Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Sún Mọ́ Wa

Àwọn Ọ̀nà Tí Jèhófà Gbà Ń Sún Mọ́ Wa

“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁK. 4:8.

1. Kí ló máa ń wu àwa èèyàn pé ká ní, ta ló sì lè fún wa lóhun tó wù wá náà?

Ó MÁA ń wu àwa èèyàn gan-an pé ká ní àwọn tá a jọ sún mọ́ra. A máa ń sọ pé àwọn kan sún mọ́ ara wọn tá a bá rí i pé wọ́n fẹ́ràn ara wọn gan-an, tí wọ́n sì mọwọ́ ara wọn dáadáa. A sábà máa ń ṣìkẹ́ àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn ẹbí wa àtàwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n mọyì wa, tí ọ̀rọ̀ wa sì yéra dáadáa. Àmọ́, nínú gbogbo àwọn yìí, Ẹlẹ́dàá wa ló yẹ ká sún mọ́ jù lọ.—Oníw. 12:1.

2. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún wa, àmọ́ kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi gbà pé ó ṣeé ṣe?

2 Jèhófà rọ̀ wá nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ká “sún mọ́” òun, ó sì ṣèlérí fún wa pé tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun náà ‘yóò sún mọ́’ wa. (Ják. 4:8) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn ronú pé ó wu Ọlọ́run láti sún mọ́ òun; wọ́n rò pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó lè sún mọ́ ọn àti pé ó jìnnà jù fáwọn láti dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ lóòótọ́ ló ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run?

3. Kí ni òótọ́ pọ́ńbélé kan tá a gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà?

3 Òótọ́ pọ́ńbélé kan ni pé Jèhófà “kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan” tó fẹ́ mọ̀ ọ́n, torí náà èèyàn lè mọ Ọlọ́run. (Ka Ìṣe 17:26, 27;  Sáàmù 145:18.) Kódà, Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ̀dá èèyàn aláìpé sún mọ́ òun, kì í ṣe pé ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ nìkan, ó tún wù ú láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísá. 41:8; 55:6) Onísáàmù kan sọ nípa Jèhófà látinú ohun tí òun fúnra rẹ̀ ti rí pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá. Aláyọ̀ ni ẹni tí ìwọ yàn, tí ìwọ sì mú kí ó tọ̀ ọ́ wá.” (Sm. 65:2, 4) Ìtàn Ásà Ọba Júdà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kéèyàn sún mọ́ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà ṣe. *

KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÁWỌN ÈÈYÀN ÌGBÀANÌ

4. Àpẹẹrẹ wo ni Ásà Ọba fi lélẹ̀ fáwọn èèyàn Júdà?

4 Ásà Ọba fi hàn pé òun ní ìtara gan-an fún ìjọsìn tòótọ́. Ó mú iṣẹ́ kárùwà kúrò nínú tẹ́ńpìlì, ó tún mú ìbọ̀rìṣà tó ti gbalẹ̀ gbòde ní orílẹ̀-èdè náà kúrò. (1 Ọba 15:9-13) Ẹnu rẹ̀ gbà á láti rọ àwọn èèyàn pé “kí wọ́n wá Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn, kí wọ́n sì pa òfin àti àṣẹ mọ́.” Jèhófà fi àlàáfíà jíǹkí ọdún mẹ́wàá àkọ́kọ́ ìgbà ìjọba Ásà. Ta ni Ásà fi ògo àlàáfíà tó ní yẹn fún? Ó sọ fáwọn èèyàn náà pé: “Ilẹ̀ náà ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa, nítorí pé a ti wá Jèhófà Ọlọ́run wa. A ti wá a, ó sì fún wa ní ìsinmi yí ká.” (2 Kíró. 14:1-7) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e.

5. Kí ló ṣẹlẹ̀ tó dán ìgbẹ́kẹ̀lé Ásà nínú Ọlọ́run wò, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?

5 Jẹ́ ká sọ pé ìwọ ló wà nípò Ásà. Síírà ará Etiópíà kó àádọ́ta ọ̀kẹ́ [1,000,000] ọkùnrin àti ọ̀ọ́dúnrún [300] kẹ̀kẹ́ ẹṣin wá kí wọ́n lè gbógun ja Júdà. (2 Kíró. 14:8-10) Kí lo máa ṣe bó o ṣe gbójú sókè tó o rí ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ ọmọ ogún tí wọ́n ya wọ ilẹ̀ rẹ? Ìwọ rèé tó ò ní ju ọmọ ogun ọ̀kẹ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [580,000] lọ! Lédè míì, àwọn ọmọ ogun yìí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì tìrẹ. Ǹjẹ́ o ò ní máa rò ó pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Ṣé wàá tìtorí pé wàhálà ti bẹ́ sílẹ̀ báyìí kó o wá fẹ́ lo ọgbọ́n tara rẹ láti fi wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà? Ohun tí Ásà ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé ó sún mọ́ Jèhófà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Ó gbàdúrà tọkàntọkàn pé: “Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, nítorí ìwọ ni a gbára lé, orúkọ rẹ sì ni a fi dojú kọ ogunlọ́gọ̀ yìí. Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run wa. Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú ní okun láti dojú kọ ọ́.” Kí ni Ọlọ́run ṣe sí àdúrà àtọkànwá tí Ásà gbà yìí? Bíbélì sọ pé, “Jèhófà ṣẹ́gun àwọn ará Etiópíà.” Gbogbo àwọn ọ̀tá náà pátá ló bógun yẹn lọ!—2 Kíró. 14:11-13.

6. Kí ni Ásà ṣe tó jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa?

6 Kí ló mú kí Ásà gbára lé ìtọ́sọ́nà àti ààbò Ọlọ́run pátápátá? Bíbélì sọ pé, “Ásà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà” àti pé “ọkàn-àyà [rẹ̀] wà ní pípé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà.” (1 Ọba 15:11, 14) Àwa náà gbọ́dọ̀ máa fi ọkàn tó pé pérépéré sin Ọlọ́run. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà lo ìdánúṣe láti fà wá sún mọ́ ara rẹ̀, tó jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ ká sì tún máa ṣìkẹ́ àjọṣe náà! Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tí Ọlọ́run gbà ṣe èyí.

JÈHÓFÀ TI FÀ WÁ SÚN MỌ́ ARA RẸ̀ NÍPASẸ̀ ÌRÀPADÀ

7. (a) Kí ni Jèhófà ti ṣe tó jẹ́ ká lè sún mọ́ ọn? (b) Ọ̀nà tó ta yọ jù lọ wo ni Ọlọ́run gbà fà wá sún mọ́ ara rẹ̀?

7 Ayé tó dára rèǹtèrente tí Jèhófà dá fún wa yìí fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ ìran èèyàn. Ó ń jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa nípa bó ṣe ń pèsè oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì fún wa kó lè máa gbé ẹ̀mí wa ró. (Ìṣe 17:28;  Ìṣí. 4:11) Àmọ́, ní pàtàkì jù lọ, Jèhófà ń bójú tó wa nípa tẹ̀mí. (Lúùkù 12:42) Ó tún fi dá wa lójú pé, tá a bá gbàdúrà sí òun, òun fúnra òun máa gbọ́ àdúrà wa. (1 Jòh. 5:14) Àmọ́, ọ̀nà tó ta yọ jù lọ tí Ọlọ́run gbà fà wá sún mọ́ ara rẹ̀ táwa náà sì sún mọ́ ọn ni ìfẹ́ tó fi hàn sí wa nípasẹ̀ ìràpadà. (Ka 1 Jòhánù 4:9, 10, 19.) Jèhófà rán “Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo” sí ayé ká lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Jòh. 3:16.

8, 9. Ipa wo ni Jésù ń kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ?

8 Jèhófà ti mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó gbé láyé kí Jésù tó wá sáyé láti jàǹfààní nínú ìràpadà náà. Gbàrà tí Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Olùgbàlà kan tó ń bọ̀ wá gba aráyé là ló ti dà bíi pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti ṣẹ lójú rẹ̀, torí ó mọ̀ pé ohun tí òun fẹ́ ṣe kò lè kùnà láé. (Jẹ́n. 3:15) Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún “ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” Ó wá fi kún un pé: “Nítorí òun ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì nígbà tí Ọlọ́run ń lo ìmúmọ́ra.” (Róòmù 3:21-26) Ẹ ò rí i pé ipa pàtàkì ni Jésù kó nínú bá a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run!

9 Ipasẹ̀ Jésù nìkan ni àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn fi lè mọ Jèhófà, tí wọ́n á sì láǹfààní láti sún mọ́ ọn tímọ́tímọ́. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe já ká mọ òtítọ́ yìí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:6-8) Ọlọ́run pèsè ẹbọ ìràpadà Jésù fún wa torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, kì í ṣe torí pé a lẹ́tọ̀ọ́ sí i. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” Ó tún sọ nígbà kan pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòh. 6:44; 14:6) Jèhófà ń lo ẹ̀mí mímọ́ láti fa àwọn èèyàn sún mọ́ ara rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù. Ó tún ń jẹ́ kí wọ́n lè dúró nínú ìfẹ́ òun bí wọ́n ṣe ń fojú sọ́nà fún ìyè àìnípẹkun. (Ka Júùdà 20, 21.) Ẹ jẹ́ ká tún wo ọ̀nà míì tí Jèhófà fi ń fà wá sún mọ́ ara rẹ̀.

JÈHÓFÀ FÀ WÁ SÚN MỌ́ ARA RẸ̀ NÍPASẸ̀ Ọ̀RỌ̀ RẸ̀ TÓ WÀ LÁKỌỌ́LẸ̀

10. Kí la kọ́ nínú Bíbélì tó jẹ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?

10 Láti ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí títí débi tá a dé yìí, ìwé mẹ́rìnlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ látinú Bíbélì la ti fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ tàbí tá a ti tọ́ka sí. Ká ní kò sí Bíbélì ni, báwo ni a bá ṣe mọ̀ pé a lè sún mọ́ Ẹlẹ́dàá wa? Láìsí Bíbélì, báwo là bá ṣe kọ́ nípa ìràpadà? Báwo là bá sì ṣe mọ̀ pé a lè sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ Jésù? Jèhófà lo ẹ̀mí rẹ̀ láti mí sí àwọn tó kọ Bíbélì. Bíbélì ló jẹ́ ká mọ ànímọ́ rẹ̀ tó fani mọ́ra àti ọ̀pọ̀ ohun rere tó pinnu láti ṣe fún wa. Bí àpẹẹrẹ, nínú Ẹ́kísódù 34:6, 7, Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ fún Mósè pé òun jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́, ó ń pa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, ó ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” Ta ni kò ní fẹ́ sún mọ́ irú ẹni yìí? Jèhófà mọ̀ pé bá a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun nínú Bíbélì, bẹ́ẹ̀ làá máa mọ òun sí i, á sì máa wù wá láti túbọ̀ sún mọ́ òun.

11. Kí nìdí tó fi yẹ ká sapá láti mọ àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àtàwọn ọ̀nà rẹ̀? (Wo àwòrán tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

11 Ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ṣàlàyé ohun tá a lè ṣe tá a bá fẹ́ sún mọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́, ó ní: “Kí á tó lè dọ̀rẹ́ ẹnì kan, a ó ti kọ́kọ́ mọ onítọ̀hún, ìwà àti ìṣe rẹ̀ yóò sì wù wá gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣèwádìí nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe fi hàn.” Ẹ ò rí i bí ọpẹ́ wa ti pọ̀ tó pé Jèhófà mú kí wọ́n kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà táwa èèyàn fi lè lóye rẹ̀!

12. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àwọn èèyàn ni Jèhófà lò láti kọ Bíbélì?

 12 Jèhófà lè lo àwọn áńgẹ́lì láti kọ Ìwé Mímọ́. Ó ṣe tán, ó máa ń wù wọ́n láti mọ̀ nípa wa àti nípa àwọn nǹkan tá à ń ṣe. (1 Pét. 1:12) Ó dájú pé tí Ọlọ́run bá lo àwọn áńgẹ́lì láti kọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ fáwọn èèyàn, kò ní sí àṣìṣe kankan níbẹ̀. Àmọ́, ṣé bí nǹkan ṣe máa ń rí lára èèyàn ló ṣe máa ń rí lára àwọn áńgẹ́lì? Ṣé wọ́n máa lóye ohun táwa èèyàn fẹ́? Ṣé wọ́n á mọ ibi tá a kù sí àtàwọn nǹkan tó máa ń wù wá? Wọn ò lè mọ̀ ọ́n, Jèhófà náà sì mọ̀ pé àwọn nǹkan kan wà tí wọn ò mọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, bí Jèhófà ṣe lo àwọn èèyàn láti kọ Bíbélì, ṣe ló mú kó dà bíi pé àwa ni wọ́n dìídì kọ ọ́ sí. Èyí jẹ́ ká lóye bí àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn míì tá a sọ̀rọ̀ wọn nínú Bíbélì ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe rí lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí a bá ń kà nípa ìjákulẹ̀ tí wọ́n ní, nípa bí wọ́n ṣe ṣiyèméjì, tí wọ́n ń bẹ̀rù àti nígbà tí àìpé mú kí wọ́n ṣe àwọn àṣìṣe kan, àwa náà lè mọ̀ ọ́n lára. Bákan náà, inú tiwa náà máa ń dùn nígbà tí a bá kà nípa nǹkan ayọ̀ tó ẹlẹ̀ sí wọn àti àṣeyọrí tí wọ́n ṣe. Bíi ti wòlíì Èlíjà, gbogbo àwọn tó kọ Bíbélì ló ní “ìmọ̀lára bí tiwa.”—Ják. 5:17.

Báwo ni ọwọ́ tí Jèhófà fi mú Jónà àti Pétérù ṣe mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? (Wo ìpínrọ̀  13 àti 15)

13. Báwo ni àdúrà tí Jónà gbà ṣe rí lọ́kàn rẹ?

13 Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ti Jónà, ǹjẹ́ áńgẹ́lì á lè ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí nǹkan ṣe rí lára Jónà nígbà tó sá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un. Ẹ ò rí i pé ó dáa gan-an bí Jèhófà ṣe lo Jónà láti kọ ìtàn ara rẹ̀ sílẹ̀, títí kan àdúrà àtọkànwá tó gbà sí Ọlọ́run nísàlẹ̀ òkun lọ́hùn-ún! Jónà sọ pé: “Nígbà tí àárẹ̀ mú ọkàn mi nínú mi, Jèhófà ni Ẹni tí mo rántí.”—Jónà 1:3, 10; 2:1-9.

14. Kí nìdí tí ohun tí Aísáyà kọ nípa ara rẹ̀ ṣe rọrùn fún wa láti lóye?

14 Ẹ jẹ́ ká tún wo ohun tí Jèhófà lo Aísáyà láti kọ nípa ara rẹ̀. Lẹ́yìn tí wòlíì  náà rí ògo Ọlọ́run nígbà kan, ó yà á lẹ́nu gan-an débi tó fi sọ nípa àìpé tirẹ̀ pé: “Mo gbé! Nítorí, kí a sáà kùkù sọ pé a ti pa mí lẹ́nu mọ́, nítorí pé ọkùnrin aláìmọ́ ní ètè ni mí, àárín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ètè sì ni mo ń gbé; nítorí pé ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!” (Aísá. 6:5) Áńgẹ́lì wo ni nǹkan máa jọ lójú débi tá a fi sọ irú ọ̀rọ̀ yẹn? Àmọ́ Aísáyà sọ ọ́ torí ohun tí ojú rẹ̀ rí, àwa náà sì lè mọ bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀.

15, 16. (a) Kí nìdí tó fi rọrùn fún wa láti lóye bí nǹkan ṣe rí lara àwọn èèyàn bíi tiwa? Sọ àwọn àpẹẹrẹ. (b) Kí ló máa jẹ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

15 Jékọ́bù sọ nígbà kan pé òun “kò yẹ” lẹ́ni tó ń rí ojú rere Ọlọ́run, Pétérù náà sọ pé “ẹlẹ́ṣẹ̀” lòun. Ǹjẹ́ áńgẹ́lì èyíkéyìí lè sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí? (Jẹ́n. 32:10; Lúùkù 5:8) Ṣé ‘ẹ̀rù máa bà wọ́n’ bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tàbí ṣé àwọn áńgẹ́lì olódodo máa nílò láti ṣe bíi ti Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì tí wọ́n “máyàle” lójú inúnibíni torí kí wọ́n lè wàásù ìhìn rere? (Jòh. 6:19; 1 Tẹs. 2:2) Rárá o, torí ẹ̀dá pípé ni àwọn áńgẹ́lì, agbára wọn sì ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì. Àmọ́, kíákíá ló máa yé wa tí èèyàn aláìpé bá sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ yẹn nípa ara rẹ̀, ìdí sì ni pé èèyàn ẹlẹ́ran ara làwa náà. Ó dájú pé tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè ‘yọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń yọ̀; a sì lè sunkún pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí ń sunkún.’—Róòmù 12:15.

16 Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ọwọ́ tí Jèhófà fi mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ ìgbà àtijọ́, a máa kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan rere nípa Ọlọ́run wa. A máa rí bó ṣe fi sùúrù àti ìfẹ́ sún mọ́ àwọn èèyàn yẹn, bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. Àá tipa bẹ́ẹ̀ mọ Jèhófà dunjú, àá sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Èyí sì máa jẹ́ ká lè túbọ̀ sún mọ́ ọn.—Ka Sáàmù 25:14.

NÍ ÀJỌṢE TÍMỌ́TÍMỌ́ PẸ̀LÚ ỌLỌ́RUN

17. (a) Ìmọ̀ràn rere wo ni Asaráyà fún Ásà? (b) Báwo ni Ásà ṣe kọ etí dídi sí ìmọ̀ràn Asaráyà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

17 Lẹ́yìn tí Ásà Ọba borí àwọn ọmọ ogun Etiópíà nínú ogun ńlá kan, wòlíì Ọlọ́run kan tó ń jẹ́ Asaráyà sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún Ásà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Asaráyà sọ pé: “Jèhófà wà pẹ̀lú yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà pẹ̀lú rẹ̀; bí ẹ bá sì wá a, òun yóò jẹ́ kí ẹ rí òun, ṣùgbọ́n bí ẹ bá fi í sílẹ̀, òun yóò fi yín sílẹ̀.” (2 Kíró. 15:1, 2) Àmọ́ nígbà tó yá, Ásà kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yẹn mọ́. Nígbà tí ìjọba Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá tí wọ́n jọ ń figa gbága halẹ̀ mọ́ ọn, Ásà sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Ásíríà pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Dípò kí Ásà ké pe Jèhófà, ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí ló wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi rán wòlíì Hánánì kó lọ sọ fún un pé: “Ìwọ ti hùwà òmùgọ̀ nípa èyí, nítorí, láti ìsinsìnyí lọ ogun yóò máa jà ọ́.” Ogun kan tẹ̀ lé òmíràn ni Ásà fi èyí tó kù nínú ọdún tó fi ṣàkóso jà. (2 Kíró. 16:1-9) Kí la kọ́ nínú èyí?

18, 19. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá rí i pé àlàfo ti fẹ́ máa wà láàárín àwa àti Ọlọ́run? (b) Báwo la ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

18 Ẹ má ṣe jẹ́ ká sún kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà láé. Tá a bá rí i pé àlàfo ti ń wà láàárín àwa àti Ọlọ́run, ńṣe ni ká yá a ṣe ohun tí Hóséà 12:6 sọ, ó ní: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ ni kí o padà sí, ní pípa inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mọ́; kí o sì máa ní ìrètí nínú Ọlọ́run rẹ nígbà gbogbo.” Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà pẹ́kípẹ́kí nípa ríronú jinlẹ̀ lórí ìràpadà, ká sì máa fi taratara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé.—Ka Diutarónómì 13:4.

19 Onísáàmù kan sọ pé: “Sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” (Sm. 73:28) Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa túbọ̀ máa kọ́ ohun tuntun nípa Jèhófà, ká sì mọrírì ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó ti ṣe fún wa tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ máa fà wá sún mọ́ ara rẹ̀ nísinsìnyí àti títí láé!

^ ìpínrọ̀ 3 Wo àpilẹ̀kọ kan tó sọ nípa Ásà, àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ẹ̀san Wà fún Ìgbòkègbodò Yín” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 2012.