Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ìfẹ́ Yín Lápapọ̀ Ń Pọ̀ Sí I’

‘Ìfẹ́ Yín Lápapọ̀ Ń Pọ̀ Sí I’

‘Ìfẹ́ Yín Lápapọ̀ Ń Pọ̀ Sí I’

À JÁLÙ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Japan lọ́dún 2004 kì í ṣe kékeré. Lára wọn ni ìjì líle, omíyalé àti ìmìtìtì ilẹ̀. Àjálù yìí ṣèpalára gan-an fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, títí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Oníwàásù 9:11) Àmọ́, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ yìí fún àwọn Ẹlẹ́rìí láǹfààní láti túbọ̀ fi ìfẹ́ hàn sí ara wọn.—1 Pétérù 1:22.

Bí àpẹẹrẹ, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó rọ̀ ní Japan lóṣù July mú kí odò kan lórílẹ̀-èdè náà kún àkúnya. Ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí àgbàrá bà jẹ́ lé ní ogún. Omi tó ya wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ga tó mítà kan. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí látinú àwọn ìjọ àgbègbè náà wá láti ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn kó gbogbo ẹrẹ̀ tó wọnú àwọn ilé wọ̀nyí pátá. Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì péré, wọ́n ti palẹ̀ gbogbo ìdọ̀tí tó wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba yẹn mọ́, wọ́n sì ti tún gbogbo ibi tó bà jẹ́ lára rẹ̀ ṣe.

Ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù October ọdún yẹn, ilẹ̀ mì tìtì lágbègbè yẹn kan náà. Ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé yìí lékenkà. Ó kéré tán, ogójì èèyàn ló kú sí i, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún èèyàn [100,000] làwọn aláàánú sì tètè lọ kó kúrò nílé wọn kéwu tó wu wọ́n. Omi ẹ̀rọ ò yọ mọ́, àwọn èèyàn ò rí gáàsì lò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí iná mànàmáná mọ́. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, ibi tí àjálù náà ti rinlẹ̀ jù lọ ò ju àádọ́ta kìlómítà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n tún ṣe yẹn, àmọ́ kò sí nǹkan kan tó ṣe gbọ̀ngàn náà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ibẹ̀ di ibi táwọn ará ti lọ ń gba ìrànlọ́wọ́. Kíá làwọn alàgbà ìjọ ti lọ ń wo àlàáfíà àwọn ará, ayọ̀ wọn sì pọ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ará tó fara pa tàbí tó ṣòfò ẹ̀mí. Ní kùtùkùtù àárọ̀ ọjọ́ kejì, mẹ́fà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí omíyalé gbé ilé wọn ní oṣù July yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti máa pín oúnjẹ àti omi fún àwọn tí àjálù náà kàn. Láàárín wákàtí díẹ̀ tí ìmìtìtì ilẹ̀ yìí wáyé, àwọn ará ti kó ọ̀pọ̀ nǹkan wá fún àwọn tí àjálù náà kàn.

Alàgbà ìjọ kan sọ pé: “Àwọn tí omíyalé gbé ilé wọn ka iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe láti pèsè nǹkan fáwọn tí àjálù náà kàn sí ọ̀nà kan láti gbà fi ìmọrírì wọn hàn fún ìrànlọ́wọ́ táwọn alára rí gbà. Wọ́n ṣiṣẹ́ kára látàárọ̀ kùtù títí di ọ̀gànjọ́ òru. Ayọ̀ wọn pọ̀ gan-an ni!”

Omíyalé tàbí ìmìtìtì ilẹ̀ kò lè já ìdè ìfẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní sí ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí irú àjálù yìí bá wáyé, àwọn Kristẹni máa ń rí i pé òótọ́ ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní Tẹsalóníkà pé: “Ìfẹ́ yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i lẹ́nì kìíní sí ẹnì kejì.”—2 Tẹsalóníkà 1:3.