Wọ́n Lo Ara Wọn fún Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wọn Kárí Ayé
Wọ́n Lo Ara Wọn fún Àwọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ́ Wọn Kárí Ayé
ǸJẸ́ o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “kọ́lékọ́lé láti ilẹ̀ òkèèrè” àti “ẹgbẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kárí ayé” rí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí yọ̀ǹda àkókò wọn àti òye iṣẹ́ tí wọ́n ní láti ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ àwọn ilé tá a ti ń tẹ àwọn ìhìn Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì jáde tá a sì ń pín wọn kiri. Irú àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn bẹ́ẹ̀ tún máa ń ṣèrànwọ́ nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó jẹ́ ibi tá a ti ń gba ìtọ́ni Bíbélì. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí ń ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ní orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí towó ṣe ló sì pọ̀ jù lára wọn. Àwọn ìṣòro àti ayọ̀ wo ni irú àwọn òjíṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ń ní bí wọ́n ṣe ń lo ara wọn fún ẹgbẹ́ àwọn ará tó jẹ́ Kristẹni kárí ayé? Kí ni èrò wọn nípa iṣẹ́ “ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀” tí wọ́n ń ṣe? (Ìṣípayá 7:9, 15) Láti mọ èyí, ẹ jẹ́ ká gbọ́ tẹnu àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó ń sìn ní Mẹ́síkò.
May 1992 làwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni láti ilẹ̀ òkèèrè kọ́kọ́ dé sí Mẹ́síkò. Kété lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó ipa pàtàkì nínú mímú kí ẹ̀ka tó ń bójú tó ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Mẹ́síkò gbòòrò sí i. Ìmúgbòòrò náà ní àwọn ilé tuntun mẹ́rìnlá nínú, títí kan àwọn ilé tó jẹ́ ibùgbé àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó ń sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà, ilé ìtẹ̀wé, àtàwọn ilé tí wọ́n máa lò fún ọ́fíìsì.
Láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ yìí, àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó lé ní àádọ́rin dín lẹ́gbẹ̀rin [730] tó wá láti Kánádà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ló ń sìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ Mẹ́síkò. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbàá mẹ́rìnlá [28,000] tó ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] tó wà láwọn àgbègbè tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà ló wá ń bá wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ọ̀hún láwọn òpin ọ̀sẹ̀. Gbogbo wọn ló ń fi ẹ̀mí ìmúratán ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì ń lo òye iṣẹ́ tí wọ́n ní lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n kà á sí àǹfààní ńlá láti sin Jèhófà lọ́nà yìí. Látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé náà títí tí wọ́n fi parí rẹ̀ ni wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ onímìísí tó wà nínú Sáàmù 127:1 sọ́kàn pé: “Bí kò ṣe pé Jèhófà tìkára rẹ̀ bá kọ́ ilé náà, lásán ni àwọn tí ń kọ́ ọ ti ṣiṣẹ́ kárakára lórí rẹ̀.”
Àwọn Ìṣòro Tí Wọ́n Dojú Kọ
Àwọn ìṣòro wo ni ẹgbẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kárí ayé máa ń ní nígbà tí wọ́n bá ń sìn nílẹ̀ òkèèrè? Díẹ̀ lára ohun tójú wọn ń rí rèé. Curtis àti Sally, tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ní ilẹ̀ Íńdíà, Jámánì, Mẹ́síkò, Paraguay, Romania, Rọ́ṣíà, Senegal, àti Zambia. Curtis sọ pé: “Ìṣòro tá a kọ́kọ́ ní ni ti fífi ọmọbìnrin wa, tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà [ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún] sílẹ̀, àti kíkúrò tá a kúrò nínú ìjọ wa ní Minnesota. Ọdún mẹ́rìnlélógún gbáko lèmi àti ìyàwó mi fi dara pọ̀ mọ́ ìjọ yẹn, ọkàn wa sì balẹ̀ dẹ́dẹ́ níbẹ̀.”
Sally sọ pé: “Ìṣòro ńlá ni kéèyàn bá ara rẹ̀ nínú ipò tó ṣàjèjì, ó tiẹ̀ dà bíi pé ó ṣorò fún obìnrin ju ọkùnrin lọ àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ṣeé ṣe láti mú ara ẹni bá ipò náà mu. Mo tún rí i pé mo ní láti fara da àwọn kòkòrò, tí wọ́n pọ̀ bí nǹkan mìí!” Ó tún sọ pé: “Ní orílẹ̀-èdè kan, àwa mẹ́wàá tá a yọ̀ǹda ara wa la jọ ń gbé inú ilé kan tí kò ní ilé ìdáná kankan, tó sì jẹ́ pé balùwẹ̀ méjì péré ló ní. Ibẹ̀ yẹn ni mo tí kọ́ béèyàn ṣe túbọ̀ ń ní sùúrù.”
Kíkọ́ èdè tuntun tún jẹ́ ìṣòro mìíràn tó gba ìsapá àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Sharon, tí òun àti ọkọ rẹ̀ ti kópa nínú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé ní onírúurú orílẹ̀-èdè sọ pé: “Ìpèníjà gidi ni kéèyàn máà gbọ́ èdè orílẹ̀-èdè tó ti ń sìn. Lákọ̀ọ́kọ́, á ṣòro láti sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí nígbà tó ò bá lè sọ ohun tó wà nínú rẹ jáde fàlàlà. Ìyẹn máa ń mú kí gbogbo nǹkan tojú súni. Àmọ́ àwọn arákùnrin tá a bá pàdé láwọn ilẹ̀ òkèèrè tá a lọ fi sùúrù bá wa lò gan-an, ire wa sì jẹ wọ́n lógún. Láìpẹ́, àwa náà ti bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ èdè ọ̀hún.”
Ó Gba Ìgboyà Láti Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni wọ̀nyí tí wọ́n ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ń ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà tẹ̀ síwájú, àmọ́ wọ́n tún mọ̀ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni jíjẹ́ táwọn jẹ́ oníwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń fi gbogbo ara
gbárùkù ti iṣẹ́ ìwàásù táwọn ara ń ṣe nínú àwọn ìjọ tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́. Åke àti Ing-Mari, tọkọtaya kan tó ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé tó wáyé ní Guadeloupe, Màláwì, Mẹ́síkò, àti Nàìjíríà, gbà pé lílo èdè mìíràn nígbà téèyàn bá ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ní ilẹ̀ òkèèrè gba ìgboyà gan-an.Ing-Mari ròyìn pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ìwọ̀nba ipa díẹ̀ la lè kó, nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà la máa ń tẹ̀ lé, àwọn la sì máa ń jẹ́ kó sọ̀rọ̀ ká má bàa gba ìtìjú. Àmọ́, a wá pinnu láti dá lọ sóde ẹ̀rí láàárọ̀ ọjọ́ kan. Bá a ṣe ń lọ lẹsẹ̀ wa ń gbọ̀n tí àyà wa sì ń lù kìkì. A rí obìnrin kan tó fetí sí ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí mo ti múra sílẹ̀ dáadáa. Mo ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan mo sì fún un láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Obìnrin náà wá sọ pé: ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n béèrè ohun kan lọ́wọ́ rẹ. Mo ní mọ̀lẹ́bí kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Báwo lèmi náà ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́?’ Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi. Bí mo ṣe ṣọkàn gírí nìyẹn tí mo wá bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Ing-Mari tún sọ pé: “Ẹ fojú inú wo ayọ̀ tí mo ní àti ọ̀pẹ́ mi tí kò lópin fún bí Jèhófà ṣe bù kún ìgbésẹ̀ tá a gbé àti ìfẹ́ ọkàn wa láti sọ òtítọ́ náà fáwọn èèyàn.” Obìnrin yìí tẹ̀ síwájú gan-an, ó sì sèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí ní àpéjọ àgbègbè kan ní Ìlú Mẹ́síkò. Ọ̀nà tí Åke àti Ing-Mari gbà ṣàkópọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nìyí, wọ́n ní: “A mọrírì onírúurú iṣẹ́ ìkọ́lé tá à ń ṣe gan-an ni, àmọ́ kò sóhun tó ń fúnni láyọ̀ tó sì ń fini lọ́kàn bálẹ̀ tó kéèyàn ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti wá sínú òtítọ́.”
Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ
Òótọ́ ni pé àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tó fi tẹbí tọ̀rẹ́ sílẹ̀ ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn kí wọ́n lè lo ara wọn fáwọn arákùnrin wọn nílẹ̀ òkèèrè, àmọ́ àwọn náà tún ń rí ayọ̀ tó pọ̀ gan-an. Kí layọ̀ náà?
Howard, tí òun àti Pamela aya rẹ̀ ti sìn ní Àǹgólà, Ecuador, El Salvador, Guyana, Kòlóńbíà, Mẹ́síkò àti Puerto Rico ṣàlàyé pé: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti pàdé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ní onírúurú orílẹ̀-èdè àti láti fojú ara ẹni rí ìdè ìfẹ́ tó wà láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará wa kárí ayé. A ti máa ń kà á nínú ìwé, àmọ́ ìgbà tó o bá lọ gbé láàárín àwọn ẹlòmíràn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn àti irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ látilẹ̀wá yàtọ̀ sí tìẹ tẹ́ ẹ sì tún jọ ṣiṣẹ́ pọ̀, lo máa túbọ̀ mọyì ẹgbẹ́ àwọn ará wa tó ṣeyebíye.”
Gary, tó ti sèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ní Costa Rica, Ecuador, Kòlóńbíà, Mẹ́síkò, àti Zambia, rí i pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ti ṣe òun náà láǹfààní tó pọ̀. Ó sọ pé: “Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí mo ti rí gbà láwọn ọdún wọ̀nyí nípa bíbá àwọn arákùnrin tó dàgbà dénú ṣiṣẹ́ pọ̀ láwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà láwọn orílẹ̀-èdè tá a yàn mí sí ti ràn mí lọ́wọ́ láti gbára dì dáadáa fún ìpèníjà èyíkéyìí tó lè yọjú lẹ́nu iṣẹ́ tá a bá yàn fún mi. Ó ti fún ìgbàgbọ́ mi lókun gan-an nítorí pé ó jẹ́ kí n láǹfààní àtirí ìṣọ̀kan tó wà nínú ètò àjọ Jèhófà kárí ayé—ìyẹn ìṣọ̀kan tó ré kọjá èdè, ẹ̀yà, tàbí àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra.”
Ní báyìí, a ti parí iṣẹ́ ìkọ́lé tá à ń ṣe ní Mẹ́síkò, a sì ya ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tá a mú gbòòrò náà sí mímọ́ lọ́dún yìí. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ló mú káwọn kọ́lékọ́lé láti ilẹ̀ òkèèrè àti ẹgbẹ́ àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni kárí ayé ṣe gudugudu méje láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ gbòòrò sí i ní Mẹ́síkò àti láwọn ibòmíràn. Gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ló fi ìmọrírì tó ga hàn fún ẹ̀mí ìmúratán wọn àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n fi lo ara wọn fún àwọn Kristẹni arákùnrin wọn kárí ayé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ecuador
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Kòlóńbíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àǹgólà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọgbà tó wà nínú ẹ̀ka náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ láwọn ilé tuntun tó wà ní ẹ̀ka ti Mẹ́síkò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nísàlẹ̀: Díẹ̀ lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìkọ́lé wà níwájú apá kan lára àwọn ilé tuntun náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé ń gbádùn bíbá àwọn ìjọ àdúgbò tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù