Má Ṣe “Kún Fún Ìhónú Sí Jèhófà”
“Ìwà òmùgọ̀ ará ayé ni ó lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po, ọkàn-àyà rẹ̀ sì wá di èyí tí ó kún fún ìhónú sí Jèhófà.”—ÒWE 19:3.
1, 2. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá Jèhófà lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro aráyé? Ṣàpèjúwe.
KÁ SỌ pé ó ti pẹ́ gan-an tó o ti ṣègbéyàwó, ìwọ àtìyàwó rẹ sì mọwọ́ ara yín dáadáa. Àmọ́, lọ́jọ́ kan, nígbà tó o délé, ńṣe lo rí i pé gbogbo nǹkan tó wà nínú ilé ló ti dojú dé, àwọn àga ti bà jẹ́, àwọn àwo ti fọ́, kápẹ́ẹ̀tì sì ti ba jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ilé tọ́kàn rẹ ti máa ń balẹ̀ wá dà bí ibi tí ogún ti jà. Ṣé wàá fìbínú sọ pé, “Kí ló dé tíyàwó mi fi ṣerú nǹkan báyìí?” Àbí ńṣe lo máa béèrè pé, “Ta ló dán irú eléyìí wò?” Ó dájú pé ìbéèrè kejì yìí lo máa béèrè. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìbéèrè kejì yìí ló máa wá sí ẹ lọ́kàn? Torí o mọ̀ pé ìyàwó rẹ àtàtà kò lè hu ìwà bàsèjẹ́ yìí.
2 Ayé tá a wà yìí ti bà jẹ́ gan-an ni. Lára nǹkan tó sì sọ ayé yìí dìdàkudà ni ìbàyíkájẹ́, ìwà ipá àti ìṣekúṣe. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé láé, kò lè jẹ́ Jèhófà ló fa àwọn ìṣòro yìí. Ńṣe ló fẹ́ kí gbogbo ayé yìí pátá jẹ́ ibi ìtura tàbí Párádísè. (Jẹ́n. 2:8, 15) Ọlọ́run ìfẹ́ ni Jèhófà. (1 Jòh. 4:8) Ẹ̀kọ́ Bíbélì tá a kọ́ ti jẹ́ ká mọ ìdí náà gan-an tí ojú fi ń pọ́n aráyé. Ìyà tó n jẹ aráyé kò ṣẹ̀yìn Sátánì Èṣù, “olùṣàkóso ayé.”—Jòh. 14:30; 2 Kọ́r. 4:4.
3. Kí ló lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tí kò tọ́?
3 Àmọ́ ṣá o, a ò lè di ẹ̀bi gbogbo ìṣòro wa ru Sátánì. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó lè jẹ́ àṣìṣe tiwa fúnra wa ló fa àwọn ìṣòro kan tó ń bá wa fínra. (Ka Diutarónómì 32:4-6.) A lè gbà pé lóòótọ́ la máa ń ṣàṣìṣe, àmọ́ torí pé a jẹ́ aláìpé, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lọ́nà tí kò tọ́ nípa ìṣòro wa, èyí sì léwu gan-an. (Òwe 14:12) Èrò tí kò tọ́ wo la lè ní? A lè bẹ̀rẹ̀ sí í dá Jèhófà lẹ́bi nítorí àwọn ìṣòro wa dípò tá a fi máa dá ara wa tàbí Sátánì lẹ́bi. Ó tiẹ̀ lè mú ká “kún fún ìhónú sí Jèhófà.”—Òwe 19:3.
4, 5. Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè “kún fún ìhónú sí Jèhófà”?
4 Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe lóòótọ́ pé ká “kún fún ìhónú Aísá. 41:11) Àbí, kí lèèyàn máa rí nídìí bíbá Ọlọ́run bínú? Òdodo ọ̀rọ̀ kan ni pé, ńṣe lẹni tó bá fẹ́ bá Ọlọ́run jà máa tẹ́. Òótọ́ ni pé a lè má sọ̀rọ̀ ìbínú jáde sí Jèhófà, ṣùgbọ́n Òwe 19:3 sọ pé ìwà òmùgọ̀ èèyàn “ni ó lọ́ ọ̀nà rẹ̀ po, ọkàn-àyà rẹ̀ sì wá di èyí tí ó kún fún ìhónú sí Jèhófà.” Torí náà, ó ṣeé ṣe kí èèyàn máa bínú sí Jèhófà nínú ọkàn rẹ̀. Tá ò bá ṣọ́ra, láìfura a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi hàn láwọn ọnà kan pé à ń bá Ọlọ́run bínú. Lédè míì, ńṣe ló máa dà bíi pé onítọ̀hún di Jèhófà sínú. Èyí lè wá mú kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa pa ìpàdé jẹ tàbí kó máa fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìjọsìn Jèhófà.
sí Jèhófà,” tàbí ká máa bá Jèhófà bínú? Ńṣe lẹni tó bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ kàn ń jẹ ara rẹ̀ níyà. (5 Kí ló lè mú ká “kún fún ìhónú sí Jèhófà”? Báwo la ṣe lè yẹra fún ìdẹkùn yìí? Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí. Ó ṣe tán, a ò fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ MÚ KÁ “KÚN FÚN ÌHÓNÚ SÍ JÈHÓFÀ”
6, 7. Nígbà ayé Mósè, kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn sí Jèhófà?
6 Kí ló lè mú kí Kristẹni kan tó jẹ́ olóòótọ́ máa ráhùn nínú ọkàn rẹ̀ sí Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan márùn-ún tó lè mú kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, ká sì jíròrò ohun tó fà á táwọn kan nínú Bíbélì fi kó sínú ìdẹkùn yìí.—1 Kọ́r. 10:11, 12.
7 Ọ̀rọ̀ ẹnú àwọn ẹlòmíì lè ní ipa tí kò dára lórí wa. (Ka Diutarónómì 1:26-28.) Kò pẹ́ tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lóko ẹrú ní Íjíbítì. Ó ti fi ìyọnu mẹ́wàá kọlu àwọn ará Íjíbítì tó ń pọ́n wọn lójú, lẹ́yìn èyí ló wá pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kís. 12:29-32, 51; 14:29-31; Sm. 136:15) Ó ti wá tó àkókò fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, àkókò yìí gan-an làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn sí Jèhófà. Èyí fi hàn pé wọn kò nígbàgbọ́ mọ́ nínú Ọlọ́run. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé wọ́n rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn tí kò dára lẹ́nu àwọn amí tí wọ́n rán lọ pé kí wọ́n lọ wo Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 14:1-4) Kí ni èyí wá yọrí sí? Odindi ìran kan ni kò wọ “ilẹ̀ rere” náà látàrí ohun tí wọ́n ṣe yìí. (Diu. 1:34, 35) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí kò dára táwọn ẹlòmíì ń sọ kò ti máa kó èèràn ràn wá? Ṣé kò ti máa jin ìgbàgbọ́ wa lẹ́sẹ̀ débi pé a wá ń ráhùn nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà darí wa?
8. Kí nìdí táwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà ayé Aísáyà fi bẹ̀rẹ̀ sí í dá Ọlọ́run lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro wọn?
8 Ìṣòro àti ìpọ́njú lè mú wa rẹ̀wẹ̀sì. (Ka Aísáyà 8:21, 22.) Nígbà ayé Aísáyà, ìṣòro ńlá kan bá orílẹ̀-èdè Júdà. Àwọn ọ̀tá yí wọn ká. Kò sí oúnjẹ nílùú mọ́, ebi sì ń han àwọn èèyàn léèmọ̀. Ohun tó tún wá mú kí ọ̀rọ̀ wọn burú jù ni pé, wọn ò ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. (Ámósì 8:11) Àmọ́, kàkà tí wọn ì bá fi bẹ Jèhófà pé kó ran wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè borí àwọn ìṣòro náà, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “pe ibi wá” sórí ọba wọn àti sórí Ọlọ́run wọn. Ẹ ò rí nǹkan, Jèhófà ni wọ́n dá lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro wọn! Tí àjálù bá dé tàbí ńṣe là ń fojú winá àwọn ìṣòro kan, ṣé àwa náà ò ní máa sọ nínu ọkàn wa pé, ‘Ibo ni Jèhófà wà nígbà tí mo nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?’
9. Nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì, kí nìdí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ní èrò tí kò tọ́?
9 Tá ò bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an. Nígbà ayé Ísíkíẹ́lì, torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an, ńṣe ni wọ́n gbà pé ọ̀nà Jèhófà “kò gún.” (Ìsík. 18:29) Ṣe ló dà bíi pé wọ́n ń dá Ọlọ́run lẹ́jọ́, tí wọ́n sì ka ìlànà ìdájọ́ tiwọn sí ju ti Ọlọ́run lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lóye àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ń dá a lẹ́jọ́. Bákan náà, ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé a ò fi bẹ́ẹ̀ lóye ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wà nínú Bíbélì tàbí pé a ò mọ ìdí tí ohun kan fi ṣẹlẹ̀ sí wa. Tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ṣé a kì í sọ nínú ọkàn wa pé ohun tí Jèhófà ṣe kò dára, pé ọ̀nà rẹ̀ “kò gún”?—Jóòbù 35:2.
10. Báwo lẹnì kan ṣe lè fìwà jọ Ádámù?
10 Tá a bá ń di ẹ̀bi àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe wa ru àwọn ẹlòmíì. Ádámù lẹni àkọ́kọ́ tó di ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ru Ọlọ́run, èyí fi hàn pé ọjọ́ pẹ́ táwọn èèyàn ti ń dá Ọlọ́run lẹ́bi. (Jẹ́n. 3:12) Ńṣe ni Ádámù mọ̀ọ́mọ̀ rú òfin Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ ohun tó máa yọrí sí. Lẹ́yìn tó rú òfin náà tán, ńṣe ló tún ń dá Ọlọ́run lẹ́bi. Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé ìyàwó burúkú ni Jèhófà fún òun. Látìgbà yẹn náà sì ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Ádámù, ní ti pé ńṣe ni wọ́n máa ń di ẹ̀bi àṣìṣe wọn ru Ọlọ́run. Àwa náà lè bi ara wa pé, ‘Ṣé mi ò kì í jẹ́ kí ìjákulẹ̀ àti ìdààmú tó bá mi nítorí àwọn àṣìṣe mi mú ki n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn nípa àwọn ìlànà Jèhófà?’
11. Kí la lè rí kọ́ lára Jónà?
11 Tá a bá jẹ́ onímọtara ẹni nìkan. Inú wòlíì Jónà ò dùn sí bí Jèhófà ṣe ṣàánú àwọn ará Nínéfè, tó sì dá wọn sí. (Jónà 4:1-3) Kí nìdí tí inú Jónà kò fi dùn? Ó jọ pé ohun tó ń ká Jónà lára jù ni pé ojú máa tì òun tí ìparun tí òun wàásù nípa rẹ̀ kò bá dé mọ́. Jónà jẹ́ kí irú ojú táwọn èèyàn á fi máa wò ó gbà á lọ́kàn débi tí kò fi fẹ́ láti fàánú hàn sí àwọn ará Nínéfè tí wọ́n ti ronú pìwà dà. Ṣé irú ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan yìí kò ti máa ràn wá? Ṣé àwa náà kì í bínú sí Jèhófà nítorí pé òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí kò tíì dé? Tó bá jẹ́ pé a ti ń wàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé, ṣé kì í ṣe wá bíi pé kí Jèhófà tètè mú ọjọ́ náà dè, pàápàá tó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn èèyàn ń ṣàríwísí ohun tá à ń wàásù rẹ̀?—2 Pét. 3:3, 4, 9.
ÀWỌN OHUN TÍ KÒ NÍ JẸ́ KÁ “KÚN FÚN ÌHÓNÚ SÍ JÈHÓFÀ”
12, 13. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ṣe nǹkan kò tọ́, kí la gbọ́dọ̀ ṣe?
12 Kí la lè ṣe tí àìpé bá mú wa ronú pé ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ṣe nǹkan kò tọ́? Ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé kò bọ́gbọ́n mu rárá láti ronú bẹ́ẹ̀. Nínú ìtumọ̀ Bíbélì míì, Òwe sọ pé: “Nigba ti ìwà-òmùgọ̀ eniyan ba mu ìparun ba ọ̀nà ara rẹ̀, ọkàn rẹ̀ a gbóná ni ìbínú si Oluwa.” (Bíbélì Yoruba Atọ́ka) Torí náà, ẹ jẹ́ ká wá jíròrò ohun márùn-ún tó lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ni máa dá Jèhófà lẹ́bi nígbà tá a bá níṣòro. 19:3
13 Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Tá ò bá fẹ́ kí àìpé mú ká kún fún ìhónú sí Ọlọ́run, ó ṣe pàtàkì pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú rẹ̀. (Ka Òwe 3:5, 6.) A gbọ́dọ̀ fọkàn tán Jèhófà. A ò gbọ́dọ̀ máa ṣe bíi pé a gbọ́n ju Jèhófà lọ, ká má si jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. (Òwe 3:7; Oníw. 7:16) Tá a bá fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn, a ò ní máa dá Jèhófà lẹ́bi nígbà tí nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀.
14, 15. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn míì ṣàkóbá fún wa?
14 Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn míì ṣàkóbá fún ọ. Nígbà ayé Mósè, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà pé Jèhófà máa mú wọn de Ilẹ̀ Ìlérí. (Sm. 78:43-53) Àmọ́, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn tí kò dára látẹnu àwọn amí mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ náà, wọn kò “rántí ọwọ́” Jèhófà. (Sm. 78:42) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, tá a sì ń rántí àwọn ohun rere tó ṣe fún wa, èyí á mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ túbọ̀ máa lágbára. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tí kò dára táwọn míì ń sọ kò ní ba àárín àwa àti Jèhófà jẹ́.—Sm. 77:11, 12.
15 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń hùwà tí kò dára sáwọn tá a jọ ń sin Jèhófà? Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. (1 Jòh. 4:20) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ráhùn nítorí ipò tí Áárónì wà gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà, Jèhófà sọ pé òun ni wọ́n ń kùn sí. (Núm. 17:10) Táwa náà bá lọ ń ṣàríwísí àwọn tí Jèhófà ń lò láti máa darí apá ti ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀, ńṣe ni ká kúkú sọ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ là ń kùn sí.—Héb. 13:7, 17.
16, 17. Kí ló yẹ ká máa rántí nígbà tá a bá ní ìṣòro?
16 Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé Jèhófà kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa. Nígbà ayé Aísáyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti fi Jèhófà sílẹ̀, Jèhófà ṣì fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Aísá. 1:16-19) Ìṣòro yòówù ká ní, bá a ṣe mọ̀ pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Jèhófà lógún tó sì ń fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ máa ń tù wá nínú gan-an. (1 Pét. 5:7) Kódà, ó ṣèlérí fún wa pé òun á fún wa lókun ká lè máa fara dà á nìṣó.—1 Kọ́r. 10:13.
17 Tá a bá ń jìyà lórí ohun kan tá ò mọwọ́ mẹsẹ̀ rẹ̀ bíi ti Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà, ó yẹ ká máa rántí pé Jèhófà kọ́ ló ń fi irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ wá. Jèhófà kórìíra ìwà ìrẹ́jẹ àmọ́ ó nífẹ̀ẹ́ òdodo. (Sm. 33:5) Torí náà, ẹ jẹ́ kí àwa náà ní irú èrò tí Élíhù ọ̀rẹ́ Jóòbù ní, pé: “Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú, àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!” (Jóòbù 34:10) Jèhófà kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa o, dípò bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fún wa ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.”—Ják. 1:13, 17.
18, 19. Kì nìdí tí kò fi yẹ ká máa ṣiyè méjì nípa Jèhófà? Ṣàpèjúwe.
18 Má ṣiyè méjì nípa Jèhófà. Ẹni pípé ni Ọlọ́run, ìrònú rẹ̀ sì ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì. (Aísá. 55:8, 9) Torí náà, tá a bá ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, èyí á jẹ́ ká gbà pé ó níbi tí òye wa mọ. (Róòmù 9:20) Kò dájú pé a lè mọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ kan ṣe rí. Kò sí àní-àní pé a máa gbà pẹ̀lú ohun tí ìwé Òwe sọ, pé: “Ẹnikini ninu ẹjọ́ rẹ̀ dabi ẹni pe ó jàre, titi ẹnikeji rẹ̀ yoo fi de lati hudi rẹ̀ sita.”—Òwe 18:17, Bíbélì Atọ́ka.
19 Ká sọ pé a ní ọ̀rẹ́ kan tá a fọkàn tán dáadáa, àmọ́ tó ṣe nǹkan kan tí kò yé wa tàbí tó ṣàjèjì sí wa, ǹjẹ́ ojú ẹsẹ̀ la ti máa fẹ̀sùn kàn án pé aláìdáa èèyàn ni? Àbí ńṣe la máa gbà pé ọ̀rẹ́ wa kò jẹ́ hu irú ìwà àìdáa bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì tó bá jẹ́ pé a ti ń bá
ara wa bọ̀ láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn? Tó bá jẹ́ pé a ò ní kù gììrì pe ọ̀rẹ́ wa tó jẹ́ aláìpé ní aláìdáa èèyàn, kí wá nìdí tá ò fi ní lè fọkàn tán Baba wa ọ̀run, ẹni tó jẹ́ pé ọ̀nà rẹ̀ àti èrò rẹ̀ ga ju ti wa lọ fíìfíì!20, 21. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe máa dá Ọlọ́run lẹ́bi?
20 Ẹ má ṣe jẹ́ ká máa dá Ọlọrun lẹ́bi. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá Ọlọ́run lẹ́bi? Ó lè jẹ́ pé àwa fúnra wa la fa àwọn ìṣòro kan tó ń bá wa fínra. Tó bá jẹ́ pé àfọwọ́fà tiwa ni lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ gbà bẹ́ẹ̀. (Gál. 6:7) Má ṣe máa dá Jèhófà lẹ́bi pé òun ló fa ìṣòro rẹ. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé ká dá Jèhófà lẹ́bi? Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ká sọ pé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan lè sáré gan-an. Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé awakọ̀ náà sá eré àsápajúdé wọ kọ́nà, tí jàǹbá wá ṣẹlẹ̀, ṣé ẹni tó ṣe ọkọ̀ náà la máa dá lẹ́bi? Rárá o! Bákan náà, ńṣe ni Jèhófà dá wa pẹ̀lú òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá. Àmọ́, ó tún fún wa ní àwọn ìlànà tó máa jẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu. Torí náà, kí nìdí tá a fi wá ń dá Ẹlẹ́dàá wa lẹ́bi pé òun ló fa àwọn àṣìṣe wa?
21 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ló jẹ́ pé àwọn àṣìṣe wa tàbí ìwà tí kò dára tá a hù ló fa àwọn ìṣòro wa. Àwọn nǹkan kan máa ń wáyé nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.” (Oníw. 9:11) Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé pé Sátánì Èṣù gan-an ló pilẹ̀ àwọn nǹkan burúkú tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. (1 Jòh. 5:19; Ìṣí. 12:9) Òun ni ọ̀tá wa, kì í ṣe Jèhófà!—1 Pét. 5:8.
ÀJỌṢE TÓ WÀ LÁÀÁRÍN ÌWỌ ÀTI JÈHÓFÀ ṢEYEBÍYE GAN-AN
22, 23. Kí ló yẹ ká máa rántí tí àwọn ìṣòro wa bá mú ká rẹ̀wẹ̀sì?
22 Tó o bá ní àwọn ìṣòro kan tàbí ńṣe ni ojú ń pọ́n ẹ, máa rántí Jóṣúà àti Kálébù. Wọn ò dà bí àwọn amí mẹ́wàá tó kù, ìròyìn tó dára ni àwọn ọkùnrin olóòótọ́ méjì yìí mú wá. (Núm. 14:6-9) Wọ́n fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Síbẹ̀ náà, wọ́n wà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń rìn kiri nínú aginjù fún ogójì [40] ọdún. Ǹjẹ́ Jóṣúà àti Kálébù bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn, àbí ṣe ni inú wọn bà jẹ́ tí wọ́n sì ronú pé ohun tí Jèhófà ṣe kù díẹ̀ káàtó? Rárá o. Ńṣe ni wọ́n fọkàn tán Jèhófà. Ǹjẹ́ Jèhófà tiẹ̀ bù kún wọn? Bẹ́ẹ̀ ni! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odindi ìran kan ló kú sínú aginjù, Jèhófà mú Jóṣúà àti Kálébù dé Ilẹ̀ Ìlérí. (Núm. 14:30) Tí àwa náà bá ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà nìṣó tí a kò sì “ṣàárẹ̀,” Jèhófà máa bù kún wa lọ́pọ̀lọpọ̀.—Gál. 6:9; Héb. 6:10.
23 Tó bá jẹ́ pé ìṣòro ló mú ọ rẹ̀wẹ̀sì, tàbí àṣìṣe àwọn ẹlòmíì tàbí àṣìṣe tìẹ fúnra rẹ, kí ló yẹ kó o ṣe? Ńṣe ni kó o máa ronú nípa àwọn ànímọ́ àgbàyanu Jèhófà. Máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. Máa bi ara rẹ pé, ‘Ká sọ pé mi ò mọ Jèhófà ni, báwo ni ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí?’ Túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà, má sì ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ kún fún ìhónú sí Jèhófà!