‘Ọmọ Fẹ́ Láti Ṣí Baba Payá’
‘Ọmọ Fẹ́ Láti Ṣí Baba Payá’
“Ẹni tí Baba . . . jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ, àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.”—LÚÙKÙ 10:22.
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù nìkan ló kúnjú ìwọ̀n láti ṣí Baba rẹ̀ payá?
Báwo ni Jésù ṣe ṣí Baba rẹ̀ payá fún àwọn èèyàn?
Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tó o bá fẹ́ ṣí Baba payá?
1, 2. Ìbéèrè wo ló ti rú ọ̀pọ̀ èèyàn lójú, kí sì nìdí?
‘TA NI Ọlọ́run?’ Ìbéèrè yìí ti rú ọ̀pọ̀ èèyàn lójú. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni gbà gbọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn gbà pé ẹ̀kọ́ náà kò ṣeé lóye. Òǹkọ̀wé kan tó tún jẹ́ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì sọ pé: “Ẹ̀kọ́ ìsìn yìí kọjá ohun tí ọpọlọ èèyàn lè gbé. Ó kọjá èrò àti ọgbọ́n ẹ̀dá.” Ní ti àwọn tó gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn gbà pé kò sí Ọlọ́run. Wọ́n ń sọ pé nípasẹ̀ èèṣì ni gbogbo ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run dá fi wà. Síbẹ̀, dípò kí Charles Darwin tó dá ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n sílẹ̀ sọ pé kò sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Lójú tèmi o, ibi tó jọ pé ó dára jù lọ ká parí ọ̀rọ̀ náà sí ni pé gbogbo ọ̀ràn yìí kọjá ohun tá a lè fi ọgbọ́n èèyàn ṣàlàyé.”
2 Láìka ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn gbà gbọ́ sí, ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa Ọlọ́run ló ń jà gùdù nínú ọkàn wọn. Àmọ́, bí ọ̀pọ̀ lára wọn kò bá rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn, ńṣe ni wọ́n máa ń jáwọ́ nínú wíwá Ọlọ́run. Ìyẹn jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Sátánì ti “fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.” (2 Kọ́r. 4:4) Abájọ tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn tó ń gbé láyé kò fi mọ Baba tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ayé àtọ̀run, wọn kò sì mọ ohun tó yẹ kí wọ́n gbà gbọ́ nípa rẹ̀!—Aísá. 45:18.
3. (a) Ta ló ṣí Ẹlẹ́dàá payá fún wa? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?
3 Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Kí nìdí? Ìdí ni pé kìkì àwọn tó bá ń ké pe “orúkọ Jèhófà” ló máa rí ìgbàlà. (Róòmù 10:13) Lára ohun tó wé mọ́ pípe orúkọ Ọlọ́run ni pé ká mọ irú Ẹni tí Jèhófà jẹ́. Jésù Kristi fi òtítọ́ pàtàkì yìí kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó ṣí ẹni tí Baba jẹ́ payá fún wọn. (Ka Lúùkù 10:22.) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti ṣí Baba payá lọ́nà tí kò sí ẹlòmíì tó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Báwo ló ṣe ṣe é? Báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tá a bá fẹ́ ṣí Baba payá fún àwọn èèyàn? Ẹ jẹ́ ká tú iṣu àwọn ìbéèrè yìí désàlẹ̀ ìkòkò.
JÉSÙ KRISTI NÌKAN LÓ KÚNJÚ ÌWỌ̀N LÁTI ṢÍ BABA PAYÁ
4, 5. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù nìkan ló kúnjú ìwọ̀n láti ṣí Baba rẹ̀ payá?
4 Jésù ló kúnjú ìwọ̀n jù lọ láti ṣí Baba rẹ̀ payá. Kí nìdí? Ìdí ni pé kí Ọlọ́run tó dá gbogbo ohun alààyè yòókù, ẹ̀dá ẹ̀mí tó wá di ẹni tá a mọ̀ sí Jésù yìí ti wà ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.” (Jòh. 1:14; 3:18) Ipò àrà ọ̀tọ̀ mà nìyẹn o! Jésù nìkan ló wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ kó tó di pé ó dá àwọn nǹkan mìíràn. Ìyẹn mú kí Ọlọ́run pa gbogbo àfiyèsí rẹ̀ pọ̀ sórí Jésù. Bí Baba àti Ọmọ yìí sì ṣe máa ń bára wọn sọ̀rọ̀ ní fàlàlà ti mú kó ṣeé ṣe fún Jésù láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn ànímọ́ Rẹ̀. Bí àjọṣe tó wà láàárín wọn fún ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún sì ṣe ń lágbára sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Jòh. 5:20; 14:31) Ẹ sì wá wo bí òye tí Ọmọ yìí máa ní nípa ìwà Baba rẹ̀ á ṣe jinlẹ̀ tó!—Ka Kólósè 1:15-17.
5 Baba yan Ọmọ gẹ́gẹ́ bí Agbọ̀rọ̀sọ Rẹ̀, ìyẹn “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (Ìṣí. 19:13) Fún ìdí yìí, Jésù nìkan ló kúnjú ìwọ̀n láti ṣí Baba payá fún àwọn èèyàn. Ó bá a mu nígbà náà pé Jòhánù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ pé Jésù tí í ṣe “Ọ̀rọ̀ náà,” wà “ní ipò oókan àyà lọ́dọ̀ Baba.” (Jòh. 1:1, 18) Jòhánù fi gbólóhùn yẹn ṣàlàyé àṣà kan tó wọ́pọ̀ nígbà ayé rẹ̀ bí àwọn èèyàn bá ń jẹun. Ńṣe ni àlejò kan máa ń jókòó sí iwájú òmíràn lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú kan náà. Bí àwọn méjèèjì ṣe jókòó sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí lè mú kó rọrùn fún wọn láti máa bára wọn sọ̀rọ̀. Torí náà, bí Ọmọ ṣe wà “ní ipò oókan àyà” Baba rẹ̀ mú kí wọ́n jọ máa finú konú.
6, 7. Báwo ni àjọṣe tó wà láàárín Baba àti Ọmọ ṣe ń lágbára sí i?
6 Ńṣe ni àjọṣe tó wà láàárín Baba àti Ọmọ ń lágbára sí i. Ọmọ “sì wá jẹ́ ẹni tí [Ọlọ́run] ní ìfẹ́ni sí lọ́nà àkànṣe lójoojúmọ́.” (Ka Òwe 8:22, 23, 30, 31.) Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn méjèèjì máa lágbára sí i bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ tí Ọmọ sì ń kọ́ láti fi ìwà jọ Baba rẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn ẹ̀dá olóye mìíràn, Ọmọ rí bí Jèhófà ṣe ń bá olúkúlùkù wọn lò, ìmọrírì tó ní fún àwọn ànímọ́ Ọlọ́run sì wá lágbára sí i.
7 Kódà, nígbà tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé Sátánì pe ẹ̀tọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run níjà, Ọmọ ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa lo ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára lábẹ́ ipò tó ṣòro. Ó sì tún dájú pé ìyẹn múra Jésù sílẹ̀ kó lè kojú àwọn ìṣòro tí òun fúnra rẹ̀ bá pàdé nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Jòh. 5:19.
8. Báwo ni àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ ohun tó pọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Baba?
8 Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí Ọmọ ní pẹ̀lú Jèhófà mú kó lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa Baba lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò lè gbà ṣàlàyé rẹ̀. Ǹjẹ́ ọ̀nà míì wà tá a tún lè gbà mọ Baba tó kọjá pé ká ronú lórí ohun tí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kọ́ wa àti ohun tó ṣe? A lè ṣàpèjúwe rẹ̀ báyìí: Ronú nípa bó ṣe máa ṣòro fún wa tó láti lóye ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” túmọ̀ sí bó bá jẹ́ pé àlàyé tí ìwé atúmọ̀ èdè ṣe nípa rẹ̀ nìkan la kà. Síbẹ̀, tá a bá ronú lórí àlàyé tó ṣe kedere tí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere ṣe nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti bó ṣe máa ń bójú tó àwọn èèyàn, òye wa nípa gbólóhùn náà “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” á túbọ̀ pọ̀ sí i. (1 Jòh. 4:8, 16) Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nípa àwọn ànímọ́ míì tí Jésù ṣí payá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé Ọlọ́run ní nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé náà nìyẹn.
BÍ JÉSÙ ṢE ṢÍ BABA RẸ̀ PAYÁ
9. (a) Ọ̀nà pàtàkì méjì wo ni Jésù gbà ṣí Baba rẹ̀ payá? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan tó fi hàn bí Jésù ṣe fi àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣí Baba rẹ̀ payá.
9 Báwo ni Jésù ṣe ṣí Baba payá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti fún àwọn tó ń bọ̀ wá di ọmọlẹ́yìn rẹ̀? Ọ̀nà pàtàkì méjì ló gbà ṣe bẹ́ẹ̀: nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti nípasẹ̀ ìwà rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni. Ohun tí Jésù fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa Baba rẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní òye tó jinlẹ̀ gan-an nípa èrò Baba rẹ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti bó ṣe ń ṣe nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Jésù fi Baba rẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ tó wá àgùntàn rẹ̀ kan tó sọ nù lọ. Ó sọ pé nígbà tí olùṣọ́ àgùntàn náà rí àgùntàn rẹ̀ tó sọ nù, ó “yọ̀ púpọ̀ lórí rẹ̀ ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún tí kò tíì ṣáko lọ.” Àlàyé wo ni Jésù ṣe nípa àpèjúwe yìí? Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.” (Mát. 18:12-14) Kí ni àpèjúwe yìí kọ́ ẹ nípa Jèhófà? Kódà, tó bá ṣe ẹ́ bíi pé o kò já mọ́ nǹkan kan nígbà míì tàbí pé a ti gbàgbé rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ ṣì jẹ Baba rẹ ọ̀run lógún yóò sì máa bójú tó ẹ. Lójú rẹ̀, ọ̀kan lára “àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí” lo jẹ́.
10. Báwo ni Jésù ṣe fi ìwà rẹ̀ ṣí Baba rẹ̀ payá?
10 Ọ̀nà kejì tí Jésù gbà ṣí Baba rẹ̀ payá fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ ìwà rẹ̀. Torí náà, nígbà tí àpọ́sítélì Fílípì sọ fún Jésù pé: “Fi Baba hàn wá,” Jésù fèsì lọ́nà tó bá a mu pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòh. 14:8, 9) Ní báyìí, ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa bí Jésù ṣe fi àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀ hàn. Nígbà tí adẹ́tẹ̀ kan bẹ Jésù pé kó wo òun sàn, Jésù fi ọwọ́ kan ọkùnrin “tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀” náà, ó sì sọ fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Kò sí àní-àní pé nígbà tí ẹ̀tẹ̀ náà kúrò, adẹ́tẹ̀ náà rí ọwọ́ Jèhófà lára ohun tí Jésù ṣe. (Lúùkù 5:12, 13) Bákan náà nígbà tí Lásárù kú, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti ní láti rí bí Baba ṣe ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn tó nígbà tí Jésù ‘kérora nínú ẹ̀mí, tó dààmú, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé òun máa jí Lásárù dìde, ó mọ bí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Lásárù ṣe rí lára. (Jòh. 11:32-35, 40-43) Ó dájú pé àwọn àkọsílẹ̀ tó o yàn láàyò wà nínú Bíbélì, tó jẹ́ kó o rí bí ohun tí Jésù ṣe ṣe fi hàn pé Baba jẹ́ aláàánú.
11. (a) Kí ni Jésù ṣí payá nípa Baba rẹ̀ nígbà tó fọ tẹ́ńpìlì mọ́? (b) Kí nìdí tí àkọsílẹ̀ tó sọ nípa bí Jésù ṣe fọ tẹ́ńpìlì mọ́ ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
11 Àmọ́, kí lo rí fà yọ nínú bí Jésù ṣe fọ tẹ́ńpìlì mọ́? Fojú yàwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀: Jésù fi àwọn ìjàrá tàbí okùn ṣe pàṣán, ó sì lé àwọn tó ń ta màlúù àti àgùntàn jáde. Ó sojú àwọn tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé, ẹyọ owó wọn sì dà sílẹ̀. (Jòh. 2:13-17) Ìgbésẹ̀ tó lágbára tí Jésù gbé yìí mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rántí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Dáfídì Ọba pé: “Ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run.” (Sm. 69:9) Bí Jésù ṣe dá àwọn èèyàn yẹn lẹ́kun ìwà tí kò tọ́ fi hàn pé ó wù ú gan-an pé kó gbèjà ìjọsìn tòótọ́. Ǹjẹ́ o kíyè sí bí àwọn ànímọ́ Baba ṣe fara hàn nínú àkọsílẹ̀ yẹn? Ó jẹ́ ká rántí pé kì í wulẹ̀ ṣe pé Ọlọ́run ní agbára tí kò láàlà láti fọ ìwà ibi mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé nìkan ni, àmọ́ ó tún wù ú gan-an pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tí Bíbélì sọ nípa bí Jésù ṣe dá àwọn tó hùwà àìtọ́ lẹ́kun lọ́nà tó lágbára yìí jẹ́ ká mọ bí ìwà ibi tó gbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lónìí ṣe rí lára Baba rẹ̀. Ẹ sì wo bí ìyẹn ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀ tó bí wọ́n bá ń hùwà tí kò tọ́ sí wa!
12, 13. Kí lo lè rí kọ́ nípa Jèhófà nínú bí Jésù ṣe bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò?
12 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àpẹẹrẹ míì, ìyẹn ọ̀nà tí Jésù gbà bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lò. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa ń jiyàn ṣáá nípa ẹni tí ó tóbi jù láàárín wọn. (Máàkù 9:33-35; 10:43; Lúùkù 9:46) Ìrírí tí Jésù ní ní àkókò gígùn tó fi wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ mú kó mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo irú ìwà ìgbéraga bẹ́ẹ̀. (2 Sám. 22:28; Sm. 138:6) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jésù ti rí i pé irú ìwà ìgbéraga bẹ́ẹ̀ ni Sátánì Èṣù ń hù. Ó mọ̀ pé agbéraga ẹ̀dà yìí fẹ́ràn láti máa gbé ara rẹ̀ lárugẹ, ó sì máa ń wá ipò ọlá. Torí náà, ó ti ní láti ba Jésù lọ́kàn jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ṣì ń wá ipò ọlá láàárín ara wọn! Ó tún wá lọ jẹ́ láàárín àwọn tó ti yàn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì! Wọ́n ṣì fi hàn pé àwọn ń wá ipò ọlá títí di ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé. (Lúùkù 22:24-27) Síbẹ̀, Jésù ń bá a nìṣó láti máa fi inú rere hàn sí wọn nígbà tó bá ń bá wọn wí, ó nírètí pé bó bá yá wọn máa kọ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ òun.—Fílí. 2:5-8.
13 Ǹjẹ́ o rí bí ànímọ́ Jèhófà ṣe fara hàn nínú ọ̀nà tí Jésù gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ tó sì fi sùúrù ṣe àtúnṣe ìwà tí kò tọ́ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ hù? Ǹjẹ́ o kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹni tí Baba jẹ́ nínú ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe? Baba rẹ̀ kì í pa àwọn èèyàn rẹ̀ tì bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń ṣe àṣìṣe nígbà gbogbo. Ǹjẹ́ bá a ṣe mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní yìí kò mú ká fẹ́ láti ronú pìwà dà, ká sì gbàdúrà sí i pé kó dárí àwọn àṣìṣe wa jì wá?
ỌMỌ FẸ́ LÁTI ṢÍ BABA RẸ̀ PAYÁ
14. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun fẹ́ láti ṣí Baba òun payá?
14 Ọ̀pọ̀ àwọn apàṣẹwàá máa ń fi ìsọfúnni pa mọ́ fún àwọn èèyàn torí pé wọ́n fẹ́ láti máa jẹ gàba lé wọn lórí, wọn kò sì fẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó ń lọ. Àmọ́ ti Jésù kò rí bẹ́ẹ̀. Ó fẹ́ láti fi ohun tó mọ̀ nípa Baba rẹ̀ han àwọn èèyàn, kí ó sì ṣí gbogbo ohun tó yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Rẹ̀ payá fún wọn. (Ka Mátíù 11:27.) Láfikún sí i, Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní “agbára ìmòye kí [wọ́n] lè jèrè ìmọ̀ nípa ẹni tòótọ́ náà,” Jèhófà Ọlọ́run. (1 Jòh. 5:20) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Jésù ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ohun tí ó ń kọ́ wọn nípa Baba. Kò fi ẹni tí Baba rẹ̀ jẹ́ pa mọ́ nípa kíkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ tó ṣàjèjì tí kò sí ẹni tó lè lóye rẹ̀, irú bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan.
15. Kí nìdí tí Jésù kò fi sọ gbogbo nǹkan tó mọ̀ nípa Baba rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
15 Ṣé gbogbo nǹkan tí Jésù mọ̀ nípa Baba rẹ̀ ló ṣí payá? Rárá o. Ó rí i pé ó bọ́gbọ́n mu kí òun má ṣe sọ gbogbo nǹkan tí òun mọ̀ nípa rẹ̀. (Ka Jòhánù 16:12.) Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ‘kò tíì lè gba irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ mọ́ra’ nígbà yẹn. Àmọ́, bí Jésù ṣe ṣàlàyé, wọ́n máa mọ ọ̀pọ̀ ohun tí wọn kò tíì mọ̀ tẹ́lẹ̀ nígbà tí “olùrànlọ́wọ́ náà,” ìyẹn ẹ̀mí mímọ́ bá dé, á sì ṣamọ̀nà wọn “sínú òtítọ́ gbogbo.” (Jòh. 16:7, 13) Bó ṣe jẹ́ pé àwọn òbí kì í fẹ́ sọ gbogbo ohun tí wọ́n mọ̀ fún àwọn ọmọ wọn títí tí wọ́n á fi dàgbà tó láti lóye irú nǹkan bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni Jésù ṣe dúró di ìgbà tí òtítọ́ á fi jinlẹ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n á sì lè lóye àwọn ohun pàtàkì kan nípa Baba. Jésù jẹ́ onínúure, ó sì mọ̀ pé ó ní ibi tí agbára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun mọ.
TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ JÉSÙ NÍPA RÍRAN ÀWỌN ÈÈYÀN LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ MỌ JÈHÓFÀ
16, 17. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣí ẹni tí Baba jẹ́ payá fún àwọn èèyàn?
16 Tó o bá mọ ẹnì kan dáadáa tó o sì mọrírì àwọn ànímọ́ rẹ̀ tó gbádùn mọ́ni, ǹjẹ́ kò ní wù ẹ́ pé kó o sọ fún àwọn míì nípa rẹ̀? Nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ fáwọn èèyàn nípa Baba rẹ̀. (Jòh. 17:25, 26) Ǹjẹ́ àwa náà lè máa ṣí Jèhófà payá fún àwọn èèyàn bí Jésù ti ṣe?
17 Bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí, Jésù ní ìmọ̀ tó pọ̀ gan-an nípa Baba rẹ̀ ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Síbẹ̀, ó máa ń fẹ́ sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó mọ̀ fún àwọn míì, débi pé ó tiẹ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní agbára ìmòye kí wọ́n lè ní òye tó jinlẹ̀ nípa ànímọ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ìrànlọ́wọ́ tí Jésù ṣe fún wa yìí kò ti jẹ́ ká mọrírì Baba wa ní ọ̀nà tó yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé nínú ayé lónìí? A mà dúpẹ́ o pé Jésù fẹ́ láti ṣí Baba rẹ̀ payá fún wa nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ìwà rẹ̀! Kódà, mímọ̀ tá a mọ Baba tó òun tá a lè fi yangàn. (Jer. 9:24; 1 Kọ́r. 1:31) Níwọ̀n bí a ti sapá láti sún mọ́ Jèhófà, òun náà ti sún mọ́ wa. (Ják. 4:8) Torí náà, a ní àǹfààní láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tá a mọ̀ nípa Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè ṣe é?
18, 19. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣí Baba payá fún àwọn èèyàn? Ṣàlàyé.
18 Àwa náà lè ṣí Baba payá fún àwọn èèyàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa ká sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Má ṣe gbàgbé pé ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí kò mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́. Àwọn ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n fi ń kọ́ wọn ti lè mú kí wọ́n má mọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an. A lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ wa nípa orúkọ Ọlọ́run, ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé àti irú ẹni tó jẹ́ fún wọn. Síwájú sí i, àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lè máa jíròrò díẹ̀ lára àwọn ìtàn inú Bíbélì tó ṣàlàyé ànímọ́ Ọlọ́run ní ọ̀nà tó yàtọ̀ sí bá a ṣe lóye rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ìyẹn lè jẹ́ kí àwọn náà jàǹfààní ohun tá a mọ̀ yẹn.
19 Bó o ṣe ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ṣé ìwọ náà lè fi ìwà rẹ ṣí Baba payá fún àwọn èèyàn? Bí àwọn èèyàn bá rí i nínú ìwà wa pé a ní irú ìfẹ́ tí Kristi ní, ó máa wu àwọn náà pé kí wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú Baba àti Jésù. (Éfé. 5:1, 2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé ká di ‘aláfarawé òun, àní gẹ́gẹ́ bí òun ti di ti Kristi.’ (1 Kọ́r. 11:1) Àǹfààní àgbàyanu la ní láti mú kí àwọn èèyàn tipasẹ̀ ìwà wa mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti fara wé Jésù nípa ṣíṣí Baba payá fún àwọn èèyàn.
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]