Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fáwọn Tí Kò Ṣègbéyàwó Àtàwọn Tó Ṣègbéyàwó
Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fáwọn Tí Kò Ṣègbéyàwó Àtàwọn Tó Ṣègbéyàwó
“Èyí ni èmi ń sọ . . . láti sún yín sí ohun tí ó yẹ àti èyí tí ó túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.”—1 KỌ́R. 7:35.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn ṣèwádìí ohun tí Bíbélì sọ nípa wíwà láìṣègbéyàwó àti nípa ìgbéyàwó?
Ó FẸ́RẸ̀Ẹ́ máà sí ohun tó ń fa ayọ̀, ìjákulẹ̀ tàbí ìdààmú nígbèésí ayé àwa ẹ̀dá bí àjọṣe tó wà láàárín ọkùnrin àti obìnrin. Ó pọn dandan ká mọ ohun tó yẹ ká ṣe, ìdí rẹ̀ sì nìyẹn tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn ìdí míì wà tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Àwọn ìbátan tàbí àwọn ọ̀rẹ́ Kristẹni kan tí kò wù pé kó ṣègbéyàwó lè máa yọ ọ́ lẹ́nu pé kó ṣègbéyàwó. Ẹlòmíì sì lè fẹ́ láti ṣègbéyàwó àmọ́ kó má tíì rí irú ọkọ tàbí aya tó wù ú. Àwọn kan lè fẹ́ láti rí ìtọ́ni gbà nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n múra sílẹ̀ fún bíbójú tó ojúṣe tó rọ̀ mọ́ jíjẹ́ ọkọ tàbí aya. Àti pé gbogbo Kristẹni tó ṣègbéyàwó àtàwọn tí kò ṣègbéyàwó ló ń dojú kọ ìdẹwò láti ṣèṣekúṣe.
2 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí lè nípa lórí ayọ̀ wa, wọ́n sì tún kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Ní orí 7 nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó fún wọn ní ìtọ́sọ́nà lórí wíwà láìṣègbéyàwó àti nípa ìgbéyàwó. Ìdí rẹ̀ sì ni pé ó fẹ́ láti sún àwọn tí wọ́n bá ka lẹ́tà tó kọ sí “ohun tí ó yẹ àti èyí tí ó túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà-ọkàn.” (1 Kọ́r. 7:35) Bó o ṣe ń gbé ìmọ̀ràn rẹ̀ yẹ̀ wò lórí àwọn kókó pàtàkì yìí, gbìyànjú láti rí bí ipò tó o wà, yálà o ti ṣègbéyàwó tàbí o kò tíì ṣègbéyàwó, ṣe lè mú kó o túbọ̀ máa sin Jèhófà ní kíkún.
Ìpinnu Pàtàkì Tó Yẹ Kí Ẹnì Kọ̀ọ̀kan Ṣe
3, 4. (a) Kí ló ń fà á nígbà míì tí ìṣòro fi máa ń wáyé báwọn èèyàn bá ti ń ṣàníyàn jù nípa ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan wọn kan tí kò ṣègbéyàwó? (b) Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ṣe lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè máa fi ojú tó tọ́ wo ìgbéyàwó?
3 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Júù ka ìgbéyàwó sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, bó sì ṣe rí nínú ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ lóde òní náà nìyẹn. Bí ọ̀dọ́kùnrin tàbí ọ̀dọ́bìnrin kan bá ti dàgbà dé ìwọ̀n àyè kan tí kò sì ṣègbéyàwó, àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ìbátan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa rẹ̀, kí wọ́n sì ronú pé àwọn gbọ́dọ̀ gbà á nímọ̀ràn. Bí wọ́n bá ń bá a sọ̀rọ̀, wọ́n lè rọ̀ ọ́ pé kó tètè lọ wákan ṣe. Wọ́n lè sọ fún un pé àwọn mọ ọkùnrin tàbí obìnrin kan tó dáa léèyàn. Wọ́n sì lè dọ́gbọ́n fa ojú ọkùnrin kan àti obìnrin kan mọ́ra. Nígbà míì, irú nǹkan báyìí máa ń kó ìtìjú báni, ó lè ba ọ̀rẹ́ jẹ́, ó sì lè mú kéèyàn ṣẹ àwọn ẹlòmíì.
4 Pọ́ọ̀lù kò fipá mú àwọn míì pé kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n má ṣègbéyàwó. (1 Kọ́r. 7:7) Ó tẹ́ ẹ lọ́rùn láti máa sin Jèhófà láìláya, àmọ́ kò fojú tẹ́ńbẹ́lú ẹ̀tọ́ táwọn míì ní láti ṣègbéyàwó. Lóde òní pẹ̀lú, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀tọ́ láti pinnu yálà kóun ṣègbéyàwó tàbí kóun má ṣègbéyàwó. Àwọn míì kò gbọ́dọ̀ máa fúngun mọ́ irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n má ṣègbéyàwó.
Bí Àwọn Tí Kò Ṣègbéyàwó Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí
5, 6. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi dábàá pé káwọn kan wà láìlọ́kọ tàbí aya?
5 Apá tó gbàfiyèsí nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ará Kọ́ríńtì ni ohun rere tó sọ nípa wíwà láìlọ́kọ tàbí aya. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:8.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kò níyàwó, kò gbé ara rẹ̀ ga ju àwọn tó gbéyàwó lọ bí àwọn àlùfáà àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó jẹ́jẹ̀ẹ́ wíwà láìgbéyàwó ṣe máa ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì náà ṣàlàyé àǹfààní tí ọ̀pọ̀ àwọn òjíṣẹ́ ìhìn rere tí wọn kò ṣègbéyàwó ní. Kí ni àǹfààní náà?
6 Ó sábà máa ń rọrùn fún Kristẹni kan tí kò ṣègbéyàwó láti tẹ́wọ́ gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí wọ́n bá yàn fún un nínú ètò Jèhófà èyí tó lè má ṣeé ṣe fún ẹni tó ti ṣègbéyàwó. Pọ́ọ̀lù rí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó jẹ́ àkànṣe gbà gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 11:13) Ka Ìṣe orí 13 títí dé orí 20, kó o sì máa fojú bá òun àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ míṣọ́nnárì nìṣó bí wọ́n ṣe ń mú ìhìn rere lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ tí ìwàásù kò tíì dé rí tí wọ́n sì ń dá àwọn ìjọ sílẹ̀ láti ibì kan dé ibòmíràn. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, ó fara da ọ̀pọ̀ ìnira tí ọ̀pọ̀ nínú wa lónìí lè má dojú kọ. (2 Kọ́r. 11:23-27, 32, 33) Àmọ́, ayọ̀ tó ní bó ṣe ń ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn mú kó rí i pé òun ò kojú àwọn ìṣòro wọ̀nyẹn lásán. (1 Tẹs. 1:2-7, 9; 2:19) Ṣó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣe gbogbo ohun tó ṣe yẹn bó bá jẹ́ pé ó ti gbéyàwó tàbí ó ti ní ìdílé? Bóyá ni.
7. Fúnni ní àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò ṣègbéyàwó tí wọ́n ti lo àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run.
7 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ń lo àǹfààní tí wọ́n ní nísinsìnyí láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Aṣáájú-ọ̀nà tí kò ṣègbéyàwó ni Sara àti Limbania lórílẹ̀-èdè Bòlífíà. Wọ́n lọ sìn ní abúlé kan tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti gbọ́ ìwàásù kẹ́yìn. Ṣé àìsí iná mànàmáná ní abúlé náà máa jẹ́ ìṣòro fún wọn? Wọ́n sọ pé: “Kò sí rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n, torí náà kò sí ìpínyà ọkàn tí kò ní jẹ́ kí àwọn ará abúlé náà gbájú mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe nígbà tí ọwọ́ wọ́n bá dilẹ̀, ìyẹn ni ìwé kíkà.” Àwọn kan lára àwọn ará abúlé náà fi ẹ̀dà ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti pẹ́ ṣùgbọ́n tí a kò tẹ̀ mọ́ han Sara àti Limbania. Àmọ́, wọ́n ṣì ń ka àwọn ìwé náà. Torí pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé táwọn arábìnrin náà bá dé ni wọ́n ti máa ń gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀, ó ṣòro fún wọn láti dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù náà. Màmá àgbà kan sọ fún wọn pé: “Òpin ti ní láti sún mọ́lé torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dé ọ̀dọ̀ wa lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.” Kò pẹ́ tí àwọn kan lára àwọn ará abúlé náà fi bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé ìjọ.
8, 9. (a) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ó dára láti wà láìlọ́kọ tàbí aya? (b) Àǹfààní wo làwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó ní?
8 Òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó pẹ̀lú máa ń kẹ́sẹ járí bí wọ́n bá ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ rọgbọ. Àmọ́, àwọn iṣẹ́ kan wà táwọn aṣáájú-ọ̀nà tí kò ṣègbéyàwó lè ṣe èyí tó lè nira fáwọn tó ṣègbéyàwó tàbí àwọn tó lọ́mọ. Pọ́ọ̀lù ronú lórí àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún àwọn ìjọ tó wà nígbà náà láti mú kí ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run gbilẹ̀ sí i. Ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn láyọ̀ bíi tòun. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé ó dára láti sin Jèhófà láìlọ́kọ tàbí aya.
9 Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tí kò lọ́kọ kọ̀wé pé: “Àwọn èèyàn kan gbà gbọ́ pé èèyàn ò lè láyọ̀ bí kò bá ṣègbéyàwó. Àmọ́, mo ti rí i pé ohun tó lè mú kéèyàn ni ayọ̀ tó tọ́jọ́ ni pé kó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gba kéèyàn fi nǹkan kan du ara rẹ̀ kó tó lè wà láìlọ́kọ tàbí aya, síbẹ̀ ẹ̀bùn àgbàyanu ló jẹ́ béèyàn bá fẹ́ láti wà bẹ́ẹ̀.” Ní ti ayọ̀ tí ẹ̀bùn náà máa ń mú wá, ó sọ pé: “Ńṣe ni wíwà láìlọ́kọ tàbí aya máa ń fúnni láyọ̀ kì í fa ìdíwọ́ fúnni. Mo mọ̀ pé Jèhófà ò dá ẹnikẹ́ni yà sọ́tọ̀, ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo wa yálà a ṣègbéyàwó tàbí a kò ṣègbéyàwó.” Ní báyìí, ó ń fayọ̀ sìn ní ilẹ̀ tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Bí o kò bá tíì ṣègbéyàwó, ǹjẹ́ o lè lo òmìnira tó o ní láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i nípa fífi òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run kọ́ àwọn míì? Ìwọ pẹ̀lú lè wá rí i pé ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Jèhófà ni wíwà láìlọ́kọ tàbí aya jẹ́.
Àwọn Tó Wù Láti Lọ́kọ Tàbí Aya
10, 11. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tó fẹ́ láti ṣègbéyàwó àmọ́ tí wọn kò tíì rí irú ọkọ tàbí aya tí wọ́n fẹ́?
10 Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó jẹ́ olùṣòtítọ́ ti wà láìlọ́kọ tàbí aya fún àwọn àkókò kan, wọ́n pinnu láti wá ẹni tí wọ́n máa bá ṣègbéyàwó. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn nílò ìtọ́sọ́nà Jèhófà, wọ́n gbàdúrà sí i pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti rí irú ọkọ tàbí aya tó wu àwọn.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:36.
11 Bó o bá fẹ́ láti ní ọkọ tàbí aya tí ẹ̀yin méjèèjì á jọ máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà, gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Bó bá tiẹ̀ gba pé kó o dúró pẹ́, má ṣe bọ́hùn. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́, ó sì máa gba ọ̀rọ̀ rẹ rò ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó ò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ̀.—Héb. 13:6.
12. Kí Kristẹni kan tó gbà láti fẹ́ ẹnì kan, kí nìdí tó fi gbọ́dọ̀ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò dáadáa?
12 Bó bá wu Kristẹni kan láti ṣègbéyàwó, ẹnì kan tí kò dájú pé ó ní àjọṣe rere pẹ̀lú Jèhófà tàbí ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ pàápàá lè sọ pé kó fẹ́ òun. Bó bá jẹ́ pé ìwọ ni irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí, má ṣe gbàgbé pé ìrora ọkàn tó wà nínú kéèyàn ṣi ọkọ tàbí aya ní máa ń fa ìbànújẹ́ tó pọ̀ gan-an ju ìyánhànhàn téèyàn máa ń ní nígbà tí kò tíì ṣègbéyàwó. Bẹ́ ẹ bá sì ti fẹ́ra yín tán, ẹ̀yin méjèèjì ti dọ̀kan ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá fi jọ wà láàyè nìyẹn, ní tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. (1 Kọ́r. 7:27) Torí náà, má ṣe pinnu pé àfi dandan kó o fẹ́ ẹni tó o bá ṣáà ti rí, kó o má bàa kábàámọ̀ nígbà tó bá yá.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:39.
Múra Sílẹ̀ De Ohun Tí Ìgbéyàwó Jẹ́ Gan-an
13-15. Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó fa ìpọ́njú nínú ìgbéyàwó tí ọkùnrin àti obìnrin gbọ́dọ̀ jíròrò nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà?
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù dámọ̀ràn pé kéèyàn sin Jèhófà láìṣègbéyàwó, kò fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tó pinnu láti ṣègbéyàwó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí ran tọkùnrin tobìnrin lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ìgbéyàwó jẹ́ gan-an, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà mú kí ìgbéyàwó wọn tọ́jọ́.
14 Ó yẹ kí àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan yí ojú tí wọ́n fi ń wo ìgbéyàwó pa dà. Nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà, wọ́n lè máa wo ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn bí èyí tí kò lẹ́gbẹ́, tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, tó sì ń fi hàn pé àjọgbé wọn á dùn bí oyin. Irú èrò yìí ni wọ́n á gbé sọ́kàn títí tí wọ́n á fi fẹ́ra, wọ́n á sì gbà lọ́kàn ara wọn pé kò sí ohun tó lè ba ayọ̀ ìgbéyàwó àwọn jẹ́. Àmọ́ ọ̀ràn kì í sábàá rí bẹ́ẹ̀. Ìgbéyàwó máa ń mú kí tọkọtaya gbádùn ìfararora, ìyẹn sì máa ń gbádùn mọ́ni, àmọ́ ìyẹn nìkan kò tó láti mú kí ọkọ àti aya tóótun láti dojú kọ ìpọ́njú tó máa ń wáyé nínú gbogbo ìgbéyàwó.—Ka 1 Kọ́ríńtì 7:28. *
15 Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó bí èrò ẹnì kejì wọn bá yàtọ̀ sí tiwọn lórí àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n ní ìjákulẹ̀. Èrò àwọn méjèèjì lè yàtọ̀ síra nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa náwó àti ohun tó yẹ kí wọ́n máa ṣe bí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀, ibi tí wọ́n máa gbé àti bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn ọkọ àtàwọn èèyàn ìyàwó lemọ́lemọ́ tó. Ọkọ tàbí aya sì ní àwọn àléébù tó lè máa bí ẹnì kejì rẹ̀ nínú. Nígbà táwọn méjèèjì ń fẹ́ra sọ́nà, ó rọrùn láti fi ojú tí kò tó nǹkan wo irú àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀, àmọ́ tó bá yá wọ́n lè fa ìṣòro tó pọ̀ nínú ìgbéyàwó. Torí náà, ó dára kí ọkùnrin àti obìnrin jọ wá ojútùú sí ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó lè fa ìṣòro kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.
16. Kí nìdí tó fi yẹ kí tọkọtaya fohùn ṣọ̀kan lórí ọ̀nà tí wọ́n á máa gbà bójú tó àwọn ìṣòro ìgbéyàwó?
16 Kí tọkọtaya lè ṣàṣeyọrí kí wọ́n sì láyọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti bójú tó àwọn ìṣòro tó bá wáyé. Wọ́n gbọ́dọ̀ fohùn ṣọ̀kan lórí bí wọ́n á ṣe máa bá àwọn ọmọ wí àti bí wọ́n á ṣe máa bójú tó àwọn òbí wọn àgbà. Wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìṣòro inú ìdílé ba àárín àwọn méjèèjì jẹ́. Bí wọ́n bá ń fi ìmọ̀ràn inú Bíbélì sílò, wọ́n á yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro, wọ́n á máa fara da èyí tí kò bá rọrùn láti yanjú, àwọn méjèèjì á sì máa láyọ̀ bí wọ́n ṣe ń gbé pa pọ̀.—1 Kọ́r. 7:10, 11.
17. Kí nìdí tí àwọn tọkọtaya fi máa ń ṣàníyàn fún “àwọn ohun ti ayé”?
17 Pọ́ọ̀lù sọ ohun mìíràn tó máa ń wáyé nínú ìgbéyàwó nínú 1 Kọ́ríńtì 7:32-34. (Kà á.) Àwọn tọkọtaya máa ń “ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé,” bí oúnjẹ, aṣọ, ibùgbé àtàwọn nǹkan tara míì. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Nígbà tí arákùnrin kan wà ní àpọ́n, ó ṣeé ṣe kó ti máa lo okun rẹ̀ àti àkókò tó pọ̀ lóde ẹ̀rí. Àmọ́ ní báyìí tó ti di ọkọ, ó ti lè wá rí i pé òun gbọ́dọ̀ máa lo díẹ̀ lára àkókò àti okun yẹn láti máa bójú tó aya òun kó sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀. Irú ìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀ náà ló yẹ kí aya ní fún ọkọ rẹ̀. Torí pé Jèhófà jẹ́ ọlọgbọ́n, ó mọ̀ pé èyí ṣe pàtàkì gan-an. Ó mọ̀ pé kí ìgbéyàwó tó lè yọrí sí rere, ó máa gba díẹ̀ lára àkókò àti okun tí ọkọ àti aya máa ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn wọn nígbà tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó.
18. Lẹ́yìn táwọn kan bá ti ṣègbéyàwó, ìyípadà wo ló yẹ kó dé bá àkókò àti okun tí wọ́n fi ń ṣeré ìtura?
18 Àmọ́, àwọn ìyípadà míì ṣì wà tó yẹ kí tọkọtaya ṣe. Bí tọkọtaya bá ní láti ya díẹ̀ sọ́tọ̀ lára àkókò àti okun tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run láti fi bójú tó ara wọn, mélòómélòó wá ni àkókò àti okun tí wọ́n ń lò fún eré ìtura nígbà tí wọn kò tíì ṣègbéyàwó? Àkóbá wo ló máa ṣe fún aya bí ọkọ bá ṣì ń fi gbogbo ara lọ́wọ́ sí eré ìdárayá pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀? Àbí, báwo ló ṣe máa rí lára ọkọ bí ìyàwó rẹ̀ ò bá dẹ́kun láti máa lo àkókò tó pọ̀ láti ṣe eré tó yàn láàyò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀? Kò ní pẹ́ tí ọkọ tàbí aya tí ẹnì kejì rẹ̀ tara bọ eré ìdárayá á fi máa dá wà, tí inú rẹ̀ á máa bà jẹ́, táá sì dà bíi pé ẹnì kejì rẹ̀ kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Irú èyí kò ní wáyé bí àwọn tí wọ́n fẹ́ra bá ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú kí àjọṣe àárín wọn túbọ̀ lágbára gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya.—Éfé. 5:31.
Jèhófà Ò Fẹ́ Ká Lọ́wọ́ sí Ìṣekúṣe
19, 20. (a) Kí nìdí tí àwọn tó ti ṣègbéyàwó fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe? (b) Ewu wo ló wà nínú kí tọkọtaya máa fira wọn sílẹ̀ fún àkókò gígùn?
19 Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti pinnu pé àwọn kò ní lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe. Àwọn kan pinnu láti ṣègbéyàwó kí wọ́n má bàa kó sínú irú ìṣòro yìí. Àmọ́, pé èèyàn ṣègbéyàwó nìkan kò tó láti dáàbò boni lọ́wọ́ ìṣekúṣe. Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìlú olódi máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn kìkì bí wọn kò bá jáde kúrò nínú ìlú náà. Bí ẹnì kan bá jáde kúrò nínú ìlú náà nígbà táwọn arúfin àtàwọn onísùnmọ̀mí ń lọ káàkiri, wọ́n lè jà á lólè tàbí kí wọ́n pa á. Bákan náà, Ọlọ́run lè dáàbò bo àwọn tọkọtaya bí wọ́n bá tẹ̀ lé ohun tó sọ nípa ìbálòpọ̀ tí wọn kò sì ré kọjá ìlànà tí Ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀ fi lélẹ̀ fún wọn.
20 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bí wọn kò ṣe ní ré ìlànà yìí kọjá nínú 1 Kọ́ríńtì 7:2-5. Aya kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn àyàfi pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nìkan; bẹ́ẹ̀ sì ni ọkọ kò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn àyàfi aya rẹ̀ nìkan. Àwọn méjèèjì gbọ́dọ̀ máa fún ara wọn ní “ohun ẹ̀tọ́,” tàbí ìbálòpọ̀ tí ẹni tó ti ṣègbéyàwó lẹ́tọ̀ọ́ láti ní pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkọ tàbí àwọn aya kan máa ń fira wọn sílẹ̀ fún àkókò gígùn, wọ́n máa ń dá lọ lo àkókò ìsinmi tàbí kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ máa gbé wọn lọ fún àkókò gígùn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi “ohun ẹ̀tọ́” yìí du ara wọn. Wo bí ìbànújẹ́ náà á ṣe pọ̀ tó bí ẹnì kan nínú wọn bá fàyè gba èṣù tó sì ṣe panṣágà “nítorí àìlèmáradúró” rẹ̀. Àwọn olórí ìdílé tó bá ń pèsè àtijẹ àtimu fun taya tọmọ wọn láì fi ìgbéyàwó wọn sínú ewu, máa ń rí ìbùkún Jèhófà gbà.—Sm. 37:25.
Tá A Bá Ń Ṣègbọràn sí Ìmọ̀ràn Bíbélì Ó Máa Ṣe Wá Láǹfààní
21. (a) Kí nìdí tí ìpinnu láti ṣègbéyàwó tàbí láti má ṣègbéyàwó fi máa ń ṣòroó ṣe? (b) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì orí 7 fi wúlò?
21 Ọ̀kan lára ìpinnu tó tíì ṣòro jù lọ tí ẹnì kan lè ṣe ni pé kó ṣègbéyàwó tàbí kó má ṣègbéyàwó. Gbogbo èèyàn ni aláìpé. Àìpé ló sì máa ń fa èyí tó pọ̀ jù lọ lára ìṣòro tó máa ń da gbogbo èèyàn láàmú. Torí náà, àwọn tó rí ojú rere Jèhófà tí wọ́n sì ń gbádùn ìbùkún rẹ̀ pàápàá lè ní ìjákulẹ̀, yálà wọ́n ṣègbéyàwó tàbí wọn kò ṣègbéyàwó. Bó o bá fi ìmọ̀ràn inú 1 Kọ́ríńtì orí 7 sílò, irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ lè dín kù. Yálà o ṣègbéyàwó tàbí o kò ṣègbéyàwó, o “ṣe dáadáa” lójú Jèhófà. (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:37, 38.) Àfojúsùn tó ga jù lọ tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ni pé kó o rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Bí Ọlọ́run bá fi ojú rere rẹ̀ hàn sí ẹ, wàá lè máa tẹ̀ síwájú nìṣó kó o lè jèrè ìyè nínú ayé tuntun tó ṣèlérí. Níbẹ̀, àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ nínú àjọṣe tó wà láàárín tọkùnrin tobìnrin níbi gbogbo lónìí kò ní sí mọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
^ Wo ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, orí 2, ìpínrọ̀ 16 sí 19.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
• Kí nìdí tí ẹnikẹ́ni kò fi gbọ́dọ̀ fipá mú ẹlòmíì láti ṣègbéyàwó?
• Bó o bá jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tí kò tíì ṣègbéyàwó, báwo lo ṣe lè lo àkókò rẹ lọ́nà tó dára jù lọ?
• Báwo ni ọkùnrin àti obìnrin tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ṣe lè múra sílẹ̀ de àwọn ìṣòro tó wà nínú ìgbéyàwó?
• Kí nìdí tí ìgbéyàwó nìkan kò fi tó láti dáàbò boni lọ́wọ́ ìṣekúṣe?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Àwọn Kristẹni tí kò ṣègbéyàwó àmọ́ tí wọ́n ń lo àkókò wọn láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i máa ń láyọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn ìyípadà wo ló máa pọn dandan pé kí àwọn kan ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó?