Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Gbèjà Ìgbàgbọ́ Rẹ?
Ǹjẹ́ O Ti Múra Tán Láti Gbèjà Ìgbàgbọ́ Rẹ?
ǸJẸ́ o ti bá ara rẹ nínú ipò kan rí tó ti di dandan kó o gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ? Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó ń jẹ́ Susana, lórílẹ̀-èdè Paraguay. Nígbà kan tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìwà ọmọlúwàbí nílé ìwé wọn, wọ́n sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò gba apá ibi tí wọ́n ń pè ní Májẹ̀mú Láéláé nínú Bíbélì gbọ́, pé a ò gba Jésù Kristi gbọ́, àti pé a ò nígbàgbọ́ nínú Màríà. Wọ́n tún sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn tó máa ń gbà láti kú dípò ká lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Ká ní o wà níbẹ̀, kí lò bá ṣe?
Ńṣe ni Susana gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì nawọ́ sókè láti sọ̀rọ̀. Torí pé àkókò ẹ̀kọ́ yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ó bẹ olùkọ́ wọn pé kó fóun láyè láti wá ṣàlàyé nípa ìgbàgbọ́ òun fún gbogbo kíláàsì náà lákòókò míì, nítorí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Olùkọ́ wọn sì gbà pé kó wá ṣe bẹ́ẹ̀. Ó fi ọ̀sẹ̀ méjì múra sílẹ̀ de ìgbà tó máa ṣàlàyé nínú kíláàsì rẹ̀. Ó lo ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?
Nígbà tí ọjọ́ pé láti bá wọn sọ̀rọ̀, Susana ṣàlàyé ìdí tá a fi ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó tún ṣàlàyé ohun tá à ń retí lọ́jọ́ ọ̀la àti ìdí tá a kì í fi í gbẹ̀jẹ̀. Ó wá ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ béèrè ìbéèrè tí wọ́n bá fẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló nawọ́ tí wọ́n sì bi í ní ìbéèrè. Inú olùkọ́ rẹ̀ dùn gan-an bí ọ̀dọ́mọbìnrin náà ṣe fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè náà.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan wá sọ pé: “Mo ti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn rí, kò sì sí ẹyọ ère kan níbẹ̀.” Olùkọ́ wọn yìí fẹ́ mọ ìdí tí kò fi sí ère níbẹ̀. Ni Susana bá ka Sáàmù 115:4-8 àti Ẹ́kísódù 20:4 fún wọn. Ẹnu ya olùkọ́ náà gan-an, ó wá sọ pé: “Báwo wá ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wa ṣe kún fún ère nígbà tó jẹ́ pé Bíbélì kà á léèwọ̀?”
Ogójì ìṣẹ́jú ni wọ́n fi bi Susana ní ìbéèrè tóun náà sì ń dáhùn. Nígbà tó wá béèrè bóyá wọ́n á fẹ́ wo fídíò náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge, èyí tó dá lórí àwọn nǹkan míì téèyàn lè lò dípò ẹ̀jẹ̀, gbogbo wọn láwọn fẹ́ wò ó. Ni olùkọ́ wọn bá ṣètò pé kí wọ́n tẹ̀ síwájú lórí ọ̀rọ̀ náà lọ́jọ́ kejì. Bí wọ́n ṣe wo fídíò náà tán, Susana ṣàlàyé onírúurú ìtọ́jú míì tó wà dípò gbígba ẹ̀jẹ̀ sára, èyí táwọn kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fara mọ́. Olùkọ́ náà sọ̀rọ̀ nípa ìyẹn, ó ní: “Mi ò mọ̀ pé àwọn ìtọ́jú míì téèyàn lè gbà dípò gbígba ẹ̀jẹ̀ sára pọ̀ tó báyìí; mi ò sì mọ àǹfààní tó wà nínú gbígba àwọn ìtọ́jú míì dípò ìfàjẹ̀sínilára tẹ́lẹ̀. Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni àwọn ìtọ́jú yìí wà fún ni?” Nígbà tó gbọ́ pé gbogbo èèyàn ló wà fún, ó ní: “Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá délé mi nígbà míì, màá fàyè sílẹ̀ ká jọ jíròrò.”
Ọ̀rọ̀ ogún ìṣẹ́jú ni Susana múra sílẹ̀, àmọ́ wákàtí mẹ́ta ni wọ́n lò lórí ìjíròrò yẹn. Ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ míì náà sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn nínú ṣọ́ọ̀ṣì tiwọn. Nígbà tí wọ́n parí ọ̀rọ̀ wọn táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù bi wọ́n ní ìbéèrè, wọn kò lè gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Olùkọ́ wọn wá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tẹ́yin ò lè gbèjà ìgbàgbọ́ tiyín bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ tirẹ̀?”
Wọ́n fèsì pé: “Wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gan-an ní tiwọn. Àwa ò kọ́ ọ ní tiwa.”
Olùkọ́ wọn wá yíjú sí Susana, ó ní: “Mo gbà pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóòótọ́, o sì ń gbìyànjú láti fi ohun tó o kọ́ ṣèwà hù. O káre láé.”
Susana lè dákẹ́ nígbà tó gbọ́ ohun tí wọ́n sọ nípa àwa Ẹlẹ́rìí, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ńṣe ló tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere ti ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tí Bíbélì kò sọ orúkọ rẹ̀, èyí táwọn ará Síríà kó lẹ́rú. Ilé Náámánì, olórí ogun àwọn Síríà tó lárùn burúkú kan tí wọ́n ń pè ní ẹ̀tẹ̀, ni ọmọbìnrin yẹn ń gbé. Ọmọ Ísírẹ́lì náà kò dákẹ́, ńṣe ló sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé: “Ká ní olúwa mi wà níwájú wòlíì tí ó wà ní Samáríà ni! Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá wò ó sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Ọmọbìnrin yìí kò panu mọ́ láìsọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tòótọ́. Ìyẹn ló sì jẹ́ kí Náámánì olúwa rẹ̀ di olùjọsìn Jèhófà.—2 Ọba 5:3, 17.
Bẹ́ẹ̀ náà ni Susana kò ṣe panu mọ́ láìwàásù nípa Jèhófà àtàwọn èèyàn Rẹ̀. Bí Susana ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà táwọn èèyàn ṣáátá ohun tó gbà gbọ́, ńṣe ló tẹ̀ lé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:15) Ǹjẹ́ o ti múra tán láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ, kó o má sì dákẹ́ nígbà tó bá yẹ kó o gbèjà rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
O lè lo àwọn ìtẹ̀jáde yìí láti fi gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ