ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ October 2015

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti November 30 sí December 27, 2015 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

‘Ẹ Máa Ka Irú Àwọn Ènìyàn Bẹ́ẹ̀ Sí Ẹni Ọ̀wọ́n’

Àwọn wo ló ń ṣèrànwọ́ fún ìgbìmọ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò? Kí ni iṣẹ́ wọn?

Ǹjẹ́ Ò Ń Rí Ọwọ́ Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ?

Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ọwọ́” Jèhófà, kí ló túmọ̀ sí?

“Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”

Ṣé a lè nígbàgbọ́ nípasẹ̀ agbára àwa fúnra wa?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Kò Kábàámọ̀ Ìpinnu Tó Ṣe Nígbà Èwe Rẹ̀

Nikolai Dubovinsky sin Jèhófà láìyẹsẹ̀ nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa lórílẹ̀-èdè Soviet Union àtijọ́, iṣẹ́ tó ṣe tiẹ̀ le ju kéèyàn wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lọ.

Sin Jèhófà Láìsí Ìpínyà Ọkàn

Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ó yani lẹ́nu pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn lónìí.

Máa Ṣàṣàrò Lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ṣó ó ṣì lè máa jàǹfààní látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó o bá wà níbì kan tí wọn ò ti gbà ẹ́ láyè láti ka Bíbélì?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Sísún Mọ́ Ọlọ́run Dára fún Mi

Nígbà tí Sarah Maiga pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, kò ga ju bó ṣe wà lọ mọ́, àmọ́ ó ń dàgbà sí i nípa tẹ̀mí.

“Òpè Eniyan A Máa Gba Ohun Gbogbo Gbọ́”

Báwo lo ṣe lè mọ àwọn ìsọfúnni tó jẹ́ ẹ̀tàn, èwo ni àgbọ́sọgbánù àmọ́ tó jẹ́ irọ́ gbuu, èyí tí wọ́n fi ń purọ́ gba tọwọ́ ẹni àtàwọn ìròyìn mí ì tí ń ṣini lọ́nà táwọn èèyàn lè fi ránṣẹ́ sí ẹ lórí kọ̀ǹpútà?