ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Ẹ̀yin Òbí Àtẹ̀yin Ọmọ, Ẹ Máa Bá Ara Yín Sọ̀rọ̀
GẸ́RẸ́ tí mo bí ọmọkùnrin mi tó ń jẹ́ Gary ní ọdún 1958 ni mo ti fura pé nǹkan kan ń ṣe é. Àmọ́, àwọn dókítà ò tètè rí ohun tó ń ṣe é. Lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá gbáko ni wọ́n tó rí i pé ọmọ mi níṣòro. Kódà, ọdún márùn-ún tún kọjá lẹ́yìn náà kí àwọn dókítà tí wọ́n jẹ́ ògbóǹtagí nílùú London tó gbà pé òótọ́ ló níṣòro. Ọdún mẹ́sàn-án lẹ́yìn tí mo bí Gary, mo bí ọmọbìnrin kan tá a pè ní Louise. Òun náà ní irú àrùn tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní, ó tiẹ̀ tún burú ju tẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Áà! Ńṣe ni ìbànújẹ́ dorí mi kodò.
Nígbà tá a wà nílé ìwòsàn, àwọn dókítà rọra sọ fún mi pé: “Àwọn ọmọ rẹ méjèèjì ló ní àrùn kan tí kò gbóògùn tí wọ́n ń pè ní LMBB.” * Nígbà tí mò ń sọ yìí, kò dájú pé àwọn èèyàn tíì mọ àrùn tí wọ́n ń pè bẹ́ẹ̀. Tí ìṣòro bá ti bá àwọn èròjà tó ń para pọ̀ di ọmọ inú oyún, irú ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ni àrùn yìí. Lára ohun tó sì máa ń ṣe àwọn tó bá ní àrùn náà ni pé ojú wọn lè má ríràn dáadáa, tó bá tiẹ̀ yá wọ́n lè má ríran mọ́, wọ́n lè sanra jọ̀kọ̀tọ̀, wọ́n tún lè ní ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ tó ju márùn-ún lọ, wọn ò kì í dàgbà bó ṣe yẹ, wọn ò kì ń lè pọkàn pọ̀, wọ́n tún lè ní àrùn àtọ̀gbẹ, làkúrègbé tó ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, àtàwọn àrùn míì tó máa ń ba kíndìnrín jẹ́. Ẹ ò ráyé mi lóde, ọmọ mi méjèèjì ló ní àrùn yìí. Kò rọrùn rárá fún mi láti máa bójú tó wọn. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi hàn pé tá a bá kó èèyàn ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádóje dín márùn-ún jọ [125,000], èèyàn kan péré ló ṣeé ṣe kó ní àrùn náà. Èyí fi hàn pé àwọn tó ní àrùn yìí kò pọ̀ rárá. Wọ́n sọ pé àwọn kàn sì wà tó jẹ́ pé wọ́n ní àrùn náà, àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ le.
JÈHÓFÀ JẸ́ “IBI GÍGA ÀÀBÒ” FÚN WA
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣègbéyàwó tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wàásù fún mi, mo sì rí i pé òótọ́ ni wọ́n fi ń kọ́ni. Àmọ́, ọkọ mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Bíbélì rárá. Iṣẹ́ tún máa ń gbé ọkọ mi káàkiri, a sì máa ń tẹ̀ lé e lọ sí ibikíbi tí iṣẹ́ bá gbé e lọ, torí náà, kó ṣeé ṣe fún mi láti máa lọ sípàdé. Àmọ́, mi ò yéé ka Bíbélì, mo sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà ní gbogbo ìgbà. Ó máa ń tù mi nínú gan-an tí n bá ń ka Sáàmù tó sọ pé: ‘Jèhófà yóò di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára, ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà’ àti pé ‘kì yóò fi àwọn tí ń wá a sílẹ̀ dájúdájú.’—Sm. 9:9, 10.
Torí pé Gary ò ríran dáadáa, nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́fà, ó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé tó wà fáwọn ọmọ tó níṣòro bíi tiẹ̀ ní gúúsù ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Iléèwé yìí ní ilé gbígbé fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń pè mí lórí fóònù láti sọ àwọn ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, èmi náà sí máa ń sọ àwọn òtítọ́ inú Bíbélì tó rọrùn láti lóye fún un. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí mo bí Louise àbúrò rẹ̀, àìsàn burúkú kan ṣe èmi náà, ìyẹn àrùn tó máa ń mú iṣan ara le gbagidi tàbí tó máa ń mú kí iṣan àti ẹran ara máa ro ni. Nígbà tí Gary pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], ó ṣe tán nílé ìwé tó wà yẹn, ó sì pa dà wálé. Àmọ́ ńṣe ni ojú ẹ̀ yẹn ń burú sí i, kò sì ríran tààrà mọ́. Nígbà tó sì di ọdún 1975, wọ́n kúkú wá kà á sí afọ́jú. Nígbà tó fi máa di ọdún 1977, ọkọ mi fi wá sílẹ̀, ó kó kúrò nílé, ló bá dá mi dá ìṣòrò náà.
Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Gary pa dà dé, táa fi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé déédéé tá a sì ń lọ́wọ́ sí àwọn ètò míì tí ìjọ bá ṣe. Àwọn ará ìjọ yẹn nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Ọdún 1974 ni mo ṣèrìbọmi. Nígbà tí Gary wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún, alàgbà kan mú un lọ́rẹ̀ẹ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó ṣe nípa àwọn ìyípadà tó máa ń ṣẹlẹ̀ lákòókò ìbàlágà. Èyí sì múnú mi dún gan-an. Àwọn ará tó kù nínú ìjọ náà máa ń wá bá mi ṣe àwọn iṣẹ́ ilé. Nígbà tó yá, Ìjọba tún dá ètò kan sílẹ̀ láti fi pèsè ìrànwọ́ fún àwọn ìdílé tó níṣòro bíi tèmi. Wọ́n wá yan márùn-ún lára àwọn ará tó máa ń wá ràn mí lọ́wọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí aṣojú ìjọba. Ìbùkún lèyí sì jẹ́ fún mi.
Ṣe ni Gary túbọ̀ ń ṣe dáadáa sí i nípa tẹ̀mí, nígbà tó sì di ọdún 1982, ó ṣèrìbọmi. Ó máa ń wù ú gan-an
láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, lèmi fúnra mi bá kúkú bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ká lè jọ máa ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọdún la sì jọ fi ṣe é. Lọ́jọ́ kan, alábòójútó àyíká wa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Gary, ó ò ṣe máa ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé?” Ìbéèrè yìí fún Gary níṣìírí gan-an ni, nígbà tó sì di ọdún 1990, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.Ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ tó lágbára fún un ní ìgbáròkó rẹ̀. Wọ́n ṣe ọ̀kan fún un ní ọdún 1999, èkejì ní ọdún 2008. Àmọ́, ìṣòro ti àbúrò rẹ̀ le ju tiẹ̀ lọ. Nígbà tá a bí òun, kò tiẹ̀ ríran rárá. Bí mo sì ṣe rí i pé àwọn ìka tó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kan lé ní márùn-ún ni mo ti mọ̀ pé òun náà ní àrùn tí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní. Àyẹ̀wò tún fi hàn pé púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀yà inú ara rẹ̀ ló níṣòro. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ abẹ ni wọ́n sì ti ṣe fún un, ẹ̀ẹ̀marùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ lórí kíndìnrín rẹ̀ nìkan. Òun náà tún ní àrùn àtọ̀gbẹ.
Torí pé Louise mọ̀ pé wọ́n lè ní kí òun gbẹ̀jẹ̀ nígbà tí wọ́n bá máa ṣe iṣẹ́ abẹ fún òun, ó máa ń jẹ́ kí àwọn dókítà àtàwọn míì tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn náà mọ̀ pé, ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ lòun máa fẹ́. Èyí sì mú kí púpọ̀ nínú wọn di ọ̀rẹ́ rẹ̀.
ÌGBÉSÍ AYÉ WA TÚBỌ̀ NÍTUMỌ̀
A ò jẹ́ kí àwọn ìṣòro tó dé bá wa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la kúkú pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Jèhófà. Mo máa ń lo àkókò tó pọ̀ láti ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa sí Gary àti Louise létí. Àmọ́, ní báyìí tá a ti ní àwọn àwo CD àti DVD, tí ètò sì ti wà láti máa tẹ́tí gbọ́ àwọn míì lórí Ìkànnì wa, ìyẹn www.isa4310.com, ó ti ṣeé ṣe fún kálukú wa láti máa múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan láyè ara wa. Èyí sì máa ń mú ká lè dáhùn látọkànwá láwọn ìpàdé, àwọn ìdáhùn náà sì máa ń gbéni ró.
Lọ́pọ̀ ìgbà, Gary máa ń há ìdáhùn tó fẹ́ sọ ní ìpàdé sórí. Tó bá sì níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe ló máa ń sọ ọ̀rọ̀ náà látọkànwá láìgbáralé àkọsílẹ̀ kankan. Ó di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́dún 1995, èyí sì mú kí ọwọ́ rẹ̀ máa dí gan-an nípàdé. Ó wà lára àwọn tó ń bójú tó èrò, ó sì tún ń bójú tó ẹ̀rọ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́.
Àwọn ará máa ń bá Gary ṣiṣẹ́ lóde-ẹ̀rí, wọ́n sì máa ń bá a ti kẹ̀kẹ́ arọ tó ń jókòó sí nítorí oríkèé ara tó ń yọ ọ́ lẹ́nu. Arákùnrin kan tiẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti dárí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan, ẹni náà sì ti ń wá sípàdé báyìí. Gary tún fún arábìnrin kan tó jẹ́ akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] níṣìírí, arábìnrin náà kò sì fi ìpàdé ṣeré mọ́ báyìí.
Nígbà tí Louise ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án ni màmá mi ti kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń hun aṣọ. Ọ̀kan lára àwọn tí ìjọba ṣètò láti máa ṣèrànwọ́ fún wa náà kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń kóṣẹ́ sí ara aṣọ. Ó máa ń hun bùláńkẹ́ẹ̀tì tó láwọ̀ oríṣiríṣi fún àwọn ìkókó àtàwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ, torí pé iṣẹ́ ká máa hun nǹkan máa ń gbádùn mọ́ ọn gan-an ni. Ó tún máa ń lẹ àwọn àwòrán kéékèèké mọ́ àwọn ìwé tó ti dárà sí láti fi ṣe káàdì ìkíni, ó sì máa ń fún àwọn èèyàn. Inú àwọn tó fún máa ń dùn gan-an, wọ́n sì máa ń mọyì rẹ̀. Bákan náà, nígbà tó fi máa di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], ó ti mọ bí wọ́n ṣe ń tẹ ìsọfúnni lórí ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé. Àmọ́ ní báyìí ti kọ̀ǹpútà tó lè gbé ohùn jáde ti wà, lóòrèkóòrè ló máa ń lò ó láti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] ó ṣèrìbọmi. A tiẹ̀ jọ máa ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní àwọn oṣù tá a máa ń lò lákànṣe láti wàásù, èyí sì máa ń mú inú wa dùn gan-an. Òun náà máa ń há àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì sórí bíi ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀, kí ó lè sọ ohun tó gbà gbọ́ fún àwọn èèyàn. Lára rẹ̀ ni pé Jèhófà ti ṣèlérí pé nínú ayé tuntun “ojú àwọn afọ́jú yóò là” àti pé ‘kò ní sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: “Àìsàn ń ṣe mí.”’—Aísá. 33:24; 35:5.
Inú wa dùn pé a mọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! A tún mọyì ipa ribiribi tí àwọn ará nínú ìjọ ń kó, wọn ò fi wá sílẹ̀ rárá ṣe ni wọ́n dúró tì wá. Tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, ì bá má ṣeé ṣe fún wa láti tẹ̀ síwájú tó bẹ́ẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. Jèhófà ló ni ọpẹ́ tó ga jùlọ, torí pé kò fi wá sílẹ̀, ó ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Èyí ló sì mú kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.
^ ìpínrọ̀ 5 Orúkọ àrùn náà LMBB jẹ́ ìkékúrú Laurence-Moon-Bardet-Biedl. Orúkọ àwọn dókítà mẹ́rin tí wọ́n ṣe ìwádìí àrùn yìí ni wọ́n fi sọ orúkọ àrùn náà. Wọ́n sọ pé ohun tó máa ń fa àrùn yìí ni ìṣòro tó bá àwọn èròjà tó ń para pọ̀ di ọmọ inú oyún, èyí tó wá látara bàbá àti ìyá ọmọ náà. Ní báyìí, orúkọ tí wọ́n ń pe àrùn náà ni àrùn Bardet-Biedl. Àrùn náà ò sì gbóògùn.