Jẹ́ Kí Ayọ̀ Wà Nínú Ilé Rẹ
Jẹ́ Kí Ayọ̀ Wà Nínú Ilé Rẹ
“Ọgbọ́n ni a ó fi gbé agbo ilé ró, nípa ìfòyemọ̀ sì ni yóò fi fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.”—ÒWE 24:3.
1. Báwo ni ọgbọ́n Ọlọ́run ṣe hàn nínú ohun tó sọ fún ọkùnrin àkọ́kọ́?
BABA wa ọ̀run ẹni tí ọgbọ́n rẹ̀ kò lópin mọ ohun tó máa ṣe wá láǹfààní. Bí àpẹẹrẹ, Ọlọ́run rí i pé kí ohun tí òun ní lọ́kàn láti ṣe lè ṣẹ, kò ní “dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan” nínú ọgbà Édẹ́nì. Pàtàkì nínú ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn náà sì ni pé káwọn tọkọtaya máa bímọ kí wọ́n sì “kún ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́n. 1:28; 2:18.
2. Ètò wo ni Jèhófà ṣe fún àǹfààní aráyé?
2 Ni Jèhófà bá sọ pé: “Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.” Ọlọ́run mú kí ọkùnrin àkọ́kọ́ náà sun oorun àsùnwọra, ó sì mú ọ̀kan nínú egungun ara ọkùnrin pípé náà, ó fi mọ obìnrin. Nígbà tí Jèhófà mú Éfà, obìnrin pípé náà wá fún Ádámù ọkùnrin náà, Ádámù sọ pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi. Obìnrin ni a óò máa pe èyí, nítorí pé láti ara ọkùnrin ni a ti mú èyí wá.” Àṣekún ni Éfà jẹ́ fún Ádámù. Ìwà àti ànímọ́ àwọn méjèèjì ò ní rí bákan náà, síbẹ̀ ẹni pípé tí Ọlọ́run dá ní àwòrán ara rẹ̀ làwọn méjèèjì. Èyí fi hàn pé Jèhófà ló so tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀. Inú Ádámù àti Éfà dùn sí bí Ọlọ́run ṣe so wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bí tọkọtaya, èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n lè jọ máa ṣe nǹkan pọ̀ kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́.—Jẹ́n. 1:27; 2:21-23.
3. Ọwọ́ wo làwọn kan fi mú ètò ìdílé tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?
3 Ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ ló gbayé kan lóde òní. Ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ yìí ló fa ìṣòro aráyé kì í ṣe àmúwá Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ló máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdílé tó jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n kà á sí ohun tí kò bágbà mu mọ́, pé ó jẹ́ orísun ìbànújẹ́ àti gbọ́nmi-si omi-ò-to. Ìkọ̀sílẹ̀ sì ti wá wọ́pọ̀ gan-an báyìí. Àwọn òbí kan wà tí wọn kì í fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ wọn. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kì í sì í ro tàwọn ọmọ nígbà tí ìjà bá wáyé láàárín wọn, wọ́n á wá máa fi àwọn ọmọ wọn kẹ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ inú ara wọn. Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ni kì í fẹ́ juwọ́ sílẹ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ tìtorí kí wọ́n lè gba àlááfíà àti ìrẹ́pọ̀ ìdílé láyè pàápàá. (2 Tím. 3:3) Ọ̀nà wo wá ni ayọ̀ á lè gbà máa wà nínú ilé lákòókò tó le koko yìí? Báwo ni títẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà ò ṣe ní jẹ́ kí ilé tú ká? Ẹ̀kọ́ wo lá lè rí kọ́ lára àwọn tọkọtaya tí wọ́n ń láyọ̀ nínú ilé wọn lóde òní?
Títẹ̀lé Ìtọ́sọ́nà Jèhófà Nígbà Gbogbo
4. (a) Ìtọ́ni wo ni Pọ́ọ̀lù fún wa lórí yíyan ẹni tá a máa fẹ́? (b) Báwo làwọn Kristẹni onígbọràn ṣe ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí Pọ́ọ̀lù fún wa yìí?
4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn opó ní ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí pé bí wọ́n bá fẹ́ lọ́kọ míì, kó jẹ́ “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Èyí kì í ṣe nǹkan táwọn Kristẹni tó jẹ́ Júù kò gbọ́ rí. Nínú òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Ọlọ́run sọ ọ́ kedere pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká dána. Jèhófà sì sọ ewu tó wà níbẹ̀ tí wọn kò bá ka ìlànà rẹ̀ yìí sí fún wọn. Ó ní: “Nítorí [ẹni tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì] yóò yí ọmọ rẹ padà láti má ṣe tọ̀ mí lẹ́yìn, dájúdájú, wọn yóò sì máa sin àwọn ọlọ́run mìíràn; ní tòótọ́, ìbínú Jèhófà yóò sì ru sí yín, dájúdájú, òun yóò sì pa ọ́ rẹ́ ráúráú ní wéréwéré.” (Diu. 7:3, 4) Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní náà ṣe tó bá dọ̀rọ̀ yíyan ẹni tí wọ́n máa fẹ́? Láìsí àní-àní, ẹni tó wà “nínú Olúwa,” ìyẹn ẹni tó ti yara rẹ̀ sí mímọ́, tó ti ṣèrìbọmi, tó sì ti ń sin Jèhófà ni kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi ṣe ọkọ tàbí aya. Ó dájú pé títẹ̀lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà yìí nígbà tá a bá fẹ́ yan ẹni tá a máa fẹ́ lohun tó bọ́gbọ́n mu.
5. Ojú wo ni Jèhófà àtàwọn Kristẹni tó ti ṣègbéyàwó fi ń wo ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó?
5 Ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó jẹ́ lójú Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù Ọmọ Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó àkọ́kọ́, ó ní: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Onísáàmù jẹ́ ká mọ pé ẹ̀jẹ́ kì í ṣe nǹkan ṣeréṣeré, ó sọ pé: “Rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ sí Ọlọ́run, kí o sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ fún Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Sm. 50:14) Lóòótọ́, ọjọ́ ayọ̀ ni ọjọ́ ìgbéyàwó jẹ́ fáwọn tọkọtaya, àmọ́, ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ lọ́jọ́ ìgbéyàwó kí ì ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ mú ṣẹ ni.—Diu. 23:21.
6. Kí la rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Jẹ́fútà?
6 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Jẹ́fútà, tó jẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì ní ọ̀rúndún Kejìlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà pé: “Bí o bá fi àwọn ọmọ Ámónì lé mi lọ́wọ́ láìkùnà, yóò sì ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú pé ẹni tí ó bá ń jáde bọ̀, tí ó jáde wá láti àwọn ilẹ̀kùn ilé mi láti pàdé mi nígbà tí mo bá padà dé ní àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì, òun pẹ̀lú yóò di ti Jèhófà, èmi yóò sì fi ẹni náà rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” Ǹjẹ́ Jẹ́fútà wá bó ṣe máa yẹ ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ nígbà tó rí i pé ọmọbìnrin òun, ọmọ kan ṣoṣo tóun bí, ló wá pàdé òun nígbà tó padà sílé rẹ̀ ní Mísípà? Rárá o. Ńṣe ló sọ pé: “Èmi . . . ti la ẹnu mi sí Jèhófà, èmi kò sì lè yí padà.” (Oníd. 11:30, 31, 35) Jẹ́fútà mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tó máa yọrí sí ni pé kò ní ní ọmọ-ọmọ kankan tó máa jogún rẹ̀. Lóòótọ́, ẹ̀jẹ́ tí Jẹ́fútà jẹ́ yàtọ̀ sí ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, àmọ́ mímú tó mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ jẹ́ àpẹẹrẹ fáwọn tọkọtaya Kristẹni pé káwọn náà mú ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó wọn ṣẹ.
Kí Ló Ń Mú Kí Ìgbéyàwó Yọrí sí Rere?
7. Àwọn àyípadà wo ló yẹ káwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ṣe?
7 Tí ọ̀pọ̀ tọkọtaya bá ronú padà sí àkókò tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà, ó máa ń fún wọn láyọ̀. Ọjọ́ lọjọ́ táwọn méjèèjì gbà pé àwọn á fẹ́ra àwọn! Bí wọ́n ṣe túbọ̀ jọ ń wà pa pọ̀ ni wọ́n ń mọra wọn sí i. Àmọ́, yálà àkókò kan wà táwọn méjèèjì fi fẹ́ra wọn sọ́nà kí wọ́n tó ṣègbéyàwó o tàbí ńṣe ni wọ́n kàn bá wọn ṣètò ẹni tí wọ́n bá ṣègbéyàwó o, àwọn méjèèjì ní láti ṣe àwọn àyípadà kan lẹ́yìn tí wọ́n di tọkọtaya. Ọkọ kan sọ pé: “Ìṣòro kan tá a ní nígbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni pé a máa ń gbàgbé pé a ti di méjì, pé a kì í ṣe àpọ́n mọ́. Ó kọ́kọ́ ṣòro fún wa láti mọ ibi tó yẹ kí àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ wa àti mọ̀lẹ́bí wa mọ.” Ọkùnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn sọ pé, nígbà tí òun ṣègbéyàwó, òun rí i pé kóun tó lè ṣe nǹkan bó ṣe yẹ, òun ní láti máa “rántí pé òun ti lẹ́nì kejì.” Kó tó gbà pé òun máa lọ síbì kan tàbí pé òun yóò ṣe nǹkan kan, á kọ́kọ́ bá ìyàwó rẹ̀ sọ ọ́, á wo ohun táwọn méjèèjì jọ nífẹ̀ẹ́ sí kó tó wá ṣèpinnu. Irú nǹkan báyìí gba pé kéèyàn jẹ́ ẹni tó máa ń fara mọ́ èrò ẹnì kejì rẹ̀.—Òwe 13:10.
8, 9. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa jọ sọ̀rọ̀ pọ̀ dáadáa? (b) Àwọn apá ibo ni jíjẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan ti lè ṣèrànwọ́, kí sì nìdí rẹ̀?
8 Nígbà míì, èèyàn méjì tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra máa ń fẹ́ra wọn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, báyìí là ń ṣe nílẹ̀ wa, èèwọ̀ ibòmíì ni. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí irú àwọn tọkọtaya bẹ́ẹ̀ máa jọ sọ̀rọ̀ pọ̀ dáadáa. Ọ̀nà táwọn ẹ̀yà kan gbà ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ yàtọ̀ sí tàwọn ẹ̀yà míì. Tó o bá ń wo bí ẹni tó o fẹ́ ṣe ń bá àwọn ìbátan rẹ̀ sọ̀rọ̀, wàá lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n dáadáa. Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà tẹ́nì kan gbà sọ̀rọ̀ ló máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ kì í ṣe ohun tó sọ. Mímọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ló sì máa jẹ́ kéèyàn túbọ̀ mọ irú ẹni tó jẹ́. (Òwe 16:24; Kól. 4:6) Nítorí náà, ó yẹ kí tọkọtaya máa lo ìfòyemọ̀ kí wọ́n bàa lè láyọ̀.—Ka Òwe 24:3.
9 Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ti rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn jẹ́ ẹni tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí wọ́n máa ṣe tọ́wọ́ wọn bá dilẹ̀. Kẹ́ ẹ tó ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí aya rẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí eré ìdárayá tàbí àwọn eré ìnàjú gan-an. Àmọ́ ní báyìí, ǹjẹ́ àyè ìyẹn á tún lè máa yọ bíi ti tẹ́lẹ̀? (1 Tím. 4:8) Ohun kan náà ló kan bí yóò ṣe máa pẹ́ tó lọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ̀. Láìsí àní-àní, ó yẹ káwọn tọkọtaya máa rí i dájú pé àwọn ń ṣe gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run àtàwọn nǹkan míì pa pọ̀.—Mát. 6:33.
10. Ọ̀nà wo ni ṣíṣàì rin kinkin mọ́ nǹkan yóò fi jẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó?
10 Tí ọkùnrin bá ti gbéyàwó, á fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, ohun tí obìnrin náà máa ń ṣe nìyẹn. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24.) Àmọ́ tí ẹnì kan bá tiẹ̀ ṣègbéyàwó pàápàá, ó ṣì gbọ́dọ̀ máa pa àṣẹ Ọlọ́run tó ní kí ọmọ máa bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ̀ mọ́. Nítorí náà lẹ́yìn ìgbéyàwó, ó ṣeé ṣe kí tọkọtaya kan ṣì lọ kí àwọn òbí àtàwọn àna wọn. Ọkọ kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn sọ pé: “Nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti tẹ́ ọkọ tàbí aya ẹni lọ́rùn, kéèyàn sì tún tẹ́ àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, àtàwọn àna ẹni lọ́rùn láìfì síbì kankan. Ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:24 ló ń jẹ́ kí n mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Òótọ́ ni pé èèyàn ní ojúṣe tó yẹ kó máa ṣe fáwọn ìdílé rẹ̀, àmọ́ ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí n mọ̀ pé ti aya mi ló yẹ kí n máa fi ṣáájú.” Bákan náà, àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni tí kì í rin kinkin mọ́ nǹkan máa ń rántí pé ọmọ wọn tó ti ṣègbéyàwó ti ní ìdílé tirẹ̀, àti pé ọkọ ló ni ẹrù iṣẹ́ dídarí ìdílé rẹ̀ kì í ṣe àwọn òbí.
11, 12. Kí nìdí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé àti àdúrà gbígbà fi ṣe pàtàkì fún tọkọtaya?
11 Ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé ṣe pàtàkì gan-an. Ọ̀pọ̀ ìdílé Kristẹni ló ti fi ẹ̀rí èyí hàn pé òótọ́ ni. Ó lè má rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ó sì lè ṣòro láti máa ṣe é déédéé. Baálé ilé kan sọ pé: “Ká ló ṣeé ṣe ká padà sì ìgbá tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni, àtúnṣe kan tá ò bá ṣe ni pé ẹsẹ́kẹsẹ̀ la ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láìní máa pa á jẹ rárá.” Ó tún sọ pé: “Ó máa ń wú mi lórí gan-an láti rí bínú ìyàwó mi ṣe máa ń dùn nígbà tá a bá rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa.”
12 Gbígbàdúrà pa pọ̀ jẹ́ nǹkan míì tó ń mú kí ìgbéyàwó yọrí sí rere. (Róòmù 12:12) Tí tọkọtaya bá jùmọ̀ ń sin Jèhófà pa pọ̀, àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run á mú kí ìdè ìgbéyàwó wọn jẹ́ alọ́májàá. (Ják. 4:8) Ọkọ kan tó jẹ́ Kristẹni ṣàlàyé pé: “Téèyàn bá tètè ń tọrọ àforíjì nígbà tó bá ṣàṣìṣe, tó sì ń mẹ́nu bà á nígbà tí wọ́n bá jọ ń gbàdúrà, ńṣe lèèyàn ń fi hàn pé ó dunni gan-an pé ọ̀rọ̀ náà fa ìbínú, bó ti wù kọ́rọ̀ ọ̀hún kéré mọ.”—Éfé. 6:18.
Ẹ Má Máa Rin Kinkin Mọ́ Ohun Tẹ́nì Kọ̀ọ̀kan Yín Ń Fẹ́
13. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn tọkọtaya lórí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀?
13 Àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ yàgò fún onírúurú ìwà ìbàjẹ́ tó ń jin àjọṣepọ̀ tọkọtaya lẹ́sẹ̀, èyí tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn òde òní tí ìbálòpọ̀ ń sín níwín. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ lórí kókó yìí ni pé: “Kí ọkọ máa fi ohun ẹ̀tọ́ aya rẹ̀ fún un; ṣùgbọ́n kí aya pẹ̀lú máa ṣe bákan náà fún ọkọ rẹ̀. Aya kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n ọkọ rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀; bákan náà, pẹ̀lú, ọkọ kì í lo ọlá àṣẹ lórí ara rẹ̀, ṣùgbọ́n aya rẹ̀ a máa ṣe bẹ́ẹ̀.” Pọ́ọ̀lù wá pèsè ìtọ́ni tó ṣe kedere lórí ọ̀ràn yìí, ó ní: “Ẹ má ṣe máa fi du ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, àyàfi nípasẹ̀ àjọgbà fún àkókò tí a yàn kalẹ̀.” Kí nìdí? Ó ní: “Kí ẹ lè ya àkókò sọ́tọ̀ fún àdúrà, kí ẹ sì tún lè jùmọ̀ wà pa pọ̀, kí Sátánì má bàa máa dẹ yín wò nítorí àìlèmáradúró yín.” (1 Kọ́r. 7:3-5) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ àdúrà yìí, ńṣe ló ń jẹ́ ká mọ ohun tó yẹ kó gbapò àkọ́kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni. Bákan náà ló sì tún jẹ́ kí tọkọtaya rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa tẹ́ ẹnì kejì wọn lọ́rùn tó bá dọ̀rọ̀ ìbálópọ̀.
14. Báwo la ṣe lè lo ìlànà Ìwé Mímọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya?
14 Tó bá dọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀, kò yẹ kí tọkọtaya máa fi nǹkan pa mọ́ fún ara wọn, ó sì yẹ kí wọ́n mọ̀ pé àìgba ti ẹnì kejì wọn rò lè dá ìṣòro sílẹ̀. (Ka Fílípì 2:3, 4; fi wé Mátíù 7:12.) Irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ sì ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn tọkọtaya kan tó jẹ́ pé ọ̀kan nínú wọn kò sí nínú òtítọ́. Bí èdèkòyédè bá tiẹ̀ wáyé, tí ẹni tó wà nínú òtítọ́ bá ń hùwà rere, tó jẹ́ onínúrere àtẹni tó ń fọ̀wọ́ sowọ́ pọ̀, ìṣòro náà yóò dín kù. (Ka 1 Pétérù 3:1, 2.) Tí ọkọ tàbí aya bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó nífẹ̀ẹ́ alábàáṣègbéyàwò rẹ̀, tó sì jẹ́ ẹni tó máa ń gba ti ẹnì kejì rò, ìyẹn máa ń ṣèrànwọ́ nínú irú ọ̀rọ̀ báyìí.
15. Ipa wo ni ọ̀wọ̀ ń kó láàárín tọkọtaya?
15 Láwọn apá yòókù nínú ìgbéyàwó pẹ̀lú, ọkọ ní láti máa fi ọ̀wọ̀ aya rẹ̀ wọ̀ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kí ọkọ máa gba bí nǹkan ṣe máa rí lára aya rẹ̀ rò, àní nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké pàápàá. Ọkùnrin kan tó ti ṣègbéyàwó láti ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] sọ pé: “Mo ṣì máa ń ṣàṣìṣe lórí kókó yìí.” Bíbélì gba àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ wọn. (Éfé. 5:33) Aya tó bá ń sọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ láìdáa tàbí tó ń sọ àwọn àṣìṣe ọkọ rẹ̀ lójú àwọn èèyàn, kò bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ rárá. Ohun tí Òwe 14:1 sọ ni pé: “Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.”
Ẹ Má Gba Èṣù Láyè
16. Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fi ohun tó wà nínú Éfésù 4:26, 27 sílò nínú ìdílé wọn?
16 Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfé. 4:26, 27) Tí tọkọtaya bá fi ìmọ̀ràn yìí sílò wọ́n á lè yẹra fún èdèkòyédè tàbí kí wọ́n yanjú èdèkòyédè tí wọ́n bá ní. Arábìnrin kan sọ pé: “Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín èmi àti ọkọ mi mo máa ń rí i pé a yanjú ẹ̀ ṣáá ni, ì báà tiẹ̀ gba ọ̀pọ̀ wákàtí ká tó yanjú ẹ̀.” Òun àti ọkọ rẹ̀ ti pinnu látìgbà tí wọ́n tí ṣègbéyàwó pé àwọn ò ní fi èdèkòyédè kankan sínú lọ sùn láìjẹ́ pé wọ́n yanjú rẹ̀. “A pinnu pé bó ti wù kí ìṣòro yẹn le tó, àá dárí ji ara wa, àá sì gbàgbé rẹ̀ síbẹ̀, a ó ní fi ìbínú ọjọ́ kan sínú di ọjọ́ kejì.” Nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù” rárá.
17. Kódà tó bá dà bíi pé kì í ṣe ẹni tó yẹ kẹ́nì kan fẹ́ ló fẹ́, kí ló lè ràn án lọ́wọ́?
17 Ṣùgbọ́n tó o bá wá ń wò ó pé kì í ṣe ẹni tó o fẹ́ yìí ló yẹ kó o fẹ́ ńkọ́? Ó lè wá máa ṣe ẹ́ bíi pé ìgbéyàwó rẹ kò dùn bíi tàwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, tó o bá ń rántí ojú tí Ẹlẹ́dàá fi ń wo ìgbéyàwò, ìyẹn yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Héb. 13:4) Ohun míì tó tún yẹ ká máa rántí ni pé: “Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.” (Oníw. 4:12) Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń jẹ tọkọtaya lógún ni pé àwọn kò fẹ́ ṣe ohun tó máa tàbùkù sórúkọ Jèhófà, àjọṣe àárín àwọn méjèèjì àti àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run máa túbọ̀ lágbára sí i. Ó yẹ kí wọ́n sapá gidigidi láti rí i pé ayọ̀ wà nínú ilé wọn, nítorí wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ló máa gbé Jèhófà, ẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ga.—1 Pét. 3:11.
18. Kí ló dájú nípa ètò ìdílé?
18 Ó dájú pé àwọn Kristẹni lè jẹ́ kí ayọ̀ wà nínú ìdílé wọn. Àmọ́, ó gba ìsapá kí ìyẹn tó lè ṣeé ṣe, kí wọ́n sì máa lo àwọn ànímọ́ Kristẹni, irú bíi jíjẹ́ ẹni tó ń gba tẹni rò. Lóde òní, àìmọye tọkọtaya nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ló ti fi hàn pé ayọ̀ ìdílé kì í ṣe ohun tọ́wọ́ ò lè tẹ̀.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí nìdí tó fi dájú pé ayọ̀ lè wà nínú ìdílé?
• Kí ló lè jẹ́ kí ìgbéyàwó yọrí sí rere?
• Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kí àwọn tọkọtaya ní?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ó bọ́gbọ́n mu pé kí tọkọtaya kọ́kọ́ jíròrò pa pọ̀ kí wọ́n tó gbà pé àwọn á lọ síbì kan tàbí kí wọ́n tó ṣàdéhùn pẹ̀lú ẹnì kan
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ máa rí i pé ẹ̀ kò fi èdèkòyédè sínú di ọjọ́ kejì, “kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù”