Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí ló mú kí Mósè bínú sí Élíásárì àti Ítámárì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áárónì lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀gbọ́n wọn Nádábù àti Ábíhù kú, kí ló sì mú kí ìbínú rẹ̀ rọlẹ̀?—Léf. 10:16-20.
Kété lẹ́yìn ìyànsípò àwọn àlùfáà tí wọn yóò máa ṣiṣẹ́ ìsìn níbi àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà pa Nádábù àti Ábíhù tí wọ́n jẹ́ ọmọ Áárónì torí pé wọ́n rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu níwájú Ọlọ́run. (Léf. 10:1, 2) Mósè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Áárónì tó ṣẹ́ kù pé wọn kò gbọ́dọ̀ ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ẹ̀gbọ́n wọn tó kú. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Mósè bínú sí Élíásárì àti Ítámárì torí pé wọn kò jẹ ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. (Léf. 9:3) Kí nìdí tí Mósè fi bínú sí wọn?
Òfin tí Jèhófà fún Mósè sọ pé kí àlùfáà tó bá rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ jẹ lára ẹbọ náà nínú àgbàlá àgọ́ ìpàdé. Jíjẹ lára ẹbọ náà fi hàn pé àlùfáà náà ń dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tó tìtorí wọn rúbọ. Àmọ́, bí wọ́n bá mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ náà lọ sínú Ibi Mímọ́, ìyẹn iyàrá àkọ́kọ́ nínú ibùjọsìn náà, wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹbọ náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, sísun ni wọ́n gbọ́dọ̀ sun ún.—Léf. 6:24-26, 30.
Ó dà bíi pé lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé lọ́jọ́ yẹn, Mósè rí i pé ó pọn dandan kí òun rí i dájú pé gbogbo àṣẹ Jèhófà làwọn pa mọ́. Nígbà tó kíyè sí i pé ńṣe ni Élíásárì àti Ítámárì sun ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ó bínú sí wọn, ó sì béèrè ìdí rẹ̀ tí wọn kò fi jẹ lára ẹbọ náà bí òfin ti sọ, níwọ̀n bí wọn kò ti gbé ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ náà lọ síwájú Jèhófà nínú Ibi Mímọ́.—Léf. 10:17, 18.
Áárónì ló dáhùn ìbéèrè Mósè, torí ó ṣe kedere pé ohun tí àwọn àlùfáà méjèèjì yẹn ṣe kò ṣẹ̀yìn rẹ̀. Lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ rẹ̀ méjì, ó ṣeé ṣe kí Áárónì ti máa ṣiyè méjì bóyá ó bójú mu kí èyíkéyìí lára àwọn àlùfáà jẹ lára ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ Nádábù àti Ábíhù sí wọn lọ́rùn, ó ṣeé ṣe kí Áárónì rò pé kò ní dùn mọ́ Jèhófà nínú bí wọ́n bá jẹ nínú ẹbọ yẹn.—Léf. 10:19.
Áárónì lè ti ronú pé ó yẹ kí àwọn ará ilé òun lo ìṣọ́ra láti ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ láti múnú Ọlọ́run dùn títí dé ìwọ̀n àyè tó kéré jù lọ, pàápàá lọ́jọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. Àmọ́ torí pé Nádábù àti Ábíhù sọ orúkọ Jèhófà di aláìmọ́, Ọlọ́run bínú sí wọn. Torí náà, Áárónì ti lè rò pé kò yẹ kí àwọn tó wá láti ìdílé àlùfáà tó dá irú ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ nínú ẹbọ mímọ́.
Ó dà bíi pé ìdáhùn tí Áárónì fún Mósè yìí tẹ́ ẹ lọ́rùn, torí ẹsẹ tó gbẹ̀yìn nínú orí náà sọ pé: “Nígbà tí Mósè gbọ́ ìyẹn, nígbà náà, ó já sí ìtẹ́lọ́rùn ní ojú rẹ̀.” (Léf. 10:20) Dájúdájú, ìdáhùn Áárónì yìí tẹ́ Jèhófà náà lọ́rùn.