Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

‘Ìkórè Ṣì Pọ̀’

‘Ìkórè Ṣì Pọ̀’

George Young dé sí ìlú Rio de Janeiro ní oṣù March ọdún 1923

NÍ ỌDÚN 1923, gbọ̀ngàn ijó tó wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Eré àti Orin ní ìlú São Paulo kún fọ́fọ́! Ṣé ò ń gbọ́ bí George Young ṣe ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀? Bó ṣe ń sọ àsọyé náà lẹnì kan ń túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Potogí. Gbogbo ẹgbẹ̀ta ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [585] èèyàn tó wà níbẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Wọ́n ń lo ẹ̀rọ kan láti fi àwọn ẹsẹ Bíbélì hàn lára ògiri ní èdè Potogí. Nígbà tí wọ́n máa kágbá ètò yẹn nílẹ̀, ẹ̀dà ọgọ́rùn-ún ìwé pẹlẹbẹ tó ní àkòrí náà Millions Now Living Will Never Die! ni wọ́n pín, wọ́n sì tún pín àwọn ẹ̀dà rẹ̀ tó wà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, èdè Jámánì àti èdè Ítálì. Àsọyé yẹn kẹ́sẹ járí, òkìkí rẹ̀ sì kàn! Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹta, ṣe ni gbọ̀ngàn yẹn tún kún fọ́fọ́ torí wọ́n fẹ́ gbọ́ àsọyé míì. Àmọ́ kí ló mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn wáyé?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ní ọdún 1867, obìnrin kan tó ń jẹ́ Sarah Bellona Ferguson àti ìdílé rẹ̀ kó kúrò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ sí orílẹ̀-èdè Brazil. Àmọ́, nígbà tó di ọdún 1899, àbúrò rẹ̀ ọkùnrin wá kí i láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ó sì kó àwọn ìwé kan tó ṣàlàyé Bíbélì dání. Lẹ́yìn tí Sarah ka àwọn ìwé yìí, ó gbà lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun ti rí òtítọ́. Nítorí pé ó kúndùn ìwé kíkà, ó san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ohun tó rí kà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà wú u lórí débi tó fi kọ̀wé sí Arákùnrin C. T. Russell, tó sì tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀rí tó fi hàn pé bí èèyàn bá tiẹ̀ ń gbé ibi tó jìnnà, ìyẹn ò ní kí ìhìn rere máà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.”

Can the Living Talk With the Dead? (lédè Potogí)

Sarah Ferguson ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti ṣàlàyé ohun tó wà nínú Bíbélì fún àwọn èèyàn, àmọ́ ó máa ń ṣàníyàn pé ta ló máa ran òun, ìdílé òun àtàwọn ẹniire tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ òtítọ́. Ní ọdún 1912, wọ́n ta á lólobó láti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn pé ẹnì kan ń bọ̀ wá sí ìlú São Paulo pẹ̀lú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìléwọ́ náà, Where Are the Dead? tí wọ́n ti túmọ̀ sí èdè Potogí. Ní ọdún 1915, ó sọ pé ó sábà máa ń ya òun lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń retí láti lọ sí ọ̀run láìpẹ́. Ló bá kọ̀wé láti sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀. Ó ní: “Àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil àti gbogbo àwọn tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù ńkọ́? . . . Tẹ́ ẹ bá ronú lórí bí Amẹ́ríkà ti Gúúsù ṣe tóbi tó, á jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé ìkórè ṣì pọ̀ láti ṣe.” Òótọ́ sì ni, ìkórè ṣì pọ̀ tí wọ́n máa ṣe!

 Ní nǹkan bí ọdún 1920, àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Brazil mẹ́jọ kan tí wọ́n jẹ́ awakọ̀ ojú omi lọ sí ìpàdé ìjọ lọ́jọ́ mélòó kan ní ìlú New York City, lásìkò tí wọ́n ń bá wọn tún ọkọ̀ tí wọ́n fi ń jagun ṣe. Nígbà tí wọ́n pa dà sí ìlú Rio de Janeiro, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun tí wọ́n kọ́ látinú Bíbélì fún àwọn èèyàn. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìyẹn ní March ọdún 1923, George Young tó jẹ́ arìnrìn-àjò ìsìn tàbí alábòójútó arìnrìn àjò dé sí ìlú Rio de Janeiro, ó sì rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Ó ṣètò kan tó mú kí wọ́n tú ọ̀pọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè Potogí. Kò pẹ́ lẹ́yìn yẹn tí Arákùnrin Young tún fi rìnrìn àjò lọ sí ìlú São Paulo, níbi tí àwọn èèyàn bí ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ [600,000] ń gbé nígbà yẹn. Ibẹ̀ ló ti sọ àsọyé tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí tó sì tún pín ìwé pẹlẹbẹ náà, Millions Now Living Will Never Die! Ó sọ pé: “Torí pé ó jẹ́ èmi nìkan, ìwé ìròyìn ni mo fi máa ń polówó àsọyé tí mo bá máa sọ.” Ó wá fi kún un pé, èyí ni “àsọyé tí a kọ́kọ́ fi orúkọ wa náà, I.B.S.A. polówó ní orílẹ̀-èdè Brazil.” *

Wọ́n máa ń lo ẹ̀rọ láti fi àwọn ẹsẹ Bíbélì hàn lára ògiri nígbà tí Arákùnrin Young bá ń sọ àsọyé

Nígbà tí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ December 15, 1923 [Gẹ̀ẹ́sì], ń sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè Brazil, ó sọ pé: “Tá a bá rántí pé ọjọ́ kìíní nínú oṣù June ni iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀ àti pé kò sí ìtẹ̀jáde kankan nígbà yẹn, ó jẹ́ ohun àgbàyanu bí Olúwa ti ṣe bù kún iṣẹ́ náà.” Ìròyìn yẹn tún sọ síwájú sí i pé nínú àsọyé mọ́kànlélógún [21] tí Arákùnrin Young sọ ní June 1 sí September 30, méjì péré ló wáyé ní ìlú São Paulo, àwọn tó gbọ́ àsọyé náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [3,600]. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni ìhìn rere Ìjọba náà bẹ̀rẹ̀ sí í dé etígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn ìlú Rio de Janeiro nílé lóko. Àti pé láàárín oṣù díẹ̀, wọ́n ti pín àwọn ìtẹ̀jáde wa tó lé ní ẹgbẹ̀rún méje lédè Potogí! Ní àfikún sí ìyẹn, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Potogí látorí ẹ̀dà ti November-December 1923.

Sarah Bellona Ferguson, ẹni tó kọ́kọ́ san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ti èdè Gẹ̀ẹ́sì ní orílẹ̀-èdè Brazil

Arákùnrin George Young wá lọ bẹ obìnrin tó ń jẹ́ Sarah Ferguson wò, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sì sọ pé: “Nígbà tí arábìnrin náà kọ́kọ́ wọ pálọ̀ níbi tí arákùnrin Young jókòó sí, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un. Ló bá gbá ọwọ́ Arákùnrin Young mú, ó sì tẹjú mọ́ ọn, lẹ́yìn náà ló wá sọ pé: ‘Ṣé pé arìnrìn-àjò ìsìn ni mò ń wò lójúkojú yìí?’” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí òun àti àwọn kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ ṣèrìbọmi. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sẹ́yìn ló ti yẹ kó ṣèrìbọmi! Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ August 1, ọdún 1924 sọ pé àádọ́ta [50] làwọn tó ṣèrìbọmi ní orílẹ̀-èdè Brazil, pàápàá jù lọ ní ìlú Rio de Janeiro.

Ní báyìí, lẹ́yìn nǹkan bí àádọ́rùn-ún [90] ọdún, kò yẹ ká tún ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè pé: “Àwọn èèyàn tó wà ní orílẹ̀-èdè Brazil àti gbogbo àwọn tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù ńkọ́?” Àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì [760,000] ló ń wàásù ìhìn rere náà ní orílẹ̀-èdè Brazil. Jákèjádò Amẹ́ríkà ti Gúúsù ni wọ́n ń fi èdè Potogí, Sípáníìṣì àtàwọn èdè ìbílẹ̀ míì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Òótọ́ ni ohun tí Sarah Ferguson sọ lọ́dún 1915, ‘Ìkórè ṣì pọ̀.’—Látinú àpamọ́ wa ní orílẹ̀-èdè Brazil.

^ ìpínrọ̀ 6 I.B.S.A. dúró fún International Bible Students Association, ìyẹn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé.