Ire Wa Ni Òfin Ọlọ́run Wà Fún
Ire Wa Ni Òfin Ọlọ́run Wà Fún
“Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!”—SÁÀMÙ 119:97.
1. Ojú wo lọ̀pọ̀ èèyàn lónìí fi ń wo ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run?
ÒFIN Ọlọ́run ò tà létí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí. Àwọn kan ò rí ọgbọ́n kankan nínú fífi ọ̀ràn ara wọn lọ aláṣẹ gíga tí kò ṣeé fojú rí. À ń gbé nínú ayé kan táwọn èèyàn ò fẹ́ òfin dan-indan-in kankan lórí ọ̀ràn ìwà híhù, ayé kan níbi tí kò ti sí ìyàtọ̀ lọ títí láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́, ayé kan tí kò mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí tòsì. (Òwe 17:15; Aísáyà 5:20) Ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí kan jẹ́ ká mọ èrò tó wọ́pọ̀ láwùjọ àwọn tí kò ka ọ̀ràn ẹ̀sìn sí. Ìwádìí náà fi hàn pé “ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Amẹ́ríkà ló fẹ́ máa fúnra wọn pinnu ohun tó tọ́ àtohun tó dáa àtohun tí wọ́n gbà pé ó mọ́gbọ́n dání.” Wọ́n láwọn “ò fẹ́ Ọlọ́run tí ń dáni lẹ́jọ́. Wọ́n láwọn ò fẹ́ òfin tí ń káni lọ́wọ́ kò. Wọ́n láwọn ò fẹ́ àwọn aláṣẹ tí ń ṣòfin lórí ọ̀ràn ìwà híhù tàbí òfin èyíkéyìí.” Ọ̀mọ̀ràn kan tó ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí láwùjọ sọ pé lóde òní, “kálukú la retí pé kó máa dá pinnu irú ìgbésí ayé tó kà sí ìgbésí ayé rere àti ti ọmọlúwàbí.” Ó fi kún un pé: “Ó di dandan kí aláṣẹ èyíkéyìí mú àṣẹ rẹ̀ bá ìfẹ́ inú àwọn èèyàn mu.”
2. Báwo ni ibi tá a ti kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà òfin nínú Bíbélì ṣe fi hàn pé ó tan mọ́ ìbùkún àti ojú rere Ọlọ́run?
2 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń kọminú sí ìwúlò òfin Jèhófà, á dáa ká mú un dá ara wa lójú pé ire wa ni àwọn ìlànà Ọlọ́run wà fún. Ẹ jẹ́ ká kíyè sí ibi tá a ti kọ́kọ́ lo ọ̀rọ̀ náà òfin nínú Bíbélì. Ọlọ́run sọ nínú Jẹ́nẹ́sísì 26:5 pé: “Ábúráhámù . . . ń pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe rẹ̀ sí mi mọ́, àti àwọn àṣẹ mi, àti àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, àti àwọn òfin mi.” Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún kó tó di pé ó fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òfin. Báwo ni Ọlọ́run ṣe san èrè fún Ábúráhámù nítorí pé ó ṣègbọràn, títí kan ìgbọràn sí àwọn òfin Rẹ̀? Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí fún un pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Èyí fi hàn pé ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run ń yọrí sí ìbùkún àti ojú rere Ọlọ́run.
3. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni ọ̀kan lára àwọn onísáàmù sọ láti fi bí òfin Jèhófà ṣe rí lára rẹ̀ hàn? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
3 Ọ̀kan lára àwọn onísáàmù náà—tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọmọ aládé àti ọba lọ́la ní Júdà—lo ọ̀rọ̀ kan tí a kì í sábàá lò nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa òfin, láti fi bí òfin Ọlọ́run ṣe rí lára rẹ̀ hàn. Ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o!” (Sáàmù 119:97) Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó kàn kù gìrì sọ. Ó sọ ọ̀rọ̀ yìí nítorí pé ó fẹ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé òun fẹ́ nínú òfin rẹ̀. Jésù Kristi ẹni pípé, tí í ṣe Ọmọ Ọlọ́run, sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ tọ́ka sí i pé Jésù yóò sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sáàmù 40:8; Hébérù ) Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ inú wa máa ń dùn sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ àwa náà gbà pé lóòótọ́ làwọn òfin Jèhófà wúlò, tó sì ṣàǹfààní? Irú ojú wo la fi ń wo ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run nínú ìjọsìn wa, nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe, àti nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Ohun tó máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run ni tá a bá lóye ìdí tí Ọlọ́run fi lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣòfin, kí ó sì fẹsẹ̀ òfin náà múlẹ̀. 10:9
Jèhófà Ló Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Fún Wa Lófin
4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ni Ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ jù lọ láti jẹ́ Afúnnilófin?
4 Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ni Ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ jù lọ láti jẹ́ Afúnnilófin ní gbogbo ọ̀run òun ayé. (Ìṣípayá 4:11) Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀.” (Aísáyà 33:22) Òun ló ṣe àwọn òfin àdánidá tí ń ṣàkóso ẹ̀dá abẹ̀mí àti ẹ̀dá aláìlẹ́mìí. (Jóòbù 38:4-38; 39:1-12; Sáàmù 104:5-19) Èèyàn pẹ̀lú wà lábẹ́ àwọn òfin àdánidá tí Jèhófà ṣe, nítorí pé ẹ̀dá Ọlọ́run làwọn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn jẹ́ ẹ̀dá amọnúúrò, ìyẹn ẹ̀dá tó lè dánú rò, síbẹ̀síbẹ̀ àfi tó bá fi ara rẹ̀ sábẹ́ àwọn òfin Ọlọ́run nípa ìwà híhù àtàwọn òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn ló fi lè láyọ̀.—Róòmù 12:1; 1 Kọ́ríńtì 2:14-16.
5. Báwo ni ìlànà tó wà nínú Gálátíà 6:7 ṣe kan àwọn òfin Ọlọ́run?
5 A mọ̀ pé kò sẹ́ni tó lè fojú di àwọn òfin àdánidá tí Jèhófà ṣe. (Jeremáyà 33:20, 21) Èèyàn ò lè tàpá sí àwọn òfin àdánidá, irú bí òfin òòfà, kí ó sì mú un jẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn òfin Ọlọ́run nípa ìwà híhù kò ṣeé pa tì. Èèyàn ò lè rú wọn kí ó mú un jẹ. Bí àwọn òfin àdánidá ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn òfin ìwà híhù fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó kàn jẹ́ pé ó lè máà jẹ́ ojú ẹsẹ̀ lèèyàn máa jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. “Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:7; 1 Tímótì 5:24.
Ibi Tí Òfin Jèhófà Gbòòrò Dé
6. Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe gbòòrò tó?
6 Òfin Mósè wà lára òfin títayọ tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. (Róòmù 7:12) Nígbà tó ṣe, Jèhófà Ọlọ́run fi “òfin Kristi” a rọ́pò Òfin Mósè. (Gálátíà 6:2; 1 Kọ́ríńtì 9:21) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tí ń bẹ lábẹ́ “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira,” a mọ̀ pé àwọn ìlànà Ọlọ́run kò mọ sórí apá kan ìgbésí ayé wa, irú bí ọ̀ràn ìgbàgbọ́ tàbí ìlànà ẹ̀sìn nìkan. Òfin rẹ̀ kárí gbogbo apá ìgbésí ayé, títí kan ọ̀ràn ìdílé, ọ̀ràn iṣẹ́ ajé, irú ìwà tá à ń hù sí ẹ̀yà takọtabo, ìṣesí wa sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa àti irú ọwọ́ tá a fi mú ìjọsìn tòótọ́.—Jákọ́bù 1:25, 27.
7. Tọ́ka sí díẹ̀ lára àwọn òfin Ọlọ́run tó ṣe kókó.
7 Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Rárá o, kò tọ́ láti pe panṣágà àti àgbèrè ní “eré ìfẹ́.” Bẹ́ẹ̀ náà ni kò tọ́ láti pe ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ ní “ọ̀nà mìíràn láti gbà gbé ìgbésí ayé.” Rírú òfin Jèhófà ni nǹkan wọ̀nyí jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìwà bí olè jíjà, irọ́ pípa àti ìbanilórúkọjẹ́. (Sáàmù 101:5; Kólósè 3:9; 1 Pétérù 4:15) Jákọ́bù sọ pé kò dáa láti máa fọ́nnu, Pọ́ọ̀lù sì rọ̀ wá láti yàgò fún ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ àti ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn. (Éfésù 5:4; Jákọ́bù 4:16) Fún Kristẹni, gbogbo òfin ìwà híhù wọ̀nyí ló wà lára òfin pípé ti Ọlọ́run.—Sáàmù 19:7.
8. (a) Báwo ni òfin Jèhófà ṣe rí? (b) Kí ni ìtumọ̀ pàtàkì tí ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tá a tú sí “òfin” ní?
8 Irú àwọn ìlànà pàtàkì bẹ́ẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi hàn pé òfin rẹ̀ kì í kàn-án ṣe àkójọ àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀. Títẹ̀lé ìlànà wọ̀nyẹn ń jẹ́ kó ṣeé ṣe láti gbé ìgbé ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó mìrìngìndìn, tó sì ń sọni di ọmọlúwàbí èèyàn. Òfin Ọlọ́run ń gbéni ró, ó ń jẹ́ kéèyàn mọ̀wàá hù, ó sì ń fọgbọ́n kọ́ni. (Sáàmù ) Àtinú ọ̀rọ̀ èdè Hébérù náà toh·rahʹ la ti tú ọ̀rọ̀ náà “òfin,” gẹ́gẹ́ bí onísáàmù ṣe lò ó. Ọ̀mọ̀wé kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe kan tó túmọ̀ sí láti darí, láti ṣamọ̀nà, láti fojú sùn, láti ta ọfà síwájú. Ìyẹn ni . . . ìtumọ̀ rẹ̀ fi jẹ́ ìlànà ìwà híhù.” Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni onísáàmù náà ka òfin sí. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa fi irú ojú ribiribi bẹ́ẹ̀ wò ó, ká jẹ́ kí ó máa darí ìgbésí ayé wa? 119:72
9, 10. (a) Kí nìdí tá a fi nílò ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé? (b) Kí ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí ayé wa fi lè tòrò, kí ó sì dùn bí oyin?
9 Gbogbo ẹ̀dá ló nílò ìdarí tó ṣeé fọkàn tán àti ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé. Kódà Jésù àtàwọn áńgẹ́lì yòókù, tó ga ju ẹ̀dá ènìyàn lọ nílò rẹ̀. (Sáàmù 8:5; Jòhánù 5:30; 6:38; Hébérù 2:7; Ìṣípayá 22:8, 9) Bí àwọn ẹ̀dá pípé wọ̀nyí bá nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, mélòómélòó ni àwa ẹ̀dá ènìyàn aláìpé! Ìtàn ènìyàn àtohun tí àwa alára ti rí ti fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tí wòlíì Jeremáyà sọ, pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
10 A gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run bá a bá fẹ́ kí ayé wa tòrò, kí ó dùn bí oyin. Sólómọ́nì Ọba mọ ewu tó wà nínú gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tara ẹni, láìbìkítà fún ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Òwe 14:12.
Ìdí Tó Fi Yẹ Láti Fojú Ribiribi Wo Òfin Jèhófà
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti lóye òfin Ọlọ́run?
11 Ó yẹ ká ṣe akitiyan láti lóye òfin Jèhófà. Onísáàmù náà fi irú ìfẹ́ àtọkànwá bẹ́ẹ̀ hàn nígbà tó sọ pé: “La ojú mi, kí n lè máa wo àwọn ohun àgbàyanu láti inú òfin rẹ.” (Sáàmù 119:18) Bá a bá ṣe ń mọ Ọlọ́run àtàwọn ọ̀nà rẹ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà la óò túbọ̀ máa mọyì òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ, pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́!” (Aísáyà 48:17, 18) Jèhófà kò fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ kó sí wàhálà rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí wọ́n máa gbádùn ayé wọn nípa fífetí sí àṣẹ òun. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa fojú ribiribi wo òfin Ọlọ́run.
12. Báwo ni bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá dunjú tó ṣe jẹ́ ká gbà pé òun ló wà nípò tó dára jù lọ láti fún wa lófin?
12 Òfin Ọlọ́run ń wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó mọ̀ wá jù lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá wa, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé yóò mọ ẹ̀dá ènìyàn láìkù síbì kan. (Sáàmù 139:1, 2; Ìṣe 17:24-28) Àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn, àwọn ẹbí wa, kódà àwọn òbí wa kò lè mọ̀ wá bí Jèhófà ṣe mọ̀ wá. Àní Ọlọ́run mọ̀ wá ju bá a ṣe mọ ara wa pàápàá! Ẹlẹ́dàá wa mọ àìní wa nípa tẹ̀mí, nípa ti ìmọ̀lára, nípa ti èrò orí àti nípa ti ara ju ẹnikẹ́ni lọ. Bó ṣe ń fiyè sí wa, ó ń fi hàn pé òun mọ̀ wá dunjú, òun mọ ohun tó wà lọ́kàn wa, ó sì mọ ohun tí à ń lépa. Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ, ṣùgbọ́n ó tún mọ àwọn ohun rere tá a lè gbé ṣe. Onísáàmù náà sọ pé: “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Fún ìdí yìí, ọkàn wa balẹ̀ nípa tẹ̀mí bá a ṣe ń sapá láti rìn nínú òfin rẹ̀, tá à ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.—Òwe 3:19-26.
13. Èé ṣe tá a fi lè ní ìdánilójú pé ire wa jẹ Jèhófà lógún gan-an ni?
13 Òfin Ọlọ́run ń wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa. Ire wa ayérayé jẹ Ọlọ́run lógún gan-an ni. Ǹjẹ́ kò fi ohun ńláǹlà du ara rẹ̀ nígbà tó fi Ọmọ rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn”? (Mátíù 20:28) Jèhófà kò ha ti ṣèlérí pé ‘òun ò ní jẹ́ kí a dẹ wá wò kọjá ohun tí a lè mú mọ́ra’? (1 Kọ́ríńtì 10:13) Bíbélì kò ha fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ó ‘bìkítà fún wa’? (1 Pétérù 5:7) Kò sẹ́lòmíì tó ní irú ìfẹ́ àtọkànwá tó pọ̀ tó ti Jèhófà láti fún ẹ̀dá ènìyàn ní àwọn ìtọ́sọ́nà tó jẹ́ fún ire wa. Ó mọ ohun tó lè ṣe wá láǹfààní, ó sì mọ ohun tó lè mú wa láyọ̀ àtohun tó lè kó ìbànújẹ́ bá wa. Bá a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, tá a sì ń ṣàṣìṣe, bí a bá sáà ti ń lépa òdodo, ó máa ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí wa kí a bàa lè rí ìyè àti ìbùkún.—Ìsíkíẹ́lì 33:11.
14. Ọ̀nà pàtàkì wo ni òfin Ọlọ́run fi yàtọ̀ sí àwọn èròǹgbà ẹ̀dá ènìyàn?
14 Òfin Ọlọ́run kì í yí padà rárá. Ní àkókò rúkèrúdò tí à ń gbé yìí, Jèhófà jẹ́ àpáta atóófaratì, tó wà títí ayé. (Sáàmù 90:2) Ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ṣeé gbé gbogbo ara lé—kò dà bí àwọn èròǹgbà ènìyàn tí kò dúró sójú kan. (Jákọ́bù 1:17) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn afìṣemọ̀rònú fi ń sọ pé kíkẹ́ ọmọ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́ ló dáa jù. Àmọ́ nígbà tó yá làwọn kan lára wọn tún pàlù dà, tí wọ́n ní ọ̀ràn ò rí báwọn ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ mọ́. Ńṣe ni ọ̀pá ìdiwọ̀n àti ìlànà ayé lórí ọ̀ràn yìí ń lọ tó ń bọ̀, láìdúró sójú kan bí ohun tí atẹ́gùn ń gbé kiri. Ṣùgbọ́n, Ọ̀rọ̀ Jèhófà kò ní àgbéyí. Látọjọ́ táláyé ti dáyé ni Bíbélì ti pèsè ìmọ̀ràn lórí ọ̀ràn fífi ìfẹ́ tọ́ ọmọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ẹ wo bó ṣe fini lọ́kàn balẹ̀ tó pé a lè gbára lé ìlànà Jèhófà; kò lè yí padà!
Ìbùkún fún Àwọn Tí Ń Ṣègbọràn sí Òfin Ọlọ́run
15, 16. (a) Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ bá a bá ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà? (b) Báwo ni òfin Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ atọ́nà tó jíire nínú ìgbéyàwó?
15 Ọlọ́run gbẹnu Aísáyà wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . yóò . . . ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.” (Aísáyà 55:11) Bẹ́ẹ̀ náà ló dájú pé, bá a bá ń fi tọkàntara gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a óò kẹ́sẹ járí, a ó ṣe àṣeyọrí sí rere, a ó sì láyọ̀.
16 Ṣàkíyèsí bí òfin Ọlọ́run ṣe jẹ́ atọ́nà sí ìgbéyàwó tó gbámúṣé. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin, nítorí Ọlọ́run yóò dá àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà lẹ́jọ́.” (Hébérù 13:4) Ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Irú ìfẹ́ tí à ń béèrè la ṣàpèjúwe nínú 1 Kọ́ríńtì 13:4-8, pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere. Ìfẹ́ kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í wú fùkẹ̀, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan, a kì í tán an ní sùúrù. Kì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́. A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” Ìgbéyàwó tó bá ní irú ìfẹ́ yìí kò ní tú ká.
17. Àwọn àǹfààní wo ló ń wá látinú títẹ̀lé ìlànà Jèhófà nípa ọtí mímu?
17 Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé àwọn ìlànà Jèhófà ṣàǹfààní ni òtítọ́ náà pé Ọlọ́run kórìíra ìmutíyó. Àní ó kórìíra ‘fífi ara ẹni fún ọ̀pọ̀ wáìnì.’ (1 Tímótì 3:3, 8; Róòmù 13:13) Ọ̀pọ̀ àwọn tó dágunlá sí ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí ti kó àrùn tí àmujù ọtí ń fà tàbí tó ń dá kún nínú àgọ́ ara. Àwọn kan tó dágunlá sí ìmọ̀ràn Bíbélì lórí jíjẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì ti di ẹni tí ń mutí yó kẹ́ri láti fi “pa ìrònú rẹ́.” Ìṣòro tí àmujù ọtí ń fà pọ̀ rẹpẹtẹ. Lára irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ ni dídi ẹni yẹ̀yẹ́, èdèkòyédè nínú ìdílé tàbí kí ìdílé tú ká, níná owó nínàákúnàá àti kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹni. (Òwe 23:19-21, 29-35) Ǹjẹ́ ààbò kọ́ ni ìlànà Jèhófà nípa ọtí mímu jẹ́?
18. Ǹjẹ́ àǹfààní wà nínú òfin Ọlọ́run nípa ọ̀ràn ìṣúnná owó? Ṣàlàyé.
18 Ìlànà Ọlọ́run tún ṣàǹfààní nínú ọ̀ràn ìṣúnná owó. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n jẹ́ aláìlábòsí àti aláápọn. (Lúùkù 16:10; Éfésù 4:28; Kólósè 3:23) Nítorí pé àwọn Kristẹni ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ti rí ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tàbí tí wọ́n ń báṣẹ́ wọn lọ nígbà tíṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn. Èèyàn tún máa ń lówó lọ́wọ́ tó bá yàgò fún àṣàkaṣà, àṣà bára kú, tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bíi tẹ́tẹ́ títa, sìgá mímu àti ìjoògùnyó. A mọ̀ pé àpẹẹrẹ pọ̀ tó o lè tọ́ka sí, tó fi hàn pé ìlànà Ọlọ́run ṣàǹfààní nínú ọ̀ràn ìṣúnná owó.
19, 20. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti tẹ́wọ́ gba òfin Ọlọ́run, ká sì rọ̀ mọ́ ọn?
19 Ó rọrùn fún ẹ̀dá aláìpé láti ṣáko kúrò nínú òfin àti ìlànà Ọlọ́run. Ronú nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà lórí Òkè Sínáì. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” Wọ́n fèsì pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” Ṣùgbọ́n, ẹ ò rí i pé ọ̀tọ̀ gbáà ni ipa ọ̀nà tí wọ́n tọ̀! (Ẹ́kísódù 19:5, 8; Sáàmù 106:12-43) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí àwa ní tiwa tẹ́wọ́ gba ìlànà Ọlọ́run, ká sì rọ̀ mọ́ ọn.
20 Ipa ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu, tí yóò sì fún wa láyọ̀ ni láti rọ̀ mọ́ àwọn òfin aláìlẹ́gbẹ́ tí Jèhófà ti fún wa bí atọ́nà wa nínú ìgbésí ayé. (Sáàmù 19:7-11) Ká lè ṣe èyí láṣeyọrí, a tún gbọ́dọ̀ mọyì ìjẹ́pàtàkì àwọn ìlànà Ọlọ́run. Èyí ni kókó tí a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kíkún nípa “òfin Kristi,” wo Ilé Ìṣọ́, September 1, 1996, ojú ìwé 14 sí 24.
Ṣé O Rántí?
• Èé ṣe tá a fi lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ire wa ni òfin Ọlọ́run wà fún?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fojú ribiribi wo òfin Jèhófà?
• Àwọn ọ̀nà wo ni òfin Ọlọ́run gbà ṣàǹfààní?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
A bù kún Ábúráhámù lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí pé ó ṣègbọràn sí òfin Jèhófà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Hílàhílo inú ayé sáré-n-bájà òde òní ń mú ọkàn ọ̀pọ̀ èèyàn kúrò lórí òfin Ọlọ́run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Gẹ́gẹ́ bí ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun tá a kọ́ sórí àpáta, òfin Ọlọ́run fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, kì í yí padà