Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Míṣọ́nnárì Tó Ta Yọ
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Míṣọ́nnárì Tó Ta Yọ
“Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.”—1 KỌ́R. 11:1.
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Míṣọ́nnárì tó ta yọ. Ó wá rọ àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.” (1 Kọ́r. 11:1) Lẹ́yìn tí Jésù wẹ ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kó lè fi àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lélẹ̀ fún wọn, ó sọ fún wọn pé: “Mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.” (Jòh. 13:12-15) Ojúṣe àwa Kristẹni òde òní ni pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi nínú ọ̀rọ̀, ìṣe àti ìwà tá à ń hù.—1 Pét. 2:21.
2. Bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò bá tiẹ̀ yàn ọ́ pé kó o lọ máa ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere nílẹ̀ òkèèrè, irú ẹ̀mí wo lo lè ní?
2 A ti kà á nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí pé, míṣọ́nnárì ni ẹnì kan tá a rán kó lọ máa jíhìn rere fáwọn èèyàn. Pọ́ọ̀lù béèrè àwọn ìbéèrè pàtàkì kan lórí kókó yìí. (Ka Róòmù 10:11-15.) Ara ìbéèrè Pọ́ọ̀lù ni pé: “Báwo . . . ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” Ó wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó ní: “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere mà dára rèǹtè-rente o!” (Aísá. 52:7) Kódà bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ò bá yàn ọ́ pé kó o lọ máa ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere nílẹ̀ òkèèrè, o lè dẹni tó lẹ́mìí ajíhìnrere, kó o máa fi ìtara wàásù ìhìn rere gẹ́gẹ́ bíi ti Jésù. Léṣìí, mílíọ̀nù mẹ́fà, ọ̀kẹ́ méjìdínláàádọ́ta ó dín ẹgbọ̀kànlá àti méjìléláàádọ́ta [6,957,852] akéde Ìjọba Ọlọ́run ló “ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere” ní ilẹ̀ igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236].—2 Tím. 4:5.
“Àwa Ti Fi Ohun Gbogbo Sílẹ̀, A sì Tọ̀ Ọ́ Lẹ́yìn”
3, 4. Kí ni Jésù fi sílẹ̀ lọ́run, kí la sì ní láti ṣe ká bàa lè di ọmọlẹ́yìn rẹ̀?
3 Jésù “sọ ara rẹ̀ di òfìfo, ó sì gbé ìrísí ẹrú wọ̀,” ìyẹn ni pé ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì tún fi ọ̀run tó ń gbé sílẹ̀ kó bàa lè wá ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an lórí ilẹ̀ ayé. (Fílí. 2:7) Nítorí náà, kò sóhun tó lè ná wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi tó máa já mọ́ nǹkan kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó ná Jésù láti lè wá sáyé. Síbẹ̀, a lè máa bá a lọ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láìyẹsẹ̀, ká má sì jẹ́ kí ọkàn wa máa fà sáwọn nǹkan tá a ti fi sílẹ̀ nínú ayé Sátánì.—1 Jòh. 5:19.
4 Nígbà kan, àpọ́sítélì Pétérù sọ fún Jésù pé: “Wò ó! Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (Mát. 19:27) Lóòótọ́, nígbà tí Jésù ní kí Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù máa tọ òun lẹ́yìn, ńṣe ni wọ́n pa àwọ̀n wọn tì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, tí wọ́n sì tẹ̀ lé e. Wọ́n pa iṣẹ́ ẹja pípa wọn tì, wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ ajíhìnrere. Bí Ìhìn Rere Lúùkù ṣe sọ ọ̀rọ̀ Pétérù òkè yìí ni pé: “Wò ó! Àwa ti fi àwọn ohun tiwa sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (Lúùkù 18:28) Èyí tó pọ̀ jù nínú wa ni kò ní láti fi gbogbo “ohun tiwa sílẹ̀” ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í tọ Jésù lẹ́yìn. Àmọ́ ó dájú pé a ‘sẹ́ níní ara’ wa ká tó di ọmọlẹ́yìn Kristi àtẹni tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà. (Mát. 16:24) Ohun tá a ṣe yẹn sì ti ṣe wá láǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀. (Ka Mátíù 19:29.) Jíjẹ́ ẹni tó ń fìtara jíhìn rere bíi ti Kristi ń fún wa láyọ̀, pàápàá tá a bá tún lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ fẹ́nì kan tó dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n.
5. Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí ohun táwọn tó ṣí lọ sí ilẹ̀ òkèèrè pinnu láti ṣe bí wọ́n bá ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
5 Ọmọ ilẹ̀ Brazil kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Valmir ń ṣe iṣẹ́ góòlù wíwà láàárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Suriname. Ọkùnrin yìí jẹ́ ọ̀mùtí àti oníṣekúṣe. Nígbà kan tó lọ sí ìlú ńlá kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Ó ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́, ó sì wá dẹni tó yí ìgbé ayé rẹ̀ padà pátápátá, tó sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó rí i pé iṣẹ́ òun mú kó ṣòro fóun láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ó ta ilé iṣẹ́ rẹ̀ tó ti ń pawó rẹpẹtẹ, ó sì padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ láti lọ ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí òtítọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn tó ti ṣí láti orílẹ̀-èdè wọn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè ló máa ń fi iṣẹ́ wọn lórílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù náà sílẹ̀, tí wọ́n á padà sórílẹ̀-èdè wọn láti lọ ran àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè sún mọ́ Jèhófà. Ojúlówó ẹ̀mí ajíhìnrere làwọn àkéde Ìjọba Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ní.
6. Kí la lè ṣe tí ò bá ṣeé ṣe fún wa láti ṣí lọ sáwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i?
6 Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti ṣí lọ sáwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run púpọ̀ sí i. Àní àwọn míì tiẹ̀ ṣí lọ sórílẹ̀-èdè míì. Ó lè má ṣeé ṣe fáwa láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ a ṣì lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa sísa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
Jèhófà Ń Dá Wa Lẹ́kọ̀ọ́
7. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ wo la ti ń kọ́ àwọn tó fẹ́ di akéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lọ́nà tó túbọ̀ dáa sí i?
7 A lè gba ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń fáwọn èèyàn rẹ̀ lónìí gẹ́lẹ́ bí Jésù ṣe kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀. Jésù alára sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ nínú àwọn Wòlíì pé, ‘Gbogbo wọn yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.’” (Jòh. 6:45; Aísá. 54:13) Lóde òní, onírúurú ilé ẹ̀kọ́ ti wà tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè di àkéde Ìjọba Ọlọ́run tó já fáfá. Láìsí àní-àní, gbogbo wa la ti jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run nínú ìjọ wa. Ètò Ọlọ́run fi Ilé Ẹ̀kọ́ Aṣáájú-Ọ̀nà dá àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́lá. Kódà, ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà tó ti ń sìn bọ̀ látọjọ́ pípẹ́ ló tún ti lọ gbádùn ilé ẹ̀kọ́ yẹn lẹ́ẹ̀kejì. Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà àti Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà kọ́ni àti bí wọ́n ṣe ń ṣojúṣe wọn fáwọn ará bàa lè dáa sí i. Ọ̀pọ̀ alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó jẹ́ àpọ́n ló ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, níbi tí wọ́n ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè máa ṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíì lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà. Púpọ̀ nínú àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ló ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n sì ti di míṣọ́nnárì tí ètò Ọlọ́run rán láti lọ máa ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere nílẹ̀ òkèèrè.
8. Kí làwọn arákùnrin kan yááfì kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Jèhófà ń pèsè?
8 Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe àwọn ìyípadà kan kí wọ́n tó lè lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní Kánádà, ńṣe ni Arákùnrin Yugu kọ̀wé fiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ sílẹ̀ láti lè lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ nígbà táwọn tó gbà á síṣẹ́ láwọn ò lè fún un láyè kó lọ. Yugu ní: “Mi ò kábàámọ̀ ohun tí mo ṣe yìí. Ká sòótọ́, ká ní wọ́n fún mi láyè kí n lọ ni, ńṣe ni wọ́n á torí ìyẹn máa retí pé kí n máa bá àwọn ṣiṣẹ́ lọ títí gbére. Àmọ́ ní báyìí, kò sí iṣẹ́ tí Jèhófà máa yàn fún mi tí mi ò ní ráyè ṣe.” Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ló ti fínnú-fíndọ̀ yááfì àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ràn gan-an láti lè lọ gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí Ọlọ́run ń pèsè.—Lúùkù 5:28.
9. Sọ àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká rí bí ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ àti ìsapá ṣe máa ń múni ṣàṣeyọrí.
9 Téèyàn bá kọ́ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́, tó sì sapá gan-an, èèyàn máa ń ṣàṣeyọrí tó ga. (2 Tím. 3:16, 17) Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tó ń jẹ́ Saulo lórílẹ̀-èdè Guatemala. Dìndìnrìn lọmọ náà láti kékeré, ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ sì sọ pé kí ìyá rẹ̀ má fipá kọ́ ọ ní ìwé kíkà kí wọ́n máa bàa kó ìdààmú bá a. Saulo kò mọ̀wé kà títí tó fi kúrò níléèwé. Àmọ́, Ẹlẹ́rìí kan kọ́ Saulo ní ìwé kíkà. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, Saulo dẹni tó ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tó yá, ìyá Saulo bá olùkọ́ rẹ̀ yẹn pàdé lóde ẹ̀rí. Nígbà tí olùkọ́ rẹ̀ yìí gbọ́ pé Saulo ti lè kàwé, ó ní kí ìyá rẹ̀ mú un wá sọ́dọ̀ òun lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Nígbà tí wọ́n débẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ náà, olùkọ́ náà bi Saulo pé, “Kí ni wàá kọ́ mi?” Ni Saulo bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìpínrọ̀ kan fún un nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Olùkọ́ rẹ̀ wá ní: “Áà, ìyanu! Ìwọ lo dẹni tó lè kọ́ mi báyìí.” Bí omijé ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bọ́ lójú rẹ̀ nìyẹn tó sì gbá Saulo mọ́ra.
Ẹ̀kọ́ Tó Ń Yíni Lọ́kàn Padà
10. Ìwé àtàtà wo ló ti wà tá a lè máa fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
10 Jésù kò kọ́ni ní ohun mìíràn yàtọ̀ sí ohun tí Jèhófà kọ́ ọ àti ìtọ́ni tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Lúùkù 4:16-21; Jòh. 8:28) Àpẹẹrẹ Jésù là ń tẹ̀ lé bá a ṣé ń ṣe ohun tó sọ, tá ò sì kọ́ni lóhun míì yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́. Ìyẹn ló ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àti èrò gbogbo wa bára mu, tá a sì wà níṣọ̀kan. (1 Kọ́r. 1:10) Inú wa dùn gan-an ni pé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè àwọn ìwé tí wọ́n gbé ka Bíbélì, èyí tó ń mú kí ọ̀nà ìgbàkọ́ni wa bára mu tó sì tún ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ ìjíhìnrere wa! (Mát. 24:45; 28:19, 20) Ọ̀kan lára àwọn ìwé yẹn ni ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tó ti wà ní èdè mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án [179] báyìí.
11. Báwo ni arábìnrin kan nílẹ̀ Etiópíà ṣe lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti fi borí àtakò?
11 Téèyàn bá ń lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó tiẹ̀ lè yí ẹni tó ń ta kò wá lọ́kàn padà. Nígbà kan, arábìnrin Lula tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kan nílẹ̀ Etiópíà ń bá ẹnì kan ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìbátan akẹ́kọ̀ọ́ náà já wọlé, tó sì sọ pé kó má bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Lula wá fohùn pẹ̀lẹ́ lo àkàwé ayédèrú owó tó wà ní orí Kẹẹ̀ẹ́dógún nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti fi ṣàlàyé fún un. Bí ọkàn obìnrin náà ṣe rọ̀ nìyẹn tó sì gbà kí wọ́n máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn lọ. Àní ó wá jókòó tì wọ́n nígbà tí wọ́n tún fẹ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn náà, ó sì ní kí wọ́n máa bá òun náà ṣèkẹ́kọ̀ọ́, pé òun ò tiẹ̀ kọ̀ láti sanwó tó bá la owó lọ! Kò sì pẹ́ tó fi ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹta lọ́sẹ̀, tó sì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú òtítọ́.
12. Sọ àpẹẹrẹ kan láti fi hàn pé àwọn ọmọdé lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó múná dóko?
12 Àwọn ọmọdé náà lè lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Nígbà tí ọmọ ọdún mọ́kànlá kan lórílẹ̀-èdè Hawaii tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Keanu ń ka ìwé yìí níléèwé, ọmọ kíláàsì rẹ̀ kan bi í pé, “Kí ló dé tó ò kì í ṣọdún?” Ni Keanu bá ka àkòrí náà, “Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣe Ọdún àti Àwọn Ayẹyẹ Kan?” nínú àfikún ẹ̀yìn ìwé náà fún un. Ó sì wá ṣí ìwé náà padà síbi tí wọ́n to àwọn àkòrí inú ìwé náà sí, ó ní kí ọmọ náà sọ àkòrí tó wù ú gan-an. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Léṣìí, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún ọ̀kẹ́ ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n àti egbèje ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [6,561,426]. Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la sì fi ń ṣe ọ̀pọ̀ nínú wọn. Ǹjẹ́ ò ń lo ìwé yìí láti fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
13. Ọ̀nà wo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè gbà mú káwọn èèyàn ṣèpinnu tó dáa?
13 Téèyàn bá ń fi ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lè mú káwọn tó bá fẹ́ ṣèfẹ́ Ọlọ́run ṣe ìpinnu tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lórílẹ̀-èdè Norway bẹ̀rẹ̀ sí í bá ìdílé kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Zambia ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tọkọtaya tó wá láti Zambia yìí ti bí ọmọbìnrin mẹ́ta, wọn ò sì fẹ́ bímọ mọ́. Nígbà tí èyí ìyàwó wá lóyún, wọ́n pinnu láti ṣẹ́ ẹ. Ó ku ọjọ́ mélòó kan tí wọ́n máa lọ bá dókítà láti ṣẹ́ oyún yẹn ni wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ àkòrí tó sọ pé, “Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ẹ̀mí Ni Kí Ìwọ Náà Máa Fi Wò Ó.” Bí wọ́n ṣe rí àwòrán ọlẹ̀ tí wọ́n yà síbi àkòrí yẹn, ó gún ọkàn wọn ní kẹ́ṣẹ́, ni wọn ò bá ṣẹ́ oyún yẹn mọ́. Wọ́n tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run, wọ́n sì wá fi orúkọ èyí tó jẹ́ ọkọ nínú àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yẹn sọ orúkọ ọmọkùnrin tí wọ́n foyún ọ̀hún bí.
14. Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé fífi ohun tá à ń kọ́ni ṣèwà hù máa ń nípa tó dára lórí àwọn ẹlòmìí.
14 Ọ̀kan pàtàkì nínú ọ̀nà tí Jésù gbà ń kọ́ni ni bó ṣe ń fi ohun tó ń kọ́ni ṣèwà hù. Inú ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń dùn sí ìwà rere àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí bá a ṣe ń fi ohun tá à ń kọ́ni ṣèwà hù bíi ti Jésù. Ó ṣẹlẹ̀ pé àwọn olè wọnú mọ́tò ọkùnrin oníṣòwò kan lórílẹ̀-èdè New Zealand, wọ́n sì jí àpò rẹ̀ gbé lọ. Ló bá lọ sọ fáwọn ọlọ́pàá. Àwọn ọlọ́pàá sì sọ fún un pé: “Àfi tó bá jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣèèṣì bá ọ rí àpò náà lo tún fi lè rí i padà.” Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń ta ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ ló rí àpò náà. Nígbà tí oníṣòwò náà gbọ́ pé arábìnrin yìí bá òun rí i ó wá a lọ sílé. Inú rẹ̀ dùn nígbà tó ṣì rí ìwé rẹ̀ kan tó ṣe pàtàkì gan-an níbẹ̀. Arábìnrin náà sọ fún un pé: “Gbogbo nǹkan tí mo bá yín rí náà ni mo ní láti fún yín, pàápàá tí mo tún jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Èyí ya oníṣòwò náà lẹ́nu gan-an, torí ó rántí ohun tí ọlọ́pàá yẹn sọ fún un láàárọ̀ ọjọ́ yẹn. Dájúdájú, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe bíi ti Jésù, wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣèwà hù.—Héb. 13:18.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Bí Jésù Ṣe Ń Hùwà Sáwọn Èèyàn
15, 16. Báwo la ṣe lè mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere tá à ń wàásù?
15 Ìwà tí Jésù ń hù sáwọn èèyàn ń mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ mú káwọn tálákà fà mọ́ ọn. Ó máa ń yọ́nú sáwọn tó bá tọ̀ ọ́ wá, ó máa ń sọ̀rọ̀ tó ń tù wọ́n nínú, ó sì tún wo ọ̀pọ̀ nínú wọn sàn. (Ka Máàkù 2:1-5.) A ò lè ṣe iṣẹ́ ìyanu ní tiwa, àmọ́ a lè lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìfẹ́ àti ìyọ́nú, tó jẹ́ àwọn ànímọ́ tó máa ń mú káwọn èèyàn fẹ́ wá sínú òtítọ́.
16 Ẹ̀mí ìyọ́nú ṣèrànlọ́wọ́ gan-an nígbà tí aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Tariua dé ilé bàbá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Beere. Erékùṣù kan tó dá wà ní kọ̀rọ̀ kan lórílẹ̀-èdè Kiribati tó wà ní Gúúsù Òkun Pàsífíìkì ló ń gbé. Bàbá yìí ti fi hàn pé òun ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù Tariua, àmọ́ Tariua ṣàkíyèsí pé àrùn rọpárọsẹ̀ ti gba apá kan ara rẹ̀, àánú bàbá yẹn sì ṣe é. Ni Tariua bá bi í pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí fáwọn àgbàlagbà tó jẹ́ aláìsàn?” Ó sì wá ka díẹ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Aísáyà fún un. (Ka Aísáyà 35:5, 6.) Nígbà tí bàbá yìí gbọ́ ibi tó kà, ó yà á lẹ́nu gan-an. Ó wá sọ pé: “Ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ń ka Bíbélì, táwọn olórí ẹ̀sìn mi sì ti ń wá mi wá, àmọ́ mi ò tíì bá ohun tó o kà yìí pàdé rí nínú Bíbélì.” Bí Beere ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn, tó sì ń tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́. Lóòótọ́, ó yarọ àmọ́ ó ti ṣèrìbọmi, ó ń múpò iwájú nínú bíbójútó àwùjọ àwọn ará kan tó wà ní àdádó, ó sì ń wàásù ìhìn rere káàkiri erékùṣù yẹn.
Máa Bá A Nìṣó Ní Títẹ̀lé Àpẹẹrẹ Kristi
17, 18. (a) Báwo lo ṣe lè ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ajíhìnrere? (b) Kí ló máa jẹ́ tàwọn tó bá fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?
17 Àwọn ìrírí tó dùn mọ́ni tá à ń ní léraléra lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fi hàn pé a máa ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere tá a bá ní àwọn ànímọ́ tí Jésù ní tá a sì ń lò ó. Ẹ ò rí i pé ó bá a mu gan-an pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi, ká máa fi ìtara jíhìn rere!
18 Nígbà táwọn kan di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní, Pétérù béèrè pé: “Kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” Jésù wá fèsì pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Mát. 19:27-29) Bó ṣe máa rí fún wa gan-an nìyẹn tá a bá ń bá a nìṣó ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi tó jẹ́ Míṣọ́nnárì tó ta yọ.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń kọ́ wa ká lè di ajíhìnrere?
• Kí nìdí tí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni fi wúlò gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
• Báwo la ṣe lè fìwà jọ Jésù nínú bá a ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Nígbà tí Jésù ní kí Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù máa tẹ̀ lé òun, ńṣe ni wọ́n tẹ̀ lé e láìjáfara
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ìwé bíi “Bíbélì Fi Kọ́ni” ń jẹ́ kí ọ̀nà ìgbàkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa bára mu