Ṣé Ọlọ́run Ni Tàbí Èèyàn?
Ṣé Ọlọ́run Ni Tàbí Èèyàn?
JÉSÙ KRISTI sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòhánù 8:12) Ọ̀mọ̀wé kan kọ̀wé nípa Jésù ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Inú rẹ̀ ni a rọra fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ti ìmọ̀ pa mọ́ sí.” (Kólósè 2:3) Síwájú sí i, Bíbélì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Ó ṣe pàtàkì ká ní ìmọ̀ pípéye nípa Jésù torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè pòùngbẹ tó bá ń gbẹ wá nípa tẹ̀mí.
Jákèjádò ayé làwọn èèyàn ti gbọ́ nípa Jésù Kristi. Kò sì sí àní-àní pé ó kó ipa pàtàkì nínú ọ̀rọ̀ àwa ọmọ èèyàn. Àní ọdún táwọn èèyàn gbà pé wọ́n bí Jésù ni wọ́n gbé kàlẹ́ńdà tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń lò jákèjádò ayé kà. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ohun táwọn kan ń pe àwọn ọdún tó wà ṣáájú ọdún tí wọ́n gbà pé wọ́n bí Jésù ni B.C., ìyẹn ṣáájú Kristi. Wọ́n sì ń pe àwọn ọdún ẹ̀yìn ìgbà yẹn ní A.D tàbí anno Domini, ìyẹn ọdún Olúwa wa.”
Síbẹ̀, èrò àwọn èèyàn yàtọ̀ síra nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Lójú àwọn kan, ńṣe ni Jésù kàn jẹ́ akíkanjú ẹ̀dá tó gbé ohun ribiribi ṣe nílé ayé. Ṣùgbọ́n àwọn míì gbà pé òun ni Ọlọ́run Olódùmarè, wọ́n sì ń sìn ín. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù kan sọ pé Jésù Kristi ò yàtọ̀ sí Krishna ìyẹn òòṣà àwọn Híńdù tí wọ́n gbà pé ó para dà di èèyàn. Ṣé èèyàn ẹlẹ́ran ara kan lásán ni Jésù ni àbí ẹni tó yẹ ká máa sìn? Ta ni Jésù yìí? Ibo ló ti wá? Irú ẹ̀dá wo ló jẹ́? Ibo ló sì wà báyìí? Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò rí ìdáhùn tó jóòótọ́ sáwọn ìbéèrè yìí látinú ìwé kan tó ṣàlàyé púpọ̀ nípa Jésù.