Ìfẹ́ Ṣe Kókó
Ìfẹ́ Ṣe Kókó
LÁÌKA ọjọ́ orí, àṣà, èdè, tàbí ẹ̀yà èèyàn sí, kò sẹ́ni tí ò fẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Tí wọn ò bá sì rẹ́ni fìfẹ́ hàn sí wọn, inú wọn kì í dùn. Olùwádìí kan lórí ọ̀ràn ìṣègùn kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ àti ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ ni gbòǹgbò ohun tó máa ń mú wa ṣàìsàn àti ohun tó máa ń mú kára wa yá, ohun tó máa ń fa ìbànújẹ́ àti ohun tó máa ń fún wa láyọ̀, ohun tó máa ń jẹ́ ká jìyà àti ohun tó máa ń wò wá sàn. Bí egbòogi tuntun kan bá lè ṣe irú iṣẹ́ yẹn, ṣàṣà oníṣègùn tó wà lórílẹ̀-èdè yìí ni kò ní í máa kọ ọ́ fáwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú. Tẹ́nì kan bá sì sọ pé káwọn aláìsàn máà lò ó, a jẹ́ pé onítọ̀hún kò mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ ni.”
Àmọ́, ohun tí àwùjọ òde òní, àgàgà àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde àtàwọn gbajúmọ̀ tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, sábà máa ń gbé lárugẹ ni ọ̀ràn nípa ọrọ̀, agbára, òkìkí, àti ìbálòpọ̀, dípò tí wọn ì bá fi máa sọ̀rọ̀ nípa ọ̀yàyà, àti àjọṣe onífẹ̀ẹ́ táwọn èèyàn nílò. Ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ́ni ló máa ń tẹnu mọ́ béèyàn ṣe kàwé tó àti ipò téèyàn wà láwùjọ, ìyẹn gan-an sì ni olórí ohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n béèyàn ṣe rí ṣe tó. Ní ti tòótọ́, ẹ̀kọ́ àti lílo ẹ̀bùn téèyàn ní ṣe pàtàkì púpọ̀, àmọ́ ṣé ó wá yẹ kéèyàn máa lépa ìyẹn nìkan ṣoṣo débi tí ò fi ní ráyè fún ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ mọ́? Ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ òǹkọ̀wé láyé ìgbàanì, tó tún máa ń kíyè sí irú ẹ̀dá téèyàn jẹ́, fi ẹni tó lẹ́bùn àmọ́ tí ò nífẹ̀ẹ́ wé “abala idẹ kan tí ń dún tàbí aro aláriwo gooro.” (1 Kọ́ríńtì 13:1) Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ lè di olówó rẹpẹtẹ, kódà kí wọ́n di olókìkí pàápàá, àmọ́ wọn ò lè láyọ̀ láé.
Ohun tí Jésù Kristi tó lóye jíjinlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, tó sì tún nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún wa, fi ṣe olórí ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò ẹni. Ó sọ pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ. . . . Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:37-39) Kìkì àwọn tó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ yìí ló lè jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ní ti tòótọ́. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.
Báwo wá lẹnì kan ṣe lè nífẹ̀ẹ́ láyé òde òní? Báwo làwọn òbí sì ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìpèníjà gidi ló jẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ nínú ayé tí ìwọra ti gbòde kan