Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là.” (Róòmù 11:26) Ṣé ohun tó ń sọ ni pé tó bá dìgbà kan gbogbo àwọn Júù pátá máa di Kristẹni?
Rárá o, ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn kọ́ nìyẹn. Gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù lápapọ̀ bí orílẹ̀-èdè kan kò gbà pé Jésù ni Mèsáyà náà. Lẹ́yìn ìgbà tí Jésù kú, ó ṣe kedere pé kì í ṣe gbogbo àwọn Júù lápapọ̀ ló di Kristẹni. Síbẹ̀ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé “a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là” ṣì jóòótọ́. Lọ́nà wo?
Jésù sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Júù ìgbà ayé rẹ̀ pé: “A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.” (Mát. 21:43) Nítorí pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ kọ Jésù sílẹ̀, Jèhófà yíjú sí orílẹ̀-èdè tuntun, ìyẹn orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. Pọ́ọ̀lù pe orílẹ̀-èdè náà ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gál. 6:16.
Àwọn apá ibòmíràn nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn ló para pọ̀ jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Róòmù 8:15-17; Ìṣí. 7:4) Ìṣípayá 5:9, 10 jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí kì í ṣe Júù wà lára Ísírẹ́lì yìí, èyí sì fi hàn pé “láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti wá. Ọlọ́run yan àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí lọ́nà àkànṣe láti jẹ́ “ìjọba kan àti àlùfáà . . . , wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti kọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tóun yàn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè padà bá Ọlọ́run rẹ́. Ohun táwọn àpọ́sítélì àti ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe nìyẹn. Àmọ́ o, a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi ra irú àwọn Júù bẹ́ẹ̀ àti gbogbo èèyàn padà.—1 Tím. 2:5, 6; Héb. 2:9; 1 Pét. 1:17-19.
Lóòótọ́, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn Júù nípa tara ló sọ àǹfààní láti di alákòóso pẹ̀lú Jésù nù, àmọ́ ìyẹn kò dí ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe lọ́wọ́. Òdodo ọ̀rọ̀ ni, nítorí pé Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ kan sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísá. 55:11.
Bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, kò sóhun tó máa yẹ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn, ìyẹn yíyan àwọn ọ̀ké méje ó lé ẹgbàájì gẹ́gẹ́ bí alákòóso pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ ní ọ̀run. Bíbélì sọ ọ́ kedere pé Ọlọ́run yóò yan àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàájì pé pérépéré. Wọn ò ní dín, wọn ò sì ní lé!—Ìṣí. 14:1-5.
Nítorí náà, nígbàti Pọ́ọ̀lù sọ pé ‘a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là,’ kì í ṣe ohun tó ń sọ ni pé gbogbo àwọn Júù lápapọ̀ máa di Kristẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ní lọ́kàn ni pé yíyàn tí Ọlọ́run máa yan àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí láti ṣàkóso pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi ní ọ̀run kò ní ṣaláì rí bẹ́ẹ̀. Tó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, mìmì kan ò ní mi “gbogbo Ísírẹ́lì” tó pé pérépéré, wọ́n á sì máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba Mèsáyà náà.— Éfé. 2:8.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè” ní àwọn ẹni àmì òróró ti wá