Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tá A Fi Ń Rántí Àwọn Kan

Ohun Tá A Fi Ń Rántí Àwọn Kan

Ohun Tá A Fi Ń Rántí Àwọn Kan

NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, Dáfídì ń sá kiri nítorí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì. Dáfídì ránṣẹ́ sí Nábálì, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ tó ní àgùntàn àti ewúrẹ́ lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ pé kó fún òun ní oúnjẹ àti omi. Ní ti gidi, ó yẹ kí Nábálì ṣe Dáfídì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀ lóore nítorí pé àwọn ló dáàbò bo agbo ẹran Nábálì nígbà kan rí. Àmọ́ Nábálì kọ̀ kò fún wọn ní ohunkóhun. Àní ńṣe ló láálí àwọn ọkùnrin tí Dáfídì rán sí i. Ikú ni Nábálì fi ń ṣeré yìí o, nítorí pé Dáfídì kì í ṣe ẹni téèyàn ń fojú di.—1 Sámúẹ́lì 25:5, 8, 10, 11, 14.

Ìwà tí Nábálì hù yìí kò bá àṣà àwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé mu nítorí pé wọ́n mọ aájò àwọn àlejò àti àjèjì ṣe púpọ̀. Irú orúkọ wo ni Nábálì tipa bẹ́ẹ̀ ṣe fún ara rẹ̀? Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé ó “le koko, ó sì burú ní àwọn ìṣe rẹ̀,” pé “àwé tí kò dára fún ohunkóhun rárá” ni. Orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “òpònú,” orúkọ náà sì rò ó gan-an. (1 Sámúẹ́lì 25:3, 17, 25) Ṣé bí ìwọ náà ṣe fẹ́ kí wọ́n máa rántí rẹ nìyẹn? Ṣé ńṣe ni ìwọ náà máa ń kanra tó o sì máa ń le koko mọ́ àwọn èèyàn tí nǹkan ò ṣẹnuure fún? Tàbí o jẹ́ onínúure, tó láàánú tó sì ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò?

Ábígẹ́lì—Obìnrin Tí Orí Rẹ̀ Pé

Ìwà lílekoko Nábálì yìí kó o sí ìjàngbọ̀n. Dáfídì kó irínwó ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n so idà wọn mọ́dìí háháhá pé àwọn á lọ kọ́ Nábálì lọ́gbọ́n. Ábígẹ́lì aya Nábálì gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó mọ̀ pé gbẹgẹdẹ ló fẹ́ gbiná yìí o. Kí ló lè ṣe? Ó sáré lọ ṣe oúnjẹ àtàwọn nǹkan mìíràn ó sì lọ pàdé Dáfídì àtàwọn ọkùnrin rẹ̀. Nígbà tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ó bẹ Dáfídì pé kó dákun kó má tàjẹ̀ sílẹ̀ láìnídìí. Ìbínú Dáfídì sì rọlẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ obìnrin yìí kò sì ṣe ohun tó ní lọ́kàn tẹ́lẹ̀ mọ́. Kò pẹ́ sákòókò yìí ni Nábálì kú. Dáfídì sì mú Ábígẹ́lì ṣaya nítorí ìwà rere tó ní.—1 Sámúẹ́lì 25:14-42.

Irú orúkọ wo ni Ábígẹ́lì ṣe fún ara rẹ̀? Ó ní “ọgbọ́n inú dáadáa” gẹ́gẹ́ bá a ṣe túmọ̀ rẹ̀ látinú èdè Hébérù ìjímìjí. Ó hàn gbangba pé orí rẹ̀ pé ó sì mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe, bákan náà ló mọ ọ̀nà tó yẹ kéèyàn gbà ṣe nǹkan àti ìgbà tó yẹ láti ṣe é. Ó hùwà ọgbọ́n èyí tó fi gba ọkọ̀ rẹ̀ òmùgọ̀ lọ́wọ́ àjálù. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó kú àmọ́, ó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé olórí pípé ni.—1 Sámúẹ́lì 25:3.

Irú Orúkọ Wo Ni Pétérù Ṣe Fún Ara Rẹ̀?

Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká bọ́ sórí ohun táwọn àpọ́sítélì Jésù méjìlá ṣe ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Láìsí àní-àní, Pétérù tó tún ń jẹ́ Kéfà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀ jù, iṣẹ́ ẹja pípa ló ń ṣe tẹ́lẹ̀ ní Gálílì. Ó hàn gbangba pé ó jẹ́ ẹni tí ẹnu rẹ̀ gbọ̀rọ̀ tí kì í bẹ̀rù rárá láti sọ bí ọ̀ràn ṣe rí lára rẹ̀ jáde. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé Jésù ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kí ni Pétérù ṣe nígbà tó kàn án?

Pétérù sọ fún Jésù pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ wẹ ẹsẹ̀ mi ni?” Jésù dá a lóhùn pé: “Ohun tí mo ń ṣe kò yé ọ nísinsìnyí, ṣùgbọ́n yóò yé ọ lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí.” Ni Pétérù bá fèsì pé: “Dájúdájú, ìwọ kì yóò wẹ ẹsẹ̀ mi láé.” Kíyè sí i pé ńṣe ni Pétérù kọ̀ jálẹ̀. Kí wá ni Jésù sọ?

Jésù dáhùn pé: “Láìjẹ́ pé mo wẹ ẹsẹ̀ rẹ, ìwọ kò ní ipa kankan lọ́dọ̀ mi.” Símónì Pétérù sọ fún un pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n ọwọ́ mi àti orí mi pẹ̀lú.” Ṣé ẹ rí i pé Pétérù ti tún ki àṣejù bọ̀ ọ́! Àmọ́ gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ìwà Pétérù nìyẹn. Kì í ṣe pé ó ń díbọ́n.—Jòhánù 13:6-9.

A tún máa ń fi ìkùdíẹ̀-káàtó ẹ̀dá èèyàn tí Pétérù ní rántí rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sẹ́ Kristi níwájú àwọn èèyàn tí wọ́n pè é ní ọmọ ẹ̀yìn Jésù ará Násárétì tí wọ́n ti dá ẹjọ́ ikú fún. Nígbà tí Pétérù rí àṣìṣe rẹ̀, ńṣe ló bú sẹ́kún kíkorò. Ojú kò tì í rárá láti fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn pé ó kábàámọ̀ nǹkan tó ṣe. Ohun kan tó tún gbàfiyèsí ni pé àwọn to kọ ìwé Ìhìn Rere ló kọ àkọsílẹ̀ nípa sísẹ́ tí Pétérù sẹ́ Jésù yìí—ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Pétérù fúnra rẹ̀ ló fún wọn láwọn ìsọfúnni náà! Ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ débi pé ó gbà pé òun ṣàṣìṣe. Ṣé ìwọ náà ní irú ẹ̀mí yìí?—Mátíù 26:69-75; Máàkù 14:66-72; Lúùkù 22:54-62; Jòhánù 18:15-18, 25-27.

Kò ju ọ̀sẹ̀ mélòó kan lọ lẹ́yìn tí Pétérù sẹ́ Kristi tí ẹ̀mí mímọ́ fi bà lé e, tó sì fìgboyà wàásù fún ogunlọ́gọ̀ àwọn Júù ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì. Èyí jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé Jésù tá a jí dìde ní ìgbọ́kànlé nínú rẹ̀.—Ìṣe 2:14-21.

Lẹ́yìn ìyẹn, Pétérù tún ṣe àṣìṣe mìíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé kó tó di pé àwọn arákùnrin kan tí wọ́n jẹ́ Júù dé sí Áńtíókù, Pétérù ń bá àwọn Kèfèrí tí wọ́n ti di onígbàgbọ́ ṣe wọléwọ̀de. Àmọ́ nígbà tó yá, ó wá pa wọ́n tì nítorí “ìbẹ̀rù ẹgbẹ́ àwọn tí ó dádọ̀dọ́” tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti Jerúsálẹ́mù. Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìwà ṣòkèṣodò tí Pétérù hù yìí kò dára.—Gálátíà 2:11-14.

Síbẹ̀, èwo nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ló fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí ọ̀ràn dójú ọ̀gbagadè tó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ló fẹ́ padà lẹ́yìn rẹ̀? Ìyẹn ṣẹlẹ̀ lákòókò kan tí Jésù sọ àwọn ohun kan tó jẹ́ tuntun, pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara òun kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun. Ó sọ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín.” Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ Júù lọ̀rọ̀ yìí mú kọsẹ̀, wọ́n sì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Kí ló wá ṣẹlẹ̀? “Ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.”—Jòhánù 6:50-66.

Lákòókò tí ọ̀ràn dójú ọ̀gbagadè yìí, Jésù yíjú sáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá ó sì béèrè ìbéèrè láti mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, ó ní: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” Kíá ni Pétérù dáhùn pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun; àwa sì ti gbà gbọ́, a sì ti wá mọ̀ pé ìwọ ni Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”—Jòhánù 6:67-69.

Irú orúkọ wo ni Pétérù ṣe fún ara rẹ̀? Ẹnikẹ́ni tó bá ka àkọsílẹ̀ náà yóò rí i pé kì í fi dúdú pe funfun kì í sì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, yóò rí ìdúróṣinṣin rẹ̀ àti pé kì í jáfara láti gbà pé òun ṣàṣìṣe. Ẹ wo irú orúkọ rere tí ó ṣe fún ara rẹ̀!

Kí Làwọn Èèyàn Fi Ń Rántí Jésù?

Kìkì ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré ni Jésù fi ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi ń rántí rẹ̀? Ǹjẹ́ jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ ẹni pípé tí kò lẹ́ṣẹ̀ mú kó máa ya ara rẹ̀ láṣo kó má sì ṣe é sún mọ́? Ǹjẹ́ agbára máa ń gùn ún gàràgàrà nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ ó máa ń kó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láyà jẹ kó sì fipá mú wọn láti ṣègbọràn sóun? Ǹjẹ́ ó jọra rẹ̀ lójú débi pé kì í bá àwọn èèyàn ṣeré? Ǹjẹ́ ọwọ́ rẹ̀ dí débi pé kò ráyè gbọ́ tàwọn aláìlera, àwọn aláìsàn tàbí àwọn ọmọdé? Ǹjẹ́ ó máa ń fi ojú aláìtẹ́gbẹ́ wo àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà mìíràn àtàwọn obìnrin, gẹ́gẹ́ báwọn ọkùnrin ṣe máa ń ṣe nígbà náà lọ́hùn-ún? Kí ni àkọsílẹ̀ sọ fún wa nípa rẹ̀?

Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn. Tá a bá kíyè sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, à óò rí i pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló mú àwọn arọ àtàwọn aláìsàn lára dá. Ó sapá láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ògo wẹẹrẹ, ó tiẹ̀ sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má gbìyànjú láti dá wọn lẹ́kun.” Jésù wá “gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn.” Ǹjẹ́ o máa ń ráyè gbọ́ tàwọn ọmọdé, àbí ọwọ́ rẹ máa ń dí débi pé o kì í rójú gbọ́ tiwọn?—Máàkù 10:13-16; Mátíù 19:13-15.

Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn èèyàn di ẹrù òfin àti ìlànà ẹ̀sìn lé àwọn Júù lórí ju ohun tí Òfin béèrè lọ. Ẹrù ńláńlá làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń dì lé àwọn èèyàn náà lórí, àwọn fúnra wọn kò sì jẹ́ fi ọmọ ìka wọn kan ẹrù náà. (Mátíù 23:4; Lúùkù 11:46) Ẹ ò rí i pé Jésù yàtọ̀ pátápátá sí wọn! Ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28-30.

Ara máa ń tu àwọn èèyàn bí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ Jésù. Kò kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láyà jẹ kí wọ́n má lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde fàlàlà. Kódà, ńṣe ló máa ń béèrè ìbéèrè tó máa mú kí wọ́n sọ èrò ọkàn wọn jáde lọ́wọ́ wọn. (Máàkù 8:27-29) Ó máa dára káwọn Kristẹni alábòójútó béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: ‘Ṣé mo máa ń ṣe bíi ti Jésù sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi? Ǹjẹ́ àwọn alàgbà ẹlẹ́gbẹ́ mi lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde fàlàlà tàbí ẹ̀rù máa ń bà wọ́n láti ṣe bẹ́ẹ̀?’ Ó mà dára gan-an o káwọn alábòójútó jẹ́ ẹni tó ṣe é sún mọ́, tó máa ń tẹ́tí sáwọn ẹlòmíràn tí kì í sì í le koko! Lílekoko kì í jẹ́ kí àwọn èèyàn lè sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run, kò ṣi agbára rẹ̀ tàbí ọlá àṣẹ rẹ̀ lò rárá àti rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa ń fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Nígbà kan báyìí táwọn Farisí fẹ́ fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú un, tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ó ha bófin mu láti san owó orí fún Késárì tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Jésù sọ fún wọn pé kí wọ́n lọ mú ẹyọ owó kan wá ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta ni èyí?” Wọ́n dá a lóhùn pé: “Ti Késárì.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:15-21) Ọgbọ́n ìrònú tó rọrùn láti lóye ló fi dáhùn ìbéèrè wọn.

Ǹjẹ́ Jésù máa ń dẹ́rìn-ín pani? Àwọn òǹkàwé kan lè rí àpẹẹrẹ èyí nígbà tí wọ́n ka àkọsílẹ̀ Bíbélì níbi tí Jésù ti sọ pé ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá jù fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 19:23, 24) Àbùmọ́ gbáà ni pé odindi ràkúnmí á lè gba ojú ihò ìdí abẹ́rẹ́ kọjá. Àpẹẹrẹ mìíràn tó tún jẹ́ àbùmọ́ ni ti tẹni tó rí èérún pòròpórò tó wà lójú arákùnrin rẹ̀ àmọ́ tí kò rí igi ìrólé tó wà lójú òun fúnra rẹ̀. (Lúùkù 6:41, 42) Dájúdájú, Jésù kì í ṣe ẹni tí ń lejú koko. Ó lọ́yàyà ó sì ń ṣe bí ọ̀rẹ́. Fún àwọn Kristẹni lónìí, dídẹ́rìn-ín pani lè mú kéèyàn túra ká nígbà ìṣòro.

Jésù Yọ́nú Sáwọn Obìnrin

Báwo ló ṣe máa ń rí lára àwọn obìnrin bí Jésù bá wà láàárín wọn? Dájúdájú, ọ̀pọ̀ obìnrin tó jẹ́ adúróṣinṣin ló di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, títí kan Màríà tó jẹ́ ìyá rẹ̀. (Lúùkù 8:1-3; 23:55, 56; 24:9, 10) Ara máa ń tu àwọn obìnrin láti wá sọ́dọ̀ Jésù débi pé nígbà kan, obìnrin kan ‘tá a mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀’ fi omíjé ojú rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jésù ó sì fi òróró atasánsán pa á. (Lúùkù 7:37, 38) Obìnrin mìíràn tí àrùn ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ti fojú rẹ̀ rí màbo fún ọ̀pọ̀ ọdún, gba àárín èrò kọjá ó sì lọ fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀ kó lè gba ìwòsàn. Jésù gbóríyìn fún ìgbàgbọ́ tí obìnrin yìí ní. (Mátíù 9:20-22) Dájúdájú, àwọn obìnrin rí i pé Jésù jẹ́ ẹni tó ṣe é sún mọ́.

Ìgbà kan tún wà tí Jésù bá obìnrin kan ará Samáríà sọ̀rọ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kàǹgá. Ẹnu ya obìnrin yìí débi pé ó ní: “Èé ti rí tí ìwọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Júù ni ọ́, fi ń béèrè omi mímu lọ́wọ́ mi, nígbà tí mo jẹ́ obìnrin ará Samáríà?” Ṣé ẹ rí i, àwọn Júù kì í bá àwọn Samáríà ṣe nǹkan pọ̀ rárá. Jésù kọ́ ọ ní òtítọ́ pàtàkì kan tó dá lórí ‘omi tí ń tú yàà sókè tó sì ń fúnni ní ìye àìnípẹ̀kun.’ Ẹ̀rù kì í ba Jésù tó bá wà lọ́dọ̀ àwọn obìnrin. Kì í ronú pé èyí lè jin ipò òun lẹ́sẹ̀.—Jòhánù 4:7-15.

Ọ̀pọ̀ àwọn ànímọ́ rere tí Jésù ní la fi ń rántí rẹ̀ tó fi dórí ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó ní. Ó gbé ìfẹ́ Ọlọ́run yọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Jésù ti fi ìlànà lélẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Báwo lo ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tó?—1 Kọ́ríńtì 13:4-8; 1 Pétérù 2:21.

Kí La Fi Ń Rántí Àwọn Kristẹni Òde Òní?

Lọ́jọ́ tòní, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni olóòótọ́ ló ti kú. Àwọn kan ti darúgbó kùjọ́kùjọ́ kí wọ́n tó kú àwọn mìíràn ò sì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà. Àmọ́ wọ́n fi àkọsílẹ̀ rere sílẹ̀. Àwọn kan lára wọn dà bí Crystal, tó darúgbó kó tó kú, a sì ń fi ìfẹ́ tí wọ́n ní àti bí ara wọn ṣe yọ̀ mọ́ọ̀yàn rántí wọn. Àwọn mìíràn dà bí Dirk tó kú nígbà tó lé lógójì ọdún, a sì ń rántí wọn fún bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nǹkan tẹ̀ríntẹ̀yẹ tí wọ́n sì ń múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́.

Ẹlòmíràn tún ni José ní Sípéènì. Láwọn ọdún 1960 tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè náà, José ti fẹ́yàwó, ó sì ti lọ́mọbìnrin mẹ́ta nígbà yẹn. Ó níṣẹ́ tó jọjú lọ́wọ́ nílùú Barcelona. Àmọ́ nígbà tó yá, a nílò àwọn Kristẹni alàgbà tó dàgbà dénú ní gúúsù Sípéènì. José fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ òun àti ìdílé rẹ̀ sì ṣí lọ sí Málaga. Ọ̀ràn àtijẹ àtimu kò fara rọ níbẹ̀ rárá, ọ̀pọ̀ ìgbà ni kò sì sí iṣẹ́ tó lè ṣe.

Síbẹ̀, a mọ José sí olódodo èèyàn, tó fi àpẹẹrẹ tó ṣeé gbára lé lélẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì tún jẹ́ àwòkọ́ṣe lọ́nà tó gbà tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀. Àtìlẹ́yìn ìyàwó rẹ̀ Carmela ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Nígbà tá a bá nílò ẹnì kan tó máa lọ ṣètò àpéjọ àgbègbè ti àwọn Kristẹni lágbègbè náà, José máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó mà ṣe o, àìsàn kan kọ̀ lù ú nígbà tó lé lẹ́ni àádọ́ta ọdún, ó sì kú. Síbẹ̀, ó fi orúkọ rere sílẹ̀ ní ti pé o jẹ́ ẹni tó ṣe é fọkàn tẹ̀, akíkanjú alàgbà ni, ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ ni, baba rere sì tún ni pẹ̀lú.

Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti ń sọ bọ̀ yìí, kí lo fẹ́ ká fi máa rántí rẹ? Ká sọ pé o ti kú lánàá, kí làwọn èèyàn ì bá máa sọ nípa rẹ lónìí? Ìbéèrè yìí lè mú kí gbogbo wa lọ ṣàtúnṣe lórí ọ̀nà tá a gbà ń hùwà.

Kí la lè ṣe ká bàa lè ní orúkọ rere? Gbogbo ìgbà la lè máa mú ọ̀nà tá a gbà ń fi àwọn èso tẹ̀mí hàn sunwọ̀n sí i. Àwọn èso náà sì ni, ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Dájúdájú, “Orúkọ [rere] sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.”—Oníwàásù 7:1; Mátíù 7:12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Orí pípé Ábígẹ́lì la fi ń rántí rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun tá a fi ń rántí Pétérù ni bí ọ̀rọ̀ ṣe dá lẹ́nu rẹ̀ tí kì í sì í fi dúdú pe funfun

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Jésù ráyè gbọ́ tàwọn ọmọdé