Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’

Àwọn Alàgbà Jẹ́ ‘Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ Fún Ìdùnnú Wa’

“A jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín.”—2 KỌ́R. 1:24.

1. Kí ló mú inú Pọ́ọ̀lù dùn nípa àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì?

NÍGBÀ tí Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Tíróásì ní ọdún 55 Sànmánì Kristẹni, kò yéé ronú nípa àwọn tó wà ní ìjọ Kọ́ríńtì. Ìdí sì ni pé ó ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ pé ìyapa wà láàárín wọn. Ó fẹ́ràn wọn bí baba ṣe máa ń fẹ́ràn àwọn ọmọ rẹ̀, torí náà ó kọ lẹ́tà sí wọn kí wọ́n lè yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn. (1 Kọ́r. 1:11; 4:15) Pọ́ọ̀lù tún rán Títù tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ sí wọn. Ó sì ní kó wá jábọ̀ fún òun ní Tíróásì. Ní oṣù mélòó kan lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù ṣì wà ní Tíróásì, ó ń retí ìròyìn tí Títù máa mú wá nípa bí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì ṣe ń ṣe sí. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ò gbúròó Títù. Torí náà, Pọ́ọ̀lù wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Makedóníà. Títù dé bá a níbẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn gan-an. Títù sọ fún Pọ́ọ̀lù pé àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì fara mọ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó sọ fún wọn. Àwọn pẹ̀lú sì ń fẹ́ láti rí i. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbọ́ ìròyìn rere yìí, inú rẹ̀ dùn púpọ̀.—2 Kọ́r. 2:12, 13; 7:5-9.

2. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì nípa ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí?

2 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì. Ó sọ fún wọn pé: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, ṣùgbọ́n a jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín, nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” (2 Kọ́r. 1:24) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí? Kí sì ni àwọn alàgbà lè rí kọ́ nínú rẹ̀?

ÌGBÀGBỌ́ WA ÀTI ÌDÙNNÚ WA

3. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró”? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lóde òní?

3 Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ohun méjì tó ṣe pàtàkì pé ká ní, ìyẹn ìgbàgbọ́ àti ìdùnnú. Ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́. Ó ní: “Kì í ṣe pé a jẹ́ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ yín, . . . nítorí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín ni ẹ dúró.” Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ yìí láti fi hàn pé kì í ṣe torí ti òun tàbí torí ẹlòmíì ni àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì fi jẹ́ adúróṣinṣin. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run ló mú kí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin. Torí náà, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kò pọn dandan fún òun láti máa darí ìgbàgbọ́ wọn, kò sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run, wọ́n sì fẹ́ láti máa ṣe ohun tó tọ́. (2 Kọ́r. 2:3) Àwọn alàgbà náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lóde òní. Wọ́n gbà pé àwọn ará ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì ń fi ọkàn rere sìn ín. (2 Tẹs. 3:4) Wọn kì í ṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fún ìjọ. Ńṣe ni wọ́n máa ń jẹ́ káwọn ará mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Wọ́n sì máa ń gbà wọ́n níyànjú láti tẹ̀ lé ìtọ́ni látọ̀dọ̀ ètò Jèhófà. Ó ṣe tán, àwọn alàgbà òde òní kì í jẹ ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ àwọn ará.—1 Pét. 5:2, 3.

4. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “A jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín”? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lóde òní?

4 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé: “A jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín.” Àwọn wo ni Pọ́ọ̀lù pè ní “alábàáṣiṣẹ́pọ̀”? Àwọn ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù kí wọ́n lè ran àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì lọ́wọ́. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nínú lẹ́tà yẹn kan náà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì, ó dárúkọ méjì lára wọn. Ó ní: “Jésù, tí a wàásù rẹ̀ láàárín yín nípasẹ̀ wa, èyíinì ni, nípasẹ̀ èmi àti Sílífánù àti Tímótì.” (2 Kọ́r. 1:19) Yàtọ̀ síyẹn, níbikíbi tí Pọ́ọ̀lù bá ti lo ọ̀rọ̀ náà, “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀, ó sábà máa ń tọ́ka sí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Lára wọn ni Àpólò, Ákúílà, Pírísíkà, Tímótì àti Títù. (Róòmù 16:3, 21; 1 Kọ́r. 3:6-9; 2 Kọ́r. 8:23) Kí wá ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “A jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú yín”? Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Pọ́ọ̀lù àti àwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ fẹ́ láti sa gbogbo ipá wọn kí àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì lè máa fi ìdùnnú sin Ọlọ́run. Ohun tí àwọn alàgbà ń ṣe lóde òní náà nìyẹn. Wọ́n fẹ́ láti sa gbogbo ipá wọn kí gbogbo àwọn ará lè máa ‘fi ayọ̀ sin Jèhófà.’—Sm. 100:2; Fílí. 1:25.

5. Àwọn ìbéèrè wo ni wọ́n bi àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan? Kí ló yẹ ká ṣe bá a ṣe ń jíròrò ohun táwọn ará sọ nípa àwọn alàgbà?

5 Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n bi àwọn ará kan láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé ní ìbéèrè méjì. Àwọn ìbéèrè náà ni pé: “Ọ̀rọ̀ wo ni alàgbà kan sọ tó múnú rẹ dùn? Ìwà wo sì ni alàgbà kan hù tó mú kó o túbọ̀ láyọ̀?” Ní báyìí, a máa rí díẹ̀ lára ohun tí àwọn ará sọ nípa àwọn alàgbà. Bí a bá ṣe ń bá ìjíròrò náà lọ, máa ronú nípa ohun tí àwọn alàgbà ti sọ tàbí ohun tí wọ́n ti ṣe tó mú kó o túbọ̀ láyọ̀. Gbogbo wa náà sì lè máa ronú nípa ohun tá a lè ṣe láti mú kí ayọ̀ àwọn ará nínú ìjọ wa túbọ̀ pọ̀ sí i. *

‘Ẹ KÍ PÉSÍSÌ OLÙFẸ́ WA Ọ̀WỌ́N’

6, 7. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, Pọ́ọ̀lù àti àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mìíràn? (b) Kí nìdí tí inú àwọn ará fi máa ń dùn tá a bá rántí orúkọ wọn?

6 Ọ̀pọ̀ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sọ pé inú àwọn máa ń dùn táwọn bá rí i pé ọ̀rọ̀ àwọn jẹ àwọn alàgbà lógún. Àwọn alàgbà lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ará jẹ àwọn lógún bí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì, Élíhù àti Jésù. (Ka 2 Sámúẹ́lì 9:6; Jóòbù 33:1; Lúùkù 19:5.) Ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ṣe ni pé wọ́n máa ń fi orúkọ táwọn èèyàn ń jẹ́ pè wọ́n. Pọ́ọ̀lù náà sì rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí òun rántí orúkọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun, kí òun sì máa fi orúkọ wọn pè wọ́n. Ní ìparí ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tó kọ, ó dárúkọ àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ju mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lọ. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà ni Pésísì. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ kí . . . Pésísì olùfẹ́ wa ọ̀wọ́n.”—Róòmù 16:3-15.

7 Ó máa ń ṣòro fún àwọn alàgbà kan láti rántí orúkọ àwọn ará. Síbẹ̀, tí alàgbà kan bá sapá gidigidi láti máa rántí orúkọ àwọn ará nínú ìjọ, ohun tó ń sọ ni pé ọwọ́ pàtàkì lòun fi mú wọn. (Ẹ́kís. 33:17) Inú àwọn ará sì tún máa ń dùn táwọn alàgbà bá rántí orúkọ wọn nígbà tí wọ́n bá ń pè wọ́n láti dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tàbí láwọn ìpàdé míì.—Fi wé Jòhánù 10:3.

“Ó ṢE Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ÒPÒ NÍNÚ OLÚWA”

8. Ọ̀nà pàtàkì wo ni Pọ́ọ̀lù gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù?

8 Pọ́ọ̀lù tún fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ òun lógún lọ́nà mìíràn. Ó máa ń gbóríyìn fún wọn. Ìyẹn sì tún jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan táwọn alàgbà fi lè mú kí àwọn ará máa fayọ̀ sin Ọlọ́run. Nígbà tó kọ lẹ́tà sí àwọn ará ní Kọ́ríńtì, ó sọ fún wọn pé: “Mo ní ìṣògo ńláǹlà nípa yín.” (2 Kọ́r. 7:4) Ó dájú pé ìwúrí lọ̀rọ̀ yìí máa jẹ́ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì! Pọ́ọ̀lù tún gbóríyìn fún àwọn ìjọ míì nítorí iṣẹ́ rere wọn. (Róòmù 1:8; Fílí. 1:3-5; 1 Tẹs. 1:8) Kódà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti dárúkọ Pésísì tán nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Róòmù, ó sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpò nínú Olúwa.” (Róòmù 16:12) Ohun ìwúrí ni ọ̀rọ̀ yìí ti ní láti jẹ́ fún arábìnrin olùṣòtítọ́ yẹn! Ó ṣe kedere pé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù ni Pọ́ọ̀lù ń tẹ̀ lé bó ṣe ń gbóríyìn fún àwọn míì.—Ka Máàkù 1:9-11; Jòhánù 1:47; Ìṣí. 2:2, 13, 19.

9. Tí gbogbo wa bá ń gbóríyìn fún ara wa nínú ìjọ, báwo nìyẹn á ṣe mú ká máa láyọ̀?

9 Lóde òní, àwọn alàgbà náà mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa gbóríyìn fún àwọn ará. (Òwe 3:27; 15:23) Bí alàgbà kan bá ń gbóríyìn fún àwọn ará, ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ fún wọn ni pé: ‘Mò ń rí gbogbo ìsapá yín o. Mo sì mọrírì rẹ̀ gan-an ni.’ Àwọn ará máa ń fẹ́ kí àwọn alàgbà bá wọn sọ̀rọ̀, torí pé ọ̀rọ̀ àwọn alàgbà máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Arábìnrin kan tó ti lé lẹ́ni àádọ́ta [50] ọdún sọ pé: “Àwọn èèyàn kì í sábà gbóríyìn fún mi níbi iṣẹ́. Wọn ò rí ti ẹlòmíì rò rárá. Bí wọ́n ṣe máa ṣe ohun tó tayọ táwọn míì ni wọ́n ń lé. Torí náà, bí alàgbà kan bá yìn mí torí ohun kan tí mo ṣe nínú ìjọ, ó máa ń tù mí lára gan-an. Ó sì máa ń sọ agbára mi dọ̀tun! Ó máa ń jẹ́ kí n rí i pé Ọlọ́run fẹ́ràn mi.” Arákùnrin kan tó ń dá tọ́mọ méjì náà sọ ohun tó jọ èyí. Ó ní alàgbà kan sọ fún òun lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé òun mọrírì wàhálà tóun ń ṣe lórí àwọn ọmọ wọ̀nyẹn. Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára arákùnrin náà? Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ alàgbà yẹn fún mi ní ìṣírí gan-an ni!” Èyí mú kó ṣe kedere pé bí alàgbà kan bá ń yin àwọn arákùnrin àti arábìnrin látọkàn wá, ńṣe ló máa mú kí wọ́n máa bá a nìṣó láti fi ayọ̀ sin Ọlọ́run, “àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísá. 40:31.

MÁA “ṢE OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN ÌJỌ ỌLỌ́RUN”

10, 11. (a) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nehemáyà? (b) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fún ìgbàgbọ́ arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ̀ lókun nígbà tó bá lọ bẹ̀ ẹ́ wò?

10 Ọ̀nà pàtàkì míì tí àwọn alàgbà lè gbà fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ará kí wọ́n lè máa fi ayọ̀ sin Ọlọ́run ni pé kí wọ́n tètè máa ran àwọn tó bá nílò ìṣírí lọ́wọ́. (Ka Ìṣe 20:28.) Bí àwọn alàgbà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé nígbà kan, ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn arákùnrin Nehemáyà kan tí wọ́n jẹ́ Júù. Torí náà, ó dìde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì fún wọn ní ìṣírí. (Neh. 4:14) Bí àwọn alàgbà náà ṣe máa ń ṣe lóde òní nìyẹn. Bí àwọn ará nínú ìjọ bá rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn alàgbà máa ń wá àwọn ará lọ sílé wọn kí wọ́n lè fún wọn ní “ẹ̀bùn ẹ̀mí,” ìyẹn ni pé kí wọ́n bá wọn sọ̀rọ̀ tó máa gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. (Róòmù 1:11) Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè gbé ìgbàgbọ́ àwọn ará ró?

11 Alàgbà kan gbọ́dọ̀ ronú dáadáa nípa àwọn tó fẹ́ lọ fún ní ìṣírí kó tó lọ sọ́dọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè bi ara rẹ̀ pé: “Àwọn ìṣòro wo ló ń bá onítọ̀hún fínra? Kí ni mo lè sọ tó máa mú kí ara tù ú? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tàbí ìtàn Bíbélì wo ló máa fún un ní ìṣírí? Bí alàgbà kan bá bi ara rẹ̀ ní irú àwọn ìbéèrè yìí kó tó lọ bẹ arákùnrin tàbí arábìnrin kan wò, á lè mú kí alàgbà náà sọ ohun tó máa ran onítọ̀hún lọ́wọ́, kò sì ní jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n á kàn máa tàkúrọ̀sọ lásán. Bí alàgbà kan bá sì lọ bẹ àwọn ará wò, ńṣe ló yẹ kó jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tó bá wà lọ́kàn wọn. Ó sì yẹ kí alàgbà náà tẹ́tí sílẹ̀ tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. (Ják. 1:19) Arábìnrin kan sọ pé: “Ó máa ń tù mí lára gan-an tí mo bá rí i pé tọkàntọkàn ni alàgbà kan fi ń tẹ́tí gbọ́ mi.”—Lúùkù 8:18.

Àwọn alàgbà máa ń múra sílẹ̀ kí wọ́n tó bẹ̀ wá wò, kí wọ́n lè sọ ohun tó máa gbé ìgbàgbọ́ wa ró

12. Àwọn wo ló yẹ káwọn alàgbà máa fún ní ìṣírí nínú ìjọ? Kí nìdí?

12 Àwọn wo ló yẹ káwọn alàgbà máa bẹ̀ wò nínú ìjọ? Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà pé kí wọ́n “kíyè sí . . . gbogbo agbo.” Torí náà gbogbo àwọn ará nínú ìjọ ló nílò ìṣírí. Kódà, àwọn tó ti jẹ́ akéde tàbí aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún náà nílò ìṣírí. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn alàgbà máa fún wọn ní ìṣírí? Ìdí ni pé irú àwọn ará tó ń ṣe déédéé bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú máa ń ní àwọn ìṣòro kan tó ń bá wọn fínra. Ìgbà míì sì wà tó máa ń ṣe wọ́n bíi pé wọn ò lè dá ẹrù náà gbé mọ́. Ìtàn kan tiẹ̀ wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé ìgbà míì wà tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n jẹ́ onítara máa nílò ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba nígbà kan.

‘ÁBÍṢÁÌ RÀN ÁN LỌ́WỌ́’

13. (a) Ipò wo ni Dáfídì wà nígbà tí Iṣibi-bénóbù fẹ́ láti ṣá a balẹ̀? (b) Báwo ni Ábíṣáì ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ kó tó pẹ́ jù?

13 Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti fi òróró yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba, ó bá òmìrán kan jà. Gòláyátì ni orúkọ òmìrán yìí, inú ẹ̀yà Réfáímù ló sì ti wá. Dáfídì fi ìgboyà kojú òmìrán yìí, ó sì pa á. (1 Sám. 17:4, 48-51; 1 Kíró. 20:5, 8) Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì lọ bá àwọn Filísínì jà. Dáfídì tún dojú kọ òmìrán míì. Iṣibi-bénóbù ni orúkọ rẹ̀. Inú ẹ̀yà Réfáímù ni òun náà sì ti wá. (2 Sám. 21:16) Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí, díẹ̀ ló kù kí òmìrán náà pa Dáfídì. Kí nìdí? Kì í ṣe nítorí pé Dáfídì ò ní ìgboyà mọ́. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ nítorí pé kò lágbára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ó sì rẹ Dáfídì.” Gbàrà tí Iṣibi-bénóbù rí èyí, ó “ronú nípa ṣíṣá Dáfídì balẹ̀.” Àmọ́, kí òmìrán náà tó fi ohun ìjà rẹ̀ pa Dáfídì, “ní kíá, Ábíṣáì ọmọkùnrin Seruáyà wá” ran Dáfídì “lọ́wọ́, ó sì ṣá Filísínì náà balẹ̀, ó sì fi ikú pa á.” (2 Sám. 21:15-17) Bí ikú ṣe yẹ̀ lórí Dáfídì nìyẹn o! Ó dájú pé Dáfídì máa dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Ábíṣáì pé ó kíyè sí òun, ó sì yára wá yọ òun nínú ewu. Kí ni ìtàn yìí kọ́ wa?

14. (a) Kí ló lè mú ká borí àwọn ìṣòro tó kọjá àfẹnusọ? (b) Bí iṣẹ́ ìsìn àwọn kan bá ti ń jó rẹ̀yìn tí wọn ò sì láyọ̀ mọ́, báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? Kí ni arábìnrin kan sọ?

14 Bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé, Sátánì àtàwọn ọ̀tá ìhìn rere ń mú àwọn nǹkan nira fún wa. Kódà, àwọn kan lára wa ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó kọjá àfẹnusọ. Àmọ́, a máa ń bi àwọn ìṣòro náà lulẹ̀ torí pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Ṣùgbọ́n, nítorí pé bí ìṣòro kan ṣe ń lọ ni òmíràn ń yọjú, ó lè rẹ̀ wá nígbà míì ká sì rẹ̀wẹ̀sì. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, ó lè nira fún wa láti fara da àwọn ìṣòro tí a kò kà sí bàbàrà tẹ́lẹ̀. Àmọ́, alàgbà kan lè kíyè sí wa, kó sì ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a nílò rẹ̀ gan-an. Okun tá a bá rí gbà á wá mú ká lè máa bá a nìṣó láti fi ayọ̀ sin Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ nínú wa ló ti rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà. Arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ti lé lẹ́ni ọgọ́ta [60] ọdún sọ pé: “Nígbà kan, ara mi ò le, ó sì sú mi láti máa lọ sóde ẹ̀rí. Alàgbà kan ṣàkíyèsí pé ìtara mi ti ń dín kù, ó sì tọ̀ mí wá. Ó fi Bíbélì gbà mí níyànjú. Mo fi àwọn àbá tó fún mi sílò, mo sì jàǹfààní púpọ̀ látinú rẹ̀.” Ó sọ síwájú sí i pé: “Ohun tó fìfẹ́ hàn ni alàgbà yẹn ṣe o! Ó kíyè sí i pé ìtara mi ti ń dín kù, ó sì ràn mí lọ́wọ́!” Ohun àgbàyanu ló jẹ́ pé a ní àwọn alàgbà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, tí wọ́n sì ṣe tán ní gbogbo ìgbà láti ràn wá lọ́wọ́ bí Ábíṣáì ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́.

‘Ẹ MỌ ÌFẸ́ TÍ MO NÍ FÚN YÍN’

15, 16. (a) Kí nìdí tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi fẹ́ràn Pọ́ọ̀lù? (b) Kí nìdí tá a fi fẹ́ràn àwọn alàgbà ìjọ wa?

15 Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn alàgbà ń ṣe o! Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọn kì í sùn torí pé wọ́n ń ṣàníyàn nítorí àwọn ará. Ìgbà míì sì wà tí wọ́n lè ta jí lóru kí wọ́n lè gbàdúrà nítorí àwọn ará tàbí kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 11:27, 28) Àmọ́, bíi ti Pọ́ọ̀lù, inú àwọn alàgbà máa ń dùn láti ṣe ojúṣe wọn. Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kọ́ríńtì pé: “Èmi yóò máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an náwó, a ó sì ná mi tán pátápátá fún ọkàn yín.” (2 Kọ́r. 12:15) Nítorí pé Pọ́ọ̀lù fẹ́ràn àwọn ará, ó “ná” ara rẹ̀ nítorí wọn. Lédè mìíràn, ó lo gbogbo okun rẹ̀ kó bàa lè gbé ìgbàgbọ́ wọn ró. (Ka 2 Kọ́ríńtì 2:4; Fílí. 2:17; 1 Tẹs. 2:8) Abájọ táwọn ará fi nífẹ̀ẹ́ Pọ́ọ̀lù gan-an!—Ìṣe 20:31-38.

16 Àwa pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ àwọn alàgbà wa, a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń lò wọ́n láti máa bójú tó wa. Inú wa dùn pé ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ wọ́n lógún. A láyọ̀ pé wọ́n máa ń bẹ̀ wá wò kí wọ́n lè fún wa ní ìṣírí. A sì tún dúpẹ́ pé wọ́n máa ń gbára dì nígbà gbogbo kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́, pàápàá jù lọ, táwọn ìṣòro wa bá ti fẹ́ wọ̀ wá lọ́rùn. Láìsí àní-àní, irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún ìdùnnú wa.’

^ ìpínrọ̀ 5 Wọ́n tún bi àwọn arákùnrin àti arábìnrin yẹn pé: “Irú ìwà wo ló wù ẹ́ jù lọ pé kí alàgbà kan ní?” Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sọ pé àwọn fẹ́ kí alàgbà jẹ́ “ẹni tó ṣeé sún mọ́.” Àpilẹ̀kọ kan ṣì ń bọ̀ wá sọ púpọ̀ sí i nípa èyí.