LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
“Jèhófà Mú Yín Wá sí Ilẹ̀ Faransé Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́”
NÍGBÀ tí Antoine Skalecki wà ní ọmọdé, ó ní ẹṣin kan tó máa ń wà pẹ̀lú rẹ̀ nígbà gbogbo. Wọ́n jọ máa ń rìnrìn-àjò kọjá ọ̀nà abẹ́lẹ̀ tí kò mọ́lẹ̀ dáadáa, wọ́n á sì gbé èédú tó pọ̀ lọ sí àjà ilẹ̀ tó jìn tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] mítà, ìyẹn ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [1,600] ẹsẹ̀ bàtà sí ìsàlẹ̀. Bàbá Antoine ṣèṣe nígbà tí ibi tí wọ́n ti ń wa kùsà ya lulẹ̀, torí náà ìdílé wọ́n ní kí Antoine máa lọ ṣiṣẹ́ fún wákàtí mẹ́sàn-án lójúmọ́ níbi ìwakùsà náà. Lọ́jọ́ kan, ó ku díẹ̀ kí Antoine náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ibi tí wọ́n ti ń wa kùsà náà ya lulẹ̀.
Antoine wà lára àwọn ọmọ rẹpẹtẹ tí àwọn òbí tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland bí sí ilẹ̀ Faransé ní ọdún 1920 sí ọdún 1939. Àmọ́, kí nìdí tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland fi ṣí wá sí ilẹ̀ Faransé? Ìdí ni pé nígbà tí orílẹ̀-èdè Poland gba òmìnira lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn èèyàn ti pọ̀ jù ní orílẹ̀-èdè náà, èyí sì wá di ìṣòro ńlá. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ilẹ̀ Faransé ti pàdánù àwọn ọkùnrin tó ju mílíọ̀nù kan lọ nínú ogun, wọ́n sì wá nílò àwọn èèyàn tó lè ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa èédú. Torí náà, ìjọba orílẹ̀-èdè Poland àti ti ilẹ̀ Faransé ti ọwọ́ bọ ìwé àdéhùn kan ní oṣù September ọdún 1919, tó máa yọ̀ǹda fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland láti wọ ilẹ̀ Faransé. Ní ọdún 1931, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland tó wà ní ilẹ̀ Faransé ti tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàrin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [507,800], apá ibi tí wọ́n ti ń wa kùsà ní ìhà àríwá ni ọ̀pọ̀ wọn sì dó sí.
Àṣà ìbílẹ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland tó jẹ́ òṣìṣẹ́ kára yìí yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé, wọ́n sì tún ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún ẹ̀sìn. Antoine tó ti pé ọmọ àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí sọ pé: “Bàbá mi àgbà tó ń jẹ́ Joseph máa ń sọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ torí ohun tí bàbá wọn kọ́ wọn nìyẹn.” Ní gbogbo ọjọ́ Sunday, àwọn tó ń wa kùsà náà àti ìdílé wọn máa ń wọ èyí tó dáa jù nínú aṣọ wọn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bí wọ́n ṣe máa ń ṣe ní ìlú wọn, àmọ́ inú àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ju ẹ̀sìn lọ kì í dùn sí èyí.
Àgbègbè Nord-Pas-de-Calais ní ilẹ̀ Faransé ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland ti rí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ìgbà àkọ́kọ́. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ti ń fi ìtara wàásù níbẹ̀ láti ọdún 1904. Ní ọdún 1915, a bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn The Watch Tower (Ilé Ìṣọ́) ní èdè Polish lóṣooṣù, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age (tí à ń pè ní Jí! báyìí) ní èdè yẹn ní ọdún 1925. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló fara mọ́ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn yìí àti ìwé Duru Ọlọrun ní èdè Polish.
Ẹbí màmá Antoine kan lọ sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1924. Nípasẹ̀ rẹ̀ sì ni àwọn ìdílé Antoine fi rí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ọdún yẹn kan náà, àwọn
Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe àpéjọ wọn àkọ́kọ́ lédè Polish ní ìlú Bruay-en-Artois. Ní nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà, aṣojú oríléeṣẹ́ wa lágbàáyé, Arákùnrin Joseph F. Rutherford wá síbẹ̀, ó sì ṣe ìpàdé kan tí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] èèyàn pésẹ̀ sí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọ orílẹ̀-èdè Poland ló pọ̀ jù nínú àwọn tó wà níbẹ̀, èyí wú Arákùnrin Rutherford lórí, ó wá sọ fún wọn pé: “Jèhófà mú yín wá sí ilẹ̀ Faransé láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín sì gbọ́dọ̀ ran àwọn ará ilẹ̀ Faransé lọ́wọ́! Púpọ̀ ṣì wà láti ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè yìí, Jèhófà sì máa gbé àwọn akéde dìde láti ṣe é.”Ohun tí Jèhófà sì ṣe gan-an nìyẹn. Bí àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland ṣe ń ṣiṣẹ́ takuntakun níbi tí wọ́n ti ń wa kùsà náà ni wọ́n ń polongo ìhìn rere ìjọba náà tọkàntọkàn. Nígbà tó yá, àwọn kan lára wọn pa dà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn ní orílẹ̀-èdè Poland láti lọ wàásù ojúlówó ìhìn rere tí wọ́n ti gbà. Teofil Piaskowski, Szczepan Kosiak àti Jan Zabuda wà lára àwọn tó kúrò ní ilẹ̀ Faransé láti lọ wàásù ìhìn rere náà jákèjádò orílẹ̀-èdè Poland.
Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland ò kúrò nílẹ̀ Faransé, gbogbo wọ́n jùmọ̀ ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé. Ní ọdún 1926, ní àpéjọ gbogbo gbòò kan tí wọ́n ṣe ní ìlú Sin-le-Noble, ẹgbẹ̀rún kan èèyàn ló wà ní apá ibi tí wọ́n ti sọ èdè Polish nígbà tí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta èèyàn wà níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè Faransé. Ìwé Ọdọọdún wa ti ọdún 1929 sọ pé: “Láàárín ọdún yìí, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Poland tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgbọ̀n ó lé méjì [332] ti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn nípasẹ̀ ìrìbọmi.” Kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀, méjìlélọ́gbọ̀n [32] nínú àwọn ìjọ mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] tó wà ní ilẹ̀ Faransé ló jẹ́ ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Polish.
Ní ọdún 1947, ìjọba orílẹ̀-èdè Poland sọ pé kí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè àwọn pa dà wá sílé, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Poland ló sì ṣe bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n lọ tán, ìbísí tó wáyé nínú iye àwọn akéde lọ́dún yẹn fi hàn pé òpò gbogbo wọn àti tàwọn ará ní ilẹ̀ Faransé kò já sásán. Ọ̀pọ̀ ìbísí sì tún wáyé léraléra láti ọdún 1948 sí ọdún 1950. Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ọdún 1948, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ilẹ̀ Faransé yan àwọn alábòójútó àyíká kí wọ́n lè fún àwọn akéde tuntun yìí ní ìdálẹ́kọ̀ọ́. Nínú àwọn márùn-ún tí wọ́n yàn, mẹ́rin jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Poland, Antoine Skalecki sì jẹ́ ọ̀kan lára wọn.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ Faransé ṣì ń jẹ́ orúkọ àwọn baba ńlá wọn tó ṣiṣẹ́ takuntakun níbi ìwakùsà àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó kó lọ sí ilẹ̀ Faransé ló ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Yálà àwọn ajíhìnrere tó ti orílẹ̀-èdè míì wá pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n ń fìtara pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà bí àwọn baba ńlá wọn ti ṣe. Látinú àpamọ́ wa ní ilẹ̀ Faransé.