Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
Jẹ́ Kí Ìbẹ̀rù Jèhófà Wà Ní Ọkàn Rẹ
“Kìkì bí wọn yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ nígbà gbogbo.”—DIUTARÓNÓMÌ 5:29.
1. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ọjọ́ kan ń bọ̀ táwọn èèyàn á bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù?
ÌBẸ̀RÙ ti kó jìnnìjìnnì bá ìran ènìyàn fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Ìbẹ̀rù ebi, àrùn, ìwà ọ̀daràn, tàbí ogun ti kó ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn sínú hílàhílo ìgbà gbogbo. Nítorí ìdí èyí, ohun tó wà nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé fi hàn pé wọ́n fẹ́ láti mú ayé kan tí gbogbo ẹ̀dá ènìyàn á ti bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù wá. a Inú wa dùn pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti mú un dá wa lójú pé irú ayé bẹ́ẹ̀ yóò dé—bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe nípa ìsapá ènìyàn. Jèhófà tipasẹ̀ Míkà, wòlíì rẹ̀ ṣèlérí fún wa pé nínú ayé tuntun òdodo, ‘kò sí ẹnì kankan tí yóò máa mú àwọn ènìyàn òun wárìrì.’—Míkà 4:4.
2. (a) Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe rọ̀ wá láti bẹ̀rù Ọlọ́run? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló lè dìde nígbà tá a bá gbé ojúṣe wa láti bẹ̀rù Ọlọ́run yẹ̀ wò?
2 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìbẹ̀rù tún lè jẹ́ ohun tí ń mú kéèyàn ṣe rere. Nínú Ìwé Mímọ́, léraléra la rọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run pé kí wọ́n bẹ̀rù Jèhófà. Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni kí o bẹ̀rù, òun sì ni kí o máa sìn.” (Diutarónómì 6:13) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìyẹn, Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìjẹ́rìí tá a ń ṣe lábẹ́ àbójútó àwọn áńgẹ́lì, àwa náà ń rọ gbogbo èèyàn láti ‘bẹ̀rù Ọlọ́run, kí wọ́n sì fi ògo fún un.’ (Ìṣípayá 14:6, 7) Ní àfikún sí bíbẹ̀rù Jèhófà, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn-àyà wọn nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Mátíù 22:37, 38) Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká sì tún bẹ̀rù rẹ̀? Kí nìdí tá a fi ní láti bẹ̀rù Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́? Kí làwọn àǹfààní tó ń tinú níní ìbẹ̀rù Ọlọ́run wá? Ká tó lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ lóye ohun tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí àti bí irú ìbẹ̀rù yìí ṣe kó apá pàtàkì nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́wọ̀, Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀ àti Ìbẹ̀rù
3. Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí?
3 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ni ìmọ̀lára táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní sí Olùṣẹ̀dá wọn. Ọ̀kan lára ìtumọ̀ irú ìbẹ̀rù yìí ni “ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá àti ìbẹ̀rù àtọkànwá láti má ṣe mú un bínú.” Nítorí ìdí èyí, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń nípa lórí apá méjì pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa: ìyẹn ìṣarasíhùwà wa sí Ọlọ́run àti irú ojú tá a fi ń wo àwọn ìwà tó kórìíra. Ní kedere, àwọn apá méjèèjì ló ṣe pàtàkì tó sì yẹ ká gbé yẹ̀ wò dáadáa. Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Expository Dictionary of New Testament Words ti Vine, ṣe wí, fún àwọn Kristẹni, irú ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ yìí jẹ́ ‘ohun tí ń darí ìgbésí ayé ẹni, nínú àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí àti ti ìwà rere.’
4. Báwo la ṣe lè ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá wa?
4 Báwo la ṣe lè ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá? A máa ń gbóṣùbà fún Ọlọ́run nígbà tá a bá rí àgbègbè tó kún fún igi àti òdòdó ẹlẹ́wà, tá a bá rí àrágbáyamúyamù omi tó ń tú yaa látinú àpáta, tàbí wíwọ̀ oòrùn tó jẹ́ àrímáleèlọ. Irú ìmọ̀lára yìí máa ń pọ̀ sí i nígbà tá a bá fi ojú ìgbàgbọ́ rí i pé àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run. Síwájú sí i, bíi ti Dáfídì Ọba, a ń rí i pé a ò já mọ́ nǹkan kan ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn àgbàyanu ìṣẹ̀dá Jèhófà. “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn?” (Sáàmù 8:3, 4) Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ yìí ń jẹ́ kí a ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, èyí tó ń mú ká máa fi ọpẹ́ àti ìyìn fún Jèhófà nítorí gbogbo ohun tó ṣe fún wa. Dáfídì tún kọ̀wé pé: “Èmi yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.”—Sáàmù 139:14.
5. Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rù Jèhófà, àpẹẹrẹ àtàtà wo la sì ní lórí èyí?
5 Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìbẹ̀rù àtọkànwá tí ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún agbára Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti fún ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Alákòóso títọ́ fún ọ̀run òun ayé. Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, “àwọn tí ó jagunmólú lọ́wọ́ ẹranko ẹhànnà náà àti lọ́wọ́ ère rẹ̀”—ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi ní ipò wọn ní ọ̀run—pòkìkí pé: “Títóbi àti àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè. Òdodo àti òótọ́ ni àwọn ọ̀nà rẹ, Ọba ayérayé. Ta ni kì yóò bẹ̀rù rẹ ní ti gidi, Jèhófà, tí kì yóò sì yin orúkọ rẹ lógo?” (Ìṣípayá 15:2-4) Ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó jẹ yọ látinú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún ipò ọlá ńlá rẹ̀, mú káwọn tó máa bá Kristi jọba nínú Ìjọba ti ọ̀run bọlá fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ gíga jù lọ. Nígbà tá a bá ronú lórí gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe àti ọ̀nà òdodo tó gbà ń ṣàkóso ọ̀run òun ayé, ǹjẹ́ a ò ní ìdí púpọ̀ láti bẹ̀rù rẹ̀?—Sáàmù 2:11; Jeremáyà 10:7.
6. Èé ṣe tó fi yẹ ká ní ìbẹ̀rù tí ó tọ́ kí a má bàa ṣe ohun tó máa bí Jèhófà nínú?
6 Àmọ́ ṣá o, láfikún sí ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, ìbẹ̀rù Ọlọ́run tún gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù àtọkànwá láti má ṣe mú un bínú tàbí láti má ṣe ṣàìgbọràn sí i nínú. Kí nìdí? Nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà “ń lọ́ra láti bínú, [tí] ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́,” síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ máa rántí pé “lọ́nàkọnà, kì í dáni sí láìjẹni-níyà.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà jẹ́ onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, síbẹ̀ kì í fàyè gba àìṣòdodo àti ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá. (Sáàmù 5:4, 5; Hábákúkù 1:13) Àwọn tó bá mọ̀ọ́mọ̀ ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, tí wọ́n sì kọ̀ láti ronú pìwà dà àtàwọn tí wọ́n bá ń ṣe àtakò sí i kò ní lọ láìjìyà. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, “ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.” Níní ìbẹ̀rù tí ó tọ́ kí a má bàa bọ́ sínú irú ipò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ààbò ńláǹlà fún wa.—Hébérù 10:31.
‘Òun Ni Kí Ẹ Rọ̀ Mọ́’
7. Kí làwọn ìdí tá a ní fún níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú agbára Jèhófà tí ń gbani là?
7 Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àti mímọ̀ ní àmọ̀dunjú pé òun ni alágbára jù lọ, yóò sún wa láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì fọkàn tán an. Gẹ́gẹ́ bí ọkàn ọmọdé kan ṣe máa ń balẹ̀ nígbà tí baba rẹ̀ bá wà nítòsí, bẹ́ẹ̀ náà lọkàn wa ṣe máa ń balẹ̀, tá a sì máa ń ní ìgboyà lábẹ́ ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Kíyè sí ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lẹ́yìn tí Jèhófà mú wọn jáde ní Íjíbítì: “Ísírẹ́lì tún rí ọwọ́ ńlá tí Jèhófà lò ní ìlòdìsí àwọn ará Íjíbítì; àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Jèhófà, wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 14:31) Ìrírí Èlíṣà tún jẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé “áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.” (Sáàmù 34:7; 2 Àwọn Ọba 6:15-17) Ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní àti ìrírí tí àwa fúnra wa ti ní lè ti mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ń lo agbára rẹ̀ nítorí àwọn tó ń sìn ín. (2 Kíróníkà 16:9) Èyí mú ká mọ̀ pé “inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà.”—Òwe 14:26.
8. (a) Kí nìdí tí ìbẹ̀rù Ọlọ́run fi ń sún wa láti rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀? (b) Ṣàlàyé bó ṣe yẹ ká “rọ̀ mọ́” Jèhófà?
8 Kì í ṣe pé ìbẹ̀rù àtọkànwá tá a ní fún Ọlọ́run ń jẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń sún wa láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nígbà tí Sólómọ́nì ya tẹ́ńpìlì sí mímọ́, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Kí [Ísírẹ́lì] lè máa bẹ̀rù rẹ nípa rírìn ní àwọn ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà láàyè ní orí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wa.” (2 Kíróníkà 6:31) Ṣáájú àkókò yẹn, Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Jèhófà Ọlọ́run yín ni kí ẹ máa rìn tọ̀ lẹ́yìn, òun sì ni kí ẹ máa bẹ̀rù, àwọn àṣẹ rẹ̀ sì ni kí ẹ máa pa mọ́, ohùn rẹ̀ sì ni kí ẹ máa fetí sí, òun sì ni kí ẹ máa sìn, òun sì ni kí ẹ rọ̀ mọ́.” (Diutarónómì 13:4) Bí àwọn ẹsẹ wọ̀nyí ṣe fi hàn kedere, ìfẹ́ láti rìn ní àwọn ọ̀nà Jèhófà àti láti “rọ̀ mọ́” ọn wá látinú ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni o, ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń sún wa láti ṣègbọràn sí Jèhófà, láti sìn ín, àti láti rọ̀ mọ́ ọn, gẹ́gẹ́ bí ọmọ kékeré kan ṣe ń rọ̀ mọ́ baba rẹ̀ tó gbẹ́kẹ̀ lé, tó sì fọkàn tán.—Sáàmù 63:8; Aísáyà 41:13.
Tí A Bá Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, A Ó Bẹ̀rù Rẹ̀
9. Báwo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run ṣe tan mọ́ ìbẹ̀rù Ọlọ́run?
9 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí, bíbẹ̀rù Ọlọ́run kò fagi lé nínífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, a fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítọ̀ọ́ni pé kí wọ́n ‘bẹ̀rù Jèhófà . . . kí wọ́n lè máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí wọ́n sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ (Diutarónómì 10:12) Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run jọ ń rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń sún wa láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ tá a ní fún un. (1 Jòhánù 5:3) Èyí bọ́gbọ́n mú, nítorí pé tá a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, a óò máa bẹ̀rù àtiṣe ohun tó máa bà á lọ́kàn jẹ́. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ nípa ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù ní aginjù. Dájúdájú, a kò ní fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa mú ìbànújẹ́ bá Baba wa ọ̀run. (Sáàmù 78:40, 41) Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “Jèhófà ní ìdùnnú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,” ìgbọràn àti ìdúróṣinṣin wa ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Sáàmù 147:11; Òwe 27:11) Ìfẹ́ fún Ọlọ́run ń sún wa láti ṣe ohun tó máa múnú rẹ̀ dùn, ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń jẹ́ ká yàgò fún ṣíṣe ohun tó máa bà á lọ́kàn jẹ́. Ńṣe ni àwọn ànímọ́ méjèèjì yìí ń kín èkíní kejì lẹ́yìn, kì í ṣe pé wọ́n ta ko ara wọn.
10. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ní inú dídùn sí bíbẹ̀rù Jèhófà?
10 Ọ̀nà ìgbésí ayé Jésù Kristi fi bí a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ká sì tún bẹ̀rù rẹ̀ hàn kedere. Wòlíì Aísáyà kọ̀wé nípa Jésù pé: “Ẹ̀mí Jèhófà yóò sì bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ńlá, ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Jèhófà; ìgbádùn rẹ̀ yóò sì wà nínú ìbẹ̀rù Jèhófà.” (Aísáyà 11:2, 3) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí Jésù bẹ̀rù Baba rẹ̀ ọ̀run. Láfikún sí i, a ṣàkíyèsí pé ìbẹ̀rù yìí kì í ṣe ti gbígbọ̀n jìnnìjìnnì, bí kò ṣe orísun ayọ̀. Inú Jésù máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti múnú rẹ̀ dùn, kódà nígbà tí ipò nǹkan bá le koko fún un. Nígbà tí àkókò tí wọ́n máa pa á lórí igi oró sún mọ́ tòsí, ó sọ fún Jèhófà pé: “Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí èmi tí fẹ́, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti fẹ́.” (Mátíù 26:39) Nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run tó ní yìí, Jèhófà fetí sí ẹ̀bẹ̀ Ọmọ rẹ̀, ó fún un lókun, kò sì jẹ́ kí ó kú gbé.—Hébérù 5:7.
Kíkọ́ Láti Bẹ̀rù Jèhófà
11, 12. (a) Èé ṣe tó fi yẹ ká kọ́ láti bẹ̀rù Ọlọ́run? (b) Báwo ni Jésù ṣe kọ́ wa láti bẹ̀rù Jèhófà?
11 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kì í ṣàdédé wá, kò dà bí háà tó máa ń ṣe wá nígbà tá a bá rí agbára àti àwọn ohun àgbàyanu inú ìṣẹ̀dá. Ìdí nìyẹn tí Jésù Kristi tó jẹ́ Dáfídì Títóbi Jù, fi nawọ́ ìkésíni náà sí wa lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; ìbẹ̀rù Jèhófà ni èmi yóò kọ́ yín.” (Sáàmù 34:11) Báwo la ṣe lè kọ́ bá a ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà látọ̀dọ̀ Jésù?
12 Jésù kọ́ wa láti bẹ̀rù Jèhófà nípa ríràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Baba wa ọ̀run ní. (Jòhánù 1:18) Àpẹẹrẹ Jésù fi bí Ọlọ́run ṣe ń ronú àti bó ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò hàn, nítorí pé Jésù gbé àkópọ̀ ìwà Baba rẹ̀ yọ láìkù síbì kan. (Jòhánù 14:9, 10) Síwájú sí i, nípasẹ̀ ẹbọ Jésù, a láǹfààní láti dé ọ̀dọ̀ Jèhófà nígbà tá a bá gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ọ̀nà títayọ tí Ọlọ́run gbà fi àánú hàn yìí nìkan ti tó fún wa láti bẹ̀rù rẹ̀. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ìdáríjì tòótọ́ ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ.”—Sáàmù 130:4.
13. Àwọn ọ̀nà wo la tò lẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé Òwe tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà?
13 Lẹ́sẹẹsẹ ni ìwé Òwe to onírúurú ọ̀nà tá a lè gbà ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, . . . bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:1-5) Nítorí náà, tá a bá fẹ́ bẹ̀rù Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ká fi taratara sapá láti lóye ìtọ́ni rẹ̀, ká sì fara balẹ̀ fiyè sí àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀.
14. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tá a fún àwọn ọba Ísírẹ́lì?
14 Gbogbo ẹni tó bá jẹ ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì la fún nítọ̀ọ́ni láti ṣe ẹ̀dà Òfin kan, kí ó sì ‘máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin náà mọ́.’ (Diutarónómì 17:18, 19) Bíbélì kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ṣe pàtàkì fún wa gan-an bá a bá fẹ́ kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà. Bá a ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a óò máa ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. A óò wá “lóye ìbẹ̀rù Jèhófà” nítorí pé a ń rí àwọn èso rere tó ń so nínú ìgbésí ayé wa, a sì ń fojú ribiribi wo àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò mọ síbẹ̀ yẹn o, nípa pípéjọ déédéé pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, tọmọdé tàgbà lè fetí sí ohun tí Ọlọ́run ń kọ́ wa, kí a kọ́ láti bẹ̀rù Ọlọ́run, ká sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.—Diutarónómì 31:12.
Aláyọ̀ Ni Gbogbo Ẹni Tó Ń Bẹ̀rù Jèhófà
15. Àwọn ọ̀nà wo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run gbà tan mọ́ ìjọsìn wa sí i?
15 Látinú ohun tá a ti ń sọ bọ̀, a lè rí i pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run jẹ́ ànímọ́ tó dáa tó yẹ kí gbogbo wa ní, níwọ̀n bó ti jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà. Ó ń darí wa láti nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, láti máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, àti láti rọ̀ mọ́ ọn. Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Jésù Kristi, ìbẹ̀rù Ọlọ́run tún lè sún wa láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ nísinsìnyí àti títí ayérayé.
16. Kí nìdí tí Jèhófà fi ń rọ̀ wá pé ká bẹ̀rù òun?
16 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kì í kó jìnnìjìnnì báni, bẹ́ẹ̀ ni kì í káni lọ́wọ́ kò láìyẹ. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Sáàmù 128:1) Jèhófà ń rọ̀ wá pé ká bẹ̀rù òun, nítorí ó mọ̀ pé ànímọ́ yìí yóò dáàbò bò wá. A kíyè sí àníyàn onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yìí nínú ọ̀rọ̀ tó sọ fún Mósè pé: “Kìkì bí [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] yóò bá mú ọkàn-àyà wọn yìí dàgbà láti bẹ̀rù mi àti láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́ nígbà gbogbo, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn fún àkókò tí ó lọ kánrin!”—Diutarónómì 5:29.
17. (a) Kí làwọn àǹfààní tá a rí nínú bíbẹ̀rù Ọlọ́run? (b) Àwọn apá wo nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
17 Bákan náà, bí a bá jẹ́ kí ìbẹ̀rù Ọlọ́run wà ní ọkàn wa, nǹkan yóò lọ dáadáa fún wa. Láwọn ọ̀nà wo? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ yóò múnú Ọlọ́run dùn, yóò sì jẹ́ kí a sún mọ́ ọn. Ohun tí ojú Dáfídì rí jẹ́ kó mọ̀ pé “ìfẹ́-ọkàn àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ni òun yóò mú ṣẹ, igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́ ni òun yóò sì gbọ́, yóò sì gbà wọ́n là.” (Sáàmù 145:19) Lọ́nà kejì, ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò ṣe wá láǹfààní nítorí pé yóò nípa lórí ojú tá a fi ń wo ohun búburú. (Òwe 3:7) Nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí a óò gbé bí èyí ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ewu tẹ̀mí yẹ̀ wò, yóò sì tún mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ bíi mélòó kan nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n sì yà kúrò nínú ohun tó burú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Gíga Jù Lọ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́wọ́ gba Ìpolongo Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lágbàáyé ní December 10, 1948.
Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Tẹ̀ Lé E Wọ̀nyí?
• Kí ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run túmọ̀ sí, báwo ló sì ṣe kàn wá?
• Báwo ni bíbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe tan mọ́ bíbá Ọlọ́run rìn?
• Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe fi hàn pé ìbẹ̀rù Ọlọ́run tan mọ́ ìfẹ́ fún Ọlọ́run?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà mú kí ìbẹ̀rù Jèhófà wà ní ọkàn wa?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
A pa á láṣẹ fáwọn ọba Ísírẹ́lì pé kí kálukú wọ́n ṣe ẹ̀dà Òfin fún ara wọn, kí wọ́n sì máa kà á lójoojúmọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìbẹ̀rù Jèhófà ń mú kí a gbẹ́kẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bi ọmọ ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé baba rẹ̀
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ìràwọ̀: Fọ́tò látọwọ́ Malin, © IAC/RGO 1991