Bí O Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run
Bí O Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín,” ni ohun tí Jákọ́bù 4:8 sọ. Yíyọ̀ǹda tí Jèhófà Ọlọ́run yọ̀ǹda Ọmọ rẹ̀ nítorí wa, fi bó ṣe ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun hàn.
NÍ DÍDÁHÙN sí ìfẹ́ tí Ọlọ́run kọ́kọ́ fi hàn yẹn, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Àwa nífẹ̀ẹ́ [Ọlọ́run], nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:19) Ṣùgbọ́n kí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tó lè sún mọ́ Ọlọ́run, àwọn ìgbésẹ̀ kan wà tí a gbọ́dọ̀ gbé. Wọ́n jọ àwọn ọ̀nà mẹ́rin tí a ń gbà láti sún mọ́ àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, gẹ́gẹ́ bí a ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Ẹ jẹ́ kí a yẹ̀ wọ́n wò nísinsìnyí.
Ṣàkíyèsí Àwọn Ànímọ́ Àgbàyanu Ọlọ́run
Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ tó jẹ́ àgbàyanu, lára àwọn tó ta yọ jù lọ nínú wọn ni ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo, àti agbára rẹ̀. Ọgbọ́n rẹ̀ àti agbára rẹ̀ hàn kedere nínú ìsálú ọ̀run lọ́hùn-ún àti nínú ayé tí à ń gbé yìí, látorí àwọn arabaríbí ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tó fi dórí àwọn ohun tín-tìn-tín tó kéré jù lọ. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”—Sáàmù 19:1; Róòmù 1:20.
Ìṣẹ̀dá náà tún gbé ìfẹ́ Ọlọ́run yọ. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá wa fi hàn pé ó fẹ́ ká gbádùn ìgbésí ayé. Ó fún wa lágbára láti rí àwọ̀ lóríṣiríṣi, láti lè mọ ìtọ́wò ká sì tún gbóòórùn, ká gbádùn orin, ká rẹ́rìn-ín, kí ẹwà dá wa lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ló tún fún wa ní òye àti ànímọ́ rẹpẹtẹ láti lè ṣe àwọn nǹkan, tí kì í ṣe pé wọ́n pọn dandan láti lè gbé ìgbésí ayé. Dájúdájú, Ọlọ́run jẹ́ ọ̀làwọ́, onínúure, àti onífẹ̀ẹ́ ní tòótọ́—ó sì dájú pé àwọn ànímọ́ yìí jẹ́ ara ìdí tó fi jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tímótì 1:11; Ìṣe 20:35.
Jèhófà máa ń láyọ̀ gan-an nítorí pé bó ṣe ń lo ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ àti bí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ onílàákàyè ṣe ń tì í lẹ́yìn ni a gbé karí ìfẹ́. (1 Jòhánù 4:8) Lóòótọ́, Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, síbẹ̀, bí bàbá onífẹ̀ẹ́ kan ṣe ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ lò ni ó ṣe máa ń bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn lò, pàápàá jù lọ àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin. (Mátíù 5:45) Kì í fi ire kankan dù wọ́n. (Róòmù 8:38, 39) Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, ó tilẹ̀ tún yọ̀ọ̀da ìwàláàyè Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo nítorí tiwa. Bẹ́ẹ̀ ni o, nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni a fi wà tí a sì fi lè fojú sọ́nà fún ìyè ayérayé.—Jòhánù 3:16.
Jésù fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìwà Ọlọ́run nítorí pé àpẹẹrẹ Bàbá rẹ̀ lò tẹ̀ lé lọ́nà pípé pérépéré. (Jòhánù 14:9-11) Kì í ṣe olùmọtara-rẹ̀-nìkan rárá, ó ń gba tẹlòmíràn rò, ó sì láájò èèyàn. Nígbà kan, wọ́n mú ọkùnrin adití kan tó tún ní ìṣòrò ọ̀rọ̀ sísọ wá sọ́dọ̀ Jésù. Ìwọ náà lè fojú inú wò ó pé ara ọkùnrin yẹn lè má balẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ èrò. Ó mà dùn mọ́ni o, pé, ńṣe ni Jésù mú ọkùnrin yí lọ sí kọ̀rọ̀ kan, ibẹ̀ ló sì ti wò ó sàn. (Máàkù 7:32-35) Ǹjẹ́ o mọrírì àwọn èèyàn tó mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ tí wọ́n sì ń yẹ́ ọ sí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láìsí àní-àní, wà á túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti Jésù bí o ṣe túbọ̀ ń mọ̀ sí i nípa wọn.
Ronú Nípa Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run
Ẹnì kan lè ní àwọn ànímọ́ tó dára gidigidi , síbẹ̀ bí a kò bá ronú nípa ẹni yẹn a ò lè fà mọ́ ọn rárá. Ohun kan náà la gbọ́dọ̀ ṣe láti sún mọ́ Jèhófà. Ṣíṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ rẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ kejì tó ṣe pàtàkì nínú sísún mọ́ ọn. Dáfídì Ọba, ọkùnrin kan tó fẹ́ràn Jèhófà gan-an tó sì “tẹ́ ọkàn-àyà [Jèhófà] lọ́rùn” sọ pé: “Mo ti rántí àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn; mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.”—Ìṣe 13:22; Sáàmù 143:5.
Nígbà tí o bá kíyè sí àwọn iṣẹ́ àrà tí ń bẹ nínú ìṣẹ̀dá tàbí tóo ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí i ṣe Bíbélì, ǹjẹ́ o máa ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun tóo rí àti èyí tóo kà bíi ti Dáfídì? Fojú inú wo ọmọ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí lẹ́tà gbà látọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ tó fẹ́ràn gidigidi. Ojú wo ló máa fi wo lẹ́tà yẹn? Ó dájú pé kò kàn ní kà á gààràgà kó sì wá sọ ọ́ sínú àpótí kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni yóò fara balẹ̀ kà á, tí yóò sì rí i dájú pé òun lóye gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé inú rẹ̀ pátá. Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ṣeyebíye lójú wa, àní gẹ́gẹ́ bó tí jẹ́ sí onísáàmù náà, ẹni tó kọrin pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Jẹ́ Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Tó Jíire Wà
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó jíire ni kì í jẹ́ kí àjọṣepọ̀ èyíkéyìí bàjẹ́. Ó kan sísọ̀rọ̀ àti títẹ́tí sílẹ̀—kì í ṣe ká gbọ́ sétí nìkan o, ká tún gbọ́ ọ lágbọ̀ọ́yé ni pẹ̀lú. Àdúrà la fi ń bá Ẹlẹ́dàá sọ̀rọ̀, ìyẹn fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Inú Jèhófà máa ń dùn sí àdúrà àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn-ín, tí wọ́n sì tún tẹ́wọ́ gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí olórí aṣojú Rẹ̀.—Sáàmù 65:2; Jòhánù 14:6, 14.
Láyé àtijọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà ni Ọlọ́run gbà bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, bíi nínú ìran, nínú àlá, àti nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. Ṣùgbọ́n lóde òní, Bíbélì Mímọ́ tí í ṣe Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ ló ń lò. (2 Tímótì 3:16) Ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní. Ìgbàkígbà ni a lè kàn sí i. Gẹ́gẹ́ bíi lẹ́tà kan, a lè máa kà á lákàgbádùn léraléra. Bẹ́ẹ̀ ni kò sì dà bí ọ̀rọ̀ ẹnu tó sábà máa ń ní àbùmọ́ àti àyọkúrò. Nítorí náà, fojú wo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí àkójọ lẹ́tà rẹpẹtẹ kan látọ̀dọ̀ Bàbá rẹ ọ̀run onífẹ̀ẹ́, kí o sì jẹ́ kó máa bá ọ sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ nípasẹ̀ àwọn lẹ́tà wọ̀nyí.—Mátíù 4:4.
Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì la ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lẹ́sẹẹsẹ nípa ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Ó ṣàlàyé àwọn ète tó ní fún aráyé àti fún ilẹ̀ ayé. Ó sì tún ṣí ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú onírúurú ènìyàn àti orílẹ̀-èdè payá, látorí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ adúróṣinṣin títí dórí àwọn ọ̀tá rẹ̀ paraku. Nípa jíjẹ́ kí a ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà yìí, Jèhófà fún wa ní kúlẹ̀kúlẹ̀ àpèjúwe nípa ìwà rẹ̀. Ó jẹ́ ká mọ ìfẹ́, ayọ̀, ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀, ìbínú, àníyàn rẹ̀, àní, onírúurú ìrònú àti àwọn ànímọ́ rẹ̀, ló ṣí payá fún wa, kò sì ṣàìsọ àwọn ìdí tí wọ́n fi rí bẹ́ẹ̀ fún wa, ó sì sọ gbogbo rẹ̀ ní ọ̀nà tí ẹ̀dá ènìyàn lè tètè lóye.—Sáàmù 78:3-7.
Lẹ́yìn tí o bá ti ka apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, báwo lo ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tí o kà? Àti ní pàtàkì, báwo lo ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run sí i? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ronú nípa ohun tóo ti kà àti èyí tóo ti kọ́ nípa Ọlọ́run fúnra rẹ̀, ní jíjẹ́ kí àwọn kókó yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin. Lẹ́yìn náà, sọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn rẹ àti bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tóo ti gbé yẹ̀ wò ṣe wọ̀ ọ́ lára tó fún Jèhófà nínú àdúrà àti bí wàá ṣe gbìyànjú láti jàǹfààní nínú rẹ̀. Nǹkan tó ń jẹ́ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nìyẹn. Àmọ́ o, tóo bá tún ní àwọn nǹkan míì lọ́kàn, kò sóhun tó ní kí o má fi wọ́n kún àdúrà rẹ.
Máa Ṣe Nǹkan Pọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run
Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin olóòótọ́ kan láyé ọjọ́un bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn tàbí pé wọ́n rìn níwájú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9; 1 Àwọn Ọba 8:25) Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ní pàtàkì, ńṣe ni wọ́n ń gbé ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ bíi pé Ọlọ́run wà lọ́dọ̀ wọn gan-an. Ká sòótọ́, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n. Àmọ́ wọ́n fẹ́ràn àwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run, wọ́n sì gbé níbàámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń sún mọ́, tó sì ń tọ́jú, gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 32:8 ti fi hàn, pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”
Jèhófà náà lè di ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́—ẹnì kan tí wàá máa bá rìn, tí yóò máa tọ́jú rẹ, tí yóò sì máa fún ọ nímọ̀ràn bíi ti baba.Wòlíì Aísáyà ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí “Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.” (Aísáyà 48:17) Bí a ti ń rí àwọn àǹfààní wọ̀nyí, á wá dà bí ẹni pé Jèhófà jókòó sọ́dọ̀ wa “ní ọwọ́ ọ̀tún [wa],” ká sọ ọ́ lọ́nà yẹn, bí Dáfídì ti sọ gẹ́lẹ́.—Sáàmù 16:8.
Orúkọ Ọlọ́run —Orí Ohun Tí Àwọn Ànímọ́ Rẹ̀ Dá Lé
Ọ̀pọ̀ ìsìn àti àwọn olùtumọ̀ Bíbélì tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ló kọ̀ láti lo orúkọ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń jẹ́ kí wọ́n sì sọ ọ́ di mímọ̀. (Sáàmù 83:18) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, nínú Ìwé Mímọ́ Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000 ] ìgbà ni orúkọ yẹn—Jèhófà—fara hàn! (Ọ̀rọ̀ wọn kò sì ṣọ̀kan o, nítorí níbi tí wọ́n ti ń yọ orúkọ ti Ọlọ́run kúrò, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn olùtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí ló ń fi orúkọ ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́run èké tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu bà sílẹ̀ láìyọ wọ́n kúrò, àwọn bíi Báálì, Bélì, Méródákì, títí kan ti Sátánì pàápàá!)
Àwọn èèyàn kan ronú pé, yíyọ tí wọ́n yọ orúkọ Ọlọ́run dànù kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkan kan. Ìwọ rò ó wò ná: Ṣé ó máa ń rọrùn, àbí ó máa ń ṣòro, láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́, tó ní láárí pẹ̀lú ẹnì kan tí kò lórúkọ? Àwọn orúkọ oyè bí Ọlọ́run àti Olúwa (èyí tí wọ́n tún fi ń pe àwọn ọlọ́run èké) lè pe àfiyèsí sí agbára, ọlá àṣẹ, tàbí ipò Jèhófà, ṣùgbọ́n kìkì orúkọ tirẹ̀ fúnra rẹ̀ nìkan la fi ń dá a mọ̀ yàtọ̀ gedegbe. (Ẹ́kísódù 3:15; 1 Kọ́ríńtì 8:5,6) Orúkọ tí Ọlọ́run tòótọ́ fúnra rẹ̀ ń jẹ́ yìí kó gbogbo àwọn ànímọ́ rẹ̀ àti ìwà rẹ̀ mọ́ra pátápátá. Ọ̀rọ̀ gidi ni Walter Lowrie tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn sọ, pé: “Èèyàn kan tí kò bá mọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, kò tíì mọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ rárá.”
Gbé àpẹẹrẹ Màríà yẹ̀ wò, òún jẹ́ ọmọ ìjọ Kátólíìkì, olùfọkànsìn kan, tó ń gbé ní Ọsirélíà. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ pàdé rẹ̀, Màríà gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí náà fí orúkọ Ọlọ́run han òun nínú Bíbélì. Ìhà wo ló wá kọ sí i? Ó ní: “Nígbà tí mo kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì, mo sunkún. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti mọ orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ kí n sì máa lò ó mú orí mi wú gan-an ni.” Màríà tẹ̀ síwájú ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nípa bẹ́ẹ̀, fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀, ó wá dá Jèhófà fúnra rẹ̀ mọ̀, ó sì wá ṣeé ṣe fún un láti ní àjọṣe tó wà pẹ́ títí pẹ̀lú rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ la gbọ́ yìí o, a lè “sún mọ́ Ọlọ́run,” àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fojúyòójú wa rí i. Nínú èrò inú wa àti ọkàn wa, a lè “rí” ìwà rẹ̀ tó jẹ́ ọba ìwà, kí a sì máa tipa bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀ síwájú sí i. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ “jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:14.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jèhófà Ń Kọbi Ara sí Ìfẹ́ Tí O Ní fún Un
Bù fún mi n bù fún ọ lọ̀ràn àjọṣepọ̀ jẹ́. Bí a ti ń sún mọ́ Ọlọ́run, lòun náà ṣe máa ń túbọ̀ sún mọ́ àwa náà sí i. Wo bí ọ̀ràn Síméónì àti Ánà, arúgbó méjì tí Bíbélì mẹ́nu kàn lọ́nà tó ṣe pàtàkì, ṣe rí lára rẹ̀. Lúùkù, òǹkọ̀wé Ìhìn Rere sọ fún wa pé Síméónì “jẹ́ olódodo àti onífọkànsìn,” tó ń dúró de Mèsáyà. Jèhófà kíyè sí àwọn ànímọ́ dídára tí Síméónì ní yìí, ó sì fi ìfẹ́ hàn sí ọkùnrin arúgbó, ẹni ọ̀wọ́n yìí nípa ṣíṣí i payá fún un pé “kì yóò rí ikú kí ó tó rí Kristi.” Jèhófà mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, ó sì darí Síméónì sí ibi tí Jésù ọmọ kékeré jòjòló, tí àwọn òbí Rẹ̀ gbé wá sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù wà. Inú Síméónì dùn jọjọ, ó sì mọrírì rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ló bá fayọ̀ gbá ọmọdé jòjòló náà mọ́ra ó sì gbàdúrà pé: “Nísinsìnyí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ lómìnira ní àlàáfíà ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ; nítorí ojú mi ti rí ohun àmúlò rẹ fún gbígbanilà.”—Lúùkù 2:25-35.
“Ní wákàtí yẹn gan-an,” Jèhófà tún fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí Ánà tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin nípa dídarí òun náà sí ibi tí Jésù wà. Bíbélì sọ fún wa pé, opó àtàtà yìí máa ń wà ní tẹ́ńpìlì nígbà gbogbo tó “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” sí Jèhófà. Ìmọrírì rẹ̀ pọ̀ kọjá èyí tó lè pa mọ́ra, lòun náà wá ṣe gẹ́gẹ́ bíi ti Síméónì, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún inúrere rẹ̀ àrà ọ̀tọ̀, ẹ̀yìn náà ló wá sọ nípa ọmọ náà “fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.”—Lúùkù 2:36-38.
Dájúdájú, Jèhófà kíyè sí bí Síméónì àti Ánà ti nífẹ̀ẹ́ òun tó tí wọ́n sì bẹ̀rù òun jinlẹ̀ tó, àti bí wọ́n ṣe ń ṣàníyàn nípa ìmúṣẹ ète òun. Ǹjẹ́ irú àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì bí èyí kò mú ọ fà mọ́ Jèhófà?
Bíi ti Bàbá rẹ̀, Jésù pẹ̀lú máa ń fòye mọ irú ẹni ti ẹnì kan jẹ́ gan-an. Nígbà tó ń kọ́ni nínú tẹ́ńpìlì, ó ṣàkíyèsí “opó aláìní kan” tó fi kìkì “ẹyọ owó kéékèèké méjì tí ìníyelórí wọn kéré gan-an” ṣètọrẹ. Ẹ̀bùn rẹ̀ lè má já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn ẹlòmíì tó bá rí i, àmọ́ ojú tí Jésù fi wò ó kọ́ nìyẹn. Ó yin obìnrin yìí nítorí pé gbogbo ohun tó ní ló fi sílẹ̀. (Lúùkù 21:1-4) Nítorí náà, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà àti Jésù mọrírì wa bí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn wa dídára jù lọ, yálà ó tóbi tàbí ó kéré.
Bí inú Ọlọ́run ti ń dùn nítorí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó tún máa ń dùn ún nígbà tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn bá yà bàrá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì ń tọ ipa ọ̀nà ìwà àìtọ́. Jẹ́nẹ́sísì 6:6 sọ fún wa pé, ìwà búburú ìran ènìyàn ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà ‘dun Jèhófà ní ọkàn-àyà rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, Sáàmù 78:41 sọ pé léraléra ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìgbọràn “ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.” Dájúdájú, Ọlọ́run kì í ṣe “Orísun Ẹ̀dá” tó lọ dá wà níbì kan láìdá sí ẹnikẹ́ni, tí kò sì nímọ̀lára. Òun jẹ́ ẹni gidi kan ní tòótọ́, tí àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ kò di aláìṣedéédéé tàbí aláìgbéṣẹ́ bíi ti àwa ènìyàn tí àìpé ti sọ dà bẹ́ẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ríronú nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá jẹ́ ọ̀nà kan tí a lè gbà sún mọ́ ọn