Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Lè Túbọ̀ Nítumọ̀
Bí Ìgbésí Ayé Rẹ Ṣe Lè Túbọ̀ Nítumọ̀
ÒWE àtayébáyé kan sọ pé: “Má ṣe làálàá láti jèrè ọrọ̀. Ṣíwọ́ kúrò nínú òye ara rẹ. Ìwọ ha ti jẹ́ kí ojú rẹ wò ó fìrí bí, nígbà tí kò jámọ́ nǹkan kan? Nítorí láìsí àní-àní, ó máa ń ṣe ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀ bí ti idì, a sì fò lọ sí ojú ọ̀run.” (Òwe 23:4, 5) Lédè míì, kò bọ́gbọ́n mu láti máa sá eré àsáfẹ́ẹ̀ẹ́kú nítorí àtidi ọlọ́rọ̀, nítorí pé ọrọ̀ lè hu ìyẹ́ bíi ti idì, kí ó sì fò lọ.
Gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì ti fi hàn, dúkìá lè wọmi ká tó pajú pẹ́ẹ́. Ó lè parẹ́ lọ́sàn-án kan òru kan, bí àjálù bá dé, bí ipò ìṣúnná owó bá dẹnu kọlẹ̀, tàbí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí a kò retí tẹ́lẹ̀ bá lọ ṣẹlẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó ti rí jájẹ pàápàá máa ń ní ìjákulẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn John yẹ̀ wò, ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ wé mọ́ ṣíṣeré fún àwọn olóṣèlú, àwọn lóókọlóókọ eléré ìdárayá, àtàwọn olóyè.
John sọ pé: “Mo fi gbogbo ìgbésí ayé mi jin iṣẹ́ mi. Mo wá di olówó, àwọn òtẹ́ẹ̀lì ńláńlá ni mo ti ń lògbà, mo tilẹ̀ máa ń gbé ọkọ̀ òfuurufú àdáni lọ síbi iṣẹ́ nígbà míì. Mo kọ́kọ́ ń gbádùn rẹ̀, ṣùgbọ́n kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí sú mi. Ó jọ pé ojú ayé ti fẹ́ pọ̀ jù nínú ọ̀ràn gbogbo àwọn tí mo ń sapá láti dá nínú dùn. Ayé mi ò wá nítumọ̀ rárá.”
Gẹ́gẹ́ bí ó ti wá yé John nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìgbésí ayé tí kò ka nǹkan tẹ̀mí sí kò lè jẹ́ aláyọ̀. Nínú Ìwàásù olókìkí tí Jésù Kristi ṣe lórí Òkè, ó ṣàlàyé bí a ṣe lè ní ayọ̀ pípẹ́ títí. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Ní kedere, nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu láti fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé. Àmọ́ o, àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé túbọ̀ nítumọ̀.
Ìdílé Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ Ṣe Pàtàkì Gan-an
Ǹjẹ́ wàá gbádùn ìgbésí ayé bí o ò bá ní àjọṣe kankan pẹ̀lú ìdílé rẹ, tí o ò sì ní ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kankan? O ò tiẹ̀ lè gbádùn ìgbésí ayé ni. Ẹlẹ́dàá wa dá wa láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn, káwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ wa. Èyí wà lára ìdí tí Jésù fi tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì Mátíù 22:39) Ìdílé jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run níbi tí a ti lè fi ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan hàn.—Éfésù 3:14, 15.
‘nínífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa gẹ́gẹ́ bí ara wa.’ (Báwo ni ìdílé wa ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀? Tóò, a lè fi ìdílé tó wà níṣọ̀kan wé ọgbà kan tó lẹ́wà, níbi táa ti lè lọ gba ìtura kúrò lọ́wọ́ kòókòó jàn-án jàn-án ojoojúmọ́. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a lè rí àjọṣepọ̀ àti ìfararora nínú ìdílé, irú èyí tí ń tuni lára, tí kò ní jẹ́ kí a dá wà. Àmọ́ ṣá o, ìdílé kì í ṣàdédé di irú ibi ààbò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí a ti ń fún ìdè ìdílé lókun, ńṣe ni a óò túbọ̀ máa fara mọ́ra, ìgbésí ayé á sì túbọ̀ máa gbádùn mọ́ wa. Bí àpẹẹrẹ, àkókò àti àfiyèsí tí a bá yà sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ fún fífi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ hàn fún ọkọ tàbí aya wa kò lè já sásán, a ó jàǹfààní rẹ̀, nítorí pé àṣesílẹ̀ làbọ̀wábá.—Éfésù 5:33.
Bí a bá ní àwọn ọmọ, ó yẹ ká gbìyànjú láti tọ́ wọn dàgbà ní àyíká tó tọ́. Lílo àkókò pẹ̀lú wọn, ṣíṣí ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ sílẹ̀, àti fífún wọn ní ìtọ́ni tẹ̀mí lè gba aápọn. Ṣùgbọ́n irú àkókò àti ìsapá bẹ́ẹ̀ lè fún wa ní ìtẹ́lọ́rùn ńláǹlà. Àwọn òbí tó ti tọ́mọ ní àtọ́yanjú ka àwọn ọmọ sí ìbùkún, wọ́n kà wọ́n sí ogún látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí a gbọ́dọ̀ bójú tó dáadáa.—Sáàmù 127:3.
Àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà tún ń jẹ́ kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ni, kí ó sì nítumọ̀. (Òwe 27:9) A lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rẹ́ nípa fífi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn. (1 Pétérù 3:8) Ojúlówó ọ̀rẹ́ máa ń ṣèrànwọ́ láti gbé wa dìde nígbà tí a bá ṣubú. (Oníwàásù 4:9, 10) A sì mọ̀ pé “alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ . . . jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Ọ̀rẹ́ tòótọ́ mà kúkú ń máyọ̀ ẹni kún o! Wíwọ̀ oòrùn á túbọ̀ dùn-ún wò, oúnjẹ á túbọ̀ dùn-ún jẹ, orin á sì túbọ̀ dùn-ún gbọ́, bó bá jẹ́ àwa àti ọ̀rẹ́ wa la jọ ń gbádùn nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n o, ìdílé tó wà níṣọ̀kan àtàwọn ọ̀rẹ́ tó ṣeé finú hàn wulẹ̀ jẹ́ méjì péré lára àwọn ohun tó lè mú kí ìgbésí ayé nítumọ̀. Kí ni àwọn nǹkan mìíràn tí Ọlọ́run ti ṣe, tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀?
Kíkájú Àìní Wa Nípa Tẹ̀mí
Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀, Jésù Kristi sọ pé tí a óò bá láyọ̀, a gbọ́dọ̀ bójú tó àìní wa nípa tẹ̀mí. A ṣẹ̀dá wa láti máa ṣàfẹ́rí nǹkan tẹ̀mí àti ìwà rere. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa “ènìyàn ti ẹ̀mí” àti “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà.”—1 Kọ́ríńtì 2:15; 1 Pétérù 3:3, 4.
Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè An Expository Dictionary of New Testament Words, látọwọ́ W. E. Vine ti wí, ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ dúró fún “gbogbo ìgbòkègbodò ènìyàn ní ti èrò orí àti ní ti ìwà rere, títí kan àwọn ohun tó jẹ mọ́ òye àti ìmí ẹ̀dùn rẹ̀.” Ọ̀gbẹ́ni Vine tún ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Lédè mìíràn, a máa ń lo ọkàn-àyà lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún orísun tó fara sin, níbi tí ẹni ti inú náà wà.” Ìwé kan náà tún sọ pé “ọkàn-àyà, tí ń bẹ nínú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ni ‘ẹni tó fara sin,‘ . . . ẹni gidi náà, wà.”
Báwo la ṣe lè kájú àìní “ènìyàn ti ẹ̀mí,” tàbí “ẹni tó fara sin” náà, ìyẹn, “ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn-àyà”? A lè gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì ní ṣíṣe èyí àti ní kíkájú àìní wa nípa tẹ̀mí tí a bá gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ lábẹ́ ìmísí, ẹni tó kọ ọ́ lórin pé: “Kí ẹ mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Òun ni ó ṣẹ̀dá wa, kì í sì í ṣe àwa fúnra wa. Àwa ni ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀.” (Sáàmù 100:3) Tí a bá gba ohun tó sọ yìí, a óò tún gbà láìjanpata pé a óò jíhìn fún Ọlọ́run. Tí a bá fẹ́ kí á kà wá mọ́ àwọn “ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀,” a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ohun tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ṣé ohun tó burú nìyẹn? Rárá o, nítorí mímọ̀ pé ìwà wa ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run ń jẹ́ kí ayé wa túbọ̀ nítumọ̀. Ìyẹn á ru wá sókè láti tún ìwà wa ṣe—ó sì dájú pé góńgó rere ni èyí. Sáàmù 112:1 sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ní inú dídùn gidigidi sí àwọn àṣẹ rẹ̀.” Ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àti ìgbọràn àtọkànwá sáwọn àṣẹ rẹ̀ lè túbọ̀ fún ìgbésí ayé wa nítumọ̀.
Èé ṣe tí ìgbọràn sí Ọlọ́run fi ń fún wa láyọ̀? Nítorí pé a ní ẹ̀rí ọkàn, tí ó jẹ́ ẹ̀bùn kan tí Ọlọ́run ti fi jíǹkí gbogbo aráyé. Ẹ̀rí ọkàn ló ń yẹ ìwà wa wò, òun ló ń fọwọ́ sí ohun tí a ti ṣe tàbí tí a ń ronú àtiṣe, tàbí kó máa sọ fún wa pé kò dáa. Gbogbo wa la ti mọ bí a ṣe máa ń dààmú tó nígbà tí ẹ̀rí ọkàn bá bẹ̀rẹ̀ sí nà wá ní pàṣán. (Róòmù 2:15) Ṣùgbọ́n ẹ̀rí ọkàn wa tún lè san èrè fún wa. Nígbà tí a bá fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wa fún Ọlọ́run àtàwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa, a máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn ọkàn, a sì máa ń láyọ̀. A máa ń rí i pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ìdí pàtàkì kan wà tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀.
Ẹlẹ́dàá wa dá wa lọ́nà tí ìfẹ́ ọkàn àti àìní àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa fi máa ń kàn wá. Ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ ń mú inú wa dùn. Kò tán síbẹ̀ o, Bíbélì mú un dá wa lójú pé tí a bá fi nǹkan fún aláìní, Ọlọ́run kà á sí pé òun la fi nǹkan ọ̀hún fún.—Òwe 19:17
Yàtọ̀ sí pé fífún àwọn àìní wa nípa tẹ̀mí ní àfiyèsí ń máyọ̀ wá, ǹjẹ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣe wá láǹfààní ní ti gidi? Ó dára, ọkùnrin oníṣòwò kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Raymond, tó ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìhà Ìlà Oòrùn ayé, gbà pé ó lè ṣàǹfààní. Ó sọ pé: “Góńgó tí mo ń lé tẹ́lẹ̀, kò pé méjì, kí n sáà ti di olówó ni. Àmọ́ gbàrà tí mo gbà látọkànwá pé Ọlọ́run wà àti pé ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ wà nínú Bíbélì, bí mo ṣe yí ìgbésí ayé mi padà nìyẹn. Ọ̀ràn àtijẹ àtimu ti kọjá sí ipò kejì báyìí nínú ìgbésí ayé mi. Nípa gbígbìyànjú láti mú inú Ọlọ́run dùn, mo ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀mí ìkórìíra tí ń jẹni run. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà táwọn kan ń jà ni wọ́n pa bàbá mi, kò sí lọ́kàn mi láti gbẹ̀san lára wọn.”
Gẹ́gẹ́ bí Raymond ti wá rí i, fífarabalẹ̀ bójú tó àwọn àìní “ènìyàn ti ẹ̀mí” lè wo ẹ̀dùn ọkàn tó jinlẹ̀ sàn. Àmọ́ o, bí a kò bá fàyà rán àwọn ìṣòro tó ń dìde ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ìgbésí ayé ò ní tẹ́ni lọ́rùn dáadáa.
A Lè Ní “Àlàáfíà Ọlọ́run”
Nínú ayé bóò-lọ-o-yàá-mi yìí, ṣàṣà lọjọ́ tí gbogbo nǹkan ń lọ geere. Jàǹbá máa ń ṣẹlẹ̀, nígbà míì sì rèé, ibi tí a fojú sí ọ̀nà lè má gbabẹ̀, àwọn èèyàn sì máa ń já wa kulẹ̀. Ìṣòro wọ̀nyí lè kó ìbànújẹ́ bá wa. Àmọ́ ṣá o, fún àwọn tí ń sin Jèhófà Ọlọ́run, Bíbélì ṣèlérí ìtẹ́lọ́rùn ti inú lọ́hùn-ún—èyíinì ni “àlàáfíà Ọlọ́run.” Báwo la ṣe lè rí àlàáfíà yìí?
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Dípò gbígbìyànjú láti dá àwọn òkè ìṣòro wa gbé, ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa gbàdúrà tọkàntọkàn, ká máa wọ́ ẹrù ìnira wa ojoojúmọ́ lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 55:22) Ìgbàgbọ́ pé òun yóò dáhùn irú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, yóò túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ bí a ti ń dàgbà nípa tẹ̀mí, tí a sì ń rí i bí Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́.—Jòhánù 14:6, 14; 2 Tẹsalóníkà 1:3.
Gbàrà tí a bá ti gbọ́kàn lé Jèhófà Ọlọ́run, “Olùgbọ́ àdúrà,” yóò rọrùn fún wa láti kojú àwọn àdánwò, bí àìsàn tí kì í lọ bọ̀rọ̀, ọjọ́ ogbó, tàbí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ wá. (Sáàmù 65:2) Ṣùgbọ́n bí ìgbésí ayé wa yóò bá nítumọ̀ ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ronú nípa ọjọ́ ọ̀la.
Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Tí Ń Bẹ Níwájú
Bíbélì ṣèlérí “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” ìyẹn, ìjọba òdodo ti ọ̀run tó bìkítà, tó ń ṣàkóso lórí ìdílé ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn. (2 Pétérù 3:13) Nínú ayé tuntun yẹn tí Ọlọ́run ṣèlérí, àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo yóò rọ́pò ogun àti ìwà ìrẹ́nijẹ. Èyí kì í kàn-án ṣe àlá tí kò lè ṣẹ, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìgbàgbọ́ dídájú, tó sì lè túbọ̀ máa dáni lójú sí i lójoojúmọ́. Ìhìn rere ni lóòótọ́, dájúdájú ó sì jẹ́ ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀.—Róòmù 12:12; Títù 1:2.
John, tí a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀, wá rí i báyìí pé ìgbésí ayé òun túbọ̀ nítumọ̀. Ó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò fẹ̀ẹ̀kàn ka ẹ̀sìn sí tẹ́lẹ̀, mi ò ṣàìgba Ọlọ́run gbọ́. Ṣùgbọ́n n ò ṣe nǹkan kan nípa ìgbàgbọ́ yẹn títí di ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá bẹ̀ mí wò. Mo da ìbéèrè bò wọ́n, àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí la wálé ayé wá ṣe? Ibo layé wa dorí kọ?’ Ìdáhùn wọn, tí ń tẹ́ni lọ́rùn, tó sì wá látinú Ìwé Mímọ́, jẹ́ kí n rí ète tó wà nínú ìgbésí ayé fún ìgbà àkọ́kọ́ láyé mi. Àṣé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Òùngbẹ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ mí, mo sì jáwọ́ nínú gbogbo ohun tí mo kà sí bàbàrà tẹ́lẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò kì í ṣe ọlọ́rọ̀ nípa tara mọ́, àmọ́ milọníà ni mí nípa tẹ̀mí.”
Gẹ́gẹ́ bíi ti John, bóyá ìwọ náà ò ṣú já àwọn nǹkan tẹ̀mí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ṣùgbọ́n nípa níní “ọkàn-àyà ọgbọ́n,” o lè mú ìfẹ́ fún nǹkan tẹ̀mí sọ jí. (Sáàmù 90:12) Pẹ̀lú ìpinnu àti ìsapá, o lè ní ojúlówó ayọ̀, àlàáfíà, àti ìrètí. (Róòmù 15:13) Dájúdájú, ìgbésí ayé rẹ lè túbọ̀ nítumọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Àdúrà lè fún wa ní “àlàáfíà Ọlọ́run”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ǹjẹ́ o mọ ohun tó lè mú kí ìgbésí ayé ìdílé túbọ̀ láyọ̀?