Èrò Ọlọ́run Nípa Àwọn Tó Ti Kú
Èrò Ọlọ́run Nípa Àwọn Tó Ti Kú
ÌBÀNÚJẸ́ máa ń báni nígbà téèyàn ẹni bá kú. Ìmọ̀lára pé ẹni náà ò sí mọ́, pé èèyàn dá nìkan wà àti àdánù tó báni máa ń pọ̀ gan-an ni. Ikú èèyàn ẹni lè mú kéèyàn ronú pé òun ò ní alátìlẹyìn, nítorí pé èèyàn ì báà lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kó lágbára tàbí kó jẹ́ ẹni tí gbogbo ayé ń wárí fún, kò lè jí ẹni tó kú dìde.
Àmọ́ ṣá o, ọ̀nà tí Ẹlẹ́dàá wa gbà ń wo ọ̀ràn yìí yàtọ̀ o. Nígbà tó jẹ́ pé òun ló fi erùpẹ̀ ilẹ̀ dá ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, ó tún lágbára láti ṣe àtúndá ẹnì kan tó ti kú. Ìdí rèé tí ẹnì tó ti kú fi dà bí ẹni tó ṣì wà láàyè lójú Ọlọ́run. Ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ ayé àtijọ́ tí wọ́n ti kú ni pé: “Gbogbo wọn wà láàyè lójú [Ọlọ́run].”—Lúùkù 20:38.
A fún Jésù lágbára láti jí òkú dìde nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 5:21) Ìdí rèé tó fi ní èrò kan náà pẹ̀lú Baba rẹ̀ nípa àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ títí wọ́n fi kú. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù kú, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo ń rìnrìn àjò lọ . . . láti jí i kúrò lójú oorun.” (Jòhánù 11:11) Lójú ẹ̀dá èèyàn, Lásárù ti kú àmọ́ lójú Jèhófà àti Jésù, ńṣe ni Lásárù ń sùn.
Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Jésù, “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” yóò wà. (Ìṣe 24:15) Tó bá sì yá, Ọlọ́run á kọ́ àwọn tá a jí dìde lẹ́kọ̀ọ́ wọ́n á sì láǹfààní láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29.
Dájúdájú, ikú èèyàn ẹni lè fa ìrora àti ìbànújẹ́ ọkàn tó lè wà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àmọ́ ṣá o, níní irú èrò tí Ọlọ́run ní nípa àwọn tó ti kú lè tù wá nínú kó sì fún wa nírètí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.