Sá Fún Àwọn Nǹkan Tí Kò Ní Jẹ́ Kí Ọlọ́run Dá ẹ Lọ́lá
“Ẹni tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ẹ̀mí yóò di ògo mú.”—ÒWE 29:23.
1, 2. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ògo” túmọ̀ sí? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí?
TÓ O bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ògo” tàbí “ọlá,” kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ṣé ó máa ń rán ẹ létí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run? (Sm. 19:1) Àbí ńṣe ló máa ń mú kó o ronú nípa bí àwọn èèyàn ṣe máa ń bọlá fún àwọn olówó, àwọn ọ̀mọ̀ràn, tàbí àwọn gbajúmọ̀? Wọ́n máa ń fi ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ògo” lédè Yorùbá ṣàlàyé ohun kan tó wúwo. Ní ìgbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn nǹkan bíi wúrà tàbí fàdákà ni wọ́n fi ń ṣe owó ẹyọ. Bí owó ẹyọ náà bá sì ṣe wúwo lọ́wọ́ tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa níye lórí tó. Torí náà, bí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ògo,” ńṣe ló máa ń mú kí wọ́n ronú nípa ohun tó níye lórí gan-an tàbí nǹkan tó jọjú lọ́pọ̀lọpọ̀.
2 Àwọn èèyàn sábà máa ń dá àwọn alágbára tàbí olókìkí èèyàn lọ́lá. Àmọ́ kí ni Ọlọ́run máa ń rí lára ẹnì kan kó tó dá irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́lá? Bíbélì ló máa dáhùn ìbéèrè yìí. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bibeli Mimọ, Òwe 22:4 sọ pé: “Ere irẹlẹ ati ibẹru Oluwa li ọrọ̀, ọlá, ati iye.” Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù sì sọ pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ojú Jèhófà, yóò sì gbé yín ga.” (Ják. 4:10) Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń dá àwa èèyàn lọ́lá? Kí ló lè mú kí Ọlọ́run má ṣe dá wa lọ́lá? Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí Ọlọ́run lè dá wọn lọ́lá?
3-5. Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń dá àwa èèyàn lọ́lá?
3 Ohun tí onísáàmù kan sọ fi hàn pé ó gbà pé Jèhófà máa dá òun lọ́lá. (Ka Sáàmù 73:23, 24.) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dá àwọn tó bá jẹ́ onígbọràn lọ́lá? Bó ṣe máa ń dá wọn lọ́lá ni pé ó máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà òun, ó sì máa ń bù kún wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí òun fẹ́, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun.—1 Kọ́r. 2:7; Ják. 4:8.
2 Kọ́r. 4:1, 7) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ń fún wa ní àǹfààní láti máa fi ògo fún Ọlọ́run. Jèhófà ṣe ìlérí kan fún àwọn tó ń fi iṣẹ́ ìwàásù yìn ín tí wọ́n sì ń ran àwọn míì lọ́wọ́. Ó ní: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún.” (1 Sám. 2:30) Láìsí àní-àní, Jèhófà ń dá àwọn tó bá ń fògo fún un nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lọ́lá. Wọ́n ní orúkọ rere lọ́dọ̀ rẹ̀ ní ti pé wọ́n rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. A sì máa ń sọ̀rọ̀ wọn ní rere nínú ìjọ.—Òwe 11:16; 22:1.
4 Jèhófà tún fi iṣẹ́ ìwàásù dá wa lọ́lá. (5 Kí ló máa jẹ́ èrè àwọn tó bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà? Bíbélì sọ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wọn. Ó ní: “Òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.” (Sm. 37:34) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run máa dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́lá lọ́nà tí kò lẹ́gbẹ́ ní ti pé ó máa fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 37:29.
“ÈMI KÌ Í TẸ́WỌ́ GBA ÒGO LÁTI Ọ̀DỌ̀ ÈNÌYÀN”
6, 7. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi gbà gbọ́ pé Jésù ni Mèsáyà?
6 Ǹjẹ́ ohun kan wà tó lè mú kí Jèhófà má ṣe dá wa lọ́lá? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà kò ní dá wa lọ́lá tá a bá jẹ́ kí èrò àwọn tí kò ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀ jẹ wá lógún ju bó ṣe yẹ lọ. Ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ nípa àwọn alákòóso kan nígbà ayé Jésù nìyẹn. Ó ní wọ́n gba Jésù gbọ́, “ṣùgbọ́n nítorí àwọn Farisí wọn kì í jẹ́wọ́ rẹ̀, kí a má bàa lé wọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù; nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn ju ògo Ọlọ́run pàápàá.” (Jòh. 12:42, 43) Àmọ́, kò yẹ kí àwọn alákòóso yẹn jẹ́ kí ohun táwọn Farisí rò nípa wọn jẹ wọ́n lógún ju bó ṣe yẹ lọ.
7 Ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó ti sọ ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi gbà pé òun ni Mèsáyà. (Ka Jòhánù 5:39-44.) Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ti ń retí Mèsáyà. Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan ti fòye mọ̀ pé àkókò ti tó fún Mèsáyà láti dé gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Kódà, ní oṣù mélòó kan ṣáájú àkókò yẹn, nígbà tí Jòhánù Arinibọmi ń wàásù, ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń sọ pé: “Àbí òun ni Kristi náà ni?” (Lúùkù 3:15) Àmọ́, nígbà tí Mèsáyà dé, àwọn tó jẹ́ olùkọ́ Òfin gan-an ni wọn ò wá gbà á gbọ́. Kí nìdí? Jésù sọ ìdí náà nínú ìbéèrè kan tó bi wọ́n. Ó ní: “Báwo ni ẹ ṣe lè gbà gbọ́, nígbà tí ẹ ń tẹ́wọ́ gba ògo láti ọ̀dọ̀ ara yín, tí ẹ kì í sì í wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan ṣoṣo náà wá?”
8, 9. Báwo ni ògo tó ń wá látọ̀dọ̀ èèyàn ṣe lè di ohun tó ṣe pàtàkì sí ẹnì kan ju ọlá Ọlọ́run lọ? Ṣàpèjúwe.
8 Tá ò bá ṣọ́ra, ó rọrùn láti jẹ́ kí ògo tó ń wá látọ̀dọ̀ èèyàn ṣe pàtàkì sí wa ju ti Ọlọ́run lọ. Èyí lè yé wa dáadáa tá a bá fi ògo wé ìmọ́lẹ̀. Tó o bá jáde síta, tó o sì gbójú sókè lálẹ́ ọjọ́ kan tí ìkùukùu kò bo ojú sánmà, ó dájú pé wàá rí àìmọye ìràwọ̀. Àwọn ìràwọ̀ tó pọ̀ lọ salalu yẹn á sì fà ẹ́ mọ́ra. (1 Kọ́r. 15:40, 41) Àmọ́, láwọn ibì kan tí iná tó mọ́lẹ̀ dáadáa ti pọ̀ láàárín ìlú, èèyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè rí àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú sánmà. Kí nìdí? Ṣé torí pé iná tó wà lójú títì, èyí tó wà láwọn pápá ìṣeré àti èyí táwọn èèyàn tàn sínú ilé wọn ń tàn yanran ju ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ lọ ni? Àbí torí pé wọ́n lẹ́wà ju ìràwọ̀ lọ ni? Rárá o. Ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn iná tó wà láàárín ìlú sún mọ́ wa dáadáa, èyí mú kó túbọ̀ ṣòro fún wa láti rí àwọn ìràwọ̀ náà. Torí náà, tá a bá fẹ́ rí ẹwà ìràwọ̀, àfi ká lọ sí abúlé kan tí kò sí iná tàbí ká wo ojú sánmà nígbà tí wọ́n bá múná lọ.
9 Lọ́nà kan náà, bó ti wù kí Jèhófà dá wa lọ́lá tó, ògo látọ̀dọ̀ èèyàn lè mú ká má fi bẹ́ẹ̀ mọyì irú ọlá bẹ́ẹ̀ mọ́. Bí Jákọ́bù 5:14-16.
àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa torí pé wọ́n ń bẹ̀rù ohun táwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìbátan wọn á máa rò nípa wọn. Kódà, tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò bá ṣọ́ra, wọ́n lè jẹ́ kí ohun táwọn míì ń rò nípa wọn ṣe pàtàkì sí wọn ju bó ṣe yẹ lọ. Bí àpẹẹrẹ, kí ni ọ̀dọ́kùnrin kan máa ṣe tí wọ́n bá ní kó lọ wàásù níbì kan tí àwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n dáadáa, ṣùgbọ́n tí wọn kò mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni? Ṣé ìbẹ̀rù á mú kó má lọ sí irú ìpínlẹ̀ ìwàásù bẹ́ẹ̀? Tàbí, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan fẹ́ láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, àmọ́ táwọn kan ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ohun tó fi ṣe àfojúsùn rẹ̀ ńkọ́? Ṣó wá yẹ kó yí ìpinnu rẹ̀ pa dà torí ohun tí àwọn tí kò mọyì iṣẹ́ ìsìn Jèhófà yẹn ń sọ? Bí ẹnì kan bá sì dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì ńkọ́, ṣó yẹ kó bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀, torí pé ẹ̀rù ń bà á pé wọ́n lè gba àwọn àǹfààní tó ní nínú ìjọ lọ́wọ́ rẹ̀? Àbí ó máa bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀ torí pé kò fẹ́ já àwọn ìbátan àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ kulẹ̀? Tó bá jẹ́ pé àjọṣe irú ẹni bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún jù lọ, ńṣe ló máa tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn án lọ́wọ́.—Ka10. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá ń ṣàníyàn jù nípa ohun táwọn míì ń rò nípa wa? (b) Tá a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí ló yẹ ká máa rántí?
10 Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àmọ́ tí arákùnrin kan sábà máa ń fún ẹ nímọ̀ràn lórí ohun kan tàbí òmíràn, kí lo máa ṣe? Tó o bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn arákùnrin yẹn, wàá jàǹfààní látinú rẹ̀. Àmọ́, ìmọ̀ràn tó fún ẹ kò lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ìgbéraga ò bá jẹ́ kó o ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí torí pé o kò fẹ́ káwọn èèyàn máa fi ojú tí kò dára wò ẹ́. O kò sì lè jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn náà tó o bá ń wá àwáwí. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé iṣẹ́ ló da ìwọ àtàwọn ará kan pọ̀. Bí òye iṣẹ́ náà bá yé ẹ dáadáa, ṣé wàá fi gbogbo ara ṣe é àbí ńṣe lo máa fọwọ́ hẹ iṣẹ́ náà káwọn míì má bàa gba ògo tó o fẹ́ kó jẹ́ tìrẹ nìkan? Bí èyíkéyìí nínú àpẹẹrẹ yìí bá bá ẹ mu, máa rántí pé “ẹni tí ó ní ìrẹ̀lẹ̀ ní ẹ̀mí yóò di ògo mú.”—Òwe 29:23.
11. Bí àwọn èèyàn bá gbóríyìn fún wa, kí ló yẹ ká ṣe? Kí nìdí?
11 Àwọn alàgbà àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láti di alàgbà nínú ìjọ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn kò “wá ògo láti ọ̀dọ̀ ènìyàn.” (1 Tẹs. 2:6; 1 Tím. 3:1) Kí ló yẹ kí arákùnrin kan ṣe tí àwọn ará bá gbóríyìn fún un nítorí ohun kan tó ṣe? Ó dájú pé arákùnrin náà kò ní ṣe bíi ti Sọ́ọ̀lù Ọba tó “gbé ohun ìránnilétí kan nà ró fún ara rẹ̀.” (1 Sám. 15:12) Àmọ́, ṣó gbà pé Jèhófà ló mú kí òun ṣe àṣeyọrí àti pé nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run lòun fi lè máa bá a nìṣó láti kẹ́sẹ járí? (1 Pét. 4:11) Ohun tó bá wà lọ́kàn wa nígbà táwọn èèyàn bá gbóríyìn fún wa ló máa sọ irú ògo tàbí ọlá tá à ń wá.—Òwe 27:21.
‘Ẹ̀ Ń FẸ́ LÁTI ṢE ÌFẸ́ BABA YÍN’
12. Kí nìdí táwọn Júù kan kò fi gba ọ̀rọ̀ Jésù?
12 Ohun mìíràn tó tún lè mú kí Ọlọ́run má ṣe dá wa lọ́lá ni èrò tí kò tọ́. Bí a bá ń ní èrò tí kò tọ́, a kò ní fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rárá. (Ka Jòhánù 8:43-47.) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ fún àwọn Júù kan pé wọn kò gba ọ̀rọ̀ òun torí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Èṣù, tó jẹ́ baba wọn.
13, 14. (a) Kí ni àwọn tó ń ṣe ìwádìí sọ nípa ọpọlọ àti ohùn àwa èèyàn? (b) Báwo la ṣe lè yan ẹni tá a máa tẹ́tí sí?
13 Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ohun tá a bá fẹ́ gbọ́ la máa ń gbọ́. (2 Pét. 3:5) Jèhófà dá ọpọlọ wa lọ́nà tó fi jẹ́ pé ó lè sẹ́ ohun tí a kò bá fẹ́ gbọ́ dà nù. Bí àpẹẹrẹ, yára ronú lórí bí ìró tó ò ń gbọ́ ṣe pọ̀ tó bó o ṣe ń kàwé yìí. Bóyá lo mọ̀ pé ìró tó ò ń gbọ́ pọ̀ tóyẹn? Kí nìdí? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọlọ rẹ lè gbọ́ oríṣiríṣi ìró, síbẹ̀ ó máa ń jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun kan ṣoṣo. Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé kò ṣeé ṣe láti máa tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ẹni méjì lẹ́ẹ̀kan náà. Èyí fi hàn pé ńṣe la gbọ́dọ̀ yan ẹni tá a fẹ́ láti tẹ́tí sí nínú àwọn méjèèjì. Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn Júù fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Èṣù, tó jẹ́ baba wọn. Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi tẹ́tí sí Jésù.
14 Bíbélì sọ pé “ọgbọ́n” àti “dìndìnrìn” ń ké jáde pé ẹ “yà síhìn-ín.” Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n ń pè wá pé ká wá tẹ́tí sí àwọn. (Òwe 9:1-5, 13-17) Àwa la máa yan èyí tá a fẹ́ láti tẹ́tí sí nínú àwọn méjèèjì. Ṣùgbọ́n, èwo nínú wọn la fẹ́ láti tẹ́tí sí? Ìyẹn sinmi lórí ẹni tá a bá fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Tá a bá jẹ́ àgùntàn Jésù, a máa fẹ́ láti tẹ́tí sí i, yóò sì wù wá láti máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. (Jòh. 10:16, 27) Jésù sọ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun wà “ní ìhà ọ̀dọ̀ òtítọ́.” (Jòh. 18:37) “Wọn kò mọ ohùn àwọn àjèjì.” (Jòh. 10:5) Tá a bá ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tọ Jésù lẹ́yìn, Ọlọ́run máa dá wa lọ́lá.—Òwe 3:13, 16; 8:1, 18.
“ÌWỌ̀NYÍ TÚMỌ̀ SÍ ÒGO FÚN YÍN”
15. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ìpọ́njú òun “túmọ̀ sí ògo” fún àwọn ará Éfésù?
15 Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí Jèhófà lè dá wọn lọ́lá? Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká ní ìfaradà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Éfésù pé: “Èmi béèrè pé kí ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní tìtorí ìpọ́njú mi wọ̀nyí nítorí yín, nítorí ìwọ̀nyí túmọ̀ sí ògo fún yín.” (Éfé. 3:13) Ọ̀nà wo ni ìpọ́njú Pọ́ọ̀lù gbà “túmọ̀ sí ògo” fún àwọn ará Éfésù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù ní ìṣòro tó pọ̀, ó fara da àdánwò, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ni Kristẹni kan gbọ́dọ̀ kà sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ. Ká ní Pọ́ọ̀lù ti juwọ́ sílẹ̀ nígbà àdánwò ni, àwọn arákùnrin rẹ̀ ì bá ti lérò pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn àti ìrètí tí wọ́n ní kò ṣe pàtàkì. Àmọ́, nítorí pé Pọ́ọ̀lù ní ìfaradà, ó fi han àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin pé àdánwò yòówù ká fara dà nítorí pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
16. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ní Lísírà?
16 Ronú nípa bí ìtara àti ìfaradà Pọ́ọ̀lù ṣe ran àwọn ará lọ́wọ́. Ìwé Ìṣe 14:19, 20 sọ pé: “Àwọn Júù dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n yí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lérò padà, wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú ńlá [Lísírà], wọ́n lérò pé ó ti kú. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó dìde, ó sì wọ ìlú ńlá náà. Ní ọjọ́ kejì, òun pẹ̀lú Bánábà lọ sí Déébè.” Ẹ wo bó ṣe máa nira tó fún Pọ́ọ̀lù láti rin ìrìn àjò ọgọ́rùn-ún kìlómítà ní ọjọ́ kejì ọjọ́ tí wọ́n sọ ọ́ lókùúta tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ kú.
17, 18. (a) Báwo ni Tímótì ṣe mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù jìyà ní Lísírà? (b) Báwo ni ìfaradà Pọ́ọ̀lù ṣe ran Tímótì lọ́wọ́?
2 Tím. 3:10, 11; Ìṣe 13:50; 14:5, 19.
17 Ṣé Tímótì wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta ni? Ó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀, àmọ́ Bíbélì kò sọ fún wa. Lọ́nà kan ṣá, Tímótì gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀. Nínú lẹ́tà kejì tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì, ó sọ pé: “Ìwọ ti tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ mi pẹ́kípẹ́kí, ipa ọ̀nà ìgbésí ayé mi.” Kì í wulẹ̀ ṣe pé Tímótì mọ̀ pé wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta ní Lísírà nìkan ni, ó tún mọ̀ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní Áńtíókù, àwọn Júù lé e jáde. Àti pé àwọn kan tiẹ̀ gbìyànjú láti sọ ọ́ lókùúta ní ìlú Íkóníónì.—18 Tímótì mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ti fara da àwọn ipò líle koko wọ̀nyẹn. Torí náà, ó rí ohun púpọ̀ kọ́ lára Pọ́ọ̀lù. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sí Lísírà, ó gbọ́ pé Tímótì ń ṣe dáadáa nínú ìjọ, “àwọn ará ní Lísírà àti Íkóníónì sì ròyìn rẹ̀ dáadáa.” (Ìṣe 16:1, 2) Nígbà tó ṣe, Tímótì náà kúnjú ìwọ̀n láti gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i.—Fílí. 2:19, 20; 1 Tím. 1:3.
19. Báwo ni ìfaradà wa ṣe lè ran àwọn míì lọ́wọ́?
19 Tá a bá ń bá a nìṣó láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, àpẹẹrẹ wa lè ran àwọn èwe lọ́wọ́ láti túbọ̀ wúlò fún Jèhófà. Àwọn èwe máa ń kíyè sí wa, wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí. Kódà, wọ́n tún máa ń rí ọgbọ́n kọ́ nínú bá a ṣe máa ń ṣe tí ìṣòro bá dé bá wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ti fara da ọ̀pọ̀ nǹkan torí kí òun lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—2 Tím. 2:10.
20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá a nìṣó láti wá ọlá àti ògo Ọlọ́run?
20 Ní báyìí, a ti wá rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa “wá ògo tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan ṣoṣo náà wá.” (Jòh. 5:44; 7:18) Jèhófà máa fi “ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí ń wá ògo àti ọlá.” (Ka Róòmù 2:6, 7.) Ohun mìíràn sì tún ni pé tá a bá ń fara da ìṣòro, ìyẹn á mú kí àwọn míì jẹ́ olóòótọ́, wọ́n á sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun. Torí náà, sá fún àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kí Ọlọ́run dá ẹ lọ́lá.