó bá dọ̀rọ̀ ìlera?

16 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú “láti gbé pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú . . . nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.” (Títù 2:12) Ó yẹ ká lo “ìyèkooro èrò inú” pàápàá tó bá jẹ́ pé a ò lè fi gbogbo ẹnu ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ṣe àyẹ̀wò kan fún wa tàbí bí wọ́n ṣe máa tọ́jú irú àìsàn kan. Ṣé ẹni tó dábàá irú àyẹ̀wò tàbí irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ lè ṣàlàyé tìfun-tẹ̀dọ̀ bí wọ́n ṣe máa ṣe é? Ṣé ìtọ́jú tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa ni, ṣé àwọn tó mọ̀ nípa àìsàn náà sì gbà pé ìtọ́jú tó dáa ni? (Òwe 22:29) Àbí nǹkan tí ẹni náà kàn rò ló ń sọ ní tiẹ̀? Bóyá ohun tó gbọ́ ni pé ìlú kan tó jìnnà ni wọ́n ti ṣàwárí ẹ̀ tàbí tí wọ́n ti lò ó. Ṣé ohun tí wọ́n sọ yìí ṣeé gbára lé ṣá? Àwọn àyẹ̀wò kan àtàwọn ìtọ́jú kan wà tó la ìbẹ́mìílò lọ. A gbọ́dọ̀ yẹra fún irú àwọn ìtọ́jú yìí torí Jèhófà ti kìlọ̀ fún wa pé ká máà ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn tó ń lo “agbára abàmì” tàbí àwọn abẹ́mìílò.Aísá. 1:13; Diu. 18:10-12.

“KÍ ARA YÍN Ó LE O!”

17. Kí ni gbogbo wa ń fẹ́?

17 Ìgbìmọ̀ olùdarí tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi lẹ́tà kan tó ṣe pàtàkì ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Lẹ́yìn tí wọ́n ti sọ àwọn nǹkan táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún, wọ́n wá sọ níparí lẹ́tà náà pé: “Bí ẹ bá fi tìṣọ́ra-tìṣọ́ra pa ara yín mọ́ kúrò nínú nǹkan wọ̀nyí, ẹ óò láásìkí. Kí ara yín ó le o!” (Ìṣe 15:29) Ó dájú pé gbogbo wa la fẹ́ ‘kí ara wa le’ ká sì lókun láti sin Jèhófà, Ọlọ́run wa.

À ń fẹ́ ìlera tó dáa ká lè máa sin Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 17)

18, 19. Kí là ń retí nínú ayé tuntun?

18 Níwọ̀n bá a ti ń gbé nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí tá a sì tún jẹ́ aláìpé, kò sí bá ò ṣe ní máa ṣàìsàn. A ò sì lè retí pé kí Jèhófà wò wá sàn lọ́nà ìyanu báyìí. Àmọ́, ìwé Ìṣípayá 22:1, 2 jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà kan ń bọ̀ tí gbogbo wa ò ní ṣàìsàn mọ́. Nínú ìran, àpọ́sítélì Jòhánù rí “odò omi ìyè kan” àti “àwọn igi ìyè” tó ní àwọn ewé tó “wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” Kì í ṣe egbòogi kan tó máa wo àwọn àrùn sàn nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú ni ibi yìí ń sọ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé onígbọràn nípasẹ̀ Jésù ká lè wà láàyè títí láé ni ibí yìí ń sọ. Ohun tó sì yẹ kí gbogbo wa máa retí nìyẹn.Aísá. 35:5, 6.

19 Bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ yẹn, a mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kò sì ní fi wá sílẹ̀ kódà tá a bá ń ṣàìsàn. Bíi ti Dáfídì, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa gbé wa ró nígbàkigbà tá a bá ń ṣàìsàn. Àá sì lè sọ bíi ti Dáfídì pé: “Ní tèmi, ìwọ ti gbèjà mi nítorí ìwà títọ́ mi, ìwọ yóò sì gbé mi kalẹ̀ sí iwájú rẹ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”Sm. 41:12.

^ ìpínrọ̀ 13 Ìwé náà The Origins and Ancient History of Wine sọ pé: “Ìwádìí ti fi hàn pé ọtí wáìnì tètè máa ń pa kòkòrò ibà jẹ̀funjẹ̀fun àti àwọn kòkòrò míì tó lè fa àrùn síni lára.”