Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìsapá Mi Nínú Ìtẹ̀síwájú Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Kárí Ayé

Ìsapá Mi Nínú Ìtẹ̀síwájú Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Kárí Ayé

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Ìsapá Mi Nínú Ìtẹ̀síwájú Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì Kárí Ayé

GẸ́GẸ́ BÍ ROBERT NISBET ṢE SỌ Ọ́

Tẹ̀ríntẹ̀yẹ ni Ọba Sobhuza Kejì ti Swaziland fi kí èmi àti George àbúrò mi káàbọ̀ sí ààfin rẹ̀. Ọdún 1936 lọ̀rọ̀ ọ̀hún wáyé àmọ́ mo ṣì rántí àwọn nǹkan tá a jíròrò dáadáa. Ìdí tí mo fi lè bá ọba sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn báyìí jẹ́ ara iṣẹ́ bàǹtàbanta ti kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo ti ń ṣe bọ̀ látọjọ́ pípẹ́. Ní báyìí tí mo ti di ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún, ńṣe ni inú mi máa ń dùn bí mo bá bojú wẹ̀yìn wo ìsapá mi nínú iṣẹ́ náà, èyí tó ti gbé mi dé ibi márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lára ibi méje tá a pín ilẹ̀ ayé sí.

ỌDÚN 1925 lọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ nígbà tí ọ̀gbẹ́ni kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dobson, tó ń ta tíì bẹ̀rẹ̀ sí wá sílé wa nílùú Edinburgh, ní Scotland. Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún nígbà yẹn, mo sì ń kọ́ṣẹ́ oògùn títà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré díẹ̀, síbẹ̀ mo máa ń ṣe kàyéfì nípa ìyípadà ńláǹlà tí ogun àgbáyé tó jà lọ́dún 1914 sí ọdún 1918 ti fà fáwọn ìdílé, ẹ̀sìn àti ìgbòkègbodò àwọn èèyàn. Nígbà kan tí Ọ̀gbẹ́ni Dobson wá sílé wa, ó fún wa ní ìwé The Divine Plan of the Ages. Bí ìwé náà ṣe sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá kan tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́nlóye tó sì ní “ìpinnu” kan pàtó dà bí ohun tó bọ́gbọ́n mu gan-an lójú mi, irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ló sì wù mí láti sìn.

Kò pẹ́ tí èmi àti Màmá fi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. September ọdún 1926 ni èmi àti Màmá ṣe ìrìbọmi ní àpéjọ kan tá a ṣe ní Glasgow, láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà hàn. Wọ́n fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa tá a fẹ́ ṣèrìbọmi ní ẹ̀wù kan tó balẹ̀ dẹ́dẹ́, pé ká wọ̀ ọ́ sórí aṣọ tá a máa fi wọ odò ìrìbọmi. Irú aṣọ gígùn yìí la kà sí aṣọ tó bẹ́tọ̀ọ́ mu fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì bẹ́ẹ̀.

Láwọn àkókò ìbẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn, a ò fi bẹ́ẹ̀ ní òye tó kún tó lórí àwọn ọ̀ràn kan. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo wa pátá ló ń bá wọn ṣọdún Kérésìmesì. Ìwọ̀nba díẹ̀ ló ń lọ sóde ẹ̀rí. Kódà, àwọn alàgbà kan tiẹ̀ yarí pé pípín ìwé ìròyìn lọ́jọ́ Sunday kò tọ̀nà, pé ó lòdì sí Sábáàtì. Àmọ́ ṣá, àwọn àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́ ti ọdún 1925, bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Máàkù 13:10, tó sọ pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.”

Báwo la ṣe máa ṣe iṣẹ́ tí a ó ṣe jákèjádò ayé náà láṣeyọrí? Ìgbà àkọ́kọ́ tí mo wàásù láti ilé dé ilé, ńṣe ni mo kàn sọ fún onílé pé àwọn ìwé ẹ̀sìn tó dára ni mò ń tà káàkiri, mo sì fún un ní ìwé Duru Ọlọrun, tó ṣàlàyé ẹ̀kọ́ pàtàkì mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì tó sì fi wọ́n wé wáyà tín-ín-rín mẹ́wàá tó máa ń wà lára dùrù. Nígbà tó yá, wọ́n fún wa ní káàdì ìjẹ́rìí, èyí tá a kọ ọ̀rọ̀ ṣókí sínú rẹ̀ tí onílé á kà. A tún lo ọ̀rọ̀ oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin àtààbọ̀ tá a ti gbà sílẹ̀, tá a lè fi ẹ̀rọ giramafóònù kékeré gbọ́. Àwọn ẹ̀rọ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe jáde yìí sì wúwo bí nǹkan míì, àmọ́ àwọn tí wọ́n ṣe jáde nígbà tó yá ò fi bẹ́ẹ̀ wúwo, a tiẹ̀ lè gbé àwọn mìíràn lóòró ká sì máa gbọ́ ọ̀rọ̀ tá a gbà sílẹ̀ nínú wọn.

Ọ̀nà tá a gbà pé ó dára jù lọ lójú wa la gbà ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí náà látọdún 1925 títí dé àwọn ọdún 1930. Nígbà tó sì di ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, a dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ ní gbogbo ìjọ. Wọ́n kọ́ wa ní bí àwa fúnra wa ṣe lè wàásù ìhìn Ìjọba náà nípa bíbá àwọn onílé tó bá fẹ́ gbọ́ sọ̀rọ̀ ní tààràtà. Bákan náà la tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ṣe pàtàkì láti máa bá àwọn tó bá fìfẹ́ hàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A ò ṣì sọ tá a bá sọ pé àkókò yìí ni iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń ṣe báyìí ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀.

Ìṣírí Látọ̀dọ̀ Arákùnrin Rutherford

Ìfẹ́ tí mo ní láti túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún lọ́dún 1931. Ẹ̀yìn tá a bá parí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe nílùú London ló yẹ kí n bẹ̀rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Àmọ́ lọ́jọ́ kan tá a fẹ́ lọ jẹun ọ̀sán, Arákùnrin Joseph Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ náà lákòókò yẹn lóun fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀. Ó ti ṣètò pé aṣáájú ọ̀nà kan á lọ sí ilẹ̀ Áfíríkà. Ló bá béèrè lọ́wọ́ mi pé: “Ṣé wàá lọ? Ìbéèrè ọ̀hún bá mi lójijì, àmọ́ mo dá a lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, màá lọ.”

Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wa nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni pé ká pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ gan-an fáwọn èèyàn, èyí ló ń mú wa ti ibì kan lọ síbòmíràn nígbà gbogbo. Wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n máà tíì fẹ́yàwó, bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tá a fún lẹ́rù iṣẹ́ ṣíṣàbójútó lákòókò náà. Ìlú Cape Town, tó wà níhà gúúsù ilẹ̀ Áfíríkà, tó sì lọ títí dé apá ìlà oòrùn rẹ̀ títí kan àwọn erékùṣù etíkun Òkun Íńdíà ni wọ́n yàn fún mi. Láti dé apá ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ mi, mo ní láti gba ibi Aṣálẹ̀ Kalahari tí yanrìn rẹ̀ máa ń gbóná janjan kọjá títí dé orísun Odò Náílì níbi Adágún Victoria. Lọ́dọọdún, èmi àti ẹnì kejì mi máa ń lo oṣù mẹ́fà gbáko ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà tó wà ní àgbègbè tó lọ salalu yìí.

Igba Páálí Tó Kún fún Ọrọ̀ Nípa Tẹ̀mí

Nígbà tí mo dé ìlú Cape Town, wọ́n fi igba páálí tó kún fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń lọ sí Ìlà Oòrùn Áfíríkà hàn mí. Èdè mẹ́rin láti ilẹ̀ Yúróòpù àti èdè mẹ́rin láti ilẹ̀ Éṣíà ni wọ́n fi tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àmọ́ kò sí ìkankan nínú wọn tí wọ́n fi èdè Áfíríkà kọ. Nígbà tí mo béèrè pé kí nìdí táwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fi wà níbẹ̀ kó tiẹ̀ tó di pé mo dé pàápàá, wọ́n sọ fún mi pé Frank Smith àti Gray Smith, àwọn aṣáájú ọ̀nà méjì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sí Kẹ́ńyà láti lọ wàásù ni wọ́n fẹ́ fàwọn ìwé náà ránṣẹ́ sí tẹ́lẹ̀. Kò pẹ́ rárá tí wọ́n dé Kẹ́ńyà tí àrùn ibà fi kọlu àwọn méjèèjì, ó sì dunni pé ẹ̀mí Frank lọ sí i.

Ìròyìn tí mo gbọ́ yìí bà mí nínú jẹ́ gan-an àmọ́ kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi rárá. Èmi àti ẹnì kejì mi, ìyẹn David Norman, wọ ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Cape Town lọ sí ibi àkọ́kọ́ tí wọ́n yàn fún wa ní orílẹ̀-èdè Tanzania tó jìnnà tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] kìlómítà. Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń báwọn èèyàn ṣètò ìrìn àjò nílùú Mombasa, ní Kẹ́ńyà ló bá wa tọ́jú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tó sì ń fi wọ́n ránṣẹ́ sí ibikíbi tá a bá ní kó fi ránṣẹ́ sí. Nígbà tá a kọ́kọ́ débẹ̀, àwọn ibi okòwò—ìyẹn àwọn ilé ìtajà àtàwọn ọ́fíìsì tó wà nílùú kọ̀ọ̀kan la ti máa ń wàásù. Lára àwọn ìwé tá à ń gbà láti fi ṣiṣẹ́ lóde ni ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́sàn-án àti ìwé pẹlẹbẹ mọ́kànlá tí wọ́n máa ń dì pọ̀ ránṣẹ́, àwọn èèyàn tiẹ̀ ń pè wọ́n ní aláwọ̀ òṣùmàrè nítorí oríṣiríṣi àwọ̀ tí wọ́n ní.

Nígbà tó ṣe, a múra láti lọ sí erékùṣù Zanzibar, tó fi ọgbọ̀n kìlómítà jìnnà sí etíkun tó wà lápá ìlà oòrùn. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni ìlú Zanzibar fi jẹ́ ibùdó òwò ẹrú àmọ́ èso clove pọ̀ bí nǹkan míì níbẹ̀, èyí sì máa ń já fíkán káàkiri ìlú náà. Kò rọrùn rárá láti mọ̀nà láàárín ìgboro nítorí pé ńṣe làwọn èèyàn kàn kọ́lé wọnú ara wọn káàkiri. Ńṣe làwọn òpópónà wọnú ara wọn tó sì máa ń dà rú mọ́ èèyàn lójú, ọ̀pọ̀ ìgbà la tiẹ̀ máa ń ṣìnà. Gbogbo ohun amáyédẹrùn ló wà nínú òtẹ́ẹ̀lì tá à ń gbé, àmọ́ àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ tó rí gìrìwò-gìrìwò àti odi fàkìàfakia tí wọ́n mọ yí i ká kò jẹ́ kó jọ òtẹ́ẹ̀lì mọ́, ńṣe ló dà bí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Síbẹ̀, àwọn nǹkan rere ti ìlú náà jáde, inú wa sì dùn pé àwọn Lárúbáwá, àwọn ará Íńdíà àtàwọn mìíràn gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Ọkọ̀ Ojú Irin, Ọkọ̀ Òbèlè àti Ọkọ̀ Ayọ́kẹ́lẹ́

Kò rọrùn rárá láti rìnrìn àjò ní apá Ìlà Oòrùn Áfíríkà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ kan tá à ń ti Mombasa lọ sáwọn ilẹ̀ olókè Kẹ́ńyà, ọkọ̀ ojú irin tó gbé wa ò lè lọ mọ́ nígbà tá a débi táwọn eéṣú ti bolẹ̀ pitimu. Ọ̀kẹ́ àìmọye eéṣú ti bo gbogbo ilẹ̀ náà bámúbámú wọ́n sì tún bo orí irin tí ọkọ̀ ojú irin ń gbà, àwọn irin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ tí ò fi ṣeé ṣe fún ọkọ̀ ojú irin láti gbabẹ̀ kọjá. Ohun kan ṣoṣo tá a lè ṣe ni pé kí wọ́n máa fi omi gbígbóná tó wà nínú ọkọ̀ náà fọ ojú irin kí ọkọ̀ náà tó gbabẹ̀ kọjá. Báyìí la ṣe wá ń lọ díẹ̀díẹ̀ títí a fi kọjá ibi tí àwọn eéṣú náà bò. Ara wá tù wá pẹ̀sẹ̀ nígbà tí ọkọ ojú irin tá a wọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gòkè sápá ibi tó túbọ̀ ga díẹ̀ tá a sì bẹ̀rẹ̀ sí gba afẹ́fẹ́ tútù sára láwọn ilẹ̀ olókè náà!

Kìkìdá ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ òbèlè lèèyàn lè wọ̀ dé àwọn ìlú tó wà létí omi, àmọ́ mọ́tò ló dára jù kéèyàn máa fi káàkiri àwọn ìgbèríko. Inú mi dùn gan-an nígbà tí George àbúrò mi wá bá mi níbí yìí, nítorí pé ìgbà tó dé la ra àlòkù ọkọ̀ kan tó nílé lẹ́yìn. Ilé ẹ̀yìn ọkọ̀ náà tóbi gan-an, a kó bẹ́ẹ̀dì sínú rẹ̀, a ṣe ilé ìdáná, ibi ìkóǹkan-sí àti fèrèsé tí kì í jẹ́ kí ẹ̀fọn ríbi wọlé sínú rẹ̀. A tún so ẹ̀rọ gbohùngbohùn mọ́ orí rẹ̀. Àwọn ohun èlò wọ̀nyí tí ọkọ̀ náà ní nínú ló mú ká lè máa wàásù láti ilé-dé-ilé lọ́sàn-án tá a sì ń ké sí àwọn èèyàn pé kí wọ́n wá gbọ́ àwọn àsọyé wa ní gbàgede ọjà lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. Àkọlé àwíyé tá a sábà máa ń gbé sí i káwọn èèyàn lè gbọ́ ni “Ṣé Ọ̀run Àpáàdì Gbóná?” A fi “ilé alágbèérìn” wa rin ìrìn àjò oníkìlómítà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] láti Gúúsù Áfíríkà lọ sí Kẹ́ńyà, inú wa sì dùn pé oríṣiríṣi ìwé pẹlẹbẹ tó jẹ tí àwọn èdè bíi mélòó kan ní Áfíríkà la ní lọ́wọ́ lásìkò yẹn, tìdùnnú-tìdùnnú làwọn aráàlú sì fi gbà wọ́n lọ́wọ́ wa.

Ohun kan tó máa ń múnú wa dùn bí a bá ń rin ìrìn àjò wọ̀nyí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ìgbẹ́ ti ilẹ̀ Áfíríkà la máa ń rí. Inú ọkọ̀ la máa ń wà tí ilẹ̀ bá ti ṣú nítorí àwọn ẹranko wọ̀nyí, àmọ́ rírí onírúurú àwọn ẹranko tí Jèhófà dá ní ibùgbé wọn ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an.

Inúnibíni Bẹ̀rẹ̀

Ńṣe là ń ṣọ́ra lójú méjèèjì nítorí àwọn ẹranko ìgbẹ́ náà, àmọ́ ṣá kékeré ni tiwọn jẹ́ tá a bá fi wéra pẹ̀lú bá a ṣe gbọ́dọ̀ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba àtàwọn aṣáájú ìsìn tí inú wọn ò dùn páàpáà tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàtakò ní gbangba sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tá à ń ṣe. Ìṣòro ńlá kan tá a kojú ni ti agánnigàn ẹ̀dá kan tó lóun ń jẹ́ Mwana Lesa, èyí tó túmọ̀ sí “Ọmọ Ọlọ́run.” Orúkọ ẹgbẹ́ tó dá sílẹ̀ ni Kitawala, èyí tó túmọ̀ sí “Watchtower.” Kó tó di pé àwa débẹ̀, kò lóǹkà àwọn ará Áfíríkà ni ọ̀gbẹ́ni yìí ti pa sómi níbi tó ti sọ pé òun ń ṣèrìbọmi fún wọn. Nígbà tó ṣe, ọwọ́ àwọn agbófinró tẹ̀ ẹ́ wọ́n sì yẹgi fún un. Nígbà tó yá, mo láǹfààní láti bá ẹni tó yẹgi fún ọ̀gbẹ́ni náà fọ̀rọ̀ wérọ̀, mo sì ṣàlàyé fún un pé kò sí àjọṣe èyíkéyìí láàárín ọ̀gbẹ́ni náà àti Watch Tower Society tiwa o.

Ìṣòro mìíràn tá a ní ni ti ọ̀pọ̀ àwọn ará Yúróòpù tí inú wọn ò dùn sí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa, ohun tó sì fà á ni ọ̀ràn olówó dé. Alábòójútó ilé ìkẹ́rùsí kan ṣàròyé pé: “Ohun tó lè mú káwọn aláwọ̀ funfun máà kúrò ní orílẹ̀-èdè yìí ni pé káwọn ará Áfíríkà máà mọ báwọn aláwọ̀ funfun náà ṣe ń rẹ́ wọn jẹ. Ìdí yìí kan náà ló mú kí ọ̀gá ilé iṣẹ́ ìwakùsà kan lé mi jáde nínú ọ́fíìsì rẹ̀ bí ẹní lé ajá. Tìbínú-tìbínú ló fi tẹ̀ lé mi títí mo fi já títì.

Nígbà tó wá yá, àwọn onísìn àtàwọn oníṣòwò tó ń ṣàtakò wa kó sí ìjọba Rhodesia (tó ti di Zimbabwe báyìí) lórí, wọ́n sì sọ pé ká káńgárá wa kúrò lórílẹ̀-èdè náà. A pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, ẹjọ́ náà sì gbè wá, ilé ẹjọ́ sọ pé ká jókòó wa àmọ́ ṣá a ò gbọ́dọ̀ wàásù fún àwọn ará Áfíríkà. Ọ̀kan lára àwọn aláṣẹ sọ pé ìdí èyí ni pé àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa “kì í ṣe ohun tó yẹ káwọn ará Áfíríkà máa kà.” Àmọ́ láwọn orílẹ̀-èdè Áfíríkà mìíràn, ẹnikẹ́ni ò dí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe láàárín àwọn ará Áfíríkà lọ́wọ́, kódà tọwọ́tẹsẹ̀ làwọn èèyàn fi gbà á. Swaziland jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀.

A Gbà Wá Lálejò Láàfin Ọba ní Swaziland

Orílẹ̀-èdè kékeré, tó jẹ́ olómìnira ni orílẹ̀-èdè Swaziland tó wà ní Gúúsù Áfíríkà. Ilẹ̀ rẹ̀ fẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún, ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [17,364] kìlómítà níbùú àti lóròó. Ibẹ̀ la ti rí Ọba Sobhuza Kejì, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, tí mo mẹ́nu bà níbẹ̀rẹ̀. Bí ilá lèdè òyìnbó yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, yunifásítì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó lọ ló ti kọ́ ọ. Aṣọ ìgbafẹ́ ló kàn wọ̀ sára, ó sì kí wa tọ̀yàyàtọ̀yàyà.

A bá a fọ̀rọ̀ wérọ̀ nípa Párádísè ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fáwọn ọlọ́kàn rere. Kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí kókó tá à ń jíròrò yẹn, ó sì sọ fún wa pé ọ̀rọ̀ kan wà tó ń gbé òun lọ́kàn. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí ọba yìí ni ọ̀nà tó máa gbà tún ìgbésí ayé àwọn òtòṣì àtàwọn tí ò kàwé ṣe. Ó kórìíra ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù ń ṣe, tó jẹ́ pé kò sóhun tó kàn wọ́n kan báwọn èèyàn á ṣe mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà, gbogbo tiwọn ò ju bí ọmọ ìjọ ṣe máa pọ̀ sí i. Àmọ́ ṣá, ọba yìí mọ̀ nípa ìgbòkègbodò àwọn kan lára àwọn aṣáájú ọ̀nà wa ó sì yìn wá fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe, pàápàá bá a ṣe ń ṣe é láìbéèrè owó tàbí àwọn ohun mìíràn.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì Ń Yára Kánkán

Lọ́dún 1943, a dá ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead sílẹ̀ láti máa dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Wọ́n tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti sapá gidigidi lórí gbogbo àwọn tó fìfẹ́ hàn kó má sì jẹ́ pé kìkì pípín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan la máa gbájú mọ́. Nígbà tó di ọdún 1950, wọ́n pe èmi àti George wá sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti Gílíádì. Ibẹ̀ ni mo ti kọ́kọ́ pàdé Jean Hyde, arábìnrin olùfọkànsìn tó wá láti Ọsirélíà, wọ́n yanṣẹ́ míṣọ́nnárì fún un ní Japan lẹ́yìn táwa méjèèjì kẹ́kọ̀ọ́ yege. Ní gbogbo ìgbà yẹn, wíwà ní àpọ́n gbayì lọ́pọ̀lọpọ̀, èyí ni ò jẹ́ kí ọ̀rẹ́ àwa méjèèjì lọ jìnnà.

Lẹ́yìn tí èmi àti George parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n yàn wá síṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Mauritius, ìyẹn erékùṣù kan tó wà ní apá Òkun Íńdíà. A mú àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, a kọ́ èdè wọn à sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó ṣe, àbúrò mi William àti ìyàwó rẹ̀ Muriel náà kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì. Ibi tí mo ti wàásù lọ́jọ́un àná, ìyẹn Kẹ́ńyà ni wọ́n rán wọn lọ.

Ọdún mẹ́jọ ti yára kọjá báyìí, ni mo bá tún pàdé Jean Hyde ní àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú New York lọ́dún 1958. A tún bẹ̀rẹ̀ ọ̀rẹ́ wa títí a fi bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ra sọ́nà. Iṣẹ́ míṣọ́nnárì tún gbé mi láti Mauritius lọ sí Japan, ibẹ̀ sì lèmi àti Jean ti ṣègbéyàwó lọ́dún 1959. La bá jọ fi ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílùú Hiroshima, tí ìjọ ibẹ̀ ò ju kékeré lọ nígbà yẹn. Lónìí, ìjọ mẹ́rìndínlógójì ló wà nílùú náà.

Japan, Ó Dìgbòóṣe

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, àìlera ara àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí mú kí iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ṣòro gan-an. Nígbà tó sì yá ó di pé ká kúrò ní Japan ká sì ṣí wá sí orílẹ̀-èdè tí Jean ti wá, ìyẹn Ọsirélíà. Ọjọ́ ìbànújẹ́ gbáà lọ́jọ́ tá a kúrò ní Hiroshima. Ní ibùdókọ̀ rélùwéè la ti juwọ́ sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n pé ó dìgbòóṣe.

Ọsirélíà la wà báyìí, a sì ń fi gbogbo agbára wa sin Jèhófà pẹ̀lú Ìjọ Armidale tó wà ní ìpínlẹ̀ New South Wales. Ẹ ò rí i pé ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ láti bá àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an ṣàjọpín ìṣúra òtítọ́ Kristẹni fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin ọdún! Mo ti rí i bí ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe tẹ̀ síwájú lọ́nà yíyanilẹ́nu, mo sì ti fúnra mi rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀mí tó gbàfiyèsí gan-an. Kò sí ẹnikẹ́ni tàbí àwùjọ àwọn kan tó lè sọ pé àwọn ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Ní ti gidi, kí n sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bíi ti onísáàmù náà, “ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá; ó jẹ́ àgbàyanu ní ojú wa.”—Sáàmù 118:23.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Àbúrò mi George àti ọkọ̀ tá a fi ṣe ilé wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Èmi rèé níbi Adágún Victoria

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí wọ́n wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní Swaziland lọ́dún 1938

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Èmi àti Jean lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1959 àti lónìí