“Aláìlera Ni Mí Báyìí, àmọ́ Mi Ò Ní Wà Bẹ́ẹ̀ Títí Láé!”
“Aláìlera Ni Mí Báyìí, àmọ́ Mi Ò Ní Wà Bẹ́ẹ̀ Títí Láé!”
Gẹ́gẹ́ bí Sara van der Monde ṣe sọ ọ́
Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ fún mi pé, “Sara, ẹ̀rín máa ń dùn lẹ́nu ẹ ṣá. Kí nìdí tínú ẹ fi máa ń dùn gan-an nígbà gbogbo?” Mo máa ń sọ fún wọn pé ìrètí àrà ọ̀tọ̀ tí mo ní ló fà á. Mo lè ṣàpèjúwe ìrètí náà lọ́nà yìí, “Aláìlera ni mí báyìí, àmọ́ mi ò ní wà bẹ́ẹ̀ títí láé!”
ÌLÚ Paris, lórílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n bí mi sí lọ́dún 1974. Ó nira gan-an kí ìyá mi tó lè bí mi. Lẹ́yìn tó bí mi tán, àyẹ̀wò tí dókítà ṣe fi hàn pé mo ní àrùn cerebral palsy. Èyí jẹ́ àìlera kan nínú ọpọlọ tí kì í jẹ́ kí n lè gbé apá àti ẹsẹ̀ bí mo ṣe fẹ́, ó sì tún máa ń ṣòro fáwọn èèyàn láti lóye ohun tí mo bá sọ. Mo tún ní àrùn wárápá, mo sì máa ń tètè ṣàìsàn.
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjì, ìdílé wa kó lọ sí ìlú Melbourne, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, bàbá mi já èmi àti màmá mi jù sílẹ̀. Mo rántí pé ìyẹn ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo nímọ̀lára pé mo sún mọ́ Ọlọ́run. Màmá mi jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n máa ń mú mi lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé, ibẹ̀ ni mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ràn mi ó sì bìkítà nípa mi. Ìfẹ́ ti mo mọ̀ pé Ọlọ́run ní sí mi yìí àti ìfẹ́ tí màmá mi ní sí mi àti bó ṣe máa ń fọ̀rọ̀ gbé mi ró ti jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ti já wa jù sílẹ̀.
Màmá mi tún kọ́ mi bí mo ṣe lè máa gbàdúrà sí Jèhófà. Ó sì wá rọ̀ mí lọ́rùn gan-an láti máa gbàdúrà ju kí n máa sọ̀rọ̀ lọ. Torí pé bí mo bá ń gbàdúrà, kò pọn dandan fún mi láti sọ̀rọ̀ síta, ṣùgbọ́n ohun tí mò ń gbàdúrà lé lórí máa ń ṣe kedere lọ́kàn mi. Níwọ̀n bó sì ti ṣòro fáwọn èèyàn láti lóye ohun tí mo bá sọ, ó máa ń tù mí nínú láti mọ̀ pé Jèhófà lóye gbogbo ohun tí mo bá ń sọ, yálà mò ń rò ó lọ́kàn ni o tàbí mò ń kólòlò.—Sm. 65:2.
Bí Mo Ṣe Ń Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Dé Bá Mi
Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, àìlera mi ti le débi pé mi ò lè dá rìn mọ́ àyàfi bí mo bá ki ẹsẹ̀ bọ ohun kan báyìí tí wọ́n fi irin ṣe, èyí tí ìgbáròkó mi lè sinmi lé. Mi ò kí ń lè rìn dáadáa, ńṣe ni mo máa ń ṣe tàgétàgé! Mi ò tiẹ̀ lè rìn mọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlá. Nígbà tó ṣe, mi ò lè dá bọ́ sórí bẹ́ẹ̀dì mọ́, mi ò sì lè dá dìde kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì. Ẹ̀rọ kan tó ń lo iná ló ń gbé mi látorí bẹ́ẹ̀dì sórí kẹ̀kẹ́ àrọ. Kẹ̀kẹ́ náà ní ẹ́ńjìnnì, bí mo bá ti ń fọwọ́ darí irin kan tí wọ́n ṣe sí i lára ó máa ń gbé mi káàkiri.
Mo gbà pé nígbà míì àìlera mi máa ń mú kí inú mi bà jẹ́. Ṣùgbọ́n mo máa ń rántí àkọmọ̀nà ìdílé wa tó sọ pé: “Má yọra ẹ lẹ́nu nípa àwọn nǹkan tó ò bá lè ṣe. Èyí tápá ẹ bá ká ni kó o gbájú mọ́.” Èyí ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti gun ẹṣin, kí n wa ọkọ̀ ojú omi, kí n wa ọkọ̀ ọlọ́pọ́n, kí n pàgọ́,
kí n sì tún wa ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ láyìíká ilé! Mo fẹ́ràn iṣẹ́ ọnà, torí náà mo máa ń yàwòrán, mo máa ń ránṣọ, mo máa ń hun aṣọ, mo máa ń ṣe ọnà sára aṣọ, mo sì tún máa ń fi amọ̀ mọ nǹkan.Torí àìlera ńlá tí mo ní, àwọn kan ti rò pé mi ò ní ní làákàyè tó pọ̀ tó tí màá fi lè pinnu pé màá sin Ọlọ́run. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méjìdínlógún [18], ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ mi níléèwé rọ̀ mí pé kí n fi ilé sílẹ̀ kí n lè “bọ́ lọ́wọ́” ẹ̀sìn tí màmá mi ń ṣe. Ó tiẹ̀ sọ pé òun á bá mi wá ilé. Àmọ́, mo sọ fún un pé mi ò ní fi ẹ̀sìn mi sílẹ̀ láé, ìgbà tí mo bá sì ṣe tán láti máa dá gbé ni màá tó fi ilé sílẹ̀.
Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìjíròrò tí mo ní pẹ̀lú olùkọ́ mi yẹn ni mo ṣèrìbọmi ti mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, mo kó lọ sínú ilé kékeré kan. Níbẹ̀, mò ń rí ìrànlọ́wọ́ tí mo nílò gbà, mo lè pinnu ohun tí mo fẹ́ láti ṣe, èyí sì ń fún mi láyọ̀.
Ẹnì Kan Ṣàdédé Sọ Pé Kí N Fẹ́ Òun
Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ nǹkan míì ló ti dán ìgbàgbọ́ mi wò. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi lọ́jọ́ kan nígbà tí ẹni tá a jọ jẹ́ ọmọléèwé, tóun náà ní àìlera, sọ pé kí n fẹ́ òun. Eré ni mo kọ́kọ́ rò pé ó ń ṣe. Òótọ́ ni pé bó ṣe máa ń wu èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn obìnrin pé kí wọ́n lọ́kọ ló ṣe ń wu èmi náà. Àmọ́, ti pé àwa méjèèjì jọ ní àìlera kò fi dandan túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó wa máa lárinrin. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀sìn ọ̀dọ́kùnrin náà yàtọ̀ sí tèmi. Ohun táwa méjèèjì gbà gbọ́, ìgbòkègbodò wa àtàwọn ohun tá a fi ṣe àfojúsùn wa kò jọra rárá. Torí náà, báwo la ṣe lè jọ fẹ́ra? Mo sì ti pinnu láti ṣègbọràn sí ìtọ́ni tó ṣe kedere tí Ọlọ́run fún wa pé àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ nìkan ni ká jọ ṣègbéyàwó. (1 Kọ́r. 7:39) Torí náà, mo sọ fún ọ̀dọ́kùnrin náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé mi ò lè fẹ́ ẹ.
Títí di báyìí, mo mọ̀ pé ìpinnu tí mo ṣe tọ̀nà. Ó sì dá mi lójú dáadáa pé màá láyọ̀ nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Sm. 145:16; 2 Pét. 3:13) Kó tó dìgbà yẹn, mo ti pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà kí n sì jẹ́ kí ipò tí mo wà nísinsìnyí tẹ̀ mi lọ́rùn.
Mò ń yán hànhàn láti rí ọjọ́ náà tí màá lè fò kúrò lórí kẹ̀kẹ́ arọ mi tí màá sì lè sáré kiri ní fàlàlà. Nígbà náà ni màá wá fi ohùn rara kígbe pé, “Aláìlera ni mí tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí ara mi ti jí pépé títí láé!”