Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìwà Rere Méso Jáde

Ìwà Rere Méso Jáde

Ìwà Rere Méso Jáde

NÍ ERÉKÙṢÙ kékeré kan tí kò jìnnà sí etíkun tó wà lápá gúúsù ilẹ̀ Japan, ìyá kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké mẹ́ta bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Báwọn ará àdúgbò wọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àṣà ìbílẹ̀ wọn lágbègbè àdádó yìí ṣe rí ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fojú pa obìnrin náà rẹ́ tí wọ́n bá ti rí i. Obìnrin náà sọ pé: “Ohun tó tiẹ̀ wá dùn mí ju bí wọ́n ṣe ń fojú pa mí rẹ́ ni bí wọn ò ṣe ń dá ọkọ mi àtàwọn ọmọ mi lóhùn tí wọ́n bá ti kí wọn.” Síbẹ̀síbẹ̀, ó sọ fáwọn ọmọ rẹ̀ pé: “A gbọ́dọ̀ máa kí àwọn aládùúgbò wa nítorí pé ohun tí Jèhófà fẹ́ nìyẹn.”—Mátíù 5:47, 48.

Ó kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nílé pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn báwọn èèyàn náà ò tiẹ̀ kà wọ́n sí. Tí wọ́n bá ń lọ síbi ìsun omi gbígbóná kan tí wọ́n máa ń lọ déédéé ládùúgbò wọn, àwọn ọmọ yìí á máa fi bí wọn yóò ṣe kí àwọn èèyàn dánra wò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn. Báwọn ọmọ náà bá sì ṣe ń wọnú ilé náà ni wọ́n á máa sọ tọ̀yàyàtọ̀yàyà pé, “Konnichiwa!,” tó túmọ̀ sí “Ẹ ǹ lẹ́ o!” Ìdílé yìí sáà ń fi sùúrù kí gbogbo àwọn tí wọ́n bá rí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà àwọn aládùúgbò náà kò yí padà. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ò ṣàì kíyè sí ìwà dáadáa táwọn ọmọ náà ń hù.

Nígbà tó yá làwọn aládùúgbò náà níkọ̀ọ̀kan bá bẹ̀rẹ̀ sí dá àwọn ọmọ náà lóhùn tí wọ́n bá ti kí wọn, àwọn náà á ní “Konnichiwa.” Lẹ́yìn ọdún méjì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tó wà nínú ìlú kékeré náà ló ti ń dáhùn tí ìdílé náà bá ti kí wọn. Àwọn aládùúgbò náà tiẹ̀ tún wá ń kí ara wọn, wọ́n sì túbọ̀ ń ṣe dáadáa síra wọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Èyí ló mú kí igbákejì olórí ìlú náà fẹ́ dá àwọn ọmọ náà lọ́lá fún ipa tí wọ́n kó nínú ìyípadà yìí. Àmọ́ màmá wọn ṣàlàyé fún un pé ohun tó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe làwọ́n ń ṣe. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìdíje kan lórí ọ̀rọ̀ sísọ tó kan gbogbo erékùṣù náà wáyé, ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà sì sọ bí màmá òun ṣe kọ́ gbogbo wọn nínú ìdílé wọn láti máa fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kí àwọn èèyàn yálà àwọn èèyàn dáhùn tàbí wọn ò dáhùn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló gbapò kìíní, wọ́n sì tẹ ọ̀rọ̀ náà jáde nínú ìwé ìròyìn ìlú kékeré náà. Lónìí, ńṣe ni inú ìdílé náà ń dùn gan-an pé títẹ̀lé ìlànà Kristẹni mú irú èso rere bẹ́ẹ̀ jáde. Ó máa ń rọrùn gan-an láti sọ ìhìn rere nígbà táwọn èèyàn bá túra ká síni.