Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

A ṣètò àpilẹ̀kọ yìí ní pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gba àwọn ọ̀dọ́ níyànjú láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ yìí dáadáa, kí wọ́n sì dáhùn fàlàlà nígbà tá a bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ nínú ìjọ.”

“Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”—ÒWE 27:11.

1, 2. (a) Ṣàlàyé bóyá níní òòfà ọ̀kan sí àwọn nǹkan ayé lásán ti túmọ̀ sí pé o ò tóótun láti jẹ́ Kristẹni nìyẹn. (Róòmù 7:21) (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ásáfù? (Wo àpótí, ojú ìwé 13.)

 FOJÚ inú wò ó pé o lọ ra aṣọ lọ́jà. Bó o ṣe ń wò wọ́n gààràgà lo tajú kán rí ẹ̀wù kan tó jẹ́ pé bó o ṣe fojú gán-án-ní rẹ̀ báyìí ló ti wù ẹ́ pa. Àwọ̀ rẹ̀ àti bí wọ́n ṣe rán an bá ọ mu wẹ́kú, iye owó tí wọ́n kọ sí i lára ò sì wọ́n rárá. Àmọ́, nígbà tó o wá túbọ̀ wò ó dáadáa, o wá rí i pé ẹ̀wù náà ti ń ṣá léteetí, àti pé gbogbo ojú ibi tí wọ́n ti rán an ni ò dáa. Ní ti ẹ̀wù náà, ó lẹ́wà, ó sì fani mọ́ra, àmọ́ ohun tí wọ́n rán síbẹ̀ ò dáa rárá. Ṣé wàá fowó ẹ ra irú aṣọ tí ò ní láárí bẹ́ẹ̀?

2 Fi èyí wé ipò tó lè dojú kọ ẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ọ̀dọ́ kan. Nígbà tó o bá kọ́kọ́ wò ó gààrà, àwọn ohun tó wà nínú ayé yìí lè dà bí ohun tó fani mọ́ra gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù yẹn ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ sílé ìwé lè máa lọ sáwọn ibi àríyá aláriwo, kí wọ́n máa lo oògùn líle, kí wọ́n máa mutí àmupara, kí wọ́n máa bá ẹ̀yà kejì jáde bó ṣe wù wọ́n, kí wọ́n sì máa ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà láti gbé irú ìgbésí ayé yẹn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé kí ìwọ náà tiẹ̀ tọ́ díẹ̀ wò lára ohun tí wọ́n kà sí òmìnira yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má fìkánjú ronú pé èèyàn burúkú ni ọ́ àti pé o ò tóótun láti jẹ́ Kristẹni. Ó ṣe tán, Bíbélì gbà pé ayé lè fani mọ́ra gan-an—kódà ó lè fa ẹnì tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn pàápàá mọ́ra.—2 Tímótì 4:10.

3. (a) Kí nìdí tí lílépa àwọn nǹkan ti ayé fi jẹ́ asán lórí asán? (b) Báwo ni Kristẹni kan ṣe ṣàpèjúwe ìmúlẹ̀mófo tó wà nínú lílépa àwọn nǹkan ayé?

3 Wàyí o, jọ̀wọ́ yiiri ọ̀rọ̀ náà sọ́tùn-ún kó o tún yiiri ẹ̀ sósì, kó o wá yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa, bó o ṣe máa wo aṣọ tó wù ẹ́ láti rà. Bí ara rẹ pé, ‘Báwo ni aṣọ àtàwọn ojú ibi tí wọ́n ti rán ètò àwọn nǹkan yìí ti jẹ́ ojúlówó tó?’ Bíbélì sọ pé: “ayé ń kọjá lọ.” (1 Jòhánù 2:17) Adùn èyíkéyìí téèyàn bá rí níbẹ̀ kì í tọ́jọ́. Àti pé, ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run kì í bímọọre rárá. Èèyàn ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ dán irú ìwà bẹ́ẹ̀ wò rárá. Kristẹni kan, tó ní láti fara da ohun tó pè ní “ìrora tó ń tẹ̀yìn ṣíṣi ìgbà ọ̀dọ́ ẹni lò jáde,” sọ pé: “Ayé lè dà bí èyí tó ń gbádùn mọ́ni tó sì ń fani mọ́ra. Ayé á fẹ́ kó o gbà pé o lè gbádùn ohun tó wà níbẹ̀ láìsí ìpalára kankan. Àmọ́, kò sọ́gbọ́n tí èyí fi lè rí bẹ́ẹ̀. Ayé á lò ẹ́ bó ṣe fẹ́, nígbà tó bá sì gba gbogbo àǹfààní ara ẹ tán, á wá kó ẹ́ dà nù bí ewé mọ́ínmọ́ín.” a Kí ló dé tó o máa wá fi ìgbà èwe rẹ tàfàlà lórí ọ̀nà ìgbésí ayé tí kò ní láárí bẹ́ẹ̀?

Ààbò Kúrò Lọ́wọ́ “Ẹni Búburú Náà”

4, 5. (a) Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, kí ló béèrè fún nínú àdúrà tó gbà sí Jèhófà? (b) Kí nìdí tí ẹ̀bẹ̀ yìí fi bọ́gbọ́n mu?

4 Àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti yẹra fún bíbá ayé yìí dọ́rẹ̀ẹ́ nítorí wọ́n mọ̀ pé ètò nǹkan ìsinsìnyí kò lè fúnni ní ohunkóhun tó jẹ́ ojúlówó. (Jákọ́bù 4:4) Ǹjẹ́ o wà lára àwọn ọ̀dọ́ olóòótọ́ wọ̀nyí? Tó o bá wà lára wọn, a gbóṣùbà fún ọ. Lóòótọ́, kò rọrùn láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe àti láti dá yàtọ̀ láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àmọ́ ẹnì kan wà tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

5 Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù kú, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà “máa ṣọ́” àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun “nítorí ẹni burúkú náà.” (Jòhánù 17:15) Ó nídìí pàtàkì tí Jésù fi bẹ ẹ̀bẹ̀ yìí. Ó mọ̀ pé títọ ipa ọ̀nà ìwà títọ́ ò ní í rọrùn fáwọn ọmọlẹ́yìn òun, lọ́mọdé àti lágbà. Kí nìdí? Gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, ìdí kan ni pé, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ á kojú ọ̀tá alágbára tí kò ṣeé fojú rí nì—ìyẹn “ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. Bíbélì sọ pé ẹ̀dá ẹ̀mí búburú yìí, “ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pétérù 5:8.

6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Sátánì ò lójú àánú kankan fáwọn èwe?

6 Jálẹ̀ ìtàn ni inú Sátánì ti máa ń dùn sí híhu ìwà ìkà bíburú jáì sí ẹ̀dá ènìyàn. Ronú nípa àjálù burúkú tí Sátánì mú bá Jóòbù àti ìdílé rẹ̀. (Jóòbù 1:13-19; 2:7) Bóyá o lè rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lákòókò tó ò ń gbé yìí tó fi ọṣẹ́ tí ẹ̀mí búburú Sátánì ń ṣe hàn. Èṣù ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ káàkiri bí olè, bó ṣe ń wá ẹni tí yóò pa jẹ, kò sì ṣàánú àwọn èwe rárá. Bí àpẹẹrẹ, níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Hẹ́rọ́dù gbìmọ̀ láti pa gbogbo ọmọdékùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù láti ọmọ ọdún méjì sísàlẹ̀. (Mátíù 2:16) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Sátánì ló mú kí Hẹ́rọ́dù ṣe bẹ́ẹ̀—níbi tó ti ń sapá láti pa ọmọ tó jẹ́ pé lọ́jọ́ kan, ó máa di Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, ó sì máa mú ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí Sátánì! (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ó ṣe kedere pé, Sátánì ò ní ojú àánú kankan fáwọn ọ̀dọ́. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí ẹ̀ ni pé kó pa gbogbo ẹni tó bá ṣeé ṣe fún un láti pa. Bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an nìyẹn, àgàgà lákòókò tá a wà yìí, nítorí pé a ti lé Sátánì kúrò ní ọ̀run wá sí ilẹ̀ ayé, “ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣípayá 12:9, 12.

7. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ pátápátá sí Sátánì? (b) Báwo lọ̀rọ̀ bó o ṣe máa gbádùn ìgbésí ayé ṣe rí lára Jèhófà?

7 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Sátánì tó ní “ìbínú ńlá,” Jèhófà ní “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.” (Lúùkù 1:78) Òun gan-an ni àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá kan ọ̀ràn ìfẹ́. Àní sẹ́, Ẹlẹ́dàá wa fi ànímọ́ yìí hàn lọ́nà tó ga débi tí Bíbélì fi sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) O ò rí i pé ìyàtọ̀ díẹ̀ kọ́ ló wà láàárín ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí àti Ọlọ́run tó o láǹfààní láti sìn! Nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni Sátánì ń wá ẹni tó máa pa jẹ, Jèhófà ní tiẹ̀ “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.” (2 Pétérù 3:9) Ó ka ẹ̀mí gbogbo èèyàn sí ohun iyebíye—àti ẹ̀mí tìẹ náà pẹ̀lú. Nígbà tí Jèhófà gbà ọ́ níyànjú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kó o má ṣe jẹ́ apá kan ayé, kì í ṣe pé ó fẹ́ fi adùn ìgbésí ayé dù ọ́ tàbí pé kò fẹ́ kó o wà lómìnira ara rẹ. (Jòhánù 15:19) Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ńṣe ló ń ṣọ́ ẹ nítorí ẹni burúkú náà. Baba rẹ ọ̀run fẹ́ kó o ní ohun kan tó dáa ju afẹ́ ayé yìí tí kì í tọ́jọ́ lọ. Ohun tó fẹ́ ni pé kó o jèrè “ìyè tòótọ́”—ìyẹn ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (1 Tímótì 6:17-19) Jèhófà fẹ́ kó o yege, kó o sì mókè. (1 Tímótì 2:4) Síwájú sí i, Jèhófà tún nawọ́ ohun pàtàkì kan sí ọ. Kí ni ohun náà?

“Mú Ọkàn-Àyà Mi Yọ̀”

8, 9. (a) Irú ẹ̀bùn wo lo lè fún Jèhófà? (b) Báwo ni Sátánì ṣe ń ṣáátá Jèhófà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i nínú ọ̀ràn Jóòbù?

8 Ǹjẹ́ o ti ra ẹ̀bùn fún ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan rí, tó o wá rí i bí ọ̀rẹ́ rẹ ṣe bú sẹ́rìn-ín pẹ̀lú ìyàlẹ́nu tó sì fi ìmọrírì hàn gan-an nígbà tí ẹ̀bùn náà tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́? Ó ṣeé ṣe kó ti gbà ọ́ lákòókò gan-an kó o tó mọ irú ẹ̀bùn tó yẹ kó o rà fún onítọ̀hún. Wáá gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò: Irú ẹ̀bùn wo lo lè fún Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá rẹ? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, èrò pé kó o fún un ní nǹkan lè kọ́kọ́ dà bí èyí tí kò bọ́gbọ́n mu. Kí ni Olódùmarè fẹ́ gbà lọ́wọ́ ẹ̀dà ènìyàn lásánlàsàn? Kí lo fẹ́ fún un tí ò ti ní tẹ́lẹ̀? Bíbélì dáhùn nínú Òwe 27:11 pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.”

9 Ó ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ò ń kọ́ ti jẹ́ kó o mọ̀ pé Sátánì Èṣù lẹni tó ń ṣáátá Jèhófà. Ó sọ pé ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan ló ń jẹ́ káwọn èèyàn sin Ọlọ́run, pé kì í ṣe nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Sátánì tún sọ pé tọ́wọ́ ìyà bá tẹ àwọn èèyàn, kíá ni wọ́n máa fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Sátánì sọ fún Jèhófà nípa Jóòbù ọkùnrin olódodo nì yẹ̀ wò, ó ní: “Ìwọ fúnra rẹ kò ha ti ṣe ọgbà ààbò yí i ká, àti yí ilé rẹ̀ ká, àti yí ohun gbogbo tí ó ní ká? Ìwọ ti bù kún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, àní ohun ọ̀sìn rẹ̀ ti tàn káàkiri ilẹ̀. Ṣùgbọ́n, fún ìyípadà, jọ̀wọ́, na ọwọ́ rẹ, kí o sì fọwọ́ kan ohun gbogbo tí ó ní, kí o sì rí i bóyá kì yóò bú ọ ní ojú rẹ gan-an.”—Jóòbù 1:10, 11.

10. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé kì í ṣe Jóòbù nìkan ni Sátánì pe ìwà títọ́ rẹ̀ níjà? (b) Báwo ni ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ ṣe kàn ọ́?

10 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn Bíbélì fi hàn, kì í ṣe ìdúróṣinṣin Jóòbù nìkan ni Sátánì pè níjà, àmọ́ ó tún gbé ìpèníjà dìde sí ìdúróṣinṣin gbogbo àwọn mìíràn tó ń sin Ọlọ́run—títí kan ìwọ alára. Àní nígbà tí Sátánì ń sọ̀rọ̀ nípa ìran ènìyàn lápapọ̀, ó sọ fún Jèhófà pé: “Ohun gbogbo tí ènìyàn [tó túmọ̀ sí pé kì í ṣe Jóòbù nìkan àmọ́ ẹnikẹ́ni] bá sì ní ni yóò fi fúnni nítorí ọkàn rẹ̀.” (Jóòbù 2:4) Ǹjẹ́ o ríbi tó kàn ọ́ nínú ọ̀ràn pàtàkì yìí? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé Òwe 27:11 fi hàn, Jèhófà ń sọ pé ohun kan wà tó o lè fún òun—ìyẹn ni ohun tó máa jẹ́ kóun lè fún Sátánì tó ń ṣáátá òun lésì. Fojú inú wò ó ná, pé Ọba Aláṣẹ Ọ̀run òun Ayé ń ké sí ọ pé kó o wá nípìn-ín nínú yíyanjú ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì jù lọ. O ò rí i pé àgbàyanu ẹrù iṣẹ́ àti àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ rèé! Ǹjẹ́ o lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe? Jóòbù ṣe é. (Jóòbù 2:9, 10) Bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù, àti àìmọye àwọn ẹlòmíràn jálẹ̀ ìtàn, títí kan ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ pàápàá. (Fílípì 2:8; Ìṣípayá 6:9) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ohun tó o gbọ́dọ̀ mọ̀ dájú ni pé, ọ̀rọ̀ kò-ṣeku-kò-ṣẹyẹ kọ́ lọ̀ràn yìí o. Ìwà àti ìṣe rẹ ló máa fi hàn bóyá ìṣáátá Sátánì lo fara mọ́ tàbí èsì Jèhófà. Èwo lo máa gbárùkù tì níbẹ̀?

Jèhófà Bìkítà fún Ọ!

11, 12. Ǹjẹ́ ó já mọ́ ohunkóhun fún Jèhófà, yálà o yàn láti sìn ín tàbí o kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣàlàyé.

11 Ǹjẹ́ yíyàn yòówù kó o ṣe tiẹ̀ já mọ́ ohunkóhun lójú Jèhófà? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ olóòótọ́ ò ti pọ̀ tó fún un láti fún Sátánì lésì tó yẹ? Lóòótọ́, Èṣù sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó ń fi ìfẹ́ ara rẹ̀ sin Jèhófà, a sì ti rí i pé irọ́ gbuu lọ̀rọ̀ yẹn. Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ kó o wà lọ́dọ̀ òun gbágbáágbá nínú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ, nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ. Jésù sọ pé: “Kì í ṣe ohun tí Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ní ìfẹ́-ọkàn sí, pé kí ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí ṣègbé.”—Mátíù 18:14.

12 Ó ṣe kedere pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ipa ọ̀nà tó o bá yàn láti tọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ipa tó o bá yàn tún ń nípa lórí rẹ̀. Bíbélì jẹ́ kó yéni kedere pé Jèhófà ní ìmọ̀lára tó ga, èyí tí ìgbésẹ̀ rere tàbí búburú táwọn èèyàn bá gbé máa ń jẹ́ ká mọ̀ bó ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ, ó “dun” Jèhófà nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣọ̀tẹ̀ léraléra. (Sáàmù 78:40, 41) Bẹ́ẹ̀ náà ló ‘dun Jèhófà ní ọkàn-àyà’ nígbà tí “ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu,” ṣáájú Àkúnya Omi ọjọ́ Nóà. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 6) Ronú nípa ohun tí èyí túmọ̀ sí. Ìyẹn ni pé o lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá Ẹlẹ́dàá rẹ tó o bá yan ipa ọ̀nà búburú. Èyí ò wá túmọ̀ sí pé ẹni tó tutù jù lẹ́dàá ni Ọlọ́run tàbí pé bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀ ò jẹ́ kó mọ ohun tó ń ṣe. Dípò ìyẹn, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó sì fẹ́ ọ fẹ́re. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ọkàn Jèhófà máa ń yọ̀ nígbà tó o bá ṣe ohun tó tọ́. Kì í ṣe tìtorí pé á túbọ̀ rí èsì fún Sátánì nìkan ni inú rẹ̀ ṣe ń dùn, àmọ́ nítorí pé ìyẹn á jẹ́ kó lè di Olùsẹ̀san fún ọ. Ohun tó sì wù ú láti jẹ́ gan-an nìyẹn. (Hébérù 11:6) O ò rí i pé Baba onífẹ̀ẹ́ gidi ni Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ fún ọ!

Ìbùkún Yàbùgà-Yabuga Nísinsìnyí

13. Báwo ni sísin Jèhófà ṣe ń mú ìbùkún wá nísinsìnyí?

13 Kì í ṣe ọjọ́ iwájú nìkan lèèyàn tó lè gbádùn àwọn ìbùkún tó ń wá látinú sísin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń gbádùn ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ nísinsìnyí, èyí sì yẹ bẹ́ẹ̀. Onísáàmù kọ̀wé pé: “Àwọn àṣẹ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Jèhófà dúró ṣánṣán, wọ́n ń mú ọkàn-àyà yọ̀.” (Sáàmù 19:8) Jèhófà mọ ohun tó dára fún wa ju ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí lọ. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:17, 18.

14. Báwo làwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ìbànújẹ́ tí gbèsè jíjẹ máa ń fà?

14 Títẹ̀lé àwọn ìlànà Bíbélì yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ àti ìrora ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó “ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:9, 10) Ǹjẹ́ a rí èyíkéyìí lára àwọn ojúgbà rẹ tó ti fojú winá ohun tí Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ? Gbèsè táwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin kan ti jẹ sọ́rùn ò ṣeé fẹnu sọ, kìkì nítorí pé wọ́n fẹ́ ní aṣọ tó lòde àtàwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe jáde. Ìsìnrú tí ń fa ìbànújẹ́ gidi ló máa ń yọrí sí tó o bá jẹ gbèsè ọlọ́jọ́ gbọọrọ tó máa jẹ́ kó o san èléwó tó ga nítorí àtiní ohun tọ́wọ́ rẹ ò ká!—Òwe 22:7.

15. Ọ̀nà wo làwọn ìlànà Bíbélì gbà ń dáàbò bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ ìbànújẹ́ tó ń tinú ìwà pálapàla láàárín takọtabo jáde?

15 Tún gbé ọ̀ràn ìwà pálapàla láàárín takọtabo yẹ̀ wò. Àìlóǹkà àwọn ọ̀dọ́langba tí kò ṣègbéyàwó ló ń lóyún jákèjádò ayé lọ́dọọdún. Àwọn kan ń bímọ tí ò wù wọ́n láti bí tí wọn ò sì lágbára láti tọ́. Àwọn mìíràn máa ń ṣẹ́ oyún tiwọn, ẹ̀rí ọkàn wọn sì máa ń dà wọ́n láàmù. Bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin kan tún ń kó àwọn àrùn tí ń ranni nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, ọ̀kan lára wọn ni àrùn éèdì. Àmọ́, ohun búburú jù lọ tó máa tibẹ̀ jáde fẹ́ni tó mọ Jèhófà ni pé àjọṣe àárín òun àti Jèhófà á bà jẹ́. b (Gálátíà 5:19-21) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Sísin “Ọlọ́run Aláyọ̀”

16. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ kó o gbádùn ìgbà èwe rẹ? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ fún ọ láti tẹ̀ lé?

16 Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Ó fẹ́ kíwọ náà máa fìdùnnú ṣayọ̀. Kódà, Ọ̀rọ̀ òun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Gbádùn ìgbà èwe rẹ̀. Máa yọ̀ nígbà tó o ṣì wà léwe.” (Oníwàásù 11:9, Today’s English Version) Àmọ́, Jèhófà ríran kọjá àkókò tó o wà yìí, ó sì lè mọ àwọn àbájáde ọlọ́jọ́ gbọọrọ tó máa tẹ̀yìn ìwà rere àti búburú jáde. Ìdí nìyẹn tó fi gbà ọ́ níyànjú pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin, kí àwọn ọjọ́ oníyọnu àjálù tó bẹ̀rẹ̀ sí dé, tàbí tí àwọn ọdún náà yóò dé nígbà tí ìwọ yóò wí pé: ‘Èmi kò ní inú dídùn sí wọn.’”—Oníwàásù 12:1.

17, 18. Báwo ni Kristẹni ọ̀dọ́ kan ṣe fi ayọ̀ tó ní nínú sísin Jèhófà hàn, báwo ni ìwọ náà ṣe lè nírú ayọ̀ bẹ́ẹ̀?

17 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti rí ayọ̀ púpọ̀ nínú sísin Jèhófà lóde òní. Bí àpẹẹrẹ, Lina, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sọ pé: “Mo wẹ̀ mo yán kàn-ìnkàn. Ara mi le koko nítorí pé n kì í mu sìgá, n kì í sì í lo oògùn olóró. Mo ní àwọn ìlànà ṣíṣeyebíye tí mò ń rí gbà látinú ìjọ, èyí tó ń ràn mí lọ́wọ́ láti dènà ipa búburú ti Sátánì. Inú mi ń dùn ṣìnkìn nítorí ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin tí mò ń ní ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lékè gbogbo rẹ̀, mo tún ní ìfojúsọ́nà tí kò láfiwé ti gbígbádùn ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé.”

18 Bíi ti Lina, ọ̀pọ̀ Kristẹni ọ̀dọ́ ló ń ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́, èyí sì ń fún wọn láyọ̀. Wọ́n mọ̀ pé bí ìgbésí ayé àwọn tiẹ̀ kún fún ìṣòro àti pákáǹleke nígbà mìíràn, síbẹ̀ ó ní ète tó ṣe gúnmọ́ àti ọjọ́ iwájú tó nítumọ̀. Nítorí náà, máa bá a lọ láti sin Ọlọ́run tí ire rẹ jẹ lógún gan-an. Mú ọkàn rẹ̀ yọ̀, òun náà yóò sì mú ọ láyọ̀ nísinsìnyí àti títí láé!—Sáàmù 5:11.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ “Òtítọ́ Fún Mi Ní Ìwàláàyè Mi Padà,” tó wà nínú ẹ̀dà ìwé ìròyìn Jí! ti October 22, 1996.

b Ó tuni nínú láti mọ̀ pé nígbà tẹ́nì kan bá ronú pìwà dà, tó jáwọ́ nínú ṣíṣe ibi, tó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, Jèhófà ‘yóò dárí jì í lọ́nà títóbi.’—Aísáyà 55:7.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ewu wo lò ń dojú kọ látọ̀dọ̀ Sátánì, “ẹni burúkú náà”?

• Báwo lo ṣe lè mú ọkàn Jèhófà yọ̀?

• Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà bìkítà nípa rẹ?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún tó ń wá látinú sísin Jèhófà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Díẹ̀ Ló Kù Kí Ọkùnrin Olódodo Kan Kọsẹ̀

Ọmọ Léfì kan tó jẹ́ gbajúmọ̀ olórin ni Ásáfù nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ó tiẹ̀ kọ orin kan tí wọ́n máa ń lò fún ìjọsìn ní gbogbo gbòò. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tí Ásáfù ní yìí, ìgbà kan wà tọ́kàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ìwà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run táwọn ojúgbà rẹ̀ ń hù, ìyẹn àwọn tó dà bíi pé wọ́n ń rú òfin Ọlọ́run láìsí ohun tó tẹ̀yìn rẹ̀ jáde. Ásáfù jẹ́wọ́ níkẹyìn pé: “Ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà, díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́. Nítorí ti èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo, nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.”—Sáàmù 73:2, 3.

Nígbà tó yá, Ásáfù lọ sí ibùjọsìn Ọlọ́run, ó sì gbàdúrà nípa ọ̀ràn náà. Pẹ̀lú àkọ̀tun èrò tẹ̀mí tó ní, ó wá lóye pé Jèhófà kórìíra ìwà búburú, àti pé láìpẹ́, àti ẹni búburú àti olódodo ló máa ká ohun tí wọ́n gbìn. (Sáàmù 73:17-20; Gálátíà 6:7, 8) Ní ti tòótọ́, orí ilẹ̀ yíyọ̀ ni àwọn ẹni ibi wà. Bópẹ́ bóyá, wọ́n á ṣègbé nígbà tí Jèhófà bá pa ètò aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí run.—Ìṣípayá 21:8.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ire rẹ jẹ Jèhófà lógún gan-an, àmọ́ ńṣe ni Sátánì ń wá bóun ṣe máa pa ọ́ jẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń rí ayọ̀ tó ga nípa sísin Jèhófà pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn