Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi Ìjọsìn Wa Rèé

Ibi Ìjọsìn Wa Rèé

“Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.”—JÒH. 2:17.

ORIN: 127, 118

1, 2. (a) Àwọn ibi ìjọsìn wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lò nígbà àtijọ́? (b) Ọwọ́ wo ni Jésù fi mú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù? (d) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

LÁTI ìgbà ìjímìjí ni àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti ní àwọn ibi pàtó tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn mímọ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí pẹpẹ ni Ébẹ́lì ti rúbọ sí Ọlọ́run. (Jẹ́n. 4:3, 4) Nóà, Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Mósè náà mọ pẹpẹ. (Jẹ́n. 8:20; 12:7; 26:25; 35:1; Ẹ́kís. 17:15) Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kọ́ àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kís. 25:8) Nígbà tó yá, wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì fún ìjọsìn Jèhófà. (1 Ọba 8:27, 29) Lẹ́yìn tí àwọn Júù pa dà dé láti ìgbèkùn ní Bábílónì, wọ́n máa ń péjọ pọ̀ déédéé nínú sínágọ́gù. (Máàkù 6:2; Jòh. 18:20; Ìṣe 15:21) Àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní máa ń pàdé pọ̀ nínú ilé àwọn ará. (Ìṣe 12:12; 1 Kọ́r. 16:19) Lóde òní, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì jọ́sìn nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn kárí ayé.

2 Jésù fẹ́ràn tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sì mọrírì rẹ̀. Èyí rán òǹkọ̀wé Ìhìn Rere kan létí ọ̀rọ̀ tí onísáàmù sọ pé: “Ìtara fún ilé rẹ yóò jẹ mí run.” (Sm. 69:9; Jòh. 2:17) Kò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kankan tá a lè pè ní “ilé Jèhófà” bíi ti tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 5:13; 33:4) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì ní àwọn ìlànà tó jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká máa lo àwọn ibi ìjọsìn wa lóde òní àti bí a ó ṣe máa ṣe ohun tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún un. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, á máa gbé díẹ̀ lára àwọn ìlànà yìí yẹ̀ wò, a sì máa jíròrò bí àwọn ìlànà yìí ṣe kan ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, bí a ó ṣe máa rí owó àti bí a ó ṣe máa tún wọn ṣe. *

MÁA ṢE OHUN TÓ FI Ọ̀WỌ̀ HÀN FÚN ÌJỌSÌN MÍMỌ́

3-5. Kí là ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún? Báwo ló ṣe yẹ kí èyí nípa lórí ojú tá a fi ń wo àwọn ìpàdé tá à ń ṣe níbẹ̀?

3 Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ibi tá à ń pé jọ sí láti ṣe ìjọsìn mímọ́ ní àgbègbè ibi tí à ń gbé. Àwọn ìpàdé tí à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wà lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ wa. Ibẹ̀ la ti ń rí ìtura tá a nílò nípa tẹ̀mí àti ìtọ́sọ́nà gbà nípasẹ̀ ètò rẹ̀. Torí náà, a lè sọ pé Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ló ké sí gbogbo àwọn tó ń wá síbẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti pè wá láti wá jẹun lórí ‘tábìlì rẹ̀,’ a kò gbọ́dọ̀ fojú kéré irú ìkésíni bẹ́ẹ̀ láé.—1 Kọ́r. 10:21.

4 Jèhófà ka àkókò tí a fi ń jọ́sìn rẹ̀, tí a sì fi ń fún ara wa níṣìírí sí pàtàkì. Ó mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti rọ̀ wá pé ká má ṣe máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀. (Ka Hébérù 10:24, 25.) Tí a bá ń pa àwọn ìpàdé jẹ torí àwọn ìdí tí kò pọn dandan, ǹjẹ́ ìyẹn á fi hàn pé à ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún Jèhófà? A lè fi hàn ní ti gidi pé a mọrírì àwọn ìpèsè Jèhófà tá a bá ń múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ tá a sì ń lóhùn sí àwọn ìpàdé náà tọkàntọkàn.—Sm. 22:22.

5 Ojú tí a fi ń wo Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó ń wáyé níbẹ̀ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a ní ọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa. Tá a bá sì ń fi ojú tó tọ́ wo Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ǹjẹ́ ìyẹn ò ní fi hàn pé a fi ọwọ́ pàtàkì mú orúkọ Ọlọ́run tó máa ń fara hàn lára àkọlé tó wà lára Gbọ̀ngàn Ìjọba wa?—Fi wé 1 Ọba 8:17.

6. Kí ni àwọn kan sọ nípa Gbọ̀ngàn Ìjọba wa àti àwọn tó ń wá síbẹ̀? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

6 Àwọn èèyàn máa ń kíyè sí ọ̀wọ̀ tá à ń fi hàn fún ibi ìjọsìn wa. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Tọ́kì sọ pé: “Bí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ṣe mọ́ tónítóní tó sì wà létòlétò wú mi lórí. Àwọn tó wà níbẹ̀ múra dáadáa, wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n sì kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Èyí sì wú mi lórí gan-an.” Ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé déédéé, ó sì ṣèrìbọmi láìpẹ́ sígbà yẹn. Ní ìlú kan lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, ìjọ kan ké sí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ àti àwọn aládùúgbò pé kí wọ́n wá rìn yí ká Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn kí wọ́n tó yà á sí mímọ́. Olórí ìlú náà lọ síbẹ̀. Ohun ìwúrí ló jẹ́ fún un nígbà tó rí bí ilé tí wọ́n kọ́ náà ṣe dára tó, bó ṣe wúlò tó àti ọgbà rírẹwà tó wà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Bí gbọ̀ngàn yín ṣe mọ́ tónítóní fi hàn pé ẹ̀yin gan-an lẹ̀ ń ṣe ìsìn tòótọ́.”

Ìwà wa lè fi hàn pé a kò bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run (Wo ìpínrọ̀ 7, 8)

7, 8. Ohun pàtàkì wo ló yẹ kí àwọn tó ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ máa fi sọ́kàn?

7 Ọ̀wọ̀ tí a ní fún Ọlọ́run tó ní ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ gbọ́dọ̀ fara hàn nínú ìwà wa, aṣọ wa àti ọ̀nà tá à ń gbà múra. Ọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa tún gba pé ká yẹra fún ṣíṣe àṣejù. A ti kíyè sí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan máa ń ki àṣejù bọ ohun tí wọ́n kà sí ìwà yíyẹ nígbà tá a bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, síbẹ̀ ọwọ́ dẹngbẹrẹ ni àwọn kan fi ń mú ohun tó yẹ ká máa ṣe tá a bá wà níbẹ̀. Ohun kan ni pé, Jèhófà fẹ́ kí ara tu gbogbo àwọn ará àti àwọn àlejò tó bá wá sí ìpàdé wa. Síbẹ̀, kò yẹ ká máa ṣe ohun tó máa tàbùkù sí àwọn ìpàdé wa. Kò yẹ ká máa múra lọ́nà tí kò bójú mu, kò sì yẹ ká máa tẹ àtẹ̀jíṣẹ́, ká máa sọ̀rọ̀ tàbí ká máa jẹun nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n mọ̀ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba kì í ṣe ibi ìṣeré tàbí ibi tí wọ́n á ti máa sáré kiri.—Oníw. 3:1.

8 Nígbà tí Jésù rí àwọn tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, inú bí i, ó sì lé wọn síta. (Jòh. 2:13-17) Bákan náà, àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jẹ́ ibi tí a ti ń ṣe ìjọsìn tòótọ́, tí a sì ti ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí. Torí náà, bí ọ̀rọ̀ èyíkéyìí bá la owó lọ, tí kò sì ní í ṣe pẹ̀lú ohun tá a nílò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ibòmíì ló yẹ ká ti bójú tó irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.—Fi wé Nehemáyà 13:7, 8.

BÍ A ṢE Ń RÍ OWÓ TÁ A SÌ Ń KỌ́ ÀWỌN GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA

9, 10. (a) Báwo la ṣe ń rí owó tá a sì ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí ló sì ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? (b) Ìpèsè tó fìfẹ́ hàn wo ló ti ran àwọn ìjọ tí wọn ì bá tí ní àǹfààní láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn lọ́wọ́?

9 Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni ètò Jèhófà ń ṣe láti pèsè owó kí wọ́n sì tún kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Àwọn tí a kì í sanwó fún, tí wọ́n sì yọ̀ǹda ara wọn, ló ń bá wa bójú tó yíya àwòrán, kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí ṣíṣe àtúnṣe èyí tó ti wà tẹ́lẹ̀. Kí ló ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? Láti November 1, ọdún 1999, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà, èyí tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n [28,000] kárí ayé. Ìyẹn fi hàn pé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó ti kọjá, tá a bá pín in dọ́gbadọ́gba, Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún là ń kọ́ lójoojúmọ́.

10 Ètò Ọlọ́run ń sapá láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba níbikíbi tí àwọn ará bá ti nílò rẹ̀. Ìpèsè tó fìfẹ́ hàn yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa bí àṣẹ́kùsílẹ̀ àwọn kan ṣe lè dí ànító àwọn míì, kí “ìmúdọ́gba lè ṣẹlẹ̀.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 8:13-15.) Látàrí ìyẹn, a ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó rẹwà fún àwọn ìjọ tí wọn ì bá tí ní àǹfààní láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn.

11. Kí ni àwọn ará kan sọ nípa Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, báwo ni èyí sì ṣe rí lára rẹ?

11 Ìjọ kan tó jàǹfààní látinú ìpèsè yìí ní orílẹ̀-èdè Costa Rica sọ pé: “Tá a bá dúró níwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ńṣe ló máa ń dà bí àlá lójú wa. Ó máa ń ṣòro fún wa láti gbà gbọ́. Ọjọ́ mẹ́jọ péré ni wọ́n fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wa rírẹwà náà látòkèdélẹ̀! Ìbùkún Jèhófà, ètò rẹ̀ àti ìtìlẹ́yìn àwọn ará wa ọ̀wọ́n, ló mú kó ṣeé ṣe. A ka ibi ìjọsìn yìí sí ẹ̀bùn pàtàkì àti ìṣúra iyebíye tí Jèhófà fún wa. Inú wa dùn gan-an pé ó fún wa nírú ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀.” Ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn tó o bá gbọ́ tí àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ ìmọrírì báyìí nítorí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fún wọn, tó o sì tún mọ̀ pé àwọn ará wa míì náà ń ní irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ibi kárí ayé? Jèhófà ló ń mú kí gbogbo èyí ṣeé ṣe torí pé gbàrà tá a bá ti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tán ni àwọn èèyàn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ máa ń kún inú rẹ̀.—Sm. 127:1.

12. Báwo lo ṣe lè ṣe ipa tìrẹ nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba?

12 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti kópa nínú kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí sì ti mú kí wọ́n láyọ̀ gan-an. Yálà àwa náà lè bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbogbo wa ni àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún láti kọ́wọ́ ti irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ọrẹ wa. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìtara tí àwọn èèyàn ní fún ìjọsìn tòótọ́ máa ń mú kí wọ́n fi owó ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ọlọ́run. Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ìyẹn sì ń fi ògo fún Jèhófà.—Ẹ́kís. 25:2; 2 Kọ́r. 9:7.

MÍMÚ KÍ GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA WÀ NÍ MÍMỌ́ TÓNÍTÓNÍ

13, 14. Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló kan mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò?

13 Lẹ́yìn tí a bá ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tán, ó yẹ ká máa tọ́jú rẹ̀ kó lè máa wà ní mímọ́ àti létòlétò, ìyẹn á sì fi hàn pé à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà àti ìṣe Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (Ka 1 Kọ́ríńtì 14:33, 40.) Bíbélì fi hàn pé ká lè jẹ́ mímọ́, ìjọsìn wa ò gbọ́dọ̀ ní àbààwọ́n, àwa náà sì gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní. (Ìṣí. 19:8) Torí náà, bí àwọn èèyàn bá fẹ́ láti jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lójú Jèhófà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́.

14 Tá a bá fi ìlànà yìí sọ́kàn, á máa yá wa lára láti ké sí àwọn olùfìfẹ́hàn wá sí àwọn ìpàdé wa, torí ó dá wa lójú pé ipò tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wá wà ò ní tàbùkù sí ìhìn rere tá à ń wàásù rẹ̀ fún wọn. Wọ́n á rí i pé Ọlọ́run mímọ́ là ń sìn, kò sì ní pẹ́ sọ ayé di Párádísè tí kò ní àbààwọ́n.—Aísá. 6:1-3; Ìṣí. 11:18.

15, 16. (a) Kí ló lè mú kó ṣòro láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní? Kí nìdí tí ìmọ́tótó fi ṣe pàtàkì? (b) Kí ni ètò tí ìjọ yín ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba máa wà ní mímọ́ tónítóní, àǹfààní wo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì ní?

15 Ọwọ́ tí àwọn kan fi mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó lè má ṣe pàtàkì tó ọwọ́ tí àwọn míì fi mú un. Ohun tó máa ń nípa lórí ọwọ́ tí àwọn kan fi mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ni bí wọ́n ṣe tọ́ wọn dàgbà àti àwọn nǹkan míì bí ẹrọ̀fọ̀, eruku, bí ojú ọ̀nà ṣe rí, àìsí omi tó tó àti ọṣẹ. Bó ti wù kí nǹkan rí àti láìka ọwọ́ táwọn èèyàn fi mú ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó sí, ó yẹ kí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa máa wà ní mímọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà torí pé orúkọ Jèhófà la fi ń pè é, a sì ń ṣe ìjọsìn mímọ́ níbẹ̀.—Diu. 23:14.

16 Kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa lè máa wà ní mímọ́ tónítóní a gbọ́dọ̀ ní ètò pàtó fún títọ́jú rẹ̀. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ rí i pé wọ́n ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún títún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe, kí wọ́n sì pèsè àwọn ohun tó pọ̀ tó láti fi ṣe iṣẹ́ náà, kí Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń lò fún ìjọsìn lè wà ní mímọ́ nigín-nigín. Torí pé àwọn iṣẹ́ ìmọ́tótó kan wà tá a gbọ́dọ̀ máa ṣe lẹ́yìn ìpàdé kọ̀ọ̀kan, tí àwọn míì sì wà tá a lè dájọ́ sí, ó gba pé kí ẹ ní ètò tó ṣe gúnmọ́, kẹ́ ẹ sì máa bójú tó iṣẹ́ náà lọ́nà tí ohunkóhun kò fi ní wọ́lẹ̀. Àǹfààní ló jẹ́ fún gbogbo àwọn ará nínú ìjọ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tó bá kan iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba.

BÁ A ṢE LÈ MÁA TÚN GBỌ̀NGÀN ÌJỌBA WA ṢE

17, 18. (a) Àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé ká máa tún ibi tá a ti ń ṣe ìjọsìn mímọ́ ṣe? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa máa wà ní ipò tó bójú mu?

17 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tún máa ń sapá gidigidi láti tún ibi ìjọsìn wọn ṣe. Jèhóáṣì Ọba Júdà pàṣẹ fún àwọn àlùfáà pé kí wọ́n fi ọrẹ tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà “tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe, ibikíbi tí [wọ́n] bá ti rí ibi sísán èyíkéyìí.” (2 Ọba 12:4, 5) Ní ohun tó ju igba [200] ọdún lọ lẹ́yìn náà, Jòsáyà Ọba tún lo ọrẹ táwọn èèyàn mú wá sí tẹ́ńpìlì láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.—Ka 2 Kíróníkà 34:9-11.

18 Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ròyìn pé àwọn èèyàn kì í sábàá tún ilé tàbí ohun èlò wọn ṣe. Ní àwọn ilẹ̀ yẹn, ó lè jẹ́ pé díẹ̀ ni àwọn tó mọ̀ nípa irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí tó ní ohun èlò tí wọ́n lè fi ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́, ohun tó dájú ni pé bí a kì í bá tún Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ṣe, kò ní pẹ́ tí á fi bẹ̀rẹ̀ sí í bà jẹ́, ó sì máa tàbùkù sí wa lọ́dọ̀ àwọn tó ń rí i. Ṣùgbọ́n tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ bá ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní, èyí á fi ìyìn fún Jèhófà, kò sì ní jẹ́ ká lo ọrẹ tí àwọn ara wa ṣe nílòkulò.

Gbọ̀ngàn Ìjọba wa gbọ́dọ̀ máa wà ní mímọ́ tónítóní ká sì máa tún un ṣe (Wo ìpínrọ̀ 16, 18)

19. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe ní àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn mímọ́?

19 Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ́ ilé kan tí a yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Torí náà, láìka orúkọ tá a fi ń pè é sí, kì í ṣe ti ẹnikẹ́ni tàbí ti ìjọ èyíkéyìí. Torí ìjọsìn Jèhófà la ṣe kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn ìlànà Kristẹni sì kọ́ wa pé ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún ká lè rí i dájú pé ọ̀nà tá à ń gbà bójú tó o fi hàn bẹ́ẹ̀. Gbogbo wa nínú ìjọ lè ṣe ipa tiwa nípa ṣíṣe ohun tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún ibi ìjọsìn wa, ká máa fi owó ṣètọrẹ fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ká máa lo àkókò àti okun wa láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń lò wà ní mímọ́ tónítóní ká sì máa tún un ṣe. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a ó máa fi hàn pé a ní ìtara fún ibi tá a ti ń ṣe ìjọsìn mímọ́, bíi ti Jésù.—Jòh. 2:17.

^ ìpínrọ̀ 2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ nípa Gbọ̀ngàn Ìjọba la sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, a lè lo ìlànà inú rẹ̀ fún àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti àwọn ilé míì tá à ń lò fún ìjọsìn mímọ́.