Irú Èèyàn Wo Lo Fẹ́ Jẹ́?
Irú Èèyàn Wo Lo Fẹ́ Jẹ́?
Ọ̀GÁ ọlọ́pàá ìlú kan lórílẹ̀-èdè Philippines béèrè lọ́wọ́ aṣáájú ọ̀nà kan pé, “Kí lo ṣe tí ọkùnrin yìí fi yí ìwà rẹ̀ pa dà?” Ọ̀gá ọlọ́pàá yẹn sì nawọ́ sáwọn ìwé tó ga gègèrè lórí tábìlì rẹ̀, ó ní: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé fáìlì àwọn ẹjọ́ tó ti wá jẹ́ lọ́dọ̀ wa ló kúnlẹ̀ yìí? O ti bá wa yanjú ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tá a ní nílùú yìí.” Òkú ọ̀mùtí tó máa ń fa wàhálà kiri ìgboro tẹ́lẹ̀ ni ọkùnrin tí ọlọ́pàá yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kí ló wá mú kó jáwọ́ nínú gbogbo ìwà játijàti yẹn? Ohun tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fi ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbani sọ́kàn, pé kí wọ́n ‘bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà wọn àtijọ́ ṣe déédéé, kí wọ́n sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.’ (Éfé. 4:22-24) Kéèyàn tó lè jẹ́ ojúlówó Kristẹni, ó gbọ́dọ̀ gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, ì báà jẹ́ ìyípadà púpọ̀ tàbí díẹ̀ ló máa ṣe.
Àmọ́ ṣá, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni yíyí ìwà wa pa dà àti títẹ̀ síwájú débi tá a ti máa yẹ lẹ́ni tó lè ṣèrìbọmi wulẹ̀ jẹ́. Ní àkókò tá a fẹ́ ṣèrìbọmi, ńṣe lọ̀rọ̀ wa dà bí igi tí agbẹ́gilére kan ṣì gbẹ́ kalẹ̀. Lóòótọ́, a lè mọ ohun tó fẹ́ fi igi náà gbẹ́, àmọ́ iṣẹ́ ṣì pọ̀ tí agbẹ́gilére náà máa ṣe kí igi yìí tó lè di ère tó jojú ní gbèsè. Nígbà tá a ṣèrìbọmi, a ní ìwọ̀nba ànímọ́ tó mú ká yẹ lẹ́ni tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìwà tuntun ni. A gbọ́dọ̀ máa wá bí ìwà wa yóò ṣe túbọ̀ máa dáa sí i.
Pọ́ọ̀lù pàápàá rí i pé ó pọn dandan kóun túbọ̀ máa tún ìwà òun ṣe. Ohun tó sọ rèé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” (Róòmù 7:21) Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ irú èèyàn tóun jẹ́, ó sì mọ irú èèyàn tó wu òun láti jẹ́. Àwa náà ńkọ́? Ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Irú ìwà wo ló kù sí mi lọ́wọ́? Irú èèyàn wo ni mí? Irú èèyàn wo ni mo sì fẹ́ jẹ́?’
Irú Ìwà Wo Ló Kù sí Mi Lọ́wọ́?
Tá a bá fẹ́ tún ilé àtijọ́ kan ṣe, a ò kàn ní kun ìta ilé náà lásán tá a bá rí i pé àwọn òpó kan 2 Kọ́r. 13:5) A ní láti mọ àwọn èyí tó kù díẹ̀ káàtò nínú ìwà wa ká sì mú wọn kúrò. Jèhófà sì ti ràn wá lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìyẹn.
nínú ilé náà ti jẹrà. Tá ò bá tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ lára ilé náà ṣe, ó lè dá wàhálà sílẹ̀ tó bá yá. Bákan náà, ká máa ṣe bí olódodo èèyàn nìkan kò tó. A ní láti ṣàyẹ̀wò irú èèyàn tá a jẹ́ ká sì mọ àwọn ìwà tí kò dáa tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé lórí. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ìwà tá a rò pé a ti fi sílẹ̀ yóò tún pa dà wá. Torí náà, a ní láti máa yẹ ara wa wò kínníkínní. (Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ, ó sì ń gúnni àní títí dé pípín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti àwọn oríkèé àti mùdùnmúdùn wọn, ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Héb. 4:12) Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára tó pọ̀ láti yí ìgbésí ayé wa pa dà. Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lè wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin, débi tó fi máa dà bíi pé ó dé mùdùnmúdùn inú eegun wa lọ́hùn-ún. Ó máa ń jẹ́ ká mọ èrò ọkàn wa àtawọn ohun tó ń sún wa ṣe ohun tá a ń ṣe. Èyí á sì jẹ́ ká mọ irú èèyàn tá a jẹ́ gan-an, yàtọ̀ sí irú ẹni tí àwa fúnra wa tàbí àwọn èèyàn rò pé a jẹ́. Ẹ ò rí i pé ìrànwọ́ ńlá ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ fún wa bó ṣe ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ ká ṣiṣẹ́ lé lórí!
Nígbà tá a bá ń tún ilé kan tó ti ń bà jẹ́ ṣe, a ò ní fi mọ sórí títún àwọn ohun tó bà jẹ́ níbẹ̀ ṣe. Àá fẹ́ mọ ohun tó ba nǹkan wọ̀nyẹn jẹ́, ká lè mọ ohun tó yẹ ká ṣe tírú ẹ̀ ò fi ní wáyé mọ́. Bákan náà, lẹ́yìn tá a bá mọ àwọn ìwà wa tó kù díẹ̀ káàtó, ó tún yẹ ká mọ ìdí tá a fi ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ tàbí ohun tó ń dá kún un. Èyí á jẹ́ ká lè máa borí àwọn ìkùdíẹ̀-káàtò wa. Ṣé ẹ rí i, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fà á tá a fi ń ní irú àwọn ìwà tá a ní. Lára wọn ni ipò tá a wà láwùjọ, ayíká wa, àṣà ìbílẹ̀ wa, àwọn òbí wa, àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ àti inú ẹ̀sìn tí wọ́n ti tọ́ wa dàgbà. Kódà, ètò orí tẹlifíṣọ̀n àtàwọn fíìmù tá à ń wò, títí kan àwọn eré ìnájú míì tún lè nípa lórí wa. Mímọ̀ tá a bá mọ àwọn ohun tó lè ní ipa búburú lórí wa máa mú ká mọ ohun tá a lè ṣe tí wọn ò fi ní máa lágbára púpọ̀ lórí wa.
Lẹ́yìn tá a bá ti yẹ ara wa wò tán, ó lè ṣe wá bíi ká sọ pé, ‘Bí ẹ̀dá tèmi ṣe rí nìyẹn.’ Àmọ́, irú ẹ̀mí yẹn ò dáa. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ alágbèrè, tàbí abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, tàbí ọ̀mùtípara tàbí àwọn tó ń hu irú ìwà tó jọ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́ . . . pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” (1 Kọ́r. 6:9-11) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ.
Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tá a pe orúkọ rẹ̀ ní Marcos, a tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa irú ilé tí wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, ó ní: “Ṣe làwọn òbí mi máa ń pariwo lé ara wọn lórí. Ìdí nìyẹn tí mo fi yàyàkuyà nígbà tí mo fi máa di ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún.” Marcos wá di ògbólógbò atatẹ́tẹ́, ó ń jalè, ó sì tún di adigunjalè. Òun àtàwọn kan tiẹ̀ gbèrò láti fipá já ọkọ̀ ofuurufú gbà nígbà kan rí, àmọ́ kò bọ́ sí i. Àwọn ìwà pálapàla yìí ṣì wà lọ́wọ́ Marcos títí tó fi fẹ́yàwó. Ó tiẹ̀ bá a débi pé ó fi gbogbo ohun tó ní ta tẹ́tẹ́. Kò pẹ́ sígbà yẹn ló bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìyàwó rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ ọ. Lákọ̀ọ́kọ́, Marcos rò pé irú òun ò lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, bó ṣe ń fi ohun tó ń kọ́ sílò tó sì ń lọ sípàdé, ó dẹni tó pa àwọn ìwà tó ń hù tẹ́lẹ̀ tì. Ní báyìí, ó ti ṣèribọmi, ó sì ti di Kristẹni tó ń kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà tí wọ́n lè gbà yí pa dà.
Irú Èèyàn Wo Lo Fẹ́ Jẹ́?
Àwọn àyípadà wo ló lè pọn dandan pé ká ṣe káwọn ànímọ́ Kristẹni tá a ní bàa lè máa dáa sí i? Pọ́ọ̀lù gba àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín. Ẹ má ṣe máa purọ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀.” Àpọ́sítélì yìí wá ń bá a lọ pé: “Ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a.”—Kól. 3:8-10.
Látàrí èyí, ohun tó yẹ ká máa lé ni bá a ó ṣe fi ìwà wa àtijọ́ sílẹ̀, ká bẹ̀rẹ̀ sí í hu ìwà tuntun. Àwọn ànímọ́ wo la nílò tá ó fi lè máa hu ìwà tuntun? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kól. 3:12-14) Tá a bá ń sapá gidigidi láti ní àwọn ànímọ́ yìí, a óò ‘túbọ̀ máa jẹ́ ẹni tí Jèhófà fẹ́ràn táwọn ènìyàn sì fẹ́ràn.’ (1 Sám. 2:26) Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ pé òun ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tá a sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a ó lè “di aláfarawé Ọlọ́run” gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù.—Éfé. 5:1, 2.
Ọ̀nà míì tá a lè gbà mọ àwọn ìyípadà tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn. Ká máa ronú nípa ibi tí wọ́n ti ṣe ohun tó dáa, àti ibi tí wọ́n ti ṣohun tó kù díẹ̀ káàtó. Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ Jósẹ́fù ọmọ Jékọ́bù tó jẹ́ babańlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe rẹ́ ẹ jẹ tó, ó pàpà ní ẹ̀mí tó dáa, ó sì tipa báyìí dẹni tá a mọ̀ séèyàn tó dáa. (Jẹ́n. 45:1-15) Àmọ́ ti Ábúsálómù ọmọ Dáfídì Ọba kò rí báyẹn. Ó ń ṣe bí ẹni tọ́ràn àwọn aráàlú jẹ lọ́kàn, wọ́n sì ń kókìkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí arẹwà ọkùnrin. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀dàlẹ̀ paraku àti apààyàn ni. (2 Sám. 13:28, 29; 14:25; 15:1-12) Téèyàn bá ń ṣe bíi pé òun jẹ́ ẹni rere, bó tiẹ̀ jẹ́ arẹwà èèyàn, ìyẹn ò sọ ọ́ di èèyàn dáadáa tó fani mọ́ra.
A Lè Yí Ìwà Wa Pa Dà
Tá a bá fẹ́ yí ìwà wa pa dà ká lè jẹ́ ẹni tó wu Ọlọ́run, a ní láti fiyè sí irú ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún. (1 Pét. 3:3, 4) Láti yí ìwà wa pa dà, ó gba pé ká mọ àwọn ìwà wa tó kù díẹ̀ káàtó, ó tún yẹ ká mọ ìdí tá a fi ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ tàbí ohun tó ń dá kún un. A sì tún ní láti ní àwọn ànímọ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí. Ǹjẹ́ ìwà wa lè máa dáa sí i tá a bá ń sapá láti ṣe àwọn àtúnṣe yìí?
Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ láti yí ìwà wa pa dà. Àwa náà lè gba irú àdúrà tí onísáàmù kan gbà, pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sm. 51:10) A lè gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ máa ṣiṣẹ́ nínú wa, débi táá fi máa wù wá láti mú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Láìsí àní-àní, ó dájú pé a lè di irú èèyàn táá túbọ̀ máa wu Jèhófà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ṣé ńṣe ló kàn yẹ ká kun ìta ilé tí ìjì líle ti sọ di hẹ́gẹhẹ̀gẹ yìí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣé ìwà rẹ ti dà bíi ti Kristi?