Bó O Ṣe Lè Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀ Nísinsìnyí àti Títí Ayérayé
Bó O Ṣe Lè Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀ Nísinsìnyí àti Títí Ayérayé
ÈÉ ṢE tó fi ṣòro láti ní ìfọ̀kànbalẹ̀, tá a bá sì ní in, kí ló dé tí kì í tọ́jọ́? Àbí àlá lásán lohun tá à ń pè ní ìfọ̀kànbalẹ̀—ìyẹn ohun tá a fẹ́ kó tẹ̀ wá lọ́wọ́ dípò ohun tó lè tẹ̀ wá lọ́wọ́? Irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ kò yàtọ̀ sí gbígbéra ẹni gẹṣin aáyán.
Irú ìròkurò bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn mọ́kàn kúrò lórí àwọn ewu tí ń bẹ nínú ìgbésí ayé, téèyàn á bẹ̀rẹ̀ sí fọkàn yàwòrán ipò kan tó lẹ́wà, tó fini lọ́kàn balẹ̀, téèyàn á sì di ojú rẹ̀ sí àwọn ìṣòro tó yí i ká. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà làwọn ìṣòro ilé ayé á rọ́ dé lójijì, níbi téèyàn ti ń gbéra rẹ̀ gẹṣin aáyán, tí ojú onítọ̀hún á sì wá mọ́ foo.
Ẹ jẹ́ ká wo ibì kan táwọn èèyàn ti máa ń wá ìfọ̀kànbalẹ̀—ibi téèyàn wà. Bí àpẹẹrẹ, ìlú ńlá lè dà bí ibi tó máa ṣẹnuure, tó máa jẹ́ kéèyàn ronú pé òun máa ní àsìkò ìgbádùn, owó oṣù tó pọ̀ rẹpẹtẹ, àti ibùgbé tó dára. Bẹ́ẹ̀ ni o, ó lè jọ pé ibẹ̀ lèèyàn ti máa rí ìfọ̀kànbalẹ̀ tó ti ń wá tipẹ́tipẹ́. Àmọ́ ṣé àlá tó lè ṣẹ lèyí?
Ṣé Ìfọ̀kànbalẹ̀ Wà Nílùú Ńlá àbí Àlá Lásán Ni?
Ìpolówó ọjà tó lè mú kéèyàn máa retí nǹkan ńlá ni ó ń fa àwọn èèyàn wá sí ìlú ńlá láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Kì í ṣe ìfọ̀kànbalẹ̀ tìrẹ ló jẹ àwọn àjọ tó ń ṣonígbọ̀wọ́ ìpolówó ọjà bẹ́ẹ̀ lógún, bí kò ṣe bí wọ́n ṣe máa ta ọjà tiwọn. Wọn ò ní jẹ́ sọ̀rọ̀ lọ síbi ìṣòro táwọn èèyàn ń dojú kọ, kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn tó ti rọ́wọ́ mú, tó sì dà bíi pé ọkàn wọn balẹ̀ ni wọ́n máa ń gbé jáde. Yóò wá dà bíi pé ọjà tí wọ́n ń polówó àti ìlú ńlá ló ń jẹ́ kéèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀.
Ronú nípa àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí. Àwọn aláṣẹ ìlú kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà gbé pátákó ìpolówó ọjà kan síta, tó fi hàn kedere pé kò sóhun tí sìgá mímu fi yàtọ̀ sí kéèyàn máa sun owó òógùn ojú ẹni níná. Ọ̀kan lára ọgbọ́n tí wọ́n dá láti kìlọ̀ fáwọn aráàlú pé kí wọ́n jáwọ́ nínú sìgá mímu nìyẹn. Àwọn tó ń ṣe sìgá àtàwọn tó ń tà á wá tako èyí nípa gbígbé pátákó ìpolówó ọjà mìíràn jáde, èyí tí wọ́n fọgbọ́n ṣe lọ́nà tó fi àwọn tó ń mu sìgá hàn bíi pé ojú wọn gún régé, inú wọn ń dùn, ọkàn wọn sì balẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ilé iṣẹ́ sìgá kan rán irú aṣọ kan náà tó lẹ́wà sọ́rùn àwọn kan lára àwọn òṣìṣẹ́ wọn, pẹ̀lú fìlà bẹntigọ́ọ̀ lórí wọn, wọ́n sì ní kí wọ́n lọ máa pín sìgá fáwọn ọ̀dọ́ lójú pópó, kí wọ́n máa fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn níṣìírí láti “tọ́ ọ wò.” Ọ̀pọ̀ tó ti abúlé wá lára àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí, tí wọn ò rí irú ìpolówó ọjà ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ bẹ́ẹ̀ rí, ló kó sí pańpẹ́ ohun tí wọ́n fi lọ̀ wọ́n yìí. Wọ́n di ẹni tí sìgá mímu di
bárakú sí lára. Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ará abúlé wọ̀nyí wá sílùú ńlá láti rówó tí wọ́n á fi gbọ́ bùkátà ìdílé wọn tàbí káwọn fúnra wọn lè rí towó ṣe. Dípò ìyẹn, ìnákúnàá ni wọ́n ń ná èyí tó pọ̀ jù lọ lára owó tí wọn ì bá fi dá nǹkan ṣe.Àwọn ìkéde tó máa ń fi hàn pé nǹkan ṣẹnuure nílùú ńlá kì í fi gbogbo ìgbà wá látẹnu àwọn oníṣòwò. Ó lè jẹ́ ẹnu àwọn tó kó lọ sílùú ńlá, tí ìtìjú kò sì jẹ́ kí wọ́n padà sábúlé ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ń jáde. Káwọn èèyàn má bàá pè wọ́n ní aláṣetì, wọ́n á máa fi ọrọ̀ tí wọ́n sọ pé àwọn ti kó jọ àti àwọn àṣeyọrí tí wọ́n sọ pé àwọn ti ṣe nílùú ńlá yan fanda kiri. Àmọ́, téèyàn bá fara balẹ̀ wo àṣeyọrí tí wọ́n sọ pé àwọn ti ṣe, á rí i pé kò sóhun tí ìgbésí ayé tí wọ́n ń gbé nísinsìnyí fi sàn ju èyí tí wọ́n ń gbé kí wọ́n tó kúrò lábúlé; bíi ti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mìíràn tó ń gbé nílùú ńlá làwọn náà ṣe ń forí ṣe fọrùn ṣe kí wọ́n tóó rówó ná.
Àwọn ìlú ńlá gan-an làwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé, tó ń wá ìfọ̀kànbalẹ̀ ti máa ń bọ́ sọ́wọ́ àwọn apanilẹ́kún-jayé. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọn ò tíì láwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ọ̀nà wọn sì ti jìn síbi táwọn ẹbí wọ́n wà. Nítorí náà, wọn ò lẹ́ni tó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn, tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀fìn ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó kún ìlú ńlá.
Josué ò kó sínú ọ̀fìn sìgá mímu. Síwájú sí i, ó tún rí i pé ohun tí gbígbé nílùú ńlá ń béèrè kọjá ohun tọ́wọ́ òun lè ká. Lójú tirẹ̀, gbogbo ohun téèyàn lè rí nínú ìlú ńlá kò ju kéèyàn kàn máa fọkàn yàwòrán ohun ńláńlá, kó máa lá àwọn àlá tí kò lè ṣẹ. Ó rí i pé òun kò ní ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ nílùú ńlá náà; kò tiẹ̀ yẹ kó wà níbẹ̀ rárá. Gbogbo nǹkan wá tojú sú u, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí wo ara rẹ̀ bí ẹni tí kò tẹ́gbẹ́, tó sì ti kùnà pátápátá. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ó gbé ìtìjú tà, ó sì padà sábúlé.
Ó ti ń bẹ̀rù pé wọ́n máa fi òun ṣẹ̀sín. Dípò ìyẹn, ńṣe làwọn ẹbí àtàwọn ojúlówó ọ̀rẹ́ rẹ̀ fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà kí i káàbọ̀. Kò pẹ́ rárá tí ọ̀yàyà ìdílé rẹ̀, àyíká abúlé tó ti mọ́ ọn lára àti ìfẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni, fi jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ gan-an ju tìgbà tó wà nílùú ńlá, níbi tí ìrètí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń dòfo. Sí ìyàlẹ́nu rẹ̀, iṣẹ́ àṣekára tí òun àti baba rẹ̀ jọ ń ṣe lóko wá ń mú owó tó pọ̀ gan-an wọlé fún òun àti ìdílé rẹ̀ ju owó tí ì bá máa kù sí i lọ́wọ́ nílùú ńlá.
Kí Ni Ìṣòro Tó Wà Nídìí Owó Gan-an?
Ǹjẹ́ owó lè fún ọ ní ìfọ̀kànbalẹ̀? Liz, láti Kánádà, sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo rò pé owó ló máa ń fini lọ́kàn balẹ̀.” Ìfẹ́ ọkùnrin kan tó lówó lọ́wọ́ wá kó sí i lórí. Láìpẹ́ wọ́n ṣègbéyàwó. Ṣé ọkàn rẹ̀ ti wá balẹ̀? Liz ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nígbà tí mo ṣègbéyàwó, a ní ilé kan tó lẹ́wà àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì, owó tá a sì ní pọ̀ débí pé ṣàṣà lohun tá a kì í gbádùn nínú gbogbo nǹkan téèyàn ń fowó ṣe, a ń rin ìrìn àjò, a sì ń ṣe fàájì kiri. Ó wá yà mí lẹ́nu pé, síbẹ̀ mo ṣì ń ṣàníyàn nípa owó.” Ó ṣàlàyé ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Nǹkan tá a lè pàdánù pọ̀ gan-an. Ó dà bíi pé bí ohun tó o ní bá ṣe pọ̀ tó náà ni ọkàn rẹ kò ṣe ní balẹ̀ tó. Owó kì í gbani lọ́wọ́ àníyàn tàbí ìdààmú.”
Tó o bá ń ronú pé owó tó o ní kò pọ̀ tó láti jẹ́ kó o ní ìfọ̀kànbalẹ̀, bí ara rẹ pé, ‘Kí ni ìṣòro ibẹ̀ gan-an? Ṣé àìlówó lọ́wọ́ ni lóòótọ́, tàbí àìmọ bí a ṣe ń fọgbọ́n náwó?’ Nígbà tí Liz ń rántí ìgbésí ayé rẹ̀ àtẹ̀yìnwá, ó sọ pé: “Mo wá rí i nísinsìnyí pé ohun tó fa ìṣòro ìdílé mi nígbà tí mo wà lọ́mọdé ni àìmọ bí a ṣe ń fọgbọ́n náwó. A máa ń ra nǹkan àwìn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ ká jẹ gbèsè sọ́rùn ṣáá. Èyí kó ìdààmú bá wa.”
Àmọ́ lónìí, ọkàn Liz àti ti ọkọ rẹ̀ ti balẹ̀ gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ṣíwọ́ fífetísí àwọn ọ̀rọ̀ ìtànjẹ nípa owó, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí ọgbọ́n Ọlọ́run, títí kan èyí tó Òwe 1:33) Wọ́n fẹ́ kí ìgbésí ayé àwọn túbọ̀ nítumọ̀ tó ju ohun tí owó rẹpẹtẹ ní báńkì lè fúnni. Nísinsìnyí tí wọ́n ti di míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè, Liz àti ọkọ rẹ̀ ń kọ́ àtolówó àti tálákà pé Jèhófà Ọlọ́run kò ní pẹ́ mú ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ tó kárí ayé wá. Ìgbòkègbodò yìí ń fún wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó jinlẹ̀, ó sì ń fún wọn ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó máa ń wá látinú lílépa ohun tó níláárí, tó sì níye lórí, kì í ṣe látinú kíkó owó rẹpẹtẹ jọ.
sọ pé: “Ní ti ẹni tí ń fetí sí mi, yóò máa gbé nínú ààbò, yóò sì wà láìní ìyọlẹ́nu lọ́wọ́ ìbẹ̀rùbojo ìyọnu àjálù.” (Rántí òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro yìí: Jíjẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run níye lórí gan-an ju kéèyàn kó ọrọ̀ jọ. Ohun tí Ìwé Mímọ́ tẹnu mọ́ látòkè délẹ̀ kì í ṣe kíkó ọrọ̀ jọ, bí kò ṣe pé kéèyàn ní ìdúró rere lọ́dọ̀ Jèhófà, èyí téèyàn lè máa ní lọ nípa bíbá a nìṣó láti máa fi ìgbàgbọ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Kristi Jésù rọ̀ wá láti “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” ká sì to “ìṣúra” jọ “ní ọ̀run.”—Lúùkù 12:21, 33.
Ipò Wo Lo Fẹ́ Dé?
Bó bá ń ṣe ọ́ bíi pé dídé ipò gíga láwùjọ ló máa fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀, bí ara rẹ pé: ‘Èwo lára
àwọn tó ti dépò gíga ló ti ní ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀? Ibo ni ipò mi máa ga dé kí n tó lè ní ìfọ̀kànbalẹ̀?’ Iṣẹ́ kan tó ń mówó wọlé lè jẹ́ kó o lérò pé ọkàn rẹ̀ ti balẹ̀, kó sì wá já ọ kulẹ̀ tàbí, kó tiẹ̀ ṣe ohun tó burú jùyẹn lọ, kó sọ ẹ́ di ẹdun arinlẹ̀.Àwọn ìrírí fi hàn pé níní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an ju níní orúkọ lọ́dọ̀ ènìyàn. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè fún èèyàn ní ẹ̀bùn ìyè ayérayé. Ìyẹn túmọ̀ sí kíkọ orúkọ wa sínú ìwé ìyè Ọlọ́run dípò tí wọ́n fi máa kọ ọ́ sínú ìwé ayé tórúkọ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn wà.—Ẹ́kísódù 32:32; Ìṣípayá 3:5.
Nígbà tó o bá gbé àlá tí kò lè ṣẹ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ojú wo lo fi ń wo ipò tó o wà báyìí, kí lo sì lè fi òótọ́ inú máa retí lọ́jọ́ iwájú? Kò sẹ́ni tó ní gbogbo nǹkan tán. Bí Kristẹni ọlọgbọ́n kan ṣe sọ ọ́ ni pé, “Mo ní láti kẹ́kọ̀ọ́ pé a kì í jẹ́ méjì lábà Àlàdé.” Dúró díẹ̀ ná, kó o ka àpótí tó ní àkọlé náà, “Orílẹ̀-Èdè Benin Ni Wọ́n Ti Sọ Ọ́.”
Kó o wáá dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Ibi pàtàkì wo ni mò ń lépa àtidé nínú ìgbésí ayé mi? Ọ̀nà wo ló yá jù láti gbà débẹ̀? Àbí ó lè jẹ́ pé ọ̀nà jíjìn, tó ṣe kọ́lọkọ̀lọ, tó sì léwu ni mo gbà, nígbà tó jẹ́ pé mo lè rí ohun tí mò ń wá àti ohun tó ṣeé ṣe kí ọwọ́ mi tẹ̀ ní ọ̀nà mìíràn tí kò jìn tí kò díjú tóyẹn?
Lẹ́yìn tí Jésù fúnni nímọ̀ràn lórí ibi tí ìníyelórí ohun ti ara mọ ní ìfiwéra pẹ̀lú bí ohun tẹ̀mí ṣe níye lórí tó, ó sọ pé kí a jẹ́ kí ojú wa “mú ọ̀nà kan.” (Mátíù 6:22) Ó mú un ṣe kedere pé ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé ni àwọn nǹkan tẹ̀mí àtàwọn ìlépa tá a gbé ka orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 6:9, 10) Àwọn nǹkan mìíràn kò ṣe pàtàkì tó o, tàbí ká kúkú sọ pé, wọn kì í ṣe ohun tó yẹ ká máa jẹ́ kó wà lórí ẹ̀mí wa.
Ọ̀pọ̀ awò ojú òde òní ní wọ́n ṣe láti fi rí ohun tó wà lọ́nà jíjìn àti ohun tó sún mọ́ni. Ṣé bí ìwọ náà ṣe ń wo ibí, wo ọ̀hún nìyẹn? Ṣé gbogbo ohun tó ò ń wò ló “tọ́”—ìyẹn ni pé ṣe gbogbo rẹ̀ ló ṣe pàtàkì, tó yẹ ní fífẹ́, tí ọwọ́ sì lè tẹ̀? Bí ó bá tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ló dára dé ìwọ̀n kan, síbẹ̀ bí ọ̀pọ̀ nǹkan bá gba àfiyèsí wa, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún Kristẹni, ìyẹn Ìjọba náà, lè di èyí tó rá mọ́ wa lójú. Ìmọ̀ràn pàtàkì tí Jésù fún wa ni pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:33.
Ní Ìfọ̀kànbalẹ̀ Nísinsìnyí àti Títí Láé
Gbogbo wa la lè máa lálàá ohun tó dára fún ara wa àti fún àwọn èèyàn wa. Àmọ́, òtítọ́ náà pé aláìpé ni wá, pé à ń gbé nínú ayé aláìpé, àti pé ìgbésí ayé wa kúrú ti sọ ọ́ di dandan fún wa láti pààlà sí ohun tá a lè retí pé kí ọwọ́ wa tẹ̀. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan ṣàlàyé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn pé: “Mo padà láti rí i lábẹ́ oòrùn pé eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, bẹ́ẹ̀ ni ìjà ogun kì í ṣe ti àwọn alágbára ńlá, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.
Ìgbà mìíràn wà tí kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé máa ń gbà wá lọ́kàn débi pé àá gbàgbé Oníwàásù 5:10, 12) Bẹ́ẹ̀ ni o, ibo lo ti lè rí ìfọ̀kànbalẹ̀?
láti wo àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ọ̀ràn nípa ẹni tá a jẹ́ àti ohun tá a dìídì nílò kí ọkàn wa lè balẹ̀ dáadáa. Gbé ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n àtayébáyé wọ̀nyí yẹ̀ wò: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá. Asán ni èyí pẹ̀lú. Dídùn ni oorun ẹni tí ń ṣiṣẹ́ sìn, ì báà jẹ́ oúnjẹ díẹ̀ tàbí púpọ̀ ni ó jẹ; ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ kì í jẹ́ kí ó sùn.” (Bí ipò tó o wà bá fara jọ ti àlá tí kò lè ṣẹ tí Josué lá, ǹjẹ́ o lè yí ìpinnu rẹ padà? Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ dénú yóò tì ọ́ lẹ́yìn, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹbí Josué àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ti ṣe. Ìfọ̀kànbalẹ̀ tó o lè rí ní àyíká rírẹlẹ̀ táwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ wà pọ̀ ju èyí tó o lè rí nílùú ńlá táwọn tó máa fẹ́ kó ẹ nífà wà.
Tó o bá ti ní ànító bíi ti Liz àti ọkọ rẹ̀, ǹjẹ́ o lè yí ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ padà, kó o lè túbọ̀ lo àkókò àti agbára rẹ láti ran àwọn èèyàn, yálà olówó tàbí tálákà lọ́wọ́, kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba tó máa fi èèyàn lọ́kàn balẹ̀?
Bó o bá ti ń tiraka láti gòkè àgbà láwùjọ tàbí láti dọ̀gá níbi iṣẹ́, o lè fẹ́ fi tọkàntọkàn ronú lórí ohun tó ń mú kí irú ipò bẹ́ẹ̀ wù ọ́. Lóòótọ́, àwọn nǹkan amáyédẹrùn tó o máa ní lè fi kún adùn ìgbésí ayé rẹ̀. Síbẹ̀, ǹjẹ́ yóò ṣeé ṣe fún ọ láti tẹjú mọ́ Ìjọba náà, tó jẹ́ ọ̀nà tòótọ́ láti ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pípẹ́ títí? Rántí ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Bí o bá ń kópa nínú onírúurú ìgbòkègbodò ìjọ Kristẹni, wàá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tó lérè nínú.
Àwọn tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀ ń gbádùn ìfọ̀kànbalẹ̀ amọ́kànyọ̀ nísinsìnyí, wọ́n sì ń wọ̀nà fún ìfọ̀kànbalẹ̀ tí kò ní ààlà lọ́jọ́ iwájú. Onísáàmù sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. Nítorí náà, ọkàn-àyà mi yọ̀, ògo mi sì fẹ́ láti kún fún ìdùnnú. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹran ara mi yóò máa gbé ní ààbò.”—Sáàmù 16:8, 9.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Orílẹ̀-Èdè Benin Ni Wọ́n Ti Sọ Ọ́
Àìmọye ìgbà ni wọ́n ti sọ ìtàn yìí lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni àgbàlagbà ará abúlé kan ní orílẹ̀-èdè Benin, Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, sọ èyí tó wà nísàlẹ̀ yìí fáwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan.
Bí apẹja kan ti wa òbèlè rẹ̀ padà wálé ni ọkùnrin ògbógi oníṣòwò kan látòkè òkun pàdé rẹ̀. Oníṣòwò náà ń ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà tí apẹja yìí ń gbé. Ògbógi náà béèrè ohun tó fà á tí apẹja náà fi tètè padà wálé. Ó fèsì pé òun ì bá túbọ̀ dúró pẹja díẹ̀ sí i, àmọ́ òun ti pa èyí tó pọ̀ tó láti gbọ́ bùkátà ìdílé òun.
Ògbógi náà wá béèrè pé: “Kí ló ń fi gbogbo àkókò rẹ ṣe ná?”
Apẹja náà dáhùn pé: “Tóò, màá pẹja díẹ̀. Màá bá àwọn ọmọ mi ṣeré. Gbogbo wa la máa ń sun oorun ọ̀sán nígbà tí oòrùn bá mú. Tó bá di alẹ́, gbogbo wa á jọ jẹun. Lẹ́yìn náà, màá lọ jókòó ti àwọn ọ̀rẹ́ mi láti gbádùn orin, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Ògbógi náà wá sọ pé: “Wò ó, mo gboyè jáde ní yunifásítì, mo sì ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí dáadáa. Mo fẹ́ ràn ọ́ lọ́wọ́. Ó yẹ kó o máa pẹ́ kí o lè pẹja púpọ̀ sí i. Ìyẹn a jẹ́ kó o rówó tó pọ̀, kò sì ní pẹ́ tí wàá fi ra ọkọ tó tóbi ju òbèlè yìí lọ. Tó o bá wá ní ọkọ̀ ńlá, wàá láǹfààní àtirí owó púpọ̀ sí i, kò sì ní pẹ́ tí wàá fi ní ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń pẹja.”
Apẹja náà wá sọ pé: “Lẹ́yìn náà ńkọ́?”
“Lẹ́yìn náà, dípò tó o fi ń kó ẹja fáwọn alágbàtà, wàá máa tà á ní tààràtà fún ilé iṣẹ́ ẹja títà tàbí kó o tiẹ̀ dá ilé iṣẹ́ ẹja tìrẹ sílẹ̀ pàápàá. Á ṣeé ṣe fún ọ láti fi abúlé rẹ sílẹ̀, kó o wá lọ sílùú Kútọnu, tàbí Paris, tàbí New York, kó o wá tibẹ̀ máa bójú tó iṣẹ́ okòwò rẹ. O tiẹ̀ lè ronú bó o ṣe máa gbé òwò rẹ lọ sí ọjà okòwò, kó o wá di olówó rẹpẹtẹ.”
Apẹja ọ̀hún wá béèrè pé: “Gbogbo ìyẹn á gbà tó ọdún mélòó ná?”
Ògbógi náà dáhùn pé: “Ó lè gbà tó ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ọdún.”
Apẹja náà tún bí i pé: “Lẹ́yìn ìyẹn wá ńkọ́?”
Ògbógi náà ní: “Ìgbà yẹn gan-an ni ìgbádùn ayé ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. O lè wá fẹ̀yìn tì nígbà yẹn. O lè fi gbogbo kòókòó jàn-ánjàn-án àwọn ìlú ńlá sílẹ̀, kò o rọra lọ forí pa mọ́ sábúlé kékeré kan.”
Apẹja náà wá béèrè pé: “Kí ni màá wá máa ṣe nígbà yẹn?”
“Wàá wá ráyè máa pẹja díẹ̀díẹ̀, wàá ráyè máa bá àwọn ọmọ rẹ ṣeré, ẹ̀ẹ́ máa sun oorun ọ̀sán nígbà tí oòrùn bá mú, ìwọ àti ìdílé rẹ yóò jọ máa jẹun alẹ́ pa pọ̀, wàá sì ráyè lọ jókòó ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ láti gbádùn orin.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ ìgbéga lè jẹ́ kéèyàn ní ìfọ̀kànbalẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ dìídì fẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀