Àwọn Ọrẹ Tó Ń Mú Inú Ọlọ́run Dùn
Àwọn Ọrẹ Tó Ń Mú Inú Ọlọ́run Dùn
ÌTÀN tá a fẹ́ sọ yìí ò dùn gbọ́ rárá. Ó dá lórí ohun tí Ọbabìnrin Ataláyà ṣe. Kó ṣáà lè rí i pé òun bọ́ sórí àlééfà ìjọba Júdà, ó lo ẹ̀tàn ó sì tún gbẹ̀mí àwọn èèyàn. Èrò rẹ̀ ni pé gbogbo àwọn tí ipò ọba tọ́ sí lòún ti pa láìmọ̀ pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, ló bá sọ ara rẹ̀ di ọbabìnrin. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jèhóṣébà tó jẹ́ ọmọ ọba tó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Òfin rẹ̀ gan-an fi ìgboyà gbé ọmọ ọwọ́ kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọba pa mọ́. Orúkọ ọmọ náà ni Jèhóáṣì. Odindi ọdún mẹ́fà ni Jèhóṣébà àti Jèhóádà ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà fi gbé ọmọ tí ipò ọba tọ́ sí yìí pa mọ́ níbi tí wọ́n ń gbé ní tẹ́ńpìlì.—2 Àwọn Ọba 11:1-3.
Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà, Àlùfáà Àgbà, pinnu láti ṣe ohun tó ti ń gbèrò lọ́kàn, ìyẹn ni láti mú ọbabìnrin tó fèrú gorí ìtẹ́ náà kúrò. Ó mú ọmọdékùnrin tó ti gbé pa mọ́ náà jáde, ó sì dé e ládé gẹ́gẹ́ bí ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọba náà. Làwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣiṣẹ́ láàfin bá gbé Ataláyà Ọbabìnrin búburú náà jù síta níwájú tẹ́ńpìlì wọ́n sì pà á síbẹ̀, èyí tó mú ayọ̀ àti ìtura bá àwọn èèyàn. Jèhóádà àti Jèhóṣébà ṣe gudugudu méje láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ fẹsẹ̀ múlẹ̀ padà nílẹ̀ Júdà. Àmọ́ èyí tó ṣe kókó jù ni pé, ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ kí ìran Ọba Dáfídì lè máa bá a lọ, èyí tó wá jálẹ̀ sọ́dọ̀ Mèsáyà.—2 Àwọn Ọba 11:4-21.
Ọba tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ yìí náà ní láti gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì tí yóò múnú Ọlọ́run dùn. Ilé Jèhófà ti bà jẹ́ gan-an ó sì nílò àtúnṣe. Ipò ọlá tí Ataláyà ń wá lójú méjèèjì tó fi ń dá nìkan ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ Júdà ti mú kí tẹ́ńpìlì náà di èyí tí wọ́n pa tì, wọ́n sì ti jí àwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ kó lọ. Èyí ló mú kí Jèhóáṣì pinnu láti tún tẹ́ńpìlì náà kọ́ kó sì dá a padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Kíákíá ló pàṣẹ pé kí wọ́n kó owó tí wọ́n máa fi ṣàtúnṣe ilé Jèhófà jọ. Ó sọ pé: “Gbogbo owó àwọn ọrẹ ẹbọ mímọ́ tí a bá mú wá sí ilé Jèhófà, owó tí a bá dá lé olúkúlùkù, owó àwọn ọkàn gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé ti olúkúlùkù, gbogbo owó tí ó bá wá sí ọkàn-àyà olúkúlùkù láti mú wá sí ilé Jèhófà, kí àwọn àlùfáà gbà á fún ara wọn, olúkúlùkù lọ́wọ́ ojúlùmọ̀ rẹ̀; kí àwọn, ní tiwọn, sì tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé náà ṣe, ibikíbi tí a bá ti rí ibi sísán èyíkéyìí.”—2 Àwọn Ọba 12:4, 5.
Àwọn èèyàn ṣètọrẹ tọkàntọkàn. Àmọ́ àwọn àlùfáà kò fi gbogbo ọkàn bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n gbé lé wọn lọ́wọ́ láti tún tẹ́ńpìlì náà ṣe. Èyí ló mú kí ọba pinnu pé òún á fúnra òun bójú tó ọ̀ràn náà, ó sì pàṣẹ pé inú àkànṣe àpótí kan ni káwọn èèyàn lọ máa fi ọrẹ wọn sí ní tààràtà. Ó wá fi Jèhóádà ṣe alábòójútó rẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Jèhóádà àlùfáà gbé àpótí kan wàyí, ó sì dá ihò lu sí ọmọrí rẹ̀, ó sì gbé e sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ, ní ìhà ọ̀tún bí ènìyàn bá ń wọ inú ilé Jèhófà bọ̀, ibẹ̀ sì ni àwọn àlùfáà, àwọn olùṣọ́nà, ń kó gbogbo owó tí a mú wá sí ilé Jèhófà sí. Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí wọ́n bá ti rí i pé owó púpọ̀ ń bẹ nínú àpótí náà, akọ̀wé ọba àti àlùfáà àgbà a gòkè wá, wọn a sì dì í, wọn a sì ka owó náà tí a rí ní ilé Jèhófà. Wọ́n sì kó owó tí a ti kà sọ́tọ̀ náà lé ọwọ́ àwọn olùṣe iṣẹ́ tí a yàn sí ilé Jèhófà. 2 Àwọn Ọba 12:9-12.
Àwọn, ẹ̀wẹ̀, san án fún àwọn oníṣẹ́ igi àti fún àwọn akọ́lé tí ń ṣiṣẹ́ ní ilé Jèhófà, àti fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn agbẹ́kùúta àti láti fi ra ẹ̀là gẹdú àti òkúta gbígbẹ́ láti fi tún àwọn ibi tí ó sán lára ilé Jèhófà ṣe àti fún gbogbo ohun tí a lò sí ara ilé náà láti fi tún un ṣe.”—Tọkàntọkàn làwọn èèyàn náà fi ṣètọrẹ. Ilé ìjọsìn Jèhófà sì padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ kí ìjọsìn rẹ̀ lè máa bá a lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Èyí fi hàn pé wọ́n lo gbogbo ọrẹ táwọn èèyàn mú wá náà lọ́nà tó bójú mu. Jèhóáṣì Ọba rí sí i pé wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀!
Lọ́jọ́ òní náà, ètò Jèhófà tá a lè fojú rí ń kíyè sára gan-an láti rí i dájú pé gbogbo owó táwọn èèyàn ń fi ṣètọrẹ là ń lò dáadáa láti mú ìjọsìn Jèhófà tẹ̀ síwájú. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un làwọn Kristẹni tòótọ́ sì ṣe ń fi gbogbo ọkàn wọn ṣètọrẹ. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà wà lára àwọn tó ṣètọrẹ nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá kí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run lè máa tẹ̀ síwájú. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tá a gbà lo ọrẹ rẹ.
IṢẸ́ ÌWÉ TÍTẸ̀
Jákèjádò ayé, àwọn ìwé tó wà nísàlẹ̀ yìí la tẹ̀ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti láti máa pín in fáwọn èèyàn
• Ìwé ńlá: 47,490,247
• Ìwé kékeré: 6,834,740
• Ìwé pẹlẹbẹ: 167,854,462
• Kàlẹ́ńdà: 5,405,955
• Ìwé ìròyìn: 1,179,266,348
• Ìwé ìléwọ́: 440,995,740
• Fídíò: 3,168,611
À ń tẹ̀wé nílẹ̀ Áfíríkà, láwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Àríwá, Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà, ní ilẹ̀ Éṣíà, ilẹ̀ Yúróòpù àtàwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ erékùṣù lágbègbè Òkun Pàsífíìkì. Gbogbo wọn lápapọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́kàndínlógún.
“Katelyn May lorúkọ mi. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni mí. Mo ní dọ́là méjìdínlọ́gbọ̀n [nǹkan bíi ₦3,720], mo sì fẹ́ láti fún un yín kẹ́ ẹ lè lò ó láti fi sanwó àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé wọ̀nyẹn. Èmi ni arábìnrin yín kékeré, Katelyn.”
“Ìdílé wa ṣèpàdé nípa àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tuntun yẹn. Àwọn ọmọ wa tí ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá tí èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, pinnu láti mú lára owó wọn tí wọ́n ń fi pa mọ́ káwọn náà lè ṣètọrẹ. Inú wa dùn láti fi ọrẹ wọn ránṣẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú tiwa.”
ILÉ KÍKỌ́
Díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ilé kíkọ́ tá a ṣe láti fi ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn nìwọ̀nyí:
• Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́: 2,180
• Gbọ̀ngàn Àpéjọ: 15
• Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì: 10
• Àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kárí ayé tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ilé kíkọ́: 2,342
“Lópin ọ̀sẹ̀ yìí la ṣe ìpàdé àkọ́kọ́ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tuntun. Inu wa dùn gan-an pé a ní ibi tó bójú mu láti máa fi ìyìn fún Baba wa, Jèhófà Ọlọ́run. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti lọ́wọ́ ẹ̀yin náà fún bẹ́ ẹ ṣe bá wa yanjú ìṣòro wa nípa kíkọ́ ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí i. Àní, nǹkan ńlá ni Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jẹ́ ládùúgbò tó wà.”—Chile.
“Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí ètò Jèhófà ṣe gan-an ni. Títí dòní la ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin tá a gbádùn pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ kọ́lékọ́lé.”—Moldova.
“Láìpẹ́ yìí lèmi àti aya mi ṣàjọyọ̀ ọdún karùndínlógójì tá a ṣègbéyàwó. A ronú ohun tá a lè ṣe fún ara wa fún àjọyọ̀ náà, la bá pinnu láti fún Jèhófà àti ètò rẹ̀ ní nǹkan kan padà, nítorí bí kì í bá ṣe ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n ń pèsè ni, ó ṣeé ṣe ká máà ní ayọ̀ nínú ìgbéyàwó wa. A fẹ́ kẹ́ ẹ lo owó tá a fi sínú lẹ́tà yìí láti fi ṣèrànwọ́ fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ní lọ́wọ́.”
“Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ogún kan ni, àmọ́ nítorí pé ‘àwọn ohun tó wù mí láti ní’ kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, tí ‘àwọn ohun tó pọn dandan fún mi láti ní’ sì kéré gan-an, màá fẹ́ kẹ́ ẹ lo owó tí mo fi sínú àpò ìwé yìí fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, èyí táwọn ará nílò gan-an ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.”
ÌRÀNLỌ́WỌ́ NÍGBÀ ÀJÁLÙ
Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àjálù sábà máa ń ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe àfikún ọrẹ kó lè ṣeé ṣe láti ran àwọn arákùnrin wọn tó wà láwọn àgbègbè tí àjálù ti ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. A fẹ́ kẹ́ ẹ rántí pé lára àwọn ọrẹ tá à ń ṣe fún iṣẹ́ kárí ayé là ń lò nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn ibi táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá nìwọ̀nyí:
• Áfíríkà
• Éṣíà
• Àgbègbè Caribbean
• Àwọn erékùṣù àgbègbè Òkun Pásífíìkì
“Èmi àti ọkọ mi fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gan-an fún àwọn nǹkan tẹ́ ẹ fi ránṣẹ́ pé ká fi ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tó bàjẹ́ nígbà tí ìjì líle yẹn ṣẹlẹ̀. Èyí jẹ́ ká lè fi òrùlé tuntun bo ilé wa. A mọrírì bí ẹ ṣe tètè dìde fún ìrànwọ́ wa gan-an.”
“Connor lorúkọ mi, ọmọ ọdún mọ́kànlá sì ni mí. Nígbà tí mo rí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà jàǹbá omíyalé tí wọ́n pè ní sùnámì, ó wù mí kí n ṣèrànwọ́. Mo rò pé ohun tí mo fi ránṣẹ́ yìí yóò ṣèrànwọ́ fáwọn arákùnrin mi àtàwọn arábìnrin mi.”
ÀWỌN TÓ Ń ṢE ÀKÀNṢE IṢẸ́ ÌSÌN ALÁKÒÓKÒ-KÍKÚN
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ń lo gbogbo àkókò wọn nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì. Ọrẹ àtinúwá la fi ń ṣètìlẹ́yìn fáwọn kan tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún. Lára wọn sì nìwọ̀nyí:
• Àwọn míṣọ́nnárì: 2,635
• Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò: 5,325
• Àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì: 20,092
“Níwọ̀n bí mi ò ti lè lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì báyìí [ọmọdékùnrin ọmọ ọdún márùn-ún], mo ń fi owó yìí ránṣẹ́ tìfẹ́tìfẹ́. Nígbà tí mo bá dàgbà, màá lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti lọ ṣiṣẹ́ kárakára.”
A Lò Ó Láti Mú Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tẹ̀ Síwájú
Jésù Kristi pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pa aṣẹ yẹn mọ́, wọ́n ń wàásù wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn lóhun tó wà nínú Bíbélì láìkáàárẹ̀ ní igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235] ilẹ̀. Wọ́n ń tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde ní èdè ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàlá [413].
Ká sòótọ́, ohun tó ṣeyebíye jù lọ táwọn Kristẹni lè fi ṣètọrẹ kí wọ́n lè túbọ̀ ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Ọlọ́run àtohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé ni àkókò wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń yọ̀ǹda àkókò wọn lọ́pọ̀ yanturu wọ́n sì ń lo okun wọn lójú méjèèjì láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Wọ́n tún ń fi owó wọn ṣètọrẹ gan-an, gbogbo ọrẹ tí wọ́n sì ń ṣe lọ́nà kan tàbí òmíràn ti mú kí orúkọ Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ di mímọ̀ káàkiri ayé. A gbàdúrà pé kí Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapa wa nìṣó bá a ti ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ̀ ọ́n. (Òwe 19:17) Irú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ láti ṣèrànwọ́ ń mú inú Jèhófà dùn!—Hébérù 13:15, 16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwés 28-30]
Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Ń Gbà Ṣètọrẹ
ỌRẸ FÚN IṢẸ́ YÍKÁ AYÉ
Ọ̀pọ̀ máa ń ya iye kan sọ́tọ̀ tàbí kí wọ́n ṣètò iye kan tí wọ́n á máa fi sínú àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions for the Worldwide Work [Ọrẹ fún Iṣẹ́ Kárí Ayé]—Mátíù 24:14” sí lára.
Oṣooṣù làwọn ìjọ máa ń fi àwọn owó yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè wọn. O tún lè fi ọrẹ tó o fínnúfíndọ̀ ṣe ránṣẹ́ ní tààràtà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè rẹ. Tó o bá fẹ́ fi sọ̀wédowó ránṣẹ́ sí wa, kọ “Watch Tower” sórí rẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wa láti rí owó náà gbà. O tún lè fi ohun ọ̀ṣọ́ ṣíṣeyebíye tàbí ohun àlùmọ́ọ́nì mìíràn ṣètọrẹ. Kí lẹ́tà ṣókí tó fi hàn pé ẹ̀bùn ni irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ jẹ́ wà lára rẹ̀.
ỌRẸ TÍ A WÉWÈÉ
Yàtọ̀ sí pé ká dìídì fowó ṣètọrẹ, àwọn ọ̀nà mìíràn tún wà tá a lè gbà ṣètọrẹ fún àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé. Lára àwọn ọ̀nà náà rèé:
Owó Ìbánigbófò: A lè kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò gba owó ìbánigbófò ẹ̀mí tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́.
Àkáǹtì Owó ní Báńkì: A lè fi owó tá a ní ní báńkì tàbí owó tá a fi pa mọ́ sí báńkì fún àkókò pàtó kan (fixed deposit), tàbí owó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ tó wà ní báńkì síkàáwọ́ Watch Tower láti máa lò ó tàbí ká ṣètò pé kí owó náà ṣeé san fún Watch Tower lẹ́yìn ikú ẹni, níbàámu pẹ̀lú ìlànà báńkì náà.
Ìpín Ìdókòwò (Shares), Ẹ̀tọ́ Orí Owó Ìdókòwò (Debenture Stocks) àti Ti Ètò Ẹ̀yáwó (Bonds): A lè fi ìpín ìdókòwò, ẹ̀tọ́ orí owó ìdókòwò àti ti ẹ̀yáwó ta Watch Tower lọ́rẹ.
Ilẹ̀: A lè fi ilẹ̀ tó ṣeé tà ta Watch Tower lọ́rẹ. Tó bá jẹ́ ilẹ̀ tí ilé wà lórí rẹ̀ téèyàn ṣì ń gbénú rẹ̀ ni, ẹni náà lè dá a dúró kó sì máa gbénú rẹ̀ nígbà tó bá ṣì wà láàyè. Kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè rẹ kó o tó fi ìwé àṣẹ sọ ilẹ̀ èyíkéyìí di ọrẹ. ▸
Ìwé Ìhágún àti Ohun Ìní Tá A Fi Síkàáwọ́ Onígbọ̀wọ́: A lè fi dúkìá tàbí owó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún fún Watch Tower nípasẹ̀ ìwé ìhágún tá a ṣe lábẹ́ òfin, tàbí ká kọ orúkọ Watch Tower gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò jàǹfààní ohun ìní tá a fi síkàáwọ́ onígbọ̀wọ́.
Irú àwọn ọrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí ń béèrè pé kí ẹni tó fẹ́ ṣètọrẹ náà wéwèé.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, o lè kàn sí Ẹ̀ka Iléeṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, yálà nípa kíkọ̀wé sí àdírẹ́sì tá a kọ sísàlẹ̀ yìí tàbí kó o pè wá lórí tẹlifóònù, tàbí kó o kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ.
Jehovah’s Witnesses,
P.M.B 1090,
Benin City 300001,
Edo State, Nigeria
Telephone: (234) 01-3204850-4
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]
Fídíò Faithful: Stalin: U.S. Army photo