Ìsapá Náà Tó Bẹ́ẹ̀ Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ!
Ìsapá Náà Tó Bẹ́ẹ̀ Ó Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ!
ÌJỌSÌN ÌDÍLÉ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì láti lè tọ́ àwọn ọmọ dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Àmọ́, bó o bá jẹ́ òbí, wàá ti mọ̀ pé nǹkan kì í pẹ́ sú àwọn ọmọdé. Báwo lo ṣe lè mú kí wọ́n máa pọkàn pọ̀? Ṣe àgbéyẹ̀wò ohun táwọn òbí kan ti ṣe.
Arákùnrin George, tó wà ní ìpínlẹ̀ California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà táwọn ọmọ wa ṣì kéré, èmi àti ìyàwó mi máa ń gbìyànjú láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbádùn mọ́ wọn. Nígbà míì, gbogbo wa máa múra bí àwọn tó wà nínú Bíbélì a sì máa ń ṣe àṣefihàn ohun tá à ń kà látinú Ìwé Ìtàn Bíbélì. A tiẹ̀ ṣe àwọn nǹkan tá a máa ń lò fún àṣefihàn náà, bí idà, ọ̀pá, apẹ̀rẹ̀ àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. A tún máa ń múra bí àwọn tó wà nínú Bíbélì tí a ó sì máa bi ara wa pé ‘ta ni mí?’ tàbí ká máa béèrè onírúurú ìbéèrè tó rọ̀ àtèyí tó le nípa àwọn ohun tó wà nínú Bíbélì. A sì tún máa ń fi páálí ṣe àwọn nǹkan bí ọkọ̀ Nóà tàbí ká fi déètì táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì wáyé tò wọ́n bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra. Nígbà míì a máa ń lo àkókò náà láti ya àwọn ẹni tá a kà nípa wọn nínú Bíbélì tàbí ká ya ìtàn wọn. Ní báyìí, à ń wéwèé láti bẹ̀rẹ̀ sí í yàwòrán àwọn ìhámọ́ra tẹ̀mí tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Éfésù 6:11-17, olúkúlùkù wa á sì máa ṣàlàyé ohun tí ìhámọ́ra kọ̀ọ̀kan dúró fún. Kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí ti mú ká gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa.”
Debi, ìyá kan tó wá láti ìpínlẹ̀ Michigan, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó ṣòro fún èmi àti ọkọ mi láti mú kí ọmọbìnrin wa pọkàn pọ̀ nígbà tó pé nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́ta. Àmọ́, lọ́jọ́ kan tí mò ń ka ìtàn Ísákì àti Rèbékà sókè látinú Ìwé Ìtàn Bíbélì, mo kó bèbí méjì mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n láti ṣe àṣefihàn ìtàn náà nípa mímú kó dà bíi pé àwọn ló ń sọ̀rọ̀. Bí ọmọbìnrin wa ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn bá ohun tí mò ń sọ lọ nìyẹn o! Ní àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn bèbí yẹn láti ṣàpèjúwe èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì. Lẹ́yìn tá a bá ti ka ìtàn kan tán, ọmọbìnrin wa á lọ wá àwọn bèbí tàbí àwọn nǹkan míì tó lè fi ṣe àṣefihàn ìtàn náà. Ńṣe ló dà bí ìgbà tá a ṣàwárí ohun kan tó ṣeyebíye. A fi páálí bàtà àti okùn pupa ṣe ilé Ráhábù tí wọ́n ta okùn rírẹ̀dòdò mọ́ ojú fèrèsé rẹ̀. A sì fi aṣọ tín-ín-rín tá a kó òwú sí nínú, tí gígùn rẹ̀ jẹ́ mítà kan ààbọ̀, ìyẹn ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún, ṣe ejò tá a lọ́ mọ́ ara igi láti fi ṣàpẹẹrẹ ejò bàbà inú ìwé Númérì 21:4-9. Inú àpò ńlá kan tá à ń kó àwọn iṣẹ́ ọnà àti àwòrán sí là ń tọ́jú àwọn nǹkan tá à ń lò fún àṣefihàn yìí sí. Ó dùn mọ́ wa gan-an pé lọ́pọ̀ ìgbà bí ọmọbìnrin wa bá fẹ́ ṣe àṣefihàn ìtàn inú Bíbélì, ńṣe ló máa ń jókòó sí pálọ̀ táá sì máa fọwọ́ wá inú àpò tó ń tọ́jú àwọn nǹkan tó máa ń lò sí. Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún wa pé òun fúnra rẹ̀ ti ń dá ṣe àṣefihàn àwọn ìtàn inú Bíbélì débi tó bá yé e dé!”
Kò rọrùn láti tọ́ ọmọ, tá a bá sì fẹ́ láti gbin ìfẹ́ fún sísin Jèhófà sí wọn lọ́kàn, a gbọ́dọ̀ ṣe kọjá wíwulẹ̀ kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àmọ́ Ìjọsìn Ìdílé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè jẹ́ ìpìlẹ̀ fún àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí mìíràn tó yẹ ká fún wọn. Láìsí àníàní, ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!