Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ètò èyíkéyìí wà tá a lè ṣe tí Kristẹni ẹni àmì òróró kan tó jẹ́ aláìlera ò bá lè wá síbi tí ìjọ ti ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?

Bẹ́ẹ̀ ni o. Ohun tá a lè ṣe wà ó sì yẹ ká ṣe é láti fi ìgbatẹnirò hàn fún Kristẹni ẹni àmì òróró kan tó jẹ́ aláìlera bóyá tí àìsàn ò tiẹ̀ jẹ́ kó lè dìde ńlẹ̀ mọ́ pàápàá, tí èyí ò sì jẹ́ kó lè wá síbi tí ìjọ ti ń ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí alàgbà kan tàbí Kristẹni ọkùnrin kan tó dàgbà dénú gbé lára búrẹ́dì ìṣàpẹẹrẹ náà àti wáìnì lọ sọ́dọ̀ ẹni yẹn ní alẹ́ ọjọ́ náà kí oòrùn ọjọ́ kejì tó là.

Ó sinmi lórí bí ipò nǹkan bá ṣe rí, alàgbà tàbí arákùnrin tó lọ síbẹ̀ lè sọ̀rọ̀ ní ṣókí kó sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá yẹ. Ó lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀ nígbà tó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ka Mátíù 26:26, kó sì wá gbé búrẹ́dì aláìwú náà fún un lẹ́yìn tó bá ti gbàdúrà. Lẹ́yìn náà, arákùnrin tó lọ síbẹ̀ lè wá ka Mátíù orí 26, ẹsẹ 27 àti 28, kó gbàdúrà kó sì wá gbé wáìnì náà fún un. Ó lè sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ìjẹ́pàtàkì ohun ìṣàpẹẹrẹ kọ̀ọ̀kan, kó sì gba àdúrà ìparí.

Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti pésẹ̀ síbi tí ìjọ ti ń ṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Àmọ́ kí la lè ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ pé nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni ẹni àmì òróró kan lójijì, bóyá àìsàn gbé e dè, tàbí tó wà ní ilé ìwòsàn tàbí tí nǹkan mìíràn ṣẹlẹ̀ sí i tí ò fi lè wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní Nísàn 14? Irú ẹni àmì òróró bẹ́ẹ̀ lè tẹ̀lé ohun tí wọ́n máa ń ṣe lábẹ́ Òfin Mósè láyé àtijọ́, kó fúnra rẹ̀ ṣe ayẹyẹ ọ̀hún ní ọgbọ̀n ọjọ́ lẹ́yìn náà.—Númérì 9:9-14.