Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Látinú Àpamọ́ Wa

“Ohun Mánigbàgbé” Tó Bọ́ Sákòókò

“Ohun Mánigbàgbé” Tó Bọ́ Sákòókò

“OHUN MÁNIGBÀGBÉ MÀ LÈYÍ O!” Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó wo sinimá kan tó dá lórí ìṣẹ̀dá sọ nìyẹn. Sinimá náà bọ́ sákòókò, ó sì wọ gbogbo àwọn tó wò ó lọ́kàn. Àkọlé rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ni “Creation Drama,” èyí tó túmọ̀ sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀dá. Sinimá náà jẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí sinimá yìí jáde ni ìjọba Hitler bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni tó lágbára sí àwọn èèyàn Jèhófà ní ilẹ̀ Yúróòpù. Báwo tiẹ̀ ni wọ́n ṣe ṣe sinimá náà?

Ìwé tí wọ́n gbé àkọlé sinimá náà kà rèé lédè Jámánì

Lọ́dún 1914, orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbé sinimá kan jáde. Àkọlé rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì ni “Photo-Drama of Creation,” èyí tó túmọ̀ sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ onífọ́tò nípa ìṣẹ̀dá. Sinimá aláwọ̀ mèremère ni, ó ń gbé ohùn jáde, ó sì máa ń gbà tó wákàtí mẹ́jọ kéèyàn tó wò ó tán. Àìmọye èèyàn kárí ayé ló wo sinimá náà. Ní ọdún 1914 yẹn kan náà, wọ́n gbé irú ẹ̀ míì tí kò tó wákàtí mẹ́jọ jáde. Wọ́n pè é ní “Eureka Drama,” èyí tó túmọ̀ sí àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìjagunmólú. Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929, àwọn ohun èlò tá a fi ń gbé sinimá náà jáde ti gbó, wọn kò sì ṣeé lò mọ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì ń fẹ́ láti wo sinimá náà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùgbé Ludwigsburg lórílẹ̀-èdè Jámánì béèrè pé, “Ìgbà wo lẹ tún máa fi sinimá náà hàn wá?” Kí wá ni ṣíṣe báyìí o?

Láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1929, àwọn aṣojú kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Jámánì wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá kí àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lè wo sinimá náà. Wọ́n ra fíìmù ní ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ní ìlú Paris lórílẹ̀-èdè Faransé, wọ́n sì tún ra àwọn irinṣẹ́ míì ní ilé iṣẹ́ kan ní ìlú Leipzig àti Dresden láti fi gbé sinimá náà jáde. Lẹ́yìn náà, wọ́n so fíìmù tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà náà pọ̀ mọ́ èyí tó ṣì ṣeé lò lára àwọn fíìmù tí wọ́n ń lò fún sinimá náà tẹ́lẹ̀.

Arákùnrin Erich Frost lẹ́bùn orin gan-an, òun ló ṣe àkójọ orin tá a fi gbé sinimá náà jáde. Wọ́n gbé àlàyé asọ̀tàn náà ka ìwé Creation tó sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀dá. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pè é ní àwòkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣẹ̀dá.

Sinimá tuntun náà jẹ́ oníwákàtí mẹ́jọ bíi ti tẹ́lẹ̀. Wọ́n pín in sí apá tó pọ̀. Àwọn èèyàn máa ń wo apá kọ̀ọ̀kan ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ tó sì wọni lọ́kàn nípa ọjọ́ ìṣẹ̀dá. Ó ṣàlàyé nípa ohun tí Bíbélì àti ìtàn sọ. Ó sì fi hàn pé ìsìn èké ti ṣi aráyé lọ́nà. Wọ́n fi sinimá yìí han àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè Austria, Jámánì, Luxemburg àti Switzerland àti ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń sọ èdè Jámánì kárí ayé.

Erich Frost tó ṣe ìwé orin tí wọ́n fi gbé sinimá náà jáde

Arákùnrin Erich Frost sọ ohun tó máa ń ṣe tí wọn bá ń fi sinimá yìí han àwọn èèyàn. Ó ní: “Mo máa ń gba àwọn arákùnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ níyànjú, ní pàtàkì àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ akọrin, pé kí wọ́n máa lo àkókò ìsinmi láti pín àwọn ìwé wa fún àwọn èèyàn lórí ìjókòó wọn. Àwọn ìwé tá a fi sóde lọ́nà yẹn pọ̀ ju àwọn tá a fi sóde lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé lọ.” Arákùnrin Johannes Rauthe, tó ṣètò bí wọ́n ṣe máa fi sinimá náà han àwọn èèyàn lórílẹ̀-èdè Poland àti Czech Republic, sọ pé ọ̀pọ̀ ló fi àdírẹ́sì wọn sílẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ ká wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i. Èyí mú ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fi àdírẹ́sì wọn sílẹ̀, a sì ṣàṣeyọrí gan-an.

Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1939, ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ṣètò pé kí àwọn èèyàn wá máa wo sinimá náà. Ní gbogbo ìgbà yẹn, ńṣe ni gbọ̀ngàn tá a bá lò máa ń kún àkúnya. Ìròyìn nípa sinimá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé jáde yìí wá gbòde kan. Nígbà tó fi máa di ọdún 1933, àwọn tó ti wo sinimá náà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù kan. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Käthe Krauss sọ pé: “Ká lè wo sinimá náà, a rin ìrìn ogún kìlómítà ní àlọ àtàbọ̀, lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, fún ọjọ́ márùn-ún. Inú igbó la máa ń gbà, ó sì jẹ́ ọ̀nà olókè tó rí gbágungbàgun.” Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Else Billharz sọ pé: “Sinimá yìí ló jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́.”

Arákùnrin Alfred Almendinger sọ pé nígbà tí ìyá òun lọ wo sinimá náà, “ohun tó rí wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé ó lọ ra Bíbélì kan, ó sì wò ó bóyá ọ̀rọ̀ náà, ‘pọ́gátórì’ wà nínú rẹ̀.” Nítorí pé kò rí i, ó gbà pé irọ́ ni ohun tí wọ́n fi kọ́ wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì pé àwọn òkú máa ń lọ sí pọ́gátórì. Torí náà, ó pa ṣọ́ọ̀ṣì tì, ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó sì ṣèrìbọmi. Arákùnrin Erich Frost sọ pé àìmọye èèyàn ló wá sínú òtítọ́ látàrí pé wọ́n wo sinimá náà.—3 Jòh. 1-3.

Ní gbogbo ìgbà táwọn èèyàn rẹpẹtẹ fi ń wo sinimá yẹn, ńṣe ni ẹgbẹ́ òṣèlú ìjọba Násì ń kó àwọn èèyàn sòdí, tó sì ń dá wàhálà sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1933, wọ́n fi òfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Jámánì. Látìgbà yẹn, títí tí Ogun Àgbáyé Kejì fi parí lọ́dún 1945, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Yúróòpù fojú winá inúnibíni lọ́nà tó gadabú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́jọ tí Arákùnrin Erich Frost lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àmọ́, Jèhófà kó o yọ. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó lọ sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní ìlú Wiesbaden lórílẹ̀-èdè Jámánì. Ẹ ò rí i pé ohun mánigbàgbé ni sinimá yẹn, ó sì bọ́ sákòókò gan-an! Ó sọ ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni dọ̀tun kí wọ́n lè fojú winá àwọn àdánwò tó dán ìgbàgbọ́ wọn wò nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.—Látinú àpamọ́ wa lórílẹ̀-èdè Jámánì.