Téèyàn Bá Kà Á—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Yí Ìgbésí Ayé Ẹni Padà
“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Téèyàn Bá Kà Á—Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Yí Ìgbésí Ayé Ẹni Padà
KA SỌ pé o mọ Tony nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni, wàá rí i pé agánnigàn ọmọ ni, ìwà ipá rẹ̀ sì le kú. Àwọn àgbègbè tí kò yẹ ọmọlúàbí nílùú Sydney, ní Ọsirélíà ló máa ń lọ ṣáá. Ó sọ pé àwọn ọmọ ìta wà lára àwọn ọ̀rẹ́ òun. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń lọ fọ́lé, tí wọ́n á lọ bá ẹgbẹ́ ọmọ ìta mìíràn fìjà pẹẹ́ta, tí wọ́n á sì máa yìnbọn lu ara wọn láàárín ìgboro.
Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni Tony nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá. Nígbà tó fi máa di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí mu igbó, ìṣekúṣe sì ti wọ̀ ọ́ lẹ́wù. Lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, lílo oògùn olóró heroin ti mọ́ ọn lára, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bá a dédìí cocaine, àní Tony fúnra rẹ̀ tiẹ̀ sọ pé: “Ohunkóhun tó bá ṣáà ti lè pa mí bí ọtí ni mò ń mu.” Ló bá da òwò oògùn olóró pọ̀ pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú méjì kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó. Kò pẹ́ táwọn èèyàn fi mọ Tony gẹ́gẹ́ bíi gbajúmọ̀ nínú títa oògùn olóró ní etíkun ìlà oòrùn Ọsirélíà.
Nǹkan bí ọgọ́jọ [160] sí ọ̀rìn-dín-nírínwó [320] dọ́là ni Tony fi ń ra oògùn olóró heroin àti igbó tó ń mu lójúmọ́. Àmọ́ wàhálà tí èyí ń kó bá ìdílé rẹ̀ kúrò ní kèrémí. Ó sọ pé: “Àìmọye ìgbà làwọn ọ̀daràn ti gbé ìbọn àti ọ̀bẹ sí èmi àti ìyàwó mi létí nígbà tí wọ́n wá kó oògùn olóró àti owó tó wà nílé wa.” Lẹ́yìn tí Tony ti lọ sẹ́wọ̀n lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó wá ronú pé ó yẹ kóun tún inú rò nípa ibi tí ìgbésí ayé òun dorí kọ.
Lóòótọ́ ni Tony kì í pa ṣọ́ọ̀ṣì jẹ, àmọ́ ó rí i pé òun ò sún mọ́ Ọlọ́run tó rò pé ó máa ń finá dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lóró títí láé ní ọ̀run àpáàdì. Àmọ́ nígbà tí tọkọtaya kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé ọ̀dọ̀ Tony, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé kì í ṣe bóun ṣe ronú pé Ọlọ́run rí ló rí. Inú Tony wá dùn pé ó ṣeé ṣe fóun láti tún ìgbésí ayé òun ṣe kóun sì rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ wú Tony lórí gan-an, pé: “Ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.” (Máàkù 10:27) Ọ̀rọ̀ oníṣìírí tó tiẹ̀ wú Tony lórí jù lọ lèyí tó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Ìṣòro tí Tony wá ní báyìí ni bó ṣe máa mú ìgbésí ayé rẹ̀ bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Ó sọ pé: “Ohun àkọ́kọ́ tí mo fi sílẹ̀ ni sìgá mímu, nǹkan tí mo ti gbìyànjú àtiṣe lọ́pọ̀ ìgbà tẹ́lẹ̀ àmọ́ tí mi ò lè jáwọ́ nínú rẹ̀. Pẹ̀lú agbára tí Jèhófà fún mi, mo jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró heroin àti igbó, àwọn egbòogi olóró tó ti di bárakú sí mi lára láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Mi ò mọ̀ pé mà á lè jáwọ́ nínú àṣà yìí láé.”
Dípò bíbẹ̀rù Ọlọ́run táwọn kan sọ pé ó ń dáni lóró títí ayé ní ọ̀run àpáàdì—ẹ̀kọ́ tí ò sí níbì kankan nínú Bíbélì—ńṣe ni Tony àti ìyàwó rẹ̀ yáa tẹ́wọ́ gba ìrètí gbígbé títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:10, 11; Òwe 2:21) Tony sọ pé: “Ó gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá ńláǹlà kí n tó lè mú ìgbésí ayé mi bá ìlànà Ọlọ́run mu, àmọ́ pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Jèhófà, èyí ti ṣeé ṣe.”
Ẹ ò ri nǹkan, ajoògùnyó tẹ́lẹ̀ yìí ti di Kristẹni báyìí o. Òun àti ìyàwó rẹ̀ ń yọ̀ǹda àkókò àti ohun ìní wọn nípa tara, wọ́n sì ti lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún wákàtí láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún ń tọ́ àwọn ọmọ méjì tó bẹ̀rù Ọlọ́run. Agbára tó ju agbára lọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní ló mú kí ìyípadà tó kàmàmà yìí ṣeé ṣe. Àní, òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Pẹ̀lú irú àwọn àpẹẹrẹ dáradára báyìí, àwọn kan ṣì ń fi dúdú pe funfun o, tí wọ́n ń sọ pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ń da ìdílé rú, ó sì ń jẹ́ káwọn èwe hùwà ìbàjẹ́. Àpẹẹrẹ Tony fi hàn pé irọ́ funfun báláú ni èrò yìí.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ bíi ti Tony, tí wọ́n sì ti rí i pé àwọ́n lè jáwọ́ nínú àwọn nǹkan bárakú tó lè gbẹ̀mí ẹni. Lọ́nà wo? Nípa níní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti gbígbára lé e àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti nípa àtìlẹ́yìn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa onífẹ̀ẹ́. Pẹ̀lú ìdùnnú ni Tony fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Mo ti rí bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe dáàbò bo àwọn ọmọ mi. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ni kò jẹ́ kí ìgbéyàwó mi tú ká. Àwọn aládùúgbò mi sì ti ń sùn dáadáa báyìí nítorí pé n kì í kó wọn lọ́kàn sókè mọ́.”
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
‘Jèhófà ló fún mi lágbára tí mo fi lè jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró tí mo ti ń bá bọ̀ láti ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn’
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Gbéṣẹ́
Ọ̀kan-kò-jọ̀kan àwọn ìlànà Bíbélì ti ran àwọn ajoògùnyó lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àṣà tó ń sọni dìdàkudà yìí. Lára àwọn ìlànà náà rèé:
“Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Lílo oògùn olóró kò bá òfin Ọlọ́run mu.
“Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” (Òwe 9:10) Bíbẹ̀rù Jèhófà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye rẹ̀ àti ọ̀nà rẹ̀ ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró.
“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Èèyàn lè jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ń sọni dìdàkudà nípa gbígbọ́kàn lé Ọlọ́run àti gbígbára lé e pátápátá.