Báwo Làwọn Ẹni Mímọ́ Tòótọ́ Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́?
Báwo Làwọn Ẹni Mímọ́ Tòótọ́ Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́?
ÀWỌN wo ni ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “ẹni mímọ́” nínú Ìwé Mímọ́ ń tọ́ka sí? Ìwé An Expository Dictionary of New Testament Words sọ pé: “Níbi tá a bá ti lò ó fún àwọn onígbàgbọ́ tí iye wọ́n ju ẹyọ kan lọ, gbogbo àwọn onígbàgbọ́ pátá ló ń tọ́ka sí. Kì í ṣe kìkì àwọn tí ìjẹ́mímọ́ wọn ṣàrà ọ̀tọ̀, kì í sì í ṣe àwọn táwọn èèyàn kà sí àṣàyàn èèyàn Ọlọ́run lẹ́yìn ikú wọn.”
Ìdí rèé tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi pe gbogbo àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ní ẹni mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó kọ lẹ́tà kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa “sí ìjọ Ọlọ́run tí ó wà ní Kọ́ríńtì, pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ tí ń bẹ ní gbogbo Ákáyà,” tí í ṣe ìpínlẹ̀ Róòmù. (2 Kọ́ríńtì 1:1) Nígbà tó ṣe, Pọ́ọ̀lù tún kọ lẹ́tà “sí gbogbo àwọn tí ó wà ní Róòmù gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run, tí a pè láti jẹ́ ẹni mímọ́.” (Róòmù 1:7) Ó hàn gbangba pé àwọn ẹni mímọ́ wọ̀nyí ò tíì kú, a ò sì torí pé wọ́n níwà funfun ṣà wọ́n sọ́tọ̀, pé wọ́n lọ́lá ju àwọn onígbàgbọ́ tó kù lọ. Orí ìpìlẹ̀ wo la gbé jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́ kà?
Ọlọ́run Ló Ń Sọ Wọ́n Dẹni Mímọ́
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé kì í ṣe èèyàn tàbí ètò àjọ kan ló ń sọ èèyàn dẹni mímọ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “[Ọlọ́run] gbà wá là, ó sì fi ìpè mímọ́ pè wá, kì í ṣe nítorí àwọn iṣẹ́ wa, ṣùgbọ́n nítorí ète àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tirẹ̀.” (2 Tímótì 1:9) Pípè tí Jèhófà pe àwọn ẹni mímọ́ ló ń sọ wọ́n di mímọ́, níbàámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ète Rẹ̀.
Àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọ Kristẹni kópa nínú “májẹ̀mú tuntun.” Ẹ̀jẹ̀ Jésù tá a ta sílẹ̀ ló fìdí májẹ̀mú yìí múlẹ̀, tó tún sọ àwọn tó kópa nínú rẹ̀ di mímọ́. (Hébérù 9:15; 10:29; 13:20, 24) Níwọ̀n bí a ti sọ wọ́n di mímọ́ lójú Ọlọ́run, wọ́n jẹ́ ‘àlùfáà mímọ́, tó n rú àwọn ẹbọ ti ẹ̀mí tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi.’—1 Pétérù 2:5, 9.
Gbígbàdúrà Ìrànlọ́wọ́ Sáwọn Ẹni Mímọ́ Láti Báni Ṣe Alárinà
Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń júbà àwọn ẹni mímọ́ nípa bíbọ ère wọn tàbí nípa gbígbàdúrà sí wọn kí wọ́n lè bá wọn ṣe alárinà nítorí wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn “ẹni mímọ́” lè fún onígbàgbọ́ lágbára tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ǹjẹ́ Bíbélì fi irú ẹ̀kọ́ yìí kọ́ wa? Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè tọ Ọlọ́run Mátíù 6:9) Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló yẹ kéèyàn máa gbàdúrà sí.
lọ. Ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan máa ń tọ́ka sí Róòmù 15:30, láti ti èrò pé àwọn “ẹni mímọ́” lè báni ṣe alárinà lẹ́yìn. Ibẹ̀ yẹn kà pé: “Mo gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹ̀mí, pé kí ẹ tiraka pẹ̀lú mi nínú àdúrà sí Ọlọ́run fún mi.” Ṣé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé káwọn onígbàgbọ́ wọ̀nyí máa darí àdúrà wọn sóun tàbí pé kí wọ́n máa forúkọ òun gbàdúrà sí Ọlọ́run? Rárá o. Lóòótọ́, Bíbélì sọ pé ká máa gbàdúrà nítorí àwọn ojúlówó ẹni mímọ́, ṣùgbọ́n kò síbì kankan tí Ọlọ́run ti pàṣẹ pé ká darí àdúrà wa sí wọn tàbí pé ká gbàdúrà nípasẹ̀ wọn.—Fílípì 1:1, 3, 4.
Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ti yan Alárinà kan fún àdúrà wa. Jésù Kristi sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” Jésù tún sọ pé: “Ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe èyí dájúdájú, kí a lè yin Baba lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọmọ. Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.” (Jòhánù 14:6, 13, 14) A ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà ṣe tán láti dáhùn àdúrà tá a bá gbà lórúkọ Jésù. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Jésù rèé: “Ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ [tàbí ṣe alárinà] fún wọn.”—Hébérù 7:25.
Nígbà tí Jésù ti wà níbẹ̀ láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa, kí ló dé táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tún ń pe orúkọ àwọn “ẹni mímọ́” tí wọ́n bá ń gbàdúrà? Òpìtàn náà Will Durant, ṣèwádìí nípa ibi tí àṣà yìí ti bẹ̀rẹ̀ nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Age of Faith. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ń bẹ̀rù Ọlọ́run Olódùmarè, tó sì dà bí ẹni pé èèyàn lè tètè tọ Jésù lọ, síbẹ̀ Durant sọ pé: “Ẹnì kan ò lè gbójú gbóyà pé òun fẹ́ bá [Jésù] sọ̀rọ̀ ní tààràtà lẹ́yìn tónítọ̀hún ti kọ etí ikún sí ìkéde ìbùkún tó ṣe nínú Ìwàásù Rẹ̀ Lórí Òkè. Ohun tó dà bí ẹni pé ó bọ́gbọ́n mu ni kéèyàn darí àdúrà rẹ̀ sí ẹni mímọ́ táwọn èèyàn gbà pé ó wà lọ́run, kéèyàn sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣalárinà láàárín òun àti Kristi.” Ǹjẹ́ ìdí gúnmọ́ kankan wà fún irú ìbẹ̀rù yìí téèyàn bá fẹ́ gbàdúrà sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi?
Éfésù 3:11, 12) Ọ̀nà Ọlọ́run Olódùmarè ò jìn sí ẹ̀dá èèyàn débi tí ò fi ní lè gbọ́ àdúrà wa. Pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ ni onísáàmù náà Dáfídì fi gbàdúrà pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.” (Sáàmù 65:2) Jèhófà kì í fún àwọn èèyàn lágbára nípasẹ̀ ère àwọn “ẹni mímọ́” tó ti kú o, kìkì àwọn tó ń fi ìgbàgbọ́ béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ló ń fún. Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:13.
Bíbélì kọ́ wa pé nípasẹ̀ Jésù a lè ní ‘òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àti ọ̀nà ìwọlé pẹ̀lú ìgbọ́kànlé’ nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run. (Ipa Táwọn Ẹni Mímọ́ Ń Kó
Àwọn ẹni mímọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sí ti kú ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, wọ́n sì ti gba “adé ìyè” lẹ́yìn náà, ìyẹn àjíǹde sí òkè ọ̀run. (Ìṣípayá 2:10) Àwọn olùjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run mọ̀ pé bíbọ àwọn ẹni mímọ́ tòótọ́ wọ̀nyí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kò sì ní kéèyàn má ṣàìsàn, kò ní kí ìjábá àdánidá má ṣeni, kò lè gbani lọ́wọ́ àìríjẹ àìrímu, ọjọ́ ogbó tàbí ikú. Èyí lè mú kó o béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn ẹni mímọ́ Ọlọ́run tiẹ̀ bìkítà nípa wa? Ṣó yẹ ká retí pé kí wọ́n ṣojú fún wa?’
A sọ̀rọ̀ àwọn ẹni mímọ́ lọ́pọ̀ ìgbà nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí Dáníẹ́lì kọ sílẹ̀. Ní ọ̀rúndún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó rí ìran kan tó bùyààrì. Ìran ọ̀hún ṣì ń ní ìmúṣẹ lóde òní. Àwọn ẹranko mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó bani lẹ́rù jáde látinú òkun. Wọ́n dúró fún ìjọba ẹ̀dá èèyàn tí kò lè pèsè gbogbo nǹkan tọ́mọ aráyé ń fẹ́. Dáníẹ́lì wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n àwọn ẹni mímọ́ ti Onípò Àjùlọ yóò gba ìjọba, wọn yóò sì gba ìjọba náà fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin dórí àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 7:17, 18.
Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ogún fún àwọn ẹni mímọ́” yìí, ìyẹn ni pé wọ́n á jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. (Éfésù 1:18-21) Ẹ̀jẹ̀ Jésù ló ṣí ọ̀nà fáwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́ láti rí àjíǹde sínú ògo lókè ọ̀run. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Aláyọ̀ àti mímọ́ ni ẹnikẹ́ni tí ó ní ipa nínú àjíǹde èkíní; ikú kejì kò ní àṣẹ kankan lórí àwọn wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣípayá 20:4, 6; 14:1, 3) Nínú ìran tí Jòhánù rí, ó ń gbọ́ tí ògìdìgbó àwọn ẹ̀dá ọ̀run ń kọrin níwájú Jésù tá a ti ṣe lógo pé: “O [ti] fi ẹ̀jẹ̀ rẹ ra àwọn ènìyàn fún Ọlọ́run láti inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè, o sì mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Èyí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Jèhófà Ọlọ́run ló fúnra rẹ̀ fẹ̀sọ̀ yan àwọn èèyàn yìí lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Síwájú sí i, wọ́n ti fi ìṣòtítọ́ sìn lórí ilẹ̀ ayé, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìṣòro tí ẹ̀dá èèyàn ń rí làwọn náà ti rí. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Fún ìdí yìí, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ẹni mímọ́ tá a ti jí dìde yìí á jẹ́ alákòóso tó lójú àánú, tó ń gba tẹni rò, tó mọ àwọn àìlera wa àti ibi tágbára wá mọ.
Ìbùkún Nígbà Ìṣàkóso Ìjọba Náà
Ìjọba Ọlọ́run máa tó mú ìwà ibi àti ìjìyà kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Tó bá dìgbà yẹn, àwọn èèyàn á sún mọ́ Ọlọ́run ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Jòhánù kọ̀wé pé: “Pẹ̀lú ìyẹn, mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn.’” Ìbùkún yàbùgà yabuga lèyí á mú wá fún aráyé, nítorí àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, Ìṣípayá 21:3, 4.
bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìdùnnú á mà ṣubú lu ayọ̀ nígbà yẹn o! Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Míkà 4:3, 4, túbọ̀ ṣàlàyé àǹfààní ìṣàkóso Jésù Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́. Ó sọ pé: “[Jèhófà] yóò ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, yóò sì mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá tí ó jìnnà réré. Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Wọn kì yóò gbé idà sókè, orílẹ̀-èdè lòdì sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́. Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”
Àwọn ẹni mímọ́ ló ń ké sáwọn èèyàn láti wá nípìn-ín nínú ìbùkún wọ̀nyí. A fi àwọn ojúlówó ẹni mímọ́ wé ìyàwó, wọ́n sì ń sọ pé: “ Máa bọ̀!” Ẹsẹ náà kà síwájú pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Àwọn nǹkan wo ló wà nínú “omi ìyè” náà? Lára nǹkan wọ̀nyí ni ìmọ̀ pípéye nípa ète Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) A lè gba ìmọ̀ yìí nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Inú wa mà dùn púpọ̀ o, pé nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè mọ àwọn tó jẹ́ ojúlówó ẹni mímọ́, a sì lè kẹ́kọ̀ọ́ bí Ọlọ́run á ṣe lò wọ́n fún àǹfààní ìran èèyàn títí ayé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Pọ́ọ̀lù kọ àwọn lẹ́tà tá a mí sí sáwọn ojúlówó ẹni mímọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Àwọn olóòótọ́ àpọ́sítélì Jésù di ojúlówó ẹni mímọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
A lè fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà sí Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ẹni mímọ́ tá a jí dìde á jẹ́ alákòóso oníyọ̀ọ́nú lórí aráyé