‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!
‘Ọlọ́run Ló Ń Mú Kí Ó Dàgbà’!
“Kì í ṣe ẹni tí ń gbìn ni ó jẹ́ nǹkan kan tàbí ẹni tí ń bomi rin, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń mú kí ó dàgbà.”—1 KỌ́R. 3:7.
1. Inú iṣẹ́ wo la ti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”?
NÍGBÀ tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní tí gbogbo wa ní lẹ́nu iṣẹ́ sísọni di ọmọlẹ́yìn, ó pè wá ní “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (Ka 1 Kọ́ríńtì 3:5-9.) Ó fi iṣẹ́ yìí wé iṣẹ́ fífúnrúgbìn àti bíbomi rin irúgbìn. Ká sì tó lè ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí, a nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. Ìyẹn ni Pọ́ọ̀lù fi rán wa létí pé ‘Ọlọ́run ló ń mú kí ó dàgbà.’
2. Báwo ni mímọ̀ pé ‘Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà’ ṣe ń jẹ́ ká lè fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
2 Tá a bá ń rántí òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí pé ‘Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà,’ a ó máa fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Lóòótọ́, a lè sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà lọpẹ́ yẹ fún ìtẹ̀síwájú ẹnì kan tó di ọmọlẹ́yìn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, bó ti wù ká sapá tó, kò sí èyíkéyìí nínú wa tó lè mọ gbogbo ohun tó ń mú kí ẹnì kan di ọmọlẹ́yìn, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé ká lágbára lórí nǹkan wọ̀nyẹn. Sólómọ́nì Ọba sọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́ gan-an nígbà tó sọ pé: “Ìwọ kò mọ iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, ẹni tí ń ṣe ohun gbogbo.”—Oníw. 11:5.
3. Báwo ni iṣẹ́ fífúnrúgbìn àti iṣẹ́ sísọni di ọmọlẹ́yìn ṣe jọra?
3 Ṣé bá ò ṣe mọ ohun pàtó tó ń mú kẹ́nì kan di ọmọlẹ́yìn ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù súni láti ṣe ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń jẹ́ kó dùn mọ́ni, torí ó máa ń fojú ẹni sọ́nà. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere, yálà níhìn-ín tàbí lọ́hùn-ún, tàbí kẹ̀, bóyá àwọn méjèèjì ni yóò dára bákan náà.” (Oníw. 11:6) Ká sòótọ́, tá a bá gbin irúgbìn, a kì í lè fi ìdánilójú sọ èyí tó máa hù tàbí ibi tó ti máa hù. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń ṣẹlẹ̀ kí irúgbìn tó hù, èyí tó jẹ́ pé a ò lágbára lé lórí. Bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ sísọni di ọmọlẹ́yìn ṣe rí. Jésù pàfiyèsí sí kókó yìí nínú àpèjúwe méjì kan tó ṣe, èyí tó wà lákọọ́lẹ̀ fún wa nínú orí kẹrin ìwé Ìhìn Rere Máàkù. Ẹ jẹ́ ká wo ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe méjì yìí.
Onírúurú Ilẹ̀ Tó Yàtọ̀ Síra
4, 5. Ṣàkópọ̀ àpèjúwe afúnrúgbìn tí Jésù sọ.
4 Nínú Máàkù 4:1-9, Jésù sọ̀rọ̀ nípa afúnrúgbìn kan tó fún irúgbìn káàkiri oko, tí irúgbìn rẹ̀ sì bọ́ sí onírúurú ibi tó yàtọ̀ síra. Jésù ní: “Ẹ fetí sílẹ̀. Wò ó! Afúnrúgbìn jáde lọ láti fúnrúgbìn. Bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Irúgbìn mìíràn sì bọ́ sórí ibi àpáta níbi tí, ó dájú pé, kò ti ní erùpẹ̀ púpọ̀, ó sì rúyọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí ṣíṣàìní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn là, a jó o gbẹ, àti nítorí ṣíṣàìní gbòǹgbò, ó rọ. Irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà sì yọ, wọ́n sì fún un pa, kò sì so èso kankan. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà, àti pé, ní jíjáde wá àti ní gbígbèrú sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí so èso, wọ́n sì ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n, àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.”
5 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, tí wọ́n bá fẹ́ gbin irúgbìn, ńṣe ni wọ́n sábà máa ń fọ́n ọn káàkiri oko. Afúnrúgbìn náà yóò da irúgbìn tó fẹ́ gbìn sínú ìṣẹ́po ẹ̀wù rẹ̀ tàbí sínú nǹkan kan, yóò sì máa fọwọ́ bù ú látibẹ̀, yóò wá máa fọ́n ọn káàkiri inú oko. Nítorí náà, kì í ṣe pé afúnrúgbìn yìí mọ̀ọ́mọ̀ gbin irúgbìn rẹ̀ sí onírúurú ilẹ̀ tó yàtọ̀ síra. Ńṣe ni irúgbìn tó ń fọ́n kàn bọ́ sí onírúurú ibi.
6. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé àpèjúwe afúnrúgbìn náà?
6 Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé à ń méfò nípa ìtumọ̀ àpèjúwe yẹn. Jésù ṣàlàyé rẹ̀ nínú Máàkù 4:14-20, ó ní: “Afúnrúgbìn fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. Nígbà náà, ìwọ̀nyí ni àwọn ti ẹ̀bá ojú ọ̀nà níbi tí a gbin ọ̀rọ̀ náà sí; ṣùgbọ́n gbàrà tí wọ́n ti gbọ́ ọ, Sátánì wá, ó sì mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú wọn kúrò. Bákan náà, ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí a fún sórí àwọn ibi àpáta: gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gbà á. Síbẹ̀, wọn kò ní gbòǹgbò kankan nínú ara wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ fún àkókò kan; lẹ́yìn náà, gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀. Àwọn mìíràn ṣì wà tí a fún sáàárín àwọn ẹ̀gún; ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù gbógun wọlé, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso. Níkẹyìn, àwọn tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà ni àwọn tí wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì fi ọkàn rere gbà á, tí wọ́n sì ń so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.”
7. Kí ni irúgbìn àti onírúurú ilẹ̀ yẹn ṣàpẹẹrẹ?
7 Ẹ kíyè sí i pé Jésù ò sọ pé irúgbìn tí afúnrúgbìn náà fọ́n sínú oko yàtọ̀ síra. Irúgbìn oríṣi kan náà yẹn ló sọ pé ó bọ́ sórí onírúurú ilẹ̀, ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì mú àbájáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá. Ilẹ̀ àkọ́kọ́ le gan-an, ìkejì kò fi bẹ́ẹ̀ ní erùpẹ̀, ẹ̀gún bo ilẹ̀ kẹta, ìkẹrin sì jẹ́ ilẹ̀ àtàtà, tó dára, tó sì wá mú kí irúgbìn náà so èso dáadáa. (Lúùkù 8:8) Kí ni irúgbìn náà? Ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ni, èyí tó wà nínú Bíbélì. (Mát. 13:19) Kí ni ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wọ̀nyẹn ṣàpẹẹrẹ? Wọ́n ṣàpẹẹrẹ ọkàn onírúurú èèyàn.—Ka Lúùkù 8:12, 15.
8. (a) Ta ni afúnrúgbìn náà ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí nìdí tí ohun táwọn tó ń gbọ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe fi yàtọ̀ síra?
8 Ta ni afúnrúgbìn yẹn dúró fún? Ó dúró fún àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìyẹn àwọn tó ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n sì ń bomi rin ín bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Àpólò. Ṣùgbọ́n bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣiṣẹ́ kára, àbájáde ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ilẹ̀ wọn ní. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọkàn àwọn tó ń gbọ́ ìwàásù wọn yàtọ̀ síra. Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn yẹn, afúnrúgbìn náà ò lágbára kankan lórí ohun tó máa jẹ́ àbájáde ilẹ̀ wọ̀nyẹn. Ìtùnú gbáà lèyí jẹ́ o, pàápàá fáwọn arákùnrin àti arábìnrin wa olóòótọ́ tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣiṣẹ́, àmọ́ tó jẹ́ pé àṣeyọrí díẹ̀ ni wọ́n lè rí tọ́ka sí! a Kí ló mú kó jẹ́ ìtùnú?
9. Kókó ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú wo ni Pọ́ọ̀lù àti Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
9 Kì í ṣe iye èèyàn tó tipasẹ̀ akéde tó ń fúnrúgbìn di ọmọlẹ́yìn ni ìdiwọ̀n bó ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nígbà tó sọ pé: “Ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò gba èrè tirẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òpò tirẹ̀.” (1 Kọ́r. 3:8) Béèyàn ṣe ṣòpò tó ló ń pinnu èrè téèyàn máa gbà, kì í ṣe ohun tó tipa òpò yẹn jáde. Jésù náà sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ padà dé láti ìrìn àjò ìwàásù kan tí wọ́n rìn. Ó ṣẹlẹ̀ pé inú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń dùn gan-an pé àwọn ẹ̀mí èṣù ń tẹrí ba fáwọn bí àwọn ṣe ń lo orúkọ Jésù. Lóòótọ́, ìyẹn jẹ́ ohun tó wúni lórí, àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe yọ̀ lórí èyí, pé a mú àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín ní ọ̀run.” (Lúùkù 10:17-20) Àní bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò bá tiẹ̀ di ọmọlẹ́yìn bí afúnrúgbìn kan ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù, ìyẹn ò fi hàn pé akitiyan rẹ̀ kò tó, tàbí pé kò jẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yẹn bíi tàwọn míì. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí ọkàn ẹni tó ń gbọ́ ìwàásù ṣe rí ló sábà máa ń pinnu àbájáde iṣẹ́ yẹn. Àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ọlọ́run ló ń mú kó dàgbà!
Ojúṣe Ẹni Tó Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Náà
10. Kí ló ń pinnu bóyá ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà máa dà bí ilẹ̀ àtàtà tàbí kò ní dà bẹ́ẹ̀?
10 Àwọn tó wá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run ti pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe nípa ọ̀rọ̀ náà ni? Rárá o. Fúnra wọn ni wọ́n máa pinnu bóyá wọ́n á dà bí ilẹ̀ àtàtà tàbí wọn ò ní dà bẹ́ẹ̀. Kò sí àní-àní pé ọkàn èèyàn lè yí padà, yálà sí rere tàbí sí búburú. (Róòmù 6:17) Ohun tí Jésù sọ nínú àpèjúwe rẹ̀ ni pé “gbàrà tí [àwọn kan] ti gbọ́” ọ̀rọ̀ náà ni Sátánì wá tó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò. Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀ranyàn ni pé kó rí bẹ́ẹ̀ o. Ìwé Jákọ́bù 4:7 ṣáà gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká “kọ ojú ìjà sí Èṣù,” pé yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wa. Jésù sọ pé àwọn míì fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀rẹ̀, àmọ́ wọ́n wá kọsẹ̀ torí pé “wọn kò ní gbòǹgbò kankan nínú ara wọn.” Ohun tí Bíbélì sì ní kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe ni pé ká “ta gbòǹgbò, kí [á] sì fìdí múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ náà” ká bàa lè mòye ní kíkún “ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn náà jẹ́, àti láti mọ ìfẹ́ Kristi tí ó tayọ ré kọjá ìmọ̀.”—Éfé. 3:17-19; Kól. 2:6, 7.
11. Báwo ni ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe lè yẹra fún jíjẹ́ kí àníyàn ayé àti ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbọ́ pa?
11 Ohun tí Jésù sọ nípa àwọn míì ni pé wọ́n jẹ́ kí “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn fún àwọn nǹkan yòókù” gbógun wọlé, kí wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa. (1 Tím. 6:9, 10) Báwo ni wọn ì bá ti ṣe yẹra fún èyí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ kan tó dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí òun ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’”—Héb. 13:5.
12. Kí nìdí táwọn tí erùpẹ̀ àtàtà ṣàpẹẹrẹ fi so èso ní ìwọ̀n tó yàtọ̀ síra?
12 Níkẹyìn, Jésù sọ pé àwọn irúgbìn tí wọ́n fún sórí erùpẹ̀ àtàtà “so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tó kọbi ara sí ọ̀rọ̀ náà lọ́kàn rere, tí wọ́n sì so èso, ohun tí kálukú wọn lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere yàtọ̀ síra gẹ́gẹ́ bí ipò olúkúlùkù wọn ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, ọjọ́ ogbó tàbí àìsàn tó ń dáni lọ́wọ́ kọ́ lè má jẹ́ káwọn kan lè ṣe tó bó ṣe yẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Fi wé Máàkù 12:43, 44.) Ká má sì tún gbàgbé pé afúnrúgbìn náà lè má lágbára tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ lórí nǹkan wọ̀nyí, àmọ́ ṣá, inú wọn máa ń dùn tí wọ́n bá rí i pé Jèhófà ti mú kí irúgbìn àwọn dàgbà.—Ka Sáàmù 126:5, 6.
Afúnrúgbìn Tó Sùn
13, 14. (a) Ṣàkópọ̀ àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọkùnrin tó ń fúnrúgbìn. (b) Ta ni afúnrúgbìn náà dúró fún, kí sì ni irúgbìn náà?
13 A tún rí àpèjúwe míì nípa afúnrúgbìn nínú Máàkù 4:26-29. Ó kà pé: “Lọ́nà yìí, ìjọba Ọlọ́run rí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹnì kan sọ irúgbìn sórí ilẹ̀, ó sì [ń] sùn ní òru, ó sì [ń] dìde ní ojúmọ́, irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀. Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà. Ṣùgbọ́n gbàrà tí èso bá gba èyí láyè, òun a ti dòjé bọ̀ ọ́, nítorí àkókò ìkórè ti dé.”
14 Ta ni afúnrúgbìn yìí? Àwọn kan lára àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé Jésù fúnra rẹ̀ ni. Àmọ́, ẹ gbọ́ ná, báwo la ṣe lè sọ pé Jésù ń sùn, tí kò sì wá mọ bí irúgbìn ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń dàgbà? Ó dájú hán-ún pé Jésù mọ gbogbo bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà! Lẹ́nu kan ṣá, bíi ti afúnrúgbìn tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níṣàájú náà ni eléyìí ṣe rí. Olúkúlùkù akéde Ìjọba Ọlọ́run ló dúró fún, ìyẹn àwọn tó ń gbin irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń fìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń wàásù ni irúgbìn tí wọ́n fọ́n sórí ilẹ̀. b
15, 16. Nínú àpèjúwe afúnrúgbìn, kókó pàtàkì wo ni Jésù fi hàn nípa bí irúgbìn ṣe ń dàgbà àti bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn?
15 Jésù sọ pé afúnrúgbìn náà ń “sùn ní òru,” ó sì ń “dìde ní ojúmọ́.” Kì í ṣe àìmọ iṣẹ́ ẹni níṣẹ́ ló ń jẹ́ kí afúnrúgbìn náà ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn kàn ṣàpẹẹrẹ bí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ṣe máa ń gbé ìgbésí ayé ni. Ọ̀nà tí Jésù gbà sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ yìí fi hàn pé ńṣe ni afúnrúgbìn náà ń ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án, tó sì ń sùn lóru láàárín àkókò kan. Jésù sì wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà. Ó ní: “Irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè.” Ó wá fi kún un pé: “Gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀.” Kókó kan tí ibí yìí ń fi hàn ni pé ńṣe ni irúgbìn náà dàgbà “fúnra rẹ̀.” c
16 Kí ni kókó tí Jésù fẹ́ gbìn síni lọ́kàn níhìn-ín? Ṣàkíyèsí pé, ohun tíbí yìí ń pàfiyèsí sí ni bí irúgbìn náà ṣe ń dàgbà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Jésù ní: “Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà.” (Máàkù 4:28) Díẹ̀díẹ̀ ni irúgbìn náà ń dàgbà ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Kò ṣeé fipá mú kó dàgbà ní kóyákóyá. Bí ìdàgbàsókè nípa tẹ̀mí, ìyẹn dídi ọmọlẹ́yìn, náà ṣe rí nìyẹn. Ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lòun náà ń wáyé, bí Jèhófà ṣe ń mú kí òtítọ́ dàgbà lọ́kàn ẹni tó ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́.—Ìṣe 13:48; Héb. 6:1.
17. Àwọn wo ló ń yọ̀ nígbà tí irúgbìn Ìjọba náà bá sèso?
17 Báwo ni afúnrúgbìn náà ṣe ń kópa nínú ìkórè yẹn ní “gbàrà tí èso bá gba èyí láyè”? Tí Jèhófà bá ti jẹ́ kí òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run dàgbà lọ́kàn àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọlẹ́yìn, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n á tẹ̀ síwájú, wọ́n á sì dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run débi pé wọ́n á yara wọn sí mímọ́ fún un. Wọ́n á wá ṣèrìbọmi láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn. Àwọn arákùnrin tó bá tẹ̀ síwájú débi pé òtítọ́ jinlẹ̀ gan-an nínú wọn yóò wá dẹni tá a fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ. Ẹni tó kọ́kọ́ gbin irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run sọ́kàn ẹni tó di ọmọlẹ́yìn náà, àtàwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run míì tí kò sí lára àwọn tó dìídì ran ẹni náà lọ́wọ́ láti di ọmọlẹ́yìn, á wá máa kórè irúgbìn Ìjọba náà. (Ka Jòhánù 4:36-38.) Yóò wá di pé “afúnrúgbìn àti akárúgbìn [ń] yọ̀ pa pọ̀.”
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa Lóde Òní
18, 19. (a) Ìṣírí wo lo ti rí gbà látinú àwọn àpèjúwe Jésù tá a gbé yẹ̀ wò yìí? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?
18 Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àtúnyẹ̀wò àpèjúwe méjì yìí tó wà nínú ìwé Máàkù orí kẹrin? A lè rí i kedere pé a níṣẹ́ láti ṣe, ìyẹn fífún irúgbìn. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwáwí tàbí àwọn ìṣòro àti ìnira tá a lè ní ṣèdíwọ́ fún wa ká má lè ṣe iṣẹ́ yìí. (Oníw. 11:4) Lẹ́sẹ̀ kan náà, a tún mọ̀ pé àǹfààní ńlá la ní láti jẹ́ ara àwọn tá a kà sí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Jèhófà ló ń mú kí irúgbìn wa dàgbà, ìyẹn ni pé káwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn, torí òun ló ń fìbùkún sí ìsapá wa àti tàwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. A ti rí i pé a ò lé fipá sọni di ọmọlẹ́yìn. A sì tún rí i pé kò sídìí tó fi yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì tàbí ká jẹ́ kó sú wa táwọn èèyàn kò bá fi bẹ́ẹ̀ di ọmọlẹ́yìn. Ó tún jẹ́ ìtùnú gan-an láti mọ̀ pé, kì í ṣe iye àwọn tó tipasẹ̀ wa di ọmọlẹ́yìn la fi ń díwọ̀n bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà tó tàbí bá a ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó lẹ́nu iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká “wàásù ìhìn rere ìjọba yìí . . . láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”—Mát. 24:14.
19 Kí làwọn nǹkan míì tí Jésù tún kọ́ wa nípa ìtẹ̀síwájú àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọlẹ́yìn àti ti iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run? Ìdáhùn ìbéèrè yìí wà nínú àwọn àpèjúwe míì tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. A ó gbé àwọn kan nínú wọn yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpẹẹrẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Arákùnrin Georg Fjölnir Lindal ṣe ní ilẹ̀ Iceland, èyí tí ìtàn rẹ̀ wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà September 15, 1993, ojú ìwé 24 àti 25. Tún wo ìrírí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́ tí wọ́n fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ ìwàásù fún ọ̀pọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè Ireland láìsí àṣeyọrí ojú ẹsẹ̀, èyí tó wà nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn 1988 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 82 sí 99.
b Nígbà kan rí, a ti ṣàlàyé nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ pé àwọn irúgbìn náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ànímọ́ kálukú, tí a ní láti mú dàgbà sókè, èyí tí ipò àyíká onítọ̀hún sì lágbára lé lórí. Ṣùgbọ́n, ẹ kíyè sí i pé nínú àpèjúwe Jésù, irúgbìn náà fúnra rẹ̀ kò yí padà di irúgbìn búburú tàbí èyí tó jẹrà. Ńṣe ló hù, tó sì dàgbà títí èso rẹ̀ fi gbó.—Wo Ile-Iṣọ Naa, December 15, 1980, ojú ìwé 20 sí 26.
c Ibì kan ṣoṣo tí Bíbélì èdè Gíríìkì ìjímìjí tún ti lo gbólóhùn náà “fúnra rẹ̀” ni Ìṣe 12:10, níbi tó ti sọ pé ẹnubodè onírin kan ṣí “fúnra rẹ̀.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn ọ̀nà wo ni gbígbin irúgbìn àti wíwàásù ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run gbà jọra?
• Kí ni Jèhófà fi ń díwọ̀n bí akéde Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ olóòótọ́ tó?
• Kí làwọn ohun tó jọra wọn tí Jésù tọ́ka sí nínú bí irúgbìn ṣe ń dàgbà àti bí ẹnì kan ṣe ń di ọmọlẹ́yìn?
• Báwo ni “afúnrúgbìn àti akárúgbìn” ṣe ń “yọ̀ pa pọ̀”?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Kí nìdí tí Jésù fi fi oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run wé afúnrúgbìn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn tí erùpẹ̀ àtàtà ṣàpẹẹrẹ máa ń fi tọkàntọkàn kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run bí ipò olúkúlùkù wọn ṣe rí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ọlọ́run ló ń mú kí ó dàgbà