E Fara We Eni To Seleri Iye Ainipekun
“Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—ÉFÉ. 5:1.
1. Ẹ̀bùn wo la ní tó jẹ́ ká lè fìwà jọ Ọlọ́run?
JÈHÓFÀ ti dá wa lọ́nà táá jẹ́ ká lè fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara wa wò. Dé ìwọ̀n àyè kan, a lè fọkàn yàwòrán ohun kan tí kò tíì ṣẹlẹ̀ lójú wa rí. (Ka Éfésù 5:1, 2.) Báwo la ṣe lè fọgbọ́n lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí? Kí la lè ṣe tí kò fi ní pa wá lára?
2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà, tá a bá wà nínú wàhálà?
2 Láìsí àní-àní, ayọ̀ wá kún torí pé Ọlọ́run ti ṣèlérí àìleèkú ní ọ̀run fún àwọn olóòótọ́ ẹni àmì òróró àti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé fún àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. (Jòh. 10:16; 17:3; 1 Kọ́r. 15:53) Ó dájú pé àwọn tó máa gba àìleèkú ní ọ̀run àtàwọn tó máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé kò ní fojú winá ìjìyà èyíkéyìí mọ́. Jèhófà mọ ìyà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ nígbà tí wọ́n wà lóko ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì, bẹ́ẹ̀ náà ló sì mọ ohun tá à ń dojú kọ lónìí. Àní sẹ́, “nínú gbogbo wàhálà wọn, ó jẹ́ wàhálà fún un.” (Aísá. 63:9) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìbẹ̀rùbojo mú àwọn Júù torí pé àwọn ọ̀tá ń dí wọn lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì kọ́, àmọ́ Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sek. 2:8) Bí ìyá kan ṣe máa tọ́jú ọmọ rẹ̀ jòjòló lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, Jèhófà náà máa ń fìfẹ́ gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀. (Aísá. 49:15) Ńṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà fi ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ro ara rẹ̀ wò, ó sì dá àwa náà lọ́nà tá a fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.—Sm. 103:13, 14.
JÉSÙ FÌFẸ́ HÀN BÍI TI ỌLỌ́RUN
3. Kí ni ohun tó fi hàn pé Jésù jẹ́ aláàánú?
3 Jésù mọ bí ìrora tí àwọn èèyàn ní ṣe ń rí lára, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ohun táwọn èèyàn dojú kọ ló tíì ṣẹlẹ̀ sí i rí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó di ẹrù òfin àtọwọ́dá lé wọn lórí, tí wọ́n sì ń ṣì wọ́n lọ́nà. (Mát. 23:4; Máàkù 7:1-5; Jòh. 7:13) Kò sí ohunkóhun tó ba Jésù lẹ́rù rí, kò sì sí ẹnikẹ́ni tó lè ṣì í lọ́nà, àmọ́ ó mọ bí nǹkan ṣe rí fáwọn tó wà nírú ipò yẹn. Abájọ tó fi jẹ́ pé, “nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mát. 9:36) Torí náà, Jésù fìwà jọ Baba rẹ̀, ó jẹ́ aláàánú àti onífẹ̀ẹ́.—Sm. 103:8.
4. Nígbà tí Jésù rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, báwo ló ṣe rí lára rẹ̀?
4 Nígbà tí Jésù rí ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn, àánú wọn ṣe é, torí náà, ó fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun fi ìfẹ́ jọ Baba òun. Lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù dé láti ọ̀nà jíjìn, ìyẹn níbi tí wọ́n ti lọ wàásù, wọ́n fẹ́ lọ síbì kan táwọn èèyàn kò ti ní rí wọn kí wọ́n lè sinmi. Àmọ́ torí pé Jésù káàánú ogunlọ́gọ̀ ńlá tó ń dúró dè é, ó yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ kó lè “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.”—Máàkù 6:30, 31, 34.
BÁ A ṢE LÈ MÁA FÌFẸ́ HÀN BÍI TI JÈHÓFÀ
5, 6. Tá a bá fẹ́ fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run, báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sáwọn ẹlòmíì? Ṣàpèjúwe. (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
5 A lè fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run nínú ìwà àti ìṣe wa sí àwọn ẹlòmíì. Àpẹẹrẹ kan rèé: Jẹ́ ká sọ pé Kristẹni ọ̀dọ́ kan tá a máa pe orúkọ rẹ̀ ní Alan ń ronú nípa arákùnrin àgbàlagbà kan tí kò lè kàwé dáadáa torí pé ojú rẹ̀ kò ríran kedere mọ́. Ó tún nira fún arákùnrin yìí láti máa rìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Alan wá rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.” (Lúùkù 6:31) Torí náà, Alan bi ara rẹ̀ pé, ‘Kí ni mo fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sí mi?’ Ìdáhùn tó wá sí i lọ́kàn ni pé, ‘Kí wọ́n jẹ́ ká jọ gbá bọ́ọ̀lù!’ Àmọ́, arákùnrin àgbàlagbà yìí kò ní lè gbá bọ́ọ̀lù. Tá a bá lóye ọ̀rọ̀ Jésù yìí, a gbọ́dọ̀ bi ara wa pé, ‘Kí ni mo fẹ́ kí àwọn ẹlòmíì ṣe fún mi ká ní èmi ni mo wà nípò wọn?’
6 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Alan kì í ṣe àgbàlagbà, ó lè fi bí nǹkan ṣe ń rí fún àgbàlagbà ro ara rẹ̀ wò. Ó kíyè sí bàbá àgbàlagbà náà, ó sì tẹ́tí sí i dáadáa kó lè mọ ohun tí bàbá náà nílò. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Alan mọ bó ṣe máa ń rí fún ẹnì kan tó ti dàgbà, tí kò lè ka Bíbélì dáadáa mọ́ tàbí tí kò rọrùn fún láti máa rìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Nígbà tí Alan mọ ìṣòro bàbá àgbàlagbà náà lára, ó ronú kan ohun tó máa ràn án lọ́wọ́, ó sì fẹ́ ṣèrànwọ́. Ohun tó yẹ káwa náà máa ṣe nìyẹn. Ká lè máa fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà, a gbọ́dọ̀ fi ara wa sírú ipò táwọn ará wa wà.—1 Kọ́r. 12:26.
7. Báwo la ṣe lè mọ àwọn ẹlòmíì débi tá a máa fi lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn?
7 Kì í sábà rọrùn láti mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára àwọn ẹlòmíì. A ò mọ onírúurú ìṣòro tó ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn fínra. Bí àpẹẹrẹ, jàǹbá, àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó ti sọ àwọn míì di aláìlera. Ìsoríkọ́ ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn kan, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìbẹ̀rù ò jẹ́ káwọn míì gbádùn torí àwọn apániláyà tàbí torí ìwà ipá táwọn kan ti hù sí wọn nígbà kan rí. Síbẹ̀, àwọn míì wà tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ tàbí káwọn kan lára ìdílé wọn má sin Jèhófà. Kò sẹ́ni tí kò níṣòro, èyí tó sì pọ̀ jù nínú àwọn ìṣòro yìí ni kò tíì ṣẹlẹ̀ sí wa rí. Tọ́rọ̀ bá rí báyìí, báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká máa tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ táwọn èèyàn bá ń sọ ìṣòro wọn fún wa títí tá a fi máa lóye bí nǹkan ṣe rí lára wọn déwọ̀n àyè tá a lè lóye rẹ̀ dé. Èyí máa jẹ́ ká lè fìfẹ́ hàn bíi ti Jèhófà, ká sì ṣe ohun tá a fi máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Ohun tí ẹnì kan nílò lè yàtọ̀ sí ti ẹlòmíì, àmọ́ a lè fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí, ká sì pèsè àwọn ìrànwọ́ míì fún wọn.—Ka Róòmù 12:15; 1 Pétérù 3:8.
BÁ A ṢE LÈ JẸ́ ONÍNÚURE BÍI TI JÈHÓFÀ
8. Kí ló jẹ́ kí Jésù lè máa fi inú rere hàn sáwọn èèyàn?
8 Jésù sọ pé: “Ẹni Gíga Jù Lọ . . . jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.” (Lúùkù 6:35) Ó dájú pé Jésù náà jẹ́ onínúure bíi ti Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Jésù máa ń ro bí ọ̀rọ̀ àti ìṣe òun ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì, èyí sì jẹ́ kó tipa bẹ́ẹ̀ fi inúure hàn sáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jésù, ó ń sunkún, ó sì ń fi omijé ojú rẹ̀ rin ẹsẹ̀ Jésù. Jésù fòye mọ̀ pé obìnrin náà ti ronú pìwà dà, ó sì mọ̀ pé òun máa bàá lọ́kàn jẹ́ tí òun bá kanra mọ́ ọn. Torí náà, Jésù yìn ín fún ohun tó ṣe yẹn, ó sì dárí jì í. Kódà nígbà tí Farisí kan kọminú sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, Jésù lo inú rere nígbà tó fún un lésì.—Lúùkù 7:36-48.
9. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi inú rere hàn bíi ti Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
9 Báwo la ṣe lè jẹ́ onínúure bíi ti Jèhófà? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn [tàbí ẹni tó ń fi ọgbọ́n bá gbogbo èèyàn lò].” (2 Tím. 2:24) Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń fòye mọ ohun tó máa ṣe láwọn ipò tó gbẹgẹ́ kó má bàa mú ẹnikẹ́ni bínú. Bí àpẹẹrẹ, wo bó o ṣe lè fi hàn pé o jẹ́ onínúure nínú àwọn ipò tá a fẹ́ sọ yìí: Níbi iṣẹ́, ọ̀gá rẹ ò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́. Kí lo máa ṣe? Arákùnrin kan wá sí ìpàdé fúngbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù. Kí lo máa sọ fún un? Lóde ẹ̀rí, ẹnì kan tó o fẹ́ wàásù fún sọ pé, “Ọwọ́ mi dí gan-an báyìí.” Ṣé o máa gba tiẹ̀ rò? Ọkọ tàbí aya rẹ bi ẹ́ pé, “Kí ló dé tó ò sọ fún mi pé o ti ṣètò ohun tá a máa ṣe lópin ọ̀sẹ̀?” Ṣé wàá fi ohùn pẹ̀lẹ́ dá a lóhùn? Tá a bá ń fi ara wa sípò àwọn ẹlòmíì, tá a sì ń ronú lórí ipa tí ọ̀rọ̀ wa lè ní lórí wọn, èyí á jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká sọ̀rọ̀ ká sì hùwà lọ́nà tó máa fi hàn pé a jẹ́ onínúure bíi ti Jèhófà.—Ka Òwe 15:28.
BÁ A ṢE LÈ MÁA LO ỌGBỌ́N BÍI TI ỌLỌ́RUN
10, 11. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa lo ọgbọ́n bíi ti Ọlọ́run? Sọ àpẹẹrẹ kan.
10 A lè lo ọgbọ́n bíi ti Jèhófà tá a bá ń fọkàn yàwòrán àwọn ohun tí kò tíì ṣẹlẹ̀ sí wa rí, ó sì máa jẹ́ ká lè fòye mọ ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde àwọn ìwà wa. Ọgbọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jèhófà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì lè rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa jẹ́ àbájáde àwọn ìwà tàbí ìṣe kan, ìyẹn tó bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn ò rí ju igimú wa lọ, ó dáa ká máa ro ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ohun tá a fẹ́ ṣe. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ro ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ìwà àìgbọ́ràn tí wọ́n hù sí Ọlọ́run. Mósè mọ̀ pé wọ́n máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, láìka gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn sí. Abájọ tó fi sọ ọ̀rọ̀ orin yìí níwájú gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Orílẹ̀-èdè kan tí ìmọ̀ràn ń ṣègbé lé lórí ni wọ́n, Kò sì sí òye kankan láàárín wọn. Ì bá ṣe pé wọ́n gbọ́n! Nígbà náà, wọn ì bá fẹ̀sọ̀ ronú lórí èyí. Wọn ì bá ronú nípa òpin wọn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Diu. 31:29, 30; 32:28, 29.
11 Ká lè fi hàn pé à ń lo ọgbọ́n bíi ti Ọlọ́run, ó máa dáa tá a bá ń ronú lórí ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde ìwà wa tàbí ká fọkàn yàwòrán rẹ̀ pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ní àfẹ́sọ́nà, a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé òòfà ìbálòpọ̀ lágbára. Ẹ má ṣe jẹ́ ká ṣèpinnu èyíkéyìí tó máa fi àjọṣe iyebíye tó wà láàárín àwa àti Jèhófà sínú ewu tàbí ká ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe náà jẹ́! Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ, ó ní: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 22:3.
ṢỌ́RA FÚN ÈRÒ TÓ LÈ PANI LÁRA
12. Irú èrò wo ló lè pa wá lára?
12 Afọgbọ́nhùwà mọ̀ pé ìrònú èèyàn lè dà bí iná. Téèyàn bá lo iná bó ṣe yẹ, ó máa ń wúlò, bí àpẹẹrẹ a lè fi iná se oúnjẹ. Àmọ́, iná lè fa jàǹbá tá ò bá lò ó lọ́nà tó tọ́, ó lè jó ilé kan run, kó sì pa àwọn tó wà níbẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá ń ronú lọ́nà tó tọ́, èyí lè jẹ́ ká fìwà jọ Jèhófà. Àmọ́ o, tá a bá ń ro èrò tí kò tọ́, ó lè pa wá lára. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa ronú lórí ohun tó lè múni dẹ́ṣẹ̀, èyí lè sún wa débi tá a fi máa ṣe ohun tá à ń rò lọ́kàn. Àní sẹ́, èrò tí kò tọ́ lè pa àjọṣe àwa àti Jèhófà lára!—Ka Jákọ́bù 1:14, 15.
13. Irú ìgbésí ayé wo ló ṣeé ṣe kí Éfà máa fojú inú yàwòrán?
13 Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wu Éfà tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́, pé kó jẹ nínú èso “igi ìmọ̀ rere àti búburú” tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ fún wọn. (Jẹ́n. 2:16, 17) Ejò náà sọ fún un pé: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Éfà “rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni.” Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? “Ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.” (Jẹ́n. 3:1-6) Lójú Éfà, ó rí ohun kan tó mọ́gbọ́n dání nínú ọ̀rọ̀ tí Sátánì bá a sọ. Éfà fúnra rẹ̀ ló máa pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, kò sẹ́ni tó máa pinnu fún un. Ẹ ò rí i pé irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu gan an! Torí pé ọkọ Éfà, ìyẹn Ádámù dẹ́ṣẹ̀, “ẹ̀ṣẹ̀ . . . wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
14. Báwo ni Bíbélì ṣe ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣọ́ra fún ìwà àìtọ́?
14 Éfà kò dá ẹ̀ṣẹ̀ ìṣekúṣe nínú ọgbà Édẹ́nì. Àmọ́, Jésù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe máa ro ohun tó lè mú kí ọkàn wa fà sí ìṣekúṣe. Ó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mát. 5:28) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ẹ má sì máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.”—Róòmù 13:14.
15. Irú àwọn ìṣúra wo ló yẹ ká fi pa mọ́, kí sì nìdí?
15 Èrò míì tó léwu tó sì yẹ ká yẹra fún ni kéèyàn máa ronú bó ṣe máa dolówó rẹpẹtẹ, èyí ò sì ní jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ ráyè gbọ́ ti Ọlọ́run. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, àwọn nǹkan tó níye lórí tí ọlọ́rọ̀ kan ní “dà bí ògiri adáàbòboni nínú èrò-ọkàn rẹ̀.” (Òwe 18:11) Jésù sọ ìtàn kan tó fi ṣàpèjúwe ìbànújẹ́ tó máa bá ẹnì kan “tí ó bá ń to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:16-21) Inú Jèhófà máa ń dùn tá a bá ṣe ohun tó fẹ́. (Òwe 27:11) Ẹ ò rí i pé inú wa máa dùn gan-an tá a bá rójú rere Ọlọ́run torí pé a to “ìṣúra” jọ pa mọ́ fún ara wa ní “ọ̀run”! (Mát. 6:20) Láìsí àní-àní, àjọṣe tó dán mọ́rán tó wà láàárín àwa àti Jèhófà ni ìṣúra tó ṣeyebíye jù lọ tá a lè ní.
BÁ A ṢE LÈ DÍN ÀNÍYÀN WA KÙ
16. Sọ ọ̀nà kan tí a lè gbà dín àníyàn wa kù.
16 Ẹ fojú inú yàwòrán bí àníyàn ṣe máa bò wá mọ́lẹ̀ tó, tá a bá ń forí ṣe fọrùn ṣe torí ká lè to “ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara [wa] lórí ilẹ̀ ayé.” (Mát. 6:19) Jésù sọ àpèjúwe kan tó fi hàn pé “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀” lè fún ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run pa lọ́kàn wa. (Mát. 13:18, 19, 22) Yálà à ń ṣàníyàn pé a fẹ́ lówó tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn kan wà tó jẹ́ pé nǹkan burúkú ni wọ́n máa ń fọkàn rò ṣáá. Àmọ́ tá a bá ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ, ó lè kó bá ìlera wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká má sì gbàgbé pé “àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Ọ̀rọ̀ ìṣírí tẹ́nì kan tó lóye wa dáadáa sọ fún wa lè mú kí ayọ̀ kúnnú ọkàn wa. Àníyàn wa lè dín kù tá a bá ń finú han àwọn òbí wa, ọkọ tàbí ìyàwó wa tàbí ọ̀rẹ́ wa kan tá a fọkàn tán tó máa ń fojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan wò ó.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè dín àníyàn kù?
17 Kò sẹ́lòmíì tó mọ àníyàn ọkàn wa tó Jèhófà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílí. 4:6, 7) Ó ṣe tán, a láwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, àwọn alàgbà, ẹrú olóòótọ́, àwọn áńgẹ́lì, Jésù àti Jèhófà tí wọ́n ń dáàbò bò wá kí àjọṣe àwa àti Jèhófà má bàa bà jẹ́.
18. Báwo ni èrò tó tọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
18 Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, èrò tó tọ́ lè jẹ́ ká máa fìfẹ́ hàn bíi ti Ọlọ́run. (1 Tím. 1:11; 1 Jòh. 4:8) A máa ní ayọ̀ tá a bá ń fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, tá à ń ronú lórí àbájáde àwọn ìwà wa, tá a sì ń yẹra fún àníyàn tó lè mú ká pàdánù ayọ̀ wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa lo ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa tó jẹ́ ká lè fọkàn yàwòrán ìrètí tá a máa rí gbà lọ́jọ́ iwájú, ká sì máa ní ìfẹ́, inú rere, ọgbọ́n àti ayọ̀ bíi ti Jèhófà.—Róòmù 12:12.