Wọ́n Pinnu Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere
Wọ́n Pinnu Láti Jẹ́rìí Kúnnákúnná sí Ìhìn Rere
“Ó pa àṣẹ ìtọ́ni fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná.”—ÌṢE 10:42.
1. Iṣẹ́ wo ni Pétérù sọ nípa rẹ̀, nígbà tó ń bá Kọ̀nílíù sọ̀rọ̀?
Ọ̀GÁGUN ará Ítálì náà kó àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jọ fún ìjíròrò kan tó yọrí sí ìyípadà nínú àjọṣe Ọlọ́run àtàwa èèyàn. Kọ̀nílíù ni ọkùnrin tó bẹ̀rù Ọlọ́run yẹn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fáwọn èèyàn náà pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fáwọn àpọ́sítélì “láti wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná” nípa Jésù. Ìwàásù tí Pétérù ṣe yẹn yọrí sí rere. Àwọn Kèfèrí tí ò tíì dádọ̀dọ́ gba ẹ̀mí Ọlọ́run, wọ́n ṣèrìbọmi, wọ́n sì wá ń fojú sọ́nà láti jọba lọ́run pẹ̀lú Jésù. Ẹ ò rí i pé bí Pétérù ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná yẹn mú àbájáde rere wá!—Ìṣe 10:22, 34-48.
2. Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe àwọn àpọ́sítélì méjìlá nìkan ni Ọlọ́run pàṣẹ fún láti lọ máa jẹ́rìí.
2 Ọdún 36 Sànmánì Kristẹni ni nǹkan tá à ń wí yìí ṣẹlẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, ohun kan ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń ṣàtakò gidigidi sí ẹ̀sìn Kristẹni, ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà. Sọ́ọ̀lù ará Tásù wà lójú ọ̀nà Damásíkù nígbà tí Jésù fara hàn án tó sì sọ fún un pé: “Wọ ìlú ńlá náà, a ó sì sọ ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe fún ọ.” Jésù jẹ́ kó dá Ananíà, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, lójú pé Sọ́ọ̀lù máa jẹ́rìí fún “àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Ka Ìṣe 9:3-6, 13-20.) Nígbà tí Ananíà dé ọ̀dọ̀ Sọ́ọ̀lù ó sọ fún un pé: “Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa ti yàn ọ́ . . . nítorí pé ìwọ yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún un sí gbogbo ènìyàn.” (Ìṣe 22:12-16) Irú ọwọ́ wo ni Sọ́ọ̀lù, tá a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá, fi mú iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà?
Ó Jẹ́rìí Kúnnákúnná!
3. (a) Ìtàn wo la fẹ́ gbé yẹ̀ wò báyìí? (b) Kí làwọn alàgbà ìjọ Éfésù ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù ránṣẹ́ pè wọ́n, àpẹẹrẹ rere wo ni wọ́n sì fi lélẹ̀ fún wa?
3 Ó dájú pé inú wa máa dùn gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ṣe lẹ́yìn ìgbà yẹn, àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àsọyé kan tí Pọ́ọ̀lù sọ ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, bó ṣe wà nínú ìwé Ìṣe orí 20. Ìgbà tí ìrìn àjò míṣọ́nnárì tí Pọ́ọ̀lù rìn lẹ́ẹ̀kẹta ti fẹ́ẹ̀ parí ló sọ àsọyé yìí. Ó dúró ní Mílétù, ìyẹn ibùdó kan létí Òkun Aegean, ó wá ránṣẹ́ pe àwọn alàgbà tó wà ní ìjọ Éfésù. Nǹkan bí àádọ́ta [50] kìlómítà ni ìlú Éfésù wà síbi tá à ń wí yìí, torí pé ọ̀nà yẹn sì rí kọ́lọkọ̀lọ, ó máa gbà wọ́n ní àkókò tó pọ̀ kí wọ́n tó débẹ̀. Fọkàn yàwòrán bínú àwọn alàgbà ìjọ Éfésù ti máa dùn tó nígbà tí wọ́n jíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù fún wọn. (Fi wé Òwe 10:28) Síbẹ̀, wọ́n ṣì ní láti ṣètò bí wọ́n ṣe máa rìnrìn àjò lọ sí Mílétù. Ó ṣeé ṣe káwọn kan nínú wọn tiẹ̀ gbàyè níbi iṣẹ́ tàbí kí wọ́n ti ṣọ́ọ̀bù wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí, kí wọ́n bàa lè rí i dájú pé àwọn ò pa apá kankan jẹ nínú àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún.
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù ti máa ń ṣe ní gbogbo ọdún tó lò nílùú Éfésù?
4 Kí lo rò pé Pọ́ọ̀lù ń ṣe nílùú Mílétù ní gbogbo ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin táwọn alàgbà wọ̀nyẹn fi wà lójú ọ̀nà? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni, kí ni wàá máa ṣe? (Fi wé Ìṣe 17:16, 17.) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn alàgbà ìjọ Éfésù dáhùn ìbéèrè yìí. Ó sọ ohun tó ti máa ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn títí kan ìgbà tó kọ́kọ́ wá sílùú Éfésù. (Ka Ìṣe 20:18-21.) Torí pé kò sẹ́ni tó máa jiyàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin mọ̀ dunjú, bí ó ti jẹ́ pé láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo dé sí àgbègbè Éṣíà . . . mo jẹ́rìí kúnnákúnná.” Kò sí àníàní pé ó ti pinnu láti ṣe iṣẹ́ tí Jésù yàn fún un. Báwo lo ṣe ṣiṣẹ́ náà nílùú Éfésù? Ohun kan tó ṣe ni pé ó jẹ́rìí fáwọn Júù, ó wá wọn lọ sí gbogbo ibi tó ti máa rí ọ̀pọ̀ èèyàn. Lúùkù ròyìn pé, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà nílùú Éfésù ní nǹkan bí ọdún 52 sí 55 Sànmánì Kristẹni, ‘ó sọ àsọyé, ó sì yí àwọn èèyàn lérò pa dà’ nínú sínágọ́gù. Nígbà táwọn Júù “sọ ara wọn di aláyà líle, tí wọn kò sì gbà gbọ́,” Pọ́ọ̀lù kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì nínú ìlú náà, àmọ́ ó ṣì ń wàásù. Ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí fáwọn Júù àtàwọn Gíríìkì nínú ìlú ńlá yẹn.—Ìṣe 19:1, 8, 9.
5, 6. Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé àwọn aláìgbàgbọ́ ni Pọ́ọ̀lù wàásù fún láti ilé dé ilé?
5 Nígbà tó yá, àwọn kan tí wọ́n di Kristẹni tóótun láti di alàgbà, àwọn sì ni Pọ́ọ̀lù bá sọ̀rọ̀ ní Mílétù. Pọ́ọ̀lù rán wọn létí bóun ṣe wàásù fún wọn nígbà yẹn, ó ní: “Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ èyíkéyìí lára àwọn ohun tí ó lérè nínú fún yín tàbí kúrò nínú kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.” Lákòókò wa yìí, àwọn kan ti sọ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú ẹsẹ yìí ni bó ṣe máa ń ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn onígbàgbọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ o. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàpèjúwe pé òún ‘ń kọ́ni ní gbangba àti láti ilé dé ilé’ fi hàn pé àwọn aláìgbàgbọ́ ló dìídì ń wàásù fún. Ìyẹn tún ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e, nígbà tó sọ pé òún ti ń jẹ́rìí “fún àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì nípa ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa wa Jésù.” Ó ṣe kedere pé àwọn aláìgbàgbọ́ ni Pọ́ọ̀lù ń wàásù fún, àwọn ni wọ́n nílò láti ronú pìwà dà kí wọ́n sì gba Jésù gbọ́.—Ìṣe 20:20, 21.
6 Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ohun tó sọ nípa ìwé Ìṣe 20:20 ni pé: “Ọdún mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù lò nílùú Éfésù. Ilé gbogbo èèyàn ló dé tàbí, ó kéré tán, ó wàásù fún gbogbo èèyàn (ẹsẹ 26). Èyí fi hàn pé Ìwé Mímọ́ ti iṣẹ́ wíwàásù láti ilé dé ilé lẹ́yìn títí kan wíwàásù láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń pàdé.” Yálà Pọ́ọ̀lù dé ilé gbogbo èèyàn, bí ọ̀mọ̀wé yẹn ṣe sọ tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó dájú ni pé kò fẹ́ káwọn alàgbà ìjọ Éfésù gbàgbé bóun ṣe wàásù àti ipa tí iṣẹ́ ìwàásù yẹn ní lórí àwọn èèyàn. Lúùkù ròyìn pé: “Gbogbo àwọn tí ń gbé àgbègbè Éṣíà . . . gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Gíríìkì.” (Ìṣe 19:10) Àmọ́ báwo ni “gbogbo” àwọn tó wà ní Éṣíà ṣe gbọ́, kí sì nìyẹn ń jẹ́ ká mọ̀ nípa ìṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe?
7. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù tí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣe nípa lórí àwọn ẹlòmíì yàtọ̀ sáwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní tààràtà?
7 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù torí pé ó wàásù láwọn ibi táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí àti láti ilé dé ilé. Ṣó o rò pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gbogbo àwọn tó gbọ́rọ̀ Pọ́ọ̀lù ni kò kúrò nílùú Éfésù, tí wọn ò lọ síbòmíì láti ṣòwò, kí wọ́n lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn, tàbí kí wọ́n kó lọ sáwọn abúlé nítorí ìgbésí ayé gìrìgìrì tó wà nígboro? Kò dájú pé bẹ́ẹ̀ ni. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti torí àwọn nǹkan wọ̀nyí kúrò níbi tí wọ́n ń gbé, ó sì ṣeé ṣe kíwọ pàápàá ti ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń wá ṣòwò tàbí kí wọ́n wá rí àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn nílùú Éfésù nígbà yẹn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti rí Pọ́ọ̀lù nígbà tí wọ́n wá sí Éfésù tàbí kí wọ́n ti gbọ́rọ̀ ẹ̀ níbẹ̀ nígbà tó ń wàásù. Kí nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ṣe nígbà tí wọ́n bá pa dà délé? Àwọn tó ti lóye òtítọ́ nínú wọn máa wàásù ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Àwọn míì sì lè máà tíì di onígbàgbọ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti sọ nípa ohun tí wọ́n gbọ́ nígbà tí wọ́n wà nílùú Éfésù fáwọn ẹlòmíì. Torí náà, àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn ará àdúgbò tàbí àwọn oníbàárà àwọn kan lára àwọn tó ti wá sí Éfésù ti gbọ́ òtítọ́, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n ti di onígbàgbọ́. (Fi wé Máàkù 5:14.) Kí lèyí wá jẹ́ kó o mọ̀ nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bó o ti ń jẹ́rìí kúnnákúnná?
8. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tó wà ní gbogbo àgbègbè Éṣíà ti gbọ́ nípa òtítọ́?
8 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ wá sílùú Éfésù, ó sọ pé, ‘ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò ti ṣí sílẹ̀ fún òun.’ (1 Kọ́r. 16:8, 9) Ilẹ̀kùn wo nìyẹn, báwo ló sì ṣe ṣí sílẹ̀ fún un? Iṣẹ́ ìsìn tí Pọ́ọ̀lù ò dáwọ́ rẹ̀ dúró nílùú Éfésù ló jẹ́ kí ìhìn rere tàn kálẹ̀ níbẹ̀. Kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú mẹ́ta kan tí kò jìnnà sí Éfésù, ìyẹn ìlú Kólósè, Laodíkíà àti Hirapólísì. Pọ́ọ̀lù ò débẹ̀ rí, àmọ́ ìhìn rere tàn kálẹ̀ níbẹ̀, torí àgbègbè yẹn ni Epafírásì ti wá. (Kól. 2:1; 4:12, 13) Ṣé ìlú Éfésù ni Pọ́ọ̀lù ti wàásù fún Epafírásì tó fi di Kristẹni? Bíbélì ò sọ fún wa. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Epafírásì ló wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn ní ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣojú fún Pọ́ọ̀lù. (Kól. 1:7) Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọdún tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù nílùú Éfésù ni ìhìn rere táwọn Kristẹni ń wàásù rẹ̀ ti dé àwọn ìlú bíi Filadẹ́fíà, Sádísì àti Tíátírà.
9. (a) Kí ló wu Pọ́ọ̀lù látọkàn wá? (b) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa fún ọdún 2009?
9 Èyí jẹ́ ká rí ìdí pàtàkì táwọn alàgbà ìjọ Éfésù ò fi jiyàn nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.” Inú ẹsẹ Bíbélì yìí ni ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí, tó sì ń jẹ́ ká mohun tó yẹ ní ṣíṣe, tá a fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2009 wà, ó ní: “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.”—Ìṣe 20:24.
Bá A Ṣe Lè Jẹ́rìí Kúnnákúnná Lónìí
10. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwa náà ní láti jẹ́rìí kúnnákúnná?
10 Nígbà tó yá, àṣẹ náà láti “wàásù fún àwọn ènìyàn àti láti jẹ́rìí kúnnákúnná” tún kan àwọn ẹlòmíì yàtọ̀ sáwọn àpọ́sítélì. Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí wọ́n tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500], tí wọ́n pé jọ sí Gálílì sọ̀rọ̀, ó pàṣẹ fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” Àṣẹ yìí kan gbogbo àwa Kristẹni tòótọ́ lóde òní, torí Jésù fúnra ẹ̀ sọ pé: “Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:19, 20.
11. Iṣẹ́ pàtàkì wo làwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀?
11 Gbogbo àwọn Kristẹni tó nítara ń bá a nìṣó láti máa ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, wọ́n sì ń sapá láti máa “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” Ọ̀nà pàtàkì kan tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu bà nígbà tó ń báwọn alàgbà ìjọ Éfésù sọ̀rọ̀, ìyẹn ni láti ilé dé ilé. Nínú ìwé kan tí wọ́n ṣe lọ́dún 2007, tó dá lórí iṣẹ́ míṣọ́nnárì tó gbéṣẹ́, David G. Stewart Kékeré sọ pé: “Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ ni báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti máa wàásù, ìyẹn sì ti wúlò gidigidi ju kéèyàn kàn máa sọ̀rọ̀ ẹnu lásán [látorí àga ìwàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì] lọ. Inú èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló máa ń dùn láti máa sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì.” Kí nìyẹn ti wá yọrí sí? “Lọ́dún 1999, láwọn olú ìlú méjì tí mo ti fọ̀rọ̀ wá àwọn èèyàn lẹ́nu wò ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù, ó ṣòro fún mi láti rí ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], tó sọ pé àwọn míṣọ́nnárì ‘Mormon’ láti ṣọ́ọ̀ṣì Latter-day Saints ti wàásù fóun rí. Àmọ́, ó ju ẹni méje nínú mẹ́wàá lọ tó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wàásù fáwọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan rí, kódà wọ́n ti wàásù fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà pàápàá.”
12. (a) Kí nìdí tá a fi máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn “lọ́pọ̀ ìgbà” láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa? (b) Sọ ìrírí ẹnì kan tó o mọ̀ tí kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ wa tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó ti wá yí pa dà báyìí?
12 Ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn ládùúgbò tiyín náà ti máa gbọ́ ìwàásù lẹ́nu àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà léraléra. Ó sì ṣeé ṣe kí iṣẹ́ ìwàásù ti ìwọ náà ń ṣe wà lára ohun tó jẹ́ kíyẹn ṣeé ṣe. Bó o ṣe ń bá àwọn èèyàn “lẹ́nì kọ̀ọ̀kan” sọ̀rọ̀ nígbà tó ò ń wàásù láti ilé dé ilé, wàá ti báwọn ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ nílé wọn. Àwọn kan lè máà fẹ́ gbọ́ bó o tiẹ̀ lọ sọ́dọ̀ wọn “lọ́pọ̀ ìgbà.” Àwọn kan sì lè ti gbọ́ ìwàásù ṣókí tó o ṣe bóyá nígbà tó o ka ẹsẹ Bíbélì kan tàbí tó o sọ èrò kan tó dá lórí Ìwé Mímọ́ fún wọn. Àmọ́, àwọn kan wà tó o ti láǹfààní láti jẹ́rìí fún dáadáa, tí wọ́n sì ti wá lóye òtítọ́. Onírúurú àwọn nǹkan tó lè ṣẹlẹ̀ nìyí bá a ti ń “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn tí kò kọ́kọ́ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sóhun tá a bá wọn sọ, kódà bá a tiẹ̀ lọ “lọ́pọ̀ ìgbà,” ló ti wá yí pa dà báyìí. Bóyá ohun kan ló ṣẹlẹ̀ sí wọn, tàbí sẹ́nì kan tí wọ́n fẹ́ràn, tó wá jẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere nígbà tó yá. Àwọn náà ti wá di arákùnrin àti arábìnrin wa báyìí. Torí náà, máà jẹ́ kó sú ẹ, kódà báwọn èèyàn ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ ìwàásù ẹ báyìí. A ò retí pé kí gbogbo èèyàn wá sínú òtítọ́. Àmọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa ni pé ká máa bá a nìṣó láti máa fìtara jẹ́rìí kúnnákúnná, ká sì máa fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ náà.
Àwọn Àbájáde Tá A Lè Má Mọ̀
13. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù wa ṣe lè yọrí síbi tá ò ronú kàn?
13 Kì í ṣàwọn tí Pọ́ọ̀lù ràn lọ́wọ́ láti di Kristẹni nìkan ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nípa lé lórí, bó sì ṣe máa ń rí lọ́rọ̀ tiwa náà nìyẹn. A máa ń rí i dájú pé à ń wàásù déédéé láti ilé dé ilé, a sì ń jẹ́rìí fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. A máa ń wàásù ìhìn rere fáwọn aládùúgbò wa, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé wa àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa. Ṣé a mọ gbogbo ibi tí ìwàásù wa máa ń yọrí sí? Àwọn kan wà tá a máa ń tètè rí ibi tó yọrí sí. Àmọ́, ṣe ni irúgbìn òtítọ́ máa ń wà lọ́kàn àwọn kan láìsọ kúlú fún àwọn àkókò kan, ó sì lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà, kó sì ta gbòǹgbò nígbà tó bá yá. Bọ́rọ̀ ò bá tiẹ̀ wá rí bẹ́ẹ̀, àwọn kan tá a ti bá sọ̀rọ̀ lè sọ ohun tá a ti sọ fún wọn fáwọn ẹlòmíì, wọ́n lè sọ àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ àti bá a ṣe ń hùwà fún wọn. Kò sí àníàní pé, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń fúrúgbìn òtítọ́ yẹn sọ́kàn àwọn ẹlòmíì láìfura, ó sì ṣeé ṣe kó méso jáde.
14, 15. Kí ni àbájáde iṣẹ́ ìwàásù tí arákùnrin kan ṣe?
14 Àpẹẹrẹ kan rèé: Ìlú Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Ryan àti Mandi, ìyàwó ẹ̀ ń gbé. Ryan ti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà fún ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́. Onísìn Hindu ni ọ̀gbẹ́ni yẹn, bí Ryan sì ṣe máa ń múra àti bó ṣe máa ń sọ̀rọ̀ wú u lórí gan-an. Ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde àtohun tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá ti kú wà lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Ryan bá ọ̀gbẹ́ni náà sọ. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lóṣù January, ọ̀gbẹ́ni yẹn béèrè lọ́wọ́ Jodi, ìyàwó ẹ̀ pé, kí ló mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyàwó ẹ̀ tó jẹ́ onísìn Kátólíìkì fèsì pé ohun tóun mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ju pé wọ́n máa ń “wàásù láti ilé dé ilé” lọ. Ni Jodi bá tẹ “Jehovah’s Witnesses” sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bó ṣe dórí ìkànnì wa tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nìyẹn, ìyẹn www.watchtower.org. Ó fẹ́ẹ̀ tó oṣù mẹ́ta tí Jodi fi ń ka àwọn ìwé tó wà lórí ìkànnì wa, títí kan Bíbélì àtàwọn àpilẹ̀kọ míì tó nífẹ̀ẹ́ sí.
15 Nígbà tó yá, Jodi àti Mandi pàdé ara wọn, torí pé nọ́ọ̀sì làwọn méjèèjì. Inú Mandi dùn láti dáhùn àwọn ìbéèrè Jodi. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí wọ́n fi jọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn àkòrí Bíbélì lóríṣiríṣi, Jodi sọ pé, “ó fẹ́ẹ̀ máà sí ohun tá ò sọ tán.” Jodi gbà pé kí Mandi máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Nígbà tó sì fi máa di oṣù October, Jodi ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó sì wá ṣèrìbọmi lóṣù February ọdún tó tẹ̀ lé e. Ó kọ̀wé pé: “Ní báyìí tí mo ti mọ òtítọ́, ìgbésí ayé mi ti nítumọ̀, mo sì láyọ̀.”
16. Kí ni ìrírí arákùnrin kan tó wà ní Florida jẹ́ ká mọ̀ nípa ìsapá tá à ń ṣe láti jẹ́rìí kúnnákúnná?
16 Ryan ò mọ̀ pé wíwàásù tóun wàásù fún ọ̀gbẹ́ni kan lè mú kí ẹlòmíì wá sínú òtítọ́. Òótọ́ ní pé Ryan ti wá rí ibi tí ìpinnu tóun ṣe láti “jẹ́rìí kúnnákúnná” yọrí sí. Àmọ́ ní tìẹ, iṣẹ́ ìwàásù tó ò ń ṣe lẹ́nu ọ̀nà àwọn èèyàn, níbi iṣẹ́, níléèwé tàbí láì-jẹ́-bí-àṣà lè ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ẹlòmíì láti gbọ́ ìhìn rere, síbẹ̀ tó ò mọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ò ṣe mọ ibi tí gbogbo iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe “ní agbègbè Éṣíà” yọrí sí, ó lè máà sí bí ìwọ náà ṣe lè mọ gbogbo àbájáde rere tó ti jẹ yọ látinú bó o ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná. (Ka Ìṣe 23:11; 28:23.) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa bá a nìṣó láti jẹ́rìí kúnnákúnná!
17. Kí lo pinnu láti ṣe lọ́dún 2009?
17 Jálẹ̀ ọdún 2009, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe láti ilé dé ilé àti láwọn ọ̀nà míì. Ìyẹn á jẹ́ káwa náà lè sọ bíi ti Pọ́ọ̀lù pé: “Èmi kò ka ọkàn mi sí nǹkan kan tí ó ṣọ̀wọ́n fún mi, bí mo bá sáà ti lè parí ipa ọ̀nà mi àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Jésù Olúwa, láti jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo ni àpọ́sítélì Pétérù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì ṣe jẹ́rìí kúnnákúnná ní ọ̀rúndún kìíní?
• Kí nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù tá a bá ṣe fáwọn èèyàn ṣe lè nípa rere débi tá ò mọ̀?
• Ki ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdun 2009, kí sì nìdí tó o fi rò pé ó bá a mu wẹ́kú?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2009 ni: “Jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” —Ìṣe 20:24.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn alàgbà ìjọ Éfésù mọ̀ pé ó ti mọ́ Pọ́ọ̀lù lára láti máa wàásù láti ilé dé ilé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Tó o bá ń jẹ́rìí kúnnákúnná fáwọn èèyàn, ó lè nípa débi tó ò mọ̀