Ọgbọ́n Táwọn Kan Dá sí Ìṣòro Wọn
Ọgbọ́n Táwọn Kan Dá sí Ìṣòro Wọn
Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN mẹ́ta kan ní orílẹ̀-èdè Àárín Gbùngbùn Áfíríkà fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè wọn. Àádọ́rùn-ún kìlómítà ni wọ́n máa rìn lójú ọ̀nà eléruku kí wọ́n tó débẹ̀, wọn ò sì lówó ọkọ̀. Báwo ni wọ́n ṣe máa débẹ̀? Nǹkan tí wọ́n pinnu láti ṣe ni pé káwọn yá kẹ̀kẹ́ mẹ́ta táwọn máa gùn lọ, àmọ́ wọn ò rí èyí tó dáa.
Alàgbà kan ní ìjọ wọn rí ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn yìí, ló bá gbé kẹ̀kẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kẹ̀kẹ́ náà ti gbó, ó ṣì dáa díẹ̀. Alàgbà yìí ṣàlàyé ọgbọ́n tóun àtàwọn kan dá nígbà kan kí wọ́n lè dé ibi tí wọ́n á ti ṣe àpéjọ àgbègbè. Alàgbà yẹn sọ fún wọn pé kí wọ́n pín kẹ̀kẹ́ kan tí wọ́n rí yẹn lò láàárín ara wọn. Ojútùú rẹ̀ yẹn rọrùn, àmọ́ ó máa gba pé kí wọ́n fètò sí i dáadáa. Báwo lẹni mẹ́ta ṣe máa lo kẹ̀kẹ́ kan ṣoṣo láti fi rìnrìn àjò?
Àwọn arákùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pàdé ní kùtù hàì, wọ́n di àwọn ẹrù wọn sórí kẹ̀kẹ́ náà, wọ́n sì gbéra kóòrùn má bàa pa wọ́n jù. Ẹnì kan kọ́kọ́ gun kẹ̀kẹ́ náà lọ síwájú, àwọn méjì tó kù sì ń yára rìn bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀. Lẹ́yìn tẹ́ni yẹn ti rin nǹkan bí ìdámẹ́ta máìlì kan, ó gbé kẹ̀kẹ́ náà ti ara igi níbi táwọn méjì tó ń rìn bọ̀ lẹ́yìn á ti lè tètè rí i lọ́ọ̀ọ́kán kí wọ́n máa bàa jí i lọ. Ó wá ń fẹsẹ̀ rin lọ ṣáájú wọn.
Nígbà táwọn méjì tó kù dé ibi tí kẹ̀kẹ́ náà wà, ọ̀kan nínú wọn gùn-ún, ẹnì kẹ́ta sì ń rìn bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ fún nǹkan bí ìdámẹ́ta máìlì kan kóun náà tó tún gbà á. Nítorí náà dípò kẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn fẹsẹ̀ rin àádọ́rùn-ún kìlómítà, wọ́n dín in kù sí ọgọ́ta kìlómítà nítorí wọ́n ṣètò tó dára, àti pé wọ́n ti pinnu láti rí i pé àwọn dé àpéjọ àgbègbè náà. Ìsapá wọn yìí kì í ṣe àṣedànù. Ó jẹ́ kí wọ́n lè bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ṣe àpéjọ náà, wọ́n sì gbádùn oúnjẹ tẹ̀mí náà gan-an. (Diu. 31:12) Ṣé wàá ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti rí i pé o lọ sí àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún yìí?