Máa Fi Ohun Tó o Ti Kọ́ Sílò
Máa Fi Ohun Tó o Ti Kọ́ Sílò
“Àwọn ohun tí ẹ kẹ́kọ̀ọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi, ẹ máa fi ìwọ̀nyí ṣe ìwà hù; Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.”—FÍLÍPÌ 4:9.
1, 2. Lápapọ̀, ǹjẹ́ Bíbélì ń sa ipá kankan nínú ìgbésí ayé àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ onísìn? Ṣàlàyé.
“ÌSÌN Ń Pọ̀ Sí I, àmọ́ Ìwà Rere Ń Dín Kù.” Àkọlé yìí tó wà nínú lẹ́tà ìròyìn Emerging Trends, ló ṣe àkópọ̀ àbájáde ìwádìí tí wọ́n ṣe jákèjádò Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó hàn gbangba pé ńṣe ni iye àwọn èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n sì sọ pé ìsìn ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé àwọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní orílẹ̀-èdè yẹn. Àmọ́ ṣá o, ìròyìn náà sọ pé: “Pẹ̀lú bí iye wọn ṣe pọ̀ tó, ọ̀pọ̀ àwọn ará Amẹ́ríkà ni ò tíì rí ipa tí ìsìn ní lórí ìgbésí ayé ẹnì kọ̀ọ̀kan àti lórí àwùjọ lápapọ̀.”
2 Kì í ṣe orílẹ̀-èdè kan ṣoṣo ni ohun tá à ń wí yìí ti ń ṣẹlẹ̀. Jákèjádò ayé ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ pé àwọn gba Bíbélì gbọ́, tí wọn ò sì fọ̀rọ̀ ìsìn ṣeré, ò ti jẹ́ kí Ìwé Mímọ́ sa ipá kankan nínú ìgbésí ayé wọn. (2 Tímótì 3:5) Olórí ẹgbẹ́ olùwádìí kan sọ pé: “A ṣì ń fún Bíbélì ní ọ̀wọ̀ tó ga, àmọ́ ní ti pé ká dìídì jókòó tì í ká máa kà á, ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, ká sì máa fi ohun tó wà níbẹ̀ sílò—ìyẹn ti di nǹkan àtijọ́.”
3. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe ń nípa lórí àwọn tó di Kristẹni gidi? (b) Báwo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe ń fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Fílípì 4:9 sílò?
3 Àmọ́ ti àwọn tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni yàtọ̀. Bí wọ́n ṣe ń fi ìmọ̀ràn látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ti jẹ́ kí èrò àti ìṣe wọn yí padà. Àwọn ẹlòmíràn sì ń kíyè sí àkópọ̀ ìwà tuntun tí wọ́n ń fi hàn. (Kólósè 3:5-10) Lójú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, Bíbélì kì í ṣe ìwé téèyàn kì í lò, tí eruku ń bò níbi ìkówèésí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì pé: “Àwọn ohun tí ẹ kẹ́kọ̀ọ́, tí ẹ tẹ́wọ́ gbà, tí ẹ gbọ́, tí ẹ sì rí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi, ẹ máa fi ìwọ̀nyí ṣe ìwà hù; Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (Fílípì 4:9) Àwọn Kristẹni ń ṣe ju wíwulẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan. Wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ ṣèwà hù, wọ́n ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò—nínú ìdílé, níbi iṣẹ́, nínú ìjọ, àti láwọn apá ibòmíràn nínú ìgbésí ayé wọn.
4. Èé ṣe tó fi ṣòro láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́?
4 Fífi àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run sílò kò rọrùn rárá. Inú ayé tó wà lábẹ́ agbára Sátánì Èṣù là ń gbé, ìyẹn ẹni tí Bíbélì pè ní “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19) Nítorí náà, ó pọn dandan fún wa láti wà lójúfò ká lè dènà ohunkóhun tí kò ní í jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti tọ ọ̀nà ìwà títọ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run. Báwo la ṣe lè jẹ́ olùpa ìwà títọ́ mọ́?
Di “Àpẹẹrẹ Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-nílera Mú”
5. Kí ni gbólóhùn tí Jésù sọ pé: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo” túmọ̀ sí?
5 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà fi ohun tá a ti kọ́ sílò ni pé ká fi ìdúróṣinṣin máa gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ, láìfi àtakò táwọn aláìgbàgbọ́ ń ṣe pè. Ìfaradà gba ìsapá. Jésù sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Jésù ò sọ pé ká tẹ̀ lé òun ní ọ̀sẹ̀ kan, oṣù kan, tàbí ọdún kan péré. Dípò ìyẹn, ó ní: “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé jíjẹ́ tí a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn kò lè jẹ́ ohun tá a kàn máa ṣe fún àkókò díẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìfọkànsìn onígbà díẹ̀ tá a ó ṣe lónìí tá ò ní í ṣe mọ́ lọ́la. Fífi ìdúróṣinṣin gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ túmọ̀ sí pé a ó fi tọkàntọkàn máa fara dà á ní ipa ọ̀nà tí a ti yàn, láìfi ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ pè. Báwo la ṣe lè ṣèyẹn?
6. Kí ni àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní kọ́ lọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù?
6 Pọ́ọ̀lù rọ Tímótì tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera tí ìwọ gbọ́ lọ́dọ̀ mi mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tímótì 1:13) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò fún “àpẹẹrẹ” níhìn-ín ń tọ́ka sí ní ṣáńgílítí ni àwòrán bọrọgidi tí ayàwòrán kan yà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní gbogbo ohun tó yẹ kó ní, irú àwòrán bọrọgidi bẹ́ẹ̀ ti fi àwọn nǹkan kan hàn tó máa jẹ́ kí ẹni tó ń wò ó fòye mọ bí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwòrán náà ṣe máa rí. Bákan náà ni àpẹẹrẹ òtítọ́ tí Pọ́ọ̀lù fi kọ́ Tímótì àtàwọn mìíràn kò wà fún rírí ìdáhùn pàtó sí gbogbo ìbéèrè tó lè dìde. Síbẹ̀, àpapọ̀ ẹ̀kọ́ yìí pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó tó ìyẹn ohun tá a lè pè ní ìlapa èrò, kí àwọn ọlọ́kàn tútù lè fòye mọ ohun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ wọn. Àmọ́ ṣá o, kí wọ́n tó lè múnú Ọlọ́run dùn, wọ́n ní láti máa di àpẹẹrẹ òtítọ́ yẹn mú nípa fífi ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò.
7. Báwo làwọn Kristẹni ṣe lè di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera mú?
7 Ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn kan bíi Híméníọ́sì, Alẹkisáńdà, àti Fílétọ́sì ń ṣalágbàwí àwọn èrò kan tí kò bá “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” mu. (1 Tímótì 1:18-20; 2 Tímótì 2:16, 17) Báwo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe lè yẹra fún dídi ẹni tí àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ mú kó ṣáko lọ? Ó jẹ́ nípa fífarabalẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí, kí wọ́n si máa fi wọ́n sílò nínú ìgbésí ayé wọn. Àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ lè mọ ohun tí kò bá àpẹẹrẹ òtítọ́ tí wọ́n ti kọ́ mu, kí wọ́n si yàgò fún un. (Fílípì 3:17; Hébérù 5:14) Dípò tí wọn ì bá fi jẹ́ “olókùnrùn ní èrò orí lórí bíbéèrè ìbéèrè àti fífa ọ̀rọ̀,” ńṣe ni wọ́n ń bá a lọ nínú ipa ọ̀nà ìfọkànsin Ọlọ́run wọn. (1 Tímótì 6:) Ohun táwa náà ń ṣe nìyẹn nígbà tá a bá ń bá a lọ ní fífi òtítọ́ tá a ti kọ́ sílò. Ẹ ò rí i bó ṣe ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun tó láti rí i pé ọ̀kẹ́ àìmọye tó ń sin Jèhófà jákèjádò ayé ń di àpẹẹrẹ òtítọ́ Bíbélì tá a kọ́ wọn mú ṣinṣin.— 3-61 Tẹsalóníkà 1:2-5.
Yẹra fún “Ìtàn Èké”
8. (a) Báwo ni Sátánì ṣe ń gbìyànjú láti ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́ lóde òní? (b) Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni nínú 2 Tímótì 4:3, 4?
8 Sátánì ń gbìyànjú láti ba ìwà títọ́ wa jẹ́ nípa gbígbin iyèméjì nípa ohun tá a ti kọ́ sí wa lọ́kàn. Àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn mìíràn ń gbìyànjú láti ba ìgbàgbọ́ àwọn aláìmọ̀kan jẹ́ lónìí, bíi ti ọ̀rúndún kìíní. (Gálátíà 2:4; 5:7, 8) Nígbà míì, wọ́n máa ń lo ilé iṣẹ́ ìròyìn láti gbé àwọn ìsọfúnni tí wọ́n gbé gbòdì tàbí èyí tó tiẹ̀ jẹ́ irọ́ paraku jáde nípa ọ̀nà táwọn èèyàn Jèhófà ń gbà ṣe iṣẹ́ wọn àti ète tí wọ́n fi ń ṣe é. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé a ó yí àwọn kan padà kúrò nínú òtítọ́. Ó kọ̀wé pé: “Sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́, nígbà tí ó jẹ́ pé a óò mú wọn yà sínú ìtàn èké.”—2 Tímótì 4:3, 4.
9. Kí ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó ń tọ́ka sí “ìtàn èké”?
9 Dípò dídi àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera mú, “ìtàn èké” làwọn kan máa ń fẹ́ gbọ́. Kí làwọn ìtàn èké wọ̀nyí? Ó lè jẹ́ àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn, bí irú àwọn tó wà nínú ìwé Tobit tí kò sí ẹ̀rí pé ó jẹ́ apá kan Ìwé Mímọ́. a Àwọn ìtàn èké tún lè ní àwọn àhesọ táwọn èèyàn méfò rẹ̀ tó sì lè ru ìmọ̀lára èèyàn sókè nínú. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn kan—“ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn”—ti lè jẹ́ káwọn tó fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìlànà Ọlọ́run tàbí àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ fi òye tí wọ́n ní tan àwọn jẹ. (3 Jòhánù 9, 10; Júúdà 4) Ohun ìkọ̀sẹ̀ yòówù kó ní nínú, ó hàn gbangba pé àwọn kan fẹ́ràn èké ju òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. Kò pẹ́ tí wọ́n fi dáwọ́ fífi ohun tí wọ́n ti kọ́ sílò dúró, ìyẹn sì pa ipò tẹ̀mí wọn lára.—2 Pétérù 3:15, 16.
10. Irú àwọn ìtàn èké wo ló wà lóde òní, báwo sì ni Jòhánù ṣe tẹnu mọ́ ìdí tá a fi ní láti ṣọ́ra?
10 A lè yẹra fún yíyíjú sí àwọn ìtàn èké lóde òní tí a bá ṣe àyẹ̀wò tí a sì ṣe àṣàyàn dáadáa nínú ohun tá à ń gbọ́ àti èyí tá à ń kà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn sábà máa ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe agbátẹrù ìgbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeé-mọ̀ tàbí ti àìgbà-pọ́lọ́run-wà. Àwọn aṣelámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ máa ń fi Bíbélì ṣe yẹ̀yẹ́ pé Ọlọ́run ò mí sí i. Àwọn apẹ̀yìndà òde òní sì ń gbìyànjú láti gbin iyèméjì sọ́kàn àwọn èèyàn, kí wọ́n lè ba ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni jẹ́. Nítorí ewu tó fẹ́ fara jọ ìyẹn, èyí tí àwọn wòlíì èké gbé dìde ní ọ̀rúndún kìíní ni àpọ́sítélì Jòhánù fi kìlọ̀ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.” (1 Jòhánù 4:1) Nítorí náà a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra.
11. Kí ni ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà yẹ ara wa wò ká sì rí i bóyá a ṣì wà nínú ìgbàgbọ́?
11 Nítorí ìdí èyí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kọ̀wé pé: “Ẹ máa dán ara yín wò bóyá ẹ wà nínú ìgbàgbọ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Àpọ́sítélì náà rọ̀ wá láti máa dán ara wa wò láti pinnu bóyá a fara mọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni látòkèdélẹ̀. Bí etí wa bá ń fẹ́ láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, a gbọ́dọ̀ yẹ ara wa wò tàdúràtàdúrà. (Sáàmù 139:23, 24) Ṣé a máa ń fẹ́ láti wá ẹ̀sùn sáwọn èèyàn Jèhófà lẹ́sẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí nìdí? Ṣé ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe ẹnì kan ti mú wa bínú ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ojú tó yẹ ká fi wo ọ̀ràn náà la fi ń wò ó? Ìpọ́njú èyíkéyìí tá a bá dojú kọ nínú ètò àwọn nǹkan yìí jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 4:17) Kódà bá a bá tiẹ̀ dojú kọ àwọn àdánwò kan nínú ìjọ, èé ṣe tá a fi ní láti jáwọ́ nínú sísin Ọlọ́run? Tí nǹkan kan bá ń bí wa nínú, ǹjẹ́ kó ní í dára jù láti ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà, lẹ́yìn ìyẹn ká wá fi ìyókù lé Jèhófà lọ́wọ́?—Sáàmù 4:4; Òwe 3:5, 6; Éfésù 4:26.
12. Báwo làwọn ará Bèróà ṣe fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa?
12 Dípò tí a ó fi jẹ́ aṣelámèyítọ́, ẹ jẹ́ ká ní ojú ìwòye tẹ̀mí tó dára nípa àwọn ìsọfúnni tí à ń rí gbà nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ìpàdé ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 2:14, 15) Dípò tí a ó fi máa ṣiyèméjì nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó kúkú mọ́gbọ́n dání gan-an láti ní irú ẹ̀mí táwọn ará Bèróà ọ̀rúndún kìíní ní, ìyẹn ni pé ká jẹ́ àwọn tó ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ dáadáa! (Ìṣe 17:10, 11) Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ ká ṣiṣẹ́ lórí ohun tá a kọ́, ká kọ àwọn ìtàn èké sílẹ̀ ká sì rọ̀ mọ́ òtítọ́.
13. Báwo la ṣe lè máa tan ìtàn èké kálẹ̀ láìmọ̀?
13 Oríṣi ìtàn èké mìíràn tún wà tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún. Ọ̀pọ̀ ìtàn àtẹnudẹ́nu tó ń ru ìmọ̀lára sókè láwọn èèyàn ń fi lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà sọ kiri. Ó bọ́gbọ́n mu láti ṣọ́ra fún irú ìtàn àtẹnudẹ́nu bẹ́ẹ̀, àgàgà tá ò bá mọ ibi tí ìsọfúnni náà ti pilẹ̀ gan-an. Kódà bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni kan tá a bọ̀wọ̀ fún ló fi ìrírí tàbí ìtàn kan ránṣẹ́, ẹni yẹn lè má mọ òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ gan-an. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé ká ṣọ́ra nípa títún ohun kan tá ò tíì wádìí rẹ̀ dáadáa sọ tàbí ká máa fi ránṣẹ́ sáwọn ẹlòmíràn. Ó dájú pé a ò ní fẹ́ láti máa tún “àwọn ìtàn àròsọ tó jẹ́ èké,” tàbí “àwọn ìtàn èké tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́” sọ kiri. (1 Tímótì 4:7; New International Version) Nígbà tó sì tún jẹ́ ọ̀ranyàn fún wa láti máa bá ara wa sọ òtítọ́, a ó máa hùwà ọlọgbọ́n nípa yíyẹra fún ohunkóhun tí yóò mú ká máa tan ohun tó jẹ́ irọ́ káàkiri, kódà láìmọ̀ọ́mọ̀ pàápàá.—Éfésù 4:25.
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Ṣíṣe Òtítọ́
14. Àwọn àǹfààní wo là ń rí látinú fífi àwọn ohun tá a ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò?
14 Fífi àwọn ohun tá à ń kọ́ nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìpàdé Kristẹni sílò yóò mú ọ̀pọ̀ àǹfààní wá. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí i pé àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́ sunwọ̀n sí i. (Gálátíà 6:10) Ìtẹ̀sí ọkàn tiwa fúnra wa yóò yí padà sí rere nígbà tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Sáàmù 19:8) Láfikún sí i, nípa fífi ohun tá a kọ́ sílò, à ń ‘ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọ́run lọ́ṣọ̀ọ́’ ìyẹn sì lè fa àwọn ẹlòmíràn sínú ìjọsìn tòótọ́.—Títù 2:6-10.
15. (a) Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe fìgboyà jẹ́rìí nílé ìwé? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìrírí yìí?
15 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń fi ohun tí wọ́n kọ́ nípasẹ̀ dídá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, dídá kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni àti lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé ṣèwà hù. Ẹ̀rí tó lágbára ni ìwà rere wọn ń jẹ́ fáwọn olùkọ́ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nílé ìwé. (1 Pétérù 2:12) Gbé ọ̀ràn Leslie yẹ̀ wò, ìyẹn ọmọbìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ó jẹ́wọ́ pé ó máa ń ni òun lára láti bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ òun sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ òun, àmọ́ ìyẹn yí padà lọ́jọ́ kan. “Kíláàsì náà ń sọ̀rọ̀ lórí báwọn èèyàn ṣe máa ń gbìyànjú láti ta nǹkan fúnni. Bí ọmọbìnrin kan ṣe nawọ́ sókè nìyẹn tó dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Kí ni Leslie wá ṣe gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí? Ó ní: “Mo gbèjà ìgbàgbọ́ mi, èyí tó dá mi lójú pé ó ya gbogbo wọn lẹ́nu, nítorí pé n kì í sábàá sọ̀rọ̀ nílé ìwé.” Kí ni àbájáde ìgboyà Leslie? Leslie sọ pé: “Ó ṣeé ṣe fún mi láti fún akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìwé pẹlẹbẹ kan àti ìwé àṣàrò kúkúrú kan nítorí pé ọmọbìnrin náà tún ń bi mí láwọn ìbéèrè mìíràn.” Ẹ ò rí i pé inú Jèhófà á dùn gan-an, nígbà táwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò bá ń jẹ́rìí tìgboyàtìgboyà níléèwé!—Òwe 27:11; Hébérù 6:10.
16. Báwo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ṣe ṣe ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan láǹfààní?
16 Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Elizabeth. Àtìgbà tí ọmọbìnrin yìí ti wà lọ́mọ ọdún méje títí tó fi jáde ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ló ti máa ń pe àwọn olùkọ́ rẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbàkigbà tó bá níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Bí olùkọ́ kan ò bá lè wá, Elizabeth á dúró lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde ilé ìwé, a sì ṣe iṣẹ́ náà fún olùkọ́ ọ̀hún. Nígbà tí Elizabeth fẹ́ jáde nílé ẹ̀kọ́ gíga, ó kọ ìròyìn olójú ìwé mẹ́wàá lórí àwọn àǹfààní tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní, ó sì kà á fún ìgbìmọ̀ kan tó ní àwọn olùkọ́ mẹ́rin nínú. Wọ́n tún pè é pé kó wá ṣiṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kan bí wọ́n ṣe máa ń ṣe é ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ó sì yan àkòrí tó sọ pé “Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Fi Àyè Gba Ìwà Ibi?” Elizabeth ti jàǹfààní látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ó kàn jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo lára ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Kristẹni tó ń fi ìyìn fún Jèhófà nípa fífi ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣèwà hù.
17, 18. (a) Ìmọ̀ràn wo ní Bíbélì fún wa lórí àìlábòsí? (b) Báwo ni ìwà àìlábòsí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣe kan ọkùnrin kan?
17 Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo. (Hébérù 13:18) Ìwà àbòsí lè bá àjọṣe àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn jẹ́ àti, ní pàtàkì jù lọ, ó lè ba àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà pàápàá jẹ́. (Òwe 12:22) Ìwà ẹni tó ṣeé fọkàn tán tá à ń hù ń fi ẹ̀rí hàn pe à ń fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò, ó sì ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn bọ̀wọ̀ tó ga fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
18 Gbé àpẹẹrẹ ọkùnrin jagunjagun kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Phillip yẹ̀ wò. Ó sọ ṣẹ́ẹ̀kì kan tó ti fọwọ́ sí àmọ́ tí kò tíì kọ iye pàtó kan sínú rẹ̀ nù, kò sì mọ̀ títí, àfìgbà tó gba lẹ́tà tí wọ́n fi dá ṣẹ́ẹ̀kì náà padà fún un. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ló rí ṣẹ́ẹ̀kì náà he, ó sì fi ìwé pélébé kan pẹ̀lú rẹ̀ tó ń fi hàn pé ẹ̀sìn tí ẹni tó rí i he ń ṣe ló jẹ́ kó dá a padà. Ẹ̀rù ba Phillip. Ó ní: “Àá, wọn ì bá kófà odindi ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] owó dọ́là lọ mọ́ mi lára!” Wọ́n ti fìgbà kan já a kulẹ̀ rí nígbà tí wọ́n jí fìlà rẹ̀ lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ó hàn gbangba pé ojúlùmọ̀ rẹ̀ kan ló mú fìlà náà, bẹ́ẹ̀ ẹni tí kò mọ̀ rí rárá ló dá ṣẹ́ẹ̀kì téèyàn lè fi gba ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là padà yìí! Láìsí àní-àní, àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláìlábòsí ń bọlá fún Jèhófà Ọlọ́run!
Máa Bá A Lọ Ní Fífi Ohun Tó O Ti Kọ́ Sílò
19, 20. Báwo la ó ṣe jàǹfààní látinú híhùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tá a kọ́ nínú Ìwé Mímọ́?
19 Àwọn tó ń fi ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ń rí ọ̀pọ̀ àǹfààní gbà. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.” (Jákọ́bù 1:25) Bẹ́ẹ̀ ni o, bá a bá ń hùwà níbàámu pẹ̀lú àwọn ohun tá a ti kọ́ nínú Ìwé Mímọ́, a óò ní ojúlówó ayọ̀, àá sì lè túbọ̀ kojú pákáǹleke ìgbésí ayé. Lékè gbogbo rẹ̀, àá rí ìbùkún Jèhófà a ó sì nírètí ìyè àìnípẹ̀kun!—Òwe 10:22; 1 Tímótì 6:6.
20 Ní gbogbo ọ̀nà, máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó. Máa bá àwọn olùjọsìn Jèhófà pé jọ pọ̀ déédéé, kí o sì máa fiyè sí ohun tí wọ́n ń sọ láwọn ìpàdé Kristẹni. Fi ohun tí ò ń kọ́ sílò, máa fi wọ́n ṣèwà hù, ‘Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.’—Fílípì 4:9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tobit, tó ṣeé se kí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa ní ìtàn àròsọ tó kún fún ìtàn irọ́ nípa Júù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tobias nínú. Wọ́n sọ pé ó ní ọgbọ́n bó ṣe lè gba agbára tí ń woni sàn àti èyí tó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa lílo ọkàn, òróòro, àti ẹ̀dọ̀ ẹja abàmì kan.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” báwo la sì ṣe lè pa wọ́n mọ́?
• Àwọn “ìtàn èké” wo la gbọ́dọ̀ kọ̀?
• Àwọn àǹfààní wo làwọn tó ń fi ohun tí wọ́n kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù ń rí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Báwo làwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ dídi ẹni táwọn apẹ̀yìndà mú kó ṣáko lọ?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ilé iṣẹ́ ìròyìn lè tipasẹ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì, àtàwọn apẹ̀yìndà òde òní gbin iyèméjì síni lọ́kàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Kò bọ́gbọ́n mu láti máa tan ìròyìn tí kò dá wa lójú kálẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ohun tí wọ́n kà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò níbi iṣẹ́, nílé ìwé, àti láwọn ibòmíràn